Quran with Yoruba translation - Surah Al-Kahf ayat 28 - الكَهف - Page - Juz 15
﴿وَٱصۡبِرۡ نَفۡسَكَ مَعَ ٱلَّذِينَ يَدۡعُونَ رَبَّهُم بِٱلۡغَدَوٰةِ وَٱلۡعَشِيِّ يُرِيدُونَ وَجۡهَهُۥۖ وَلَا تَعۡدُ عَيۡنَاكَ عَنۡهُمۡ تُرِيدُ زِينَةَ ٱلۡحَيَوٰةِ ٱلدُّنۡيَاۖ وَلَا تُطِعۡ مَنۡ أَغۡفَلۡنَا قَلۡبَهُۥ عَن ذِكۡرِنَا وَٱتَّبَعَ هَوَىٰهُ وَكَانَ أَمۡرُهُۥ فُرُطٗا ﴾
[الكَهف: 28]
﴿واصبر نفسك مع الذين يدعون ربهم بالغداة والعشي يريدون وجهه ولا تعد﴾ [الكَهف: 28]
Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni Ṣe sùúrù fún ẹ̀mí rẹ láti wà pẹ̀lú àwọn t’ó ń pe Olúwa wọn ní òwúrọ̀ àti ní àṣálẹ́, tí wọ́n ń wá Ojú rere Rẹ̀. Má ṣe fojú pa wọ́n rẹ́ láti wá ọ̀ṣọ́ ìṣẹ̀mí ayé (yìí). Má sì ṣe tẹ̀lé ẹni tí A mú ọkàn rẹ̀ gbàgbé ìrántí Wa. Ó tẹ̀lé ìfẹ́-inú rẹ̀; ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì jẹ́ àṣejù |