يس (1) Ya sin |
وَالْقُرْآنِ الْحَكِيمِ (2) (Allahu) bura pelu Al-Ƙur’an tira ogbon |
إِنَّكَ لَمِنَ الْمُرْسَلِينَ (3) Dajudaju iwo wa ninu awon Ojise |
عَلَىٰ صِرَاطٍ مُّسْتَقِيمٍ (4) wa lori ona taara (’Islam) |
تَنزِيلَ الْعَزِيزِ الرَّحِيمِ (5) (Al-Ƙur’an je) imisi t’o sokale lati odo Alagbara, Asake-orun |
لِتُنذِرَ قَوْمًا مَّا أُنذِرَ آبَاؤُهُمْ فَهُمْ غَافِلُونَ (6) nitori ki o le sekilo fun awon eniyan kan, (awon) ti won ko se ikilo fun awon baba won ri. Nitori naa, afonufora si ni won (nipa imona) |
لَقَدْ حَقَّ الْقَوْلُ عَلَىٰ أَكْثَرِهِمْ فَهُمْ لَا يُؤْمِنُونَ (7) Dajudaju oro naa ti ko le opolopo won lori; won ko si nii gbagbo |
إِنَّا جَعَلْنَا فِي أَعْنَاقِهِمْ أَغْلَالًا فَهِيَ إِلَى الْأَذْقَانِ فَهُم مُّقْمَحُونَ (8) Dajudaju Awa ti ko ewon si won lorun. O si ga de agbon (won). Won si ga won lorun soke |
وَجَعَلْنَا مِن بَيْنِ أَيْدِيهِمْ سَدًّا وَمِنْ خَلْفِهِمْ سَدًّا فَأَغْشَيْنَاهُمْ فَهُمْ لَا يُبْصِرُونَ (9) Ati pe Awa fi gaga kan siwaju won, gaga kan seyin won; A bo won loju, won ko si riran |
وَسَوَاءٌ عَلَيْهِمْ أَأَنذَرْتَهُمْ أَمْ لَمْ تُنذِرْهُمْ لَا يُؤْمِنُونَ (10) Bakan naa ni fun won, yala o kilo fun won tabi o o kilo fun won; won ko nii gbagbo |
إِنَّمَا تُنذِرُ مَنِ اتَّبَعَ الذِّكْرَ وَخَشِيَ الرَّحْمَٰنَ بِالْغَيْبِ ۖ فَبَشِّرْهُ بِمَغْفِرَةٍ وَأَجْرٍ كَرِيمٍ (11) Eni ti ikilo re (maa wulo fun) ni eni ti o tele Isiti (al-Ƙur’an), ti o si paya Ajoke-aye ni ikoko. Nitori naa, fun un ni iro idunnu nipa aforijin ati esan alapon-onle |
إِنَّا نَحْنُ نُحْيِي الْمَوْتَىٰ وَنَكْتُبُ مَا قَدَّمُوا وَآثَارَهُمْ ۚ وَكُلَّ شَيْءٍ أَحْصَيْنَاهُ فِي إِمَامٍ مُّبِينٍ (12) Dajudaju Awa, Awa l’A n so awon oku di alaye. A si n se akosile ohun ti won ti siwaju ati oripa (ise owo) won. Gbogbo nnkan ni A se akosile re sinu tira kan t’o yanju |
وَاضْرِبْ لَهُم مَّثَلًا أَصْحَابَ الْقَرْيَةِ إِذْ جَاءَهَا الْمُرْسَلُونَ (13) Fi apejuwe kan lele fun won nipa awon ara ilu kan nigba ti awon Ojise wa ba won |
إِذْ أَرْسَلْنَا إِلَيْهِمُ اثْنَيْنِ فَكَذَّبُوهُمَا فَعَزَّزْنَا بِثَالِثٍ فَقَالُوا إِنَّا إِلَيْكُم مُّرْسَلُونَ (14) (Ranti) nigba ti A ran Ojise meji nise si won. Won pe awon mejeeji ni opuro. A si fi eni keta ro awon mejeeji lagbara. Won si so pe: “Dajudaju awa ni Ojise ti Won ran nise si yin.” |
