Quran with Yoruba translation - Surah An-Nahl ayat 80 - النَّحل - Page - Juz 14
﴿وَٱللَّهُ جَعَلَ لَكُم مِّنۢ بُيُوتِكُمۡ سَكَنٗا وَجَعَلَ لَكُم مِّن جُلُودِ ٱلۡأَنۡعَٰمِ بُيُوتٗا تَسۡتَخِفُّونَهَا يَوۡمَ ظَعۡنِكُمۡ وَيَوۡمَ إِقَامَتِكُمۡ وَمِنۡ أَصۡوَافِهَا وَأَوۡبَارِهَا وَأَشۡعَارِهَآ أَثَٰثٗا وَمَتَٰعًا إِلَىٰ حِينٖ ﴾
[النَّحل: 80]
﴿والله جعل لكم من بيوتكم سكنا وجعل لكم من جلود الأنعام بيوتا﴾ [النَّحل: 80]
Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni Allāhu ṣe ibùsinmi fun yín sínú ilé yín. Láti ara awọ ẹran-ọ̀sìn, Ó tún ṣe àwọn ilé (àtíbàbà) kan t’ó fúyẹ́ fun yín láti gbé rìn ní ọjọ́ ìrìn-àjò yín àti ní ọjọ́ tí ẹ bá wà nínú ìlú. Láti ara irun àgùtàn, irun ràkúnmí àti irun ewúrẹ́, ẹ tún ń rí àwọn n̄ǹkan ọ̀ṣọ́ àti n̄ǹkan ìgbádùn lò títí fún ìgbà díẹ̀. aṣọ èyí tí wọ́n bá fi irun àgùtàn hún máa ń jẹ́ aṣọ t’ó rọjú jùlọ ní rírà. Nítorí èyí aṣọ irun àgùtàn jẹ́ aṣọ àwọn mẹ̀kúnnù. Àwọn olówó kì í sì fẹ́ rà á fún wíwọ̀ sọ́rùn nítorí pé olùfọkànsìn ẹni ẹ̀ṣà òǹpèrò kọ̀ọ̀kan nínú àwọn àáfà onibidiah wọ̀nyẹn bá tún bẹ̀rẹ̀ sí fi orúkọ ara rẹ̀ pèrò dípò lílo orúkọ àgbélẹ̀rọ tí wọ́n dìjọ ṣe àdádáálẹ̀ rẹ̀. Nígbà náà ni ayé wọn bá di ìlànà / tọrīkọ “at-tasọwuffu al-kọ̄diriyyah” tí ọkùnrin kan kò bá ti rí iṣẹ́ halāl ṣe ní iṣẹ́ òòjọ́ ó máa di “ṣééù” |