Quran with Yoruba translation - Surah An-Nisa’ ayat 140 - النِّسَاء - Page - Juz 5
﴿وَقَدۡ نَزَّلَ عَلَيۡكُمۡ فِي ٱلۡكِتَٰبِ أَنۡ إِذَا سَمِعۡتُمۡ ءَايَٰتِ ٱللَّهِ يُكۡفَرُ بِهَا وَيُسۡتَهۡزَأُ بِهَا فَلَا تَقۡعُدُواْ مَعَهُمۡ حَتَّىٰ يَخُوضُواْ فِي حَدِيثٍ غَيۡرِهِۦٓ إِنَّكُمۡ إِذٗا مِّثۡلُهُمۡۗ إِنَّ ٱللَّهَ جَامِعُ ٱلۡمُنَٰفِقِينَ وَٱلۡكَٰفِرِينَ فِي جَهَنَّمَ جَمِيعًا ﴾
[النِّسَاء: 140]
﴿وقد نـزل عليكم في الكتاب أن إذا سمعتم آيات الله يكفر بها﴾ [النِّسَاء: 140]
Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni (Allāhu) kúkú ti sọ̀ ọ́ kalẹ̀ fun yín nínú Tírà pé nígbà tí ẹ bá gbọ́ nípa àwọn āyah Allāhu pé wọ́n ń ṣàì gbàgbọ́ nínú rẹ̀, wọ́n sì ń fi ṣe ẹ̀fẹ̀, ẹ má ṣe jókòó tì wọ́n nígbà náà títí wọn yóò fi bọ́ sínú ọ̀rọ̀ mìíràn, bí bẹ́ẹ̀ kọ́ dájúdájú ẹ̀yin yóò dà bí irú wọn. Dájúdájú Allāhu yóò pa àwọn ṣòbẹ-ṣèlu mùsùlùmí pọ̀ mọ́ gbogbo àwọn aláìgbàgbọ́ nínú iná Jahanamọ |