قَالُوا مَا أَنتُمْ إِلَّا بَشَرٌ مِّثْلُنَا وَمَا أَنزَلَ الرَّحْمَٰنُ مِن شَيْءٍ إِنْ أَنتُمْ إِلَّا تَكْذِبُونَ (15) Won wi pe: “Eyin ko je kini kan bi ko se abara bi iru tiwa. Ajoke-aye ko si so nnkan kan kale. Eyin ko si je kini kan bi ko se opuro.” |
قَالُوا رَبُّنَا يَعْلَمُ إِنَّا إِلَيْكُمْ لَمُرْسَلُونَ (16) Won so pe: "Oluwa wa mo pe dajudaju awa ni Ojise ti Won ran nise si yin |
وَمَا عَلَيْنَا إِلَّا الْبَلَاغُ الْمُبِينُ (17) Ko si si ojuse kan fun wa bi ko se ise-jije ponnbele.” |
قَالُوا إِنَّا تَطَيَّرْنَا بِكُمْ ۖ لَئِن لَّمْ تَنتَهُوا لَنَرْجُمَنَّكُمْ وَلَيَمَسَّنَّكُم مِّنَّا عَذَابٌ أَلِيمٌ (18) Won wi pe: “Dajudaju awa ri ami aburu lara yin. Ti e o ba jawo (nibi ipepe yin), dajudaju a maa so yin loko pa. Iya eleta-elero yo si je yin lati odo wa.” |
قَالُوا طَائِرُكُم مَّعَكُمْ ۚ أَئِن ذُكِّرْتُم ۚ بَلْ أَنتُمْ قَوْمٌ مُّسْرِفُونَ (19) Won so pe: "Ami aburu yin n be pelu yin. Se nitori pe won se isiti fun yin (l’e fi ri ami aburu lara wa)? Ko ri bee! Ijo alakoyo ni yin ni |
وَجَاءَ مِنْ أَقْصَى الْمَدِينَةِ رَجُلٌ يَسْعَىٰ قَالَ يَا قَوْمِ اتَّبِعُوا الْمُرْسَلِينَ (20) Okunrin kan sare de lati opin ilu naa, o wi pe: “Eyin eniyan mi, e tele awon Ojise naa |
اتَّبِعُوا مَن لَّا يَسْأَلُكُمْ أَجْرًا وَهُم مُّهْتَدُونَ (21) E tele eni ti ko beere owo-oya kan ni owo yin. Olumona si ni won |
وَمَا لِيَ لَا أَعْبُدُ الَّذِي فَطَرَنِي وَإِلَيْهِ تُرْجَعُونَ (22) Ki ni o maa mu mi ti emi ko fi nii josin fun Eni ti O pile eda mi? Odo Re si ni won yoo da yin pada si |
أَأَتَّخِذُ مِن دُونِهِ آلِهَةً إِن يُرِدْنِ الرَّحْمَٰنُ بِضُرٍّ لَّا تُغْنِ عَنِّي شَفَاعَتُهُمْ شَيْئًا وَلَا يُنقِذُونِ (23) Se ki ng so awon kan di olohun leyin Allahu ni? Ti Ajoke-aye ba fe fi inira kan mi, isipe won ko le ro mi loro kini kan, won ko si le gba mi la |
إِنِّي إِذًا لَّفِي ضَلَالٍ مُّبِينٍ (24) (Bi emi ko ba josin fun Allahu) nigba naa dajudaju mo ti wa ninu isina ponnbele |
إِنِّي آمَنتُ بِرَبِّكُمْ فَاسْمَعُونِ (25) Dajudaju emi gbagbo ninu Oluwa Eledaa yin. Nitori naa, e gbo mi.” |
قِيلَ ادْخُلِ الْجَنَّةَ ۖ قَالَ يَا لَيْتَ قَوْمِي يَعْلَمُونَ (26) Won so pe: “Wo inu Ogba Idera.” O so pe: “Awon eniyan mi iba ni imo |
بِمَا غَفَرَ لِي رَبِّي وَجَعَلَنِي مِنَ الْمُكْرَمِينَ (27) nipa bi Oluwa mi se forijin mi ati (bi) O se fi mi si ara awon alapon-onle (won iba ronu piwada).” |
