Quran with Yoruba translation - Surah Al-Kahf ayat 110 - الكَهف - Page - Juz 16
﴿قُلۡ إِنَّمَآ أَنَا۠ بَشَرٞ مِّثۡلُكُمۡ يُوحَىٰٓ إِلَيَّ أَنَّمَآ إِلَٰهُكُمۡ إِلَٰهٞ وَٰحِدٞۖ فَمَن كَانَ يَرۡجُواْ لِقَآءَ رَبِّهِۦ فَلۡيَعۡمَلۡ عَمَلٗا صَٰلِحٗا وَلَا يُشۡرِكۡ بِعِبَادَةِ رَبِّهِۦٓ أَحَدَۢا ﴾
[الكَهف: 110]
﴿قل إنما أنا بشر مثلكم يوحى إلي أنما إلهكم إله واحد فمن﴾ [الكَهف: 110]
Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni Sọ pé: “Abara ni èmi bí irú yín. Wọ́n ń fí ìmísí ránṣẹ́ sí mi pé Ọlọ́hun yín, Ọlọ́hun Ọ̀kan ṣoṣo ni. Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá ń retí ìpàdé Olúwa rẹ̀, kí ó ṣe iṣẹ́ rere. Kò sì gbọdọ̀ fi ẹnì kan kan ṣe akẹgbẹ́ níbi jíjọ́sìn fún Olúwa rẹ̀.” |