Quran with Yoruba translation - Surah Al-Isra’ ayat 60 - الإسرَاء - Page - Juz 15
﴿وَإِذۡ قُلۡنَا لَكَ إِنَّ رَبَّكَ أَحَاطَ بِٱلنَّاسِۚ وَمَا جَعَلۡنَا ٱلرُّءۡيَا ٱلَّتِيٓ أَرَيۡنَٰكَ إِلَّا فِتۡنَةٗ لِّلنَّاسِ وَٱلشَّجَرَةَ ٱلۡمَلۡعُونَةَ فِي ٱلۡقُرۡءَانِۚ وَنُخَوِّفُهُمۡ فَمَا يَزِيدُهُمۡ إِلَّا طُغۡيَٰنٗا كَبِيرٗا ﴾
[الإسرَاء: 60]
﴿وإذ قلنا لك إن ربك أحاط بالناس وما جعلنا الرؤيا التي أريناك﴾ [الإسرَاء: 60]
Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni (Rántí) nígbà tí A sọ fún ọ pé: “Dájúdájú Olúwa rẹ yí àwọn ènìyàn po (pẹ̀lú agbára Rẹ̀). Àti pé A kò ṣe ìran (wíwò) tí A fi hàn ọ́ àti igi (zaƙūm) tí A ṣẹ́bi lé nínú al-Ƙur’ān ní kiní kan bí kò ṣe pé (ó jẹ́) àdánwò fún àwọn ènìyàn. À ń dẹ́rù bà wọ́n, àmọ́ kò ṣe àlékún kan fún wọn bí kò ṣe ìwà àgbéré t’ó tóbi |