۞ وَمَا أَنزَلْنَا عَلَىٰ قَوْمِهِ مِن بَعْدِهِ مِن جُندٍ مِّنَ السَّمَاءِ وَمَا كُنَّا مُنزِلِينَ (28) A ko so omo ogun kan kale le awon eniyan re lori lati sanmo leyin re. A o si so (molaika kan) kale (fun iparun won) |
إِن كَانَتْ إِلَّا صَيْحَةً وَاحِدَةً فَإِذَا هُمْ خَامِدُونَ (29) (Iparun won) ko je kini kan bi ko se igbe eyo kan; nigba naa ni won di oku kale |
يَا حَسْرَةً عَلَى الْعِبَادِ ۚ مَا يَأْتِيهِم مِّن رَّسُولٍ إِلَّا كَانُوا بِهِ يَسْتَهْزِئُونَ (30) Abamo ma ni fun awon erusin naa; ojise kan ko nii wa ba won ayafi ki won maa fi se yeye |
أَلَمْ يَرَوْا كَمْ أَهْلَكْنَا قَبْلَهُم مِّنَ الْقُرُونِ أَنَّهُمْ إِلَيْهِمْ لَا يَرْجِعُونَ (31) Se won ko ri i pe meloo meloo ninu awon iran ti A ti pare siwaju won? (Se won ko ri i pe) dajudaju won ko pada si odo won mo (nile aye) ni |
وَإِن كُلٌّ لَّمَّا جَمِيعٌ لَّدَيْنَا مُحْضَرُونَ (32) Dajudaju gbogbo won patapata si ni won maa ko wa si odo Wa |
وَآيَةٌ لَّهُمُ الْأَرْضُ الْمَيْتَةُ أَحْيَيْنَاهَا وَأَخْرَجْنَا مِنْهَا حَبًّا فَمِنْهُ يَأْكُلُونَ (33) Ami ni oku ile je fun won. A so o di aye. A si mu eso jade lati inu re. Won si n je ninu re |
وَجَعَلْنَا فِيهَا جَنَّاتٍ مِّن نَّخِيلٍ وَأَعْنَابٍ وَفَجَّرْنَا فِيهَا مِنَ الْعُيُونِ (34) A tun se awon ogba dabinu ati ajara sinu ile. A si mu awon odo iseleru se yo lati inu re |
لِيَأْكُلُوا مِن ثَمَرِهِ وَمَا عَمِلَتْهُ أَيْدِيهِمْ ۖ أَفَلَا يَشْكُرُونَ (35) nitori ki won le je ninu eso re ati eyi ti won fi owo ara won se! Se won ko nii dupe ni? “nitori ki won le je ninu eso re ki i si se ise owo won. Se won ko nii dupe ni?” Itumo keji duro le ise Allahu lori iseda nnkan oko. Iyen ni pe |
سُبْحَانَ الَّذِي خَلَقَ الْأَزْوَاجَ كُلَّهَا مِمَّا تُنبِتُ الْأَرْضُ وَمِنْ أَنفُسِهِمْ وَمِمَّا لَا يَعْلَمُونَ (36) Mimo ni fun Eni ti O seda gbogbo nnkan ni orisirisi ninu ohun ti ile n hu jade ati ninu emi ara won ati ninu ohun ti won ko mo. tabi oro imo ero kan tabi imo irori kan tabi eyikeyii imo kan lodi si ayah kan ninu al-Ƙur’an tabi hadith Anabi wa Muhammad (sollalahu 'alayhi wa sallam) t’o fese rinle o ti sina ni isina ponnbele. “zaoj” ni eyo. “Zaoj” si n tumo si ako tabi abo nigba ti Allahu (subhanahu wa ta'ala) ba n soro nipa iseda eniyan tabi omo bibi gege bi o se wa ninu surah an-Najm; 53:45 ati surah al-Ƙiyamoh; 75:39. amo ti ikini keji yato sira won ni ona kookan gege bi ako ati abo nnkan didun ati nnkan kikoro a le ri eso mimu tabi eso jije kan ti o maa je orisirisi. Itumo olorisirisi tun lo labe ayah ti a n tose re lowo yii. Nitori naa zaoj ko pon dandan ki o ni itumo ako ati abo nikan. Orisirisi ni “zaoj”; ako je orisi kan |
