Quran with Yoruba translation - Surah Al-Baqarah ayat 203 - البَقَرَة - Page - Juz 2
﴿۞ وَٱذۡكُرُواْ ٱللَّهَ فِيٓ أَيَّامٖ مَّعۡدُودَٰتٖۚ فَمَن تَعَجَّلَ فِي يَوۡمَيۡنِ فَلَآ إِثۡمَ عَلَيۡهِ وَمَن تَأَخَّرَ فَلَآ إِثۡمَ عَلَيۡهِۖ لِمَنِ ٱتَّقَىٰۗ وَٱتَّقُواْ ٱللَّهَ وَٱعۡلَمُوٓاْ أَنَّكُمۡ إِلَيۡهِ تُحۡشَرُونَ ﴾
[البَقَرَة: 203]
﴿واذكروا الله في أيام معدودات فمن تعجل في يومين فلا إثم عليه﴾ [البَقَرَة: 203]
Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni Ẹ ṣèrántí Allāhu láààrin àwọn ọjọ́ t’ó ní òǹkà. Nítorí náà, ẹni tí ó bá kánjú (ṣe é) fún ọjọ́ méjì, kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fún un. Ẹni tí ó bá kẹ́yìn (tí ó dúró di ọjọ́ kẹta), kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fún un fún ẹni tí ó bá ṣọ́ra (fún ìwà ẹ̀ṣẹ̀). Ẹ bẹ̀rù Allāhu. Kí ẹ sì mọ̀ pé dájúdájú wọn yóò ko yín jọ sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀ |