Quran with Yoruba translation - Surah Ya-Sin ayat 36 - يسٓ - Page - Juz 23
﴿سُبۡحَٰنَ ٱلَّذِي خَلَقَ ٱلۡأَزۡوَٰجَ كُلَّهَا مِمَّا تُنۢبِتُ ٱلۡأَرۡضُ وَمِنۡ أَنفُسِهِمۡ وَمِمَّا لَا يَعۡلَمُونَ ﴾
[يسٓ: 36]
﴿سبحان الذي خلق الأزواج كلها مما تنبت الأرض ومن أنفسهم ومما لا﴾ [يسٓ: 36]
Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni Mímọ́ ni fún Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá gbogbo n̄ǹkan ní oríṣiríṣi nínú ohun tí ilẹ̀ ń hù jáde àti nínú ẹ̀mí ara wọn àti nínú ohun tí wọn kò mọ̀. tàbí ọ̀rọ̀ ìmọ̀ ẹ̀rọ kan tàbí ìmọ̀ ìròrí kan tàbí èyíkéyìí ìmọ̀ kan lòdì sí āyah kan nínú al-Ƙur’ān tàbí hadīth Ànábì wa Muhammad (sollalāhu 'alayhi wa sallam) t’ó fẹsẹ̀ rinlẹ̀ ó ti ṣìnà ní ìṣìnà pọ́nńbélé. “zaoj” ni ẹyọ. “Zaoj” sì ń túmọ̀ sí akọ tàbí abo nígbà tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) bá ń sọ̀rọ̀ nípa ìṣẹ̀dá ènìyàn tàbí ọmọ bíbí gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wà nínú sūrah an-Najm; 53:45 àti sūrah al-Ƙiyāmọh; 75:39. àmọ́ tí ìkíní kejì yàtọ̀ síra wọn ní ọ̀nà kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí akọ àti abo n̄ǹkan dídùn àti n̄ǹkan kíkorò a lè rí èso mímu tàbí èso jíjẹ kan tí ó máa jẹ́ oríṣiríṣi. Ìtúmọ̀ olóríṣiríṣi tún lọ lábẹ́ āyah tí à ń tọsẹ̀ rẹ̀ lọ́wọ́ yìí. Nítorí náà zaoj kò pọn dandan kí ó ní ìtúmọ̀ akọ àti abo nìkan. Oríṣiríṣi ni “zaoj”; akọ jẹ oríṣi kan |