وَآيَةٌ لَّهُمُ اللَّيْلُ نَسْلَخُ مِنْهُ النَّهَارَ فَإِذَا هُم مُّظْلِمُونَ (37) Oru je ami kan fun won, ti A n yo osan jade lati inu re. Nigba naa (ti A ba yo o tan) won yoo tun wa ninu okunkun (ale miiran). ojo keje ni ojo iparan suna omo naa. Bawo ni a o se ka ojo meje naa? Teletele awon kan lero pe koda ki ojo ibimo ku iseju kan ti a o fi bo sinu ojo titun. Bi apeere ti obinrin kan ba bimo ni osan Alaadi |
وَالشَّمْسُ تَجْرِي لِمُسْتَقَرٍّ لَّهَا ۚ ذَٰلِكَ تَقْدِيرُ الْعَزِيزِ الْعَلِيمِ (38) Ati pe oorun yoo maa rin lo si aye re. Iyen ni eto (ti) Alagbara, Onimo |
وَالْقَمَرَ قَدَّرْنَاهُ مَنَازِلَ حَتَّىٰ عَادَ كَالْعُرْجُونِ الْقَدِيمِ (39) Osupa naa, A ti se odiwon awon ibuso fun un (ti o ti ma maa tobi si i) titi o maa fi pada da bii ogomo ope t’o ti pe |
لَا الشَّمْسُ يَنبَغِي لَهَا أَن تُدْرِكَ الْقَمَرَ وَلَا اللَّيْلُ سَابِقُ النَّهَارِ ۚ وَكُلٌّ فِي فَلَكٍ يَسْبَحُونَ (40) Ko ye fun oorun lati lo asiko osupa. Ko si ye fun ale lati lo asiko osan. Ikookan wa ni opopona roboto t’o n to |
وَآيَةٌ لَّهُمْ أَنَّا حَمَلْنَا ذُرِّيَّتَهُمْ فِي الْفُلْكِ الْمَشْحُونِ (41) O tun je ami fun won pe dajudaju Awa gbe awon aromodomo won gun oko oju-omi t’o kun keke |
وَخَلَقْنَا لَهُم مِّن مِّثْلِهِ مَا يَرْكَبُونَ (42) A tun seda (omiran) fun won ninu iru re ti won yoo maa gun |
وَإِن نَّشَأْ نُغْرِقْهُمْ فَلَا صَرِيخَ لَهُمْ وَلَا هُمْ يُنقَذُونَ (43) Ti A ba fe Awa iba te won ri sinu omi. Ko nii si oluranlowo kan fun won. Won ko si nii gba won la |
إِلَّا رَحْمَةً مِّنَّا وَمَتَاعًا إِلَىٰ حِينٍ (44) Afi (ki A fi) ike kan lati odo Wa (yo won jade, ki A si tun fun won ni) igbadun aye titi di igba die |
وَإِذَا قِيلَ لَهُمُ اتَّقُوا مَا بَيْنَ أَيْدِيكُمْ وَمَا خَلْفَكُمْ لَعَلَّكُمْ تُرْحَمُونَ (45) (Won maa gbunri) nigba ti A ba so fun won pe: "E sora fun ohun t’o wa niwaju yin ati ohun t’o wa leyin yin nitori ki A le ke yin |
وَمَا تَأْتِيهِم مِّنْ آيَةٍ مِّنْ آيَاتِ رَبِّهِمْ إِلَّا كَانُوا عَنْهَا مُعْرِضِينَ (46) Ati pe ayah kan ninu awon ayah Oluwa won ko nii wa ba won afi ki won maa gbunri kuro nibe |
وَإِذَا قِيلَ لَهُمْ أَنفِقُوا مِمَّا رَزَقَكُمُ اللَّهُ قَالَ الَّذِينَ كَفَرُوا لِلَّذِينَ آمَنُوا أَنُطْعِمُ مَن لَّوْ يَشَاءُ اللَّهُ أَطْعَمَهُ إِنْ أَنتُمْ إِلَّا فِي ضَلَالٍ مُّبِينٍ (47) Nigba ti A ba si so fun won pe: "E na ninu ohun ti Allahu se ni arisiki fun yin.", awon t’o sai gbagbo yoo wi fun awon t’o gbagbo pe: "Se ki a bo eni ti (o je pe) Allahu iba fe iba bo o (amo ko bo o. Awa naa ko si nii ba A bo o)?” Ki ni eyin bi ko se pe (e wa) ninu isina ponnbele |
وَيَقُولُونَ مَتَىٰ هَٰذَا الْوَعْدُ إِن كُنتُمْ صَادِقِينَ (48) Won si n wi pe: "Igba wo ni adehun yii yoo se ti e ba je olododo |
مَا يَنظُرُونَ إِلَّا صَيْحَةً وَاحِدَةً تَأْخُذُهُمْ وَهُمْ يَخِصِّمُونَ (49) Won ko reti kini kan bi ko se igbe eyo kan soso ti o maa gba won mu nigba ti won ba n se ariyanjiyan lowo |
فَلَا يَسْتَطِيعُونَ تَوْصِيَةً وَلَا إِلَىٰ أَهْلِهِمْ يَرْجِعُونَ (50) Nigba naa, won ko nii le so asoole kan. Won ko si nii le pada si odo ara ile won |
وَنُفِخَ فِي الصُّورِ فَإِذَا هُم مِّنَ الْأَجْدَاثِ إِلَىٰ رَبِّهِمْ يَنسِلُونَ (51) Won a si fon fere oniwo fun ajinde, nigba naa ni won yoo maa sare jade lati inu saree wa si odo Oluwa won |
قَالُوا يَا وَيْلَنَا مَن بَعَثَنَا مِن مَّرْقَدِنَا ۜ ۗ هَٰذَا مَا وَعَدَ الرَّحْمَٰنُ وَصَدَقَ الْمُرْسَلُونَ (52) Won a wi pe: "Egbe wa o! Ta ni o ta wa ji lati oju oorun wa?" Eyi ni nnkan ti Ajoke-aye se ni adehun. Awon Ojise si ti so ododo (nipa re) |
إِن كَانَتْ إِلَّا صَيْحَةً وَاحِدَةً فَإِذَا هُمْ جَمِيعٌ لَّدَيْنَا مُحْضَرُونَ (53) Ko je kini kan tayo igbe eyo kan soso. Nigba naa ni (awon molaika) yoo ko gbogbo won jo si odo Wa |
فَالْيَوْمَ لَا تُظْلَمُ نَفْسٌ شَيْئًا وَلَا تُجْزَوْنَ إِلَّا مَا كُنتُمْ تَعْمَلُونَ (54) Nitori naa, ni oni won ko nii se abosi kini kan fun emi kan. A o si nii san yin ni esan afi ohun ti e n se nise |
إِنَّ أَصْحَابَ الْجَنَّةِ الْيَوْمَ فِي شُغُلٍ فَاكِهُونَ (55) Dajudaju ni oni awon ero inu Ogba Idera yoo kun fun igbadun |
هُمْ وَأَزْوَاجُهُمْ فِي ظِلَالٍ عَلَى الْأَرَائِكِ مُتَّكِئُونَ (56) Awon ati awon iyawo won yoo wa labe awon iboji, won yo si rogboku sori awon ibusun |
لَهُمْ فِيهَا فَاكِهَةٌ وَلَهُم مَّا يَدَّعُونَ (57) Eso wa ninu re fun won. Ohun ti won yoo maa beere fun tun wa fun won pelu |
سَلَامٌ قَوْلًا مِّن رَّبٍّ رَّحِيمٍ (58) Alaafia ni oro ti o maa wa lati odo Oluwa, Asake-orun |
وَامْتَازُوا الْيَوْمَ أَيُّهَا الْمُجْرِمُونَ (59) Eyin elese, e bo si oto ni oni |
۞ أَلَمْ أَعْهَدْ إِلَيْكُمْ يَا بَنِي آدَمَ أَن لَّا تَعْبُدُوا الشَّيْطَانَ ۖ إِنَّهُ لَكُمْ عَدُوٌّ مُّبِينٌ (60) Eyin omo (Anabi) Adam, se Emi ko ti pa yin ni ase pe ki e ma se josin fun Esu? Dajudaju oun ni ota ponnbele fun yin |
وَأَنِ اعْبُدُونِي ۚ هَٰذَا صِرَاطٌ مُّسْتَقِيمٌ (61) Ati pe ki e josin fun Mi. Eyi ni ona taara |
وَلَقَدْ أَضَلَّ مِنكُمْ جِبِلًّا كَثِيرًا ۖ أَفَلَمْ تَكُونُوا تَعْقِلُونَ (62) Ati pe (Esu) kuku ti si opolopo eda lona ninu yin. Se e o nii se laakaye ni |
هَٰذِهِ جَهَنَّمُ الَّتِي كُنتُمْ تُوعَدُونَ (63) Eyi ni ina Jahanamo ti A n se ni adehun fun yin |
اصْلَوْهَا الْيَوْمَ بِمَا كُنتُمْ تَكْفُرُونَ (64) E wo inu re ni oni nitori pe eyin je alaigbagbo |
الْيَوْمَ نَخْتِمُ عَلَىٰ أَفْوَاهِهِمْ وَتُكَلِّمُنَا أَيْدِيهِمْ وَتَشْهَدُ أَرْجُلُهُم بِمَا كَانُوا يَكْسِبُونَ (65) Ni oni, A maa di enu won pa. Awon owo won yo si maa ba Wa soro. Awon ese won yo si maa jerii si ohun ti won n se nise |
وَلَوْ نَشَاءُ لَطَمَسْنَا عَلَىٰ أَعْيُنِهِمْ فَاسْتَبَقُوا الصِّرَاطَ فَأَنَّىٰ يُبْصِرُونَ (66) Ti o ba je pe A ba fe, Awa iba fo won loju, won iba si yara wa soju ona, bawo ni won se maa riran na |
وَلَوْ نَشَاءُ لَمَسَخْنَاهُمْ عَلَىٰ مَكَانَتِهِمْ فَمَا اسْتَطَاعُوا مُضِيًّا وَلَا يَرْجِعُونَ (67) Ti o ba je pe A ba fe, Awa iba yi won pada si eda miiran ninu ibugbe won. Won ko si nii lagbara lati lo siwaju. Won ko si nii pada seyin |
وَمَن نُّعَمِّرْهُ نُنَكِّسْهُ فِي الْخَلْقِ ۖ أَفَلَا يَعْقِلُونَ (68) Enikeni ti A ba fun ni emi gigun lo, A oo so eda re di ole, se won ko nii se laakaye ni |
وَمَا عَلَّمْنَاهُ الشِّعْرَ وَمَا يَنبَغِي لَهُ ۚ إِنْ هُوَ إِلَّا ذِكْرٌ وَقُرْآنٌ مُّبِينٌ (69) A o ko Anabi (sollalahu 'alayhi wa sallam) ni ewi. Ko si ro o lorun (lati kewi). Ki ni ohun (ti A fi ranse si i) bi ko se iranti ati al-Ƙur’an ponnbele |
لِّيُنذِرَ مَن كَانَ حَيًّا وَيَحِقَّ الْقَوْلُ عَلَى الْكَافِرِينَ (70) nitori ki o le sekilo fun eni ti o je alaaye ati nitori ki oro naa le ko lori awon alaigbagbo |
أَوَلَمْ يَرَوْا أَنَّا خَلَقْنَا لَهُم مِّمَّا عَمِلَتْ أَيْدِينَا أَنْعَامًا فَهُمْ لَهَا مَالِكُونَ (71) Se won ko ri i pe dajudaju Awa l’A seda ninu ohun ti A fi owo Wa se (ti o je) awon eran-osin fun won? Won si ni ikapa lori won |
وَذَلَّلْنَاهَا لَهُمْ فَمِنْهَا رَكُوبُهُمْ وَمِنْهَا يَأْكُلُونَ (72) A te won lori ba fun won; won n gun ninu won, won si n je ninu won |
وَلَهُمْ فِيهَا مَنَافِعُ وَمَشَارِبُ ۖ أَفَلَا يَشْكُرُونَ (73) Awon anfaani ati ohun mimu tun wa fun won ninu re. Se won ko nii dupe ni |
وَاتَّخَذُوا مِن دُونِ اللَّهِ آلِهَةً لَّعَلَّهُمْ يُنصَرُونَ (74) Won so awon kan di olohun leyin Allahu nitori ki won le saranse fun won |
لَا يَسْتَطِيعُونَ نَصْرَهُمْ وَهُمْ لَهُمْ جُندٌ مُّحْضَرُونَ (75) Won ko si le se aranse fun won; sebi awon orisa ni omo ogun ti A maa ko wo inu Ina fun awon aborisa (lati fi je won niya) |
فَلَا يَحْزُنكَ قَوْلُهُمْ ۘ إِنَّا نَعْلَمُ مَا يُسِرُّونَ وَمَا يُعْلِنُونَ (76) Nitori naa, ma se je ki oro won ba o ninu je. Dajudaju Awa mo ohun ti won n fi pamo ati ohun ti won n safi han re |
أَوَلَمْ يَرَ الْإِنسَانُ أَنَّا خَلَقْنَاهُ مِن نُّطْفَةٍ فَإِذَا هُوَ خَصِيمٌ مُّبِينٌ (77) Se eniyan ko ri i pe dajudaju Awa l’A seda re lati inu ato? (Sebi leyin) igba naa l’o di alatako ponnbele |
وَضَرَبَ لَنَا مَثَلًا وَنَسِيَ خَلْقَهُ ۖ قَالَ مَن يُحْيِي الْعِظَامَ وَهِيَ رَمِيمٌ (78) Ati pe o fi akawe lele nipa Wa. O si gbagbe iseda re. O wi pe: "Ta ni O maa so egungun di alaaye nigba ti o ti kefun |
قُلْ يُحْيِيهَا الَّذِي أَنشَأَهَا أَوَّلَ مَرَّةٍ ۖ وَهُوَ بِكُلِّ خَلْقٍ عَلِيمٌ (79) So pe: "Eni ti O seda re nigba akoko l’O maa so o di alaaye. Oun si ni Onimo nipa gbogbo eda |
الَّذِي جَعَلَ لَكُم مِّنَ الشَّجَرِ الْأَخْضَرِ نَارًا فَإِذَا أَنتُم مِّنْهُ تُوقِدُونَ (80) (Oun ni) Eni ti O mu ina jade fun yin lati ara igi tutu. E si n fi ko ina |
أَوَلَيْسَ الَّذِي خَلَقَ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضَ بِقَادِرٍ عَلَىٰ أَن يَخْلُقَ مِثْلَهُم ۚ بَلَىٰ وَهُوَ الْخَلَّاقُ الْعَلِيمُ (81) Nje Eni ti O seda awon sanmo ati ile ko ni agbara lati da iru won (miiran) bi? Rara (O ni agbara). Oun si ni Eledaa, Onimo |
إِنَّمَا أَمْرُهُ إِذَا أَرَادَ شَيْئًا أَن يَقُولَ لَهُ كُن فَيَكُونُ (82) Ase Re nigba ti O ba gbero kini kan ni pe, O maa so fun un pe "Je bee." O si maa je bee |
فَسُبْحَانَ الَّذِي بِيَدِهِ مَلَكُوتُ كُلِّ شَيْءٍ وَإِلَيْهِ تُرْجَعُونَ (83) Nitori naa, mimo ni fun Eni ti ijoba gbogbo nnkan wa ni owo Re. Odo Re si ni won yoo da yin pada si |