Quran with Yoruba translation - Surah Al-Ahqaf ayat 9 - الأحقَاف - Page - Juz 26
﴿قُلۡ مَا كُنتُ بِدۡعٗا مِّنَ ٱلرُّسُلِ وَمَآ أَدۡرِي مَا يُفۡعَلُ بِي وَلَا بِكُمۡۖ إِنۡ أَتَّبِعُ إِلَّا مَا يُوحَىٰٓ إِلَيَّ وَمَآ أَنَا۠ إِلَّا نَذِيرٞ مُّبِينٞ ﴾
[الأحقَاف: 9]
﴿قل ما كنت بدعا من الرسل وما أدري ما يفعل بي ولا﴾ [الأحقَاف: 9]
Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni Sọ pé: "Èmi kì í ṣe àkọ́kọ́ nínú àwọn Òjíṣẹ́. Èmi kò sì mọ n̄ǹkan tí wọ́n máa ṣe fún èmi àti ẹ̀yin. Èmi kò tẹ̀lé kiní kan àyàfi ohun tí Wọ́n fi ránṣẹ́ sí mi ní ìmísí. Èmi kò sì jẹ́ kiní kan bí kò ṣe olùkìlọ̀ pọ́nńbélé." wọ́n wà lábẹ́ ìjọba àwọn ọ̀ṣẹbọ nínú ìlú Mọkkah alápọ̀n-ọ́nlé. Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí níí yọwọ́ kọ́wọ́ sí àwọn ọmọlẹ́yìn Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam). Lásìkò náà ipò ọ̀lẹ ni àwọn mùsùlùmí wà nínú ìlú náà. Kò sí ohun t’ó wá lè fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀ sínú ’Islām tayọ kí Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) jẹ́ kí ó di mímọ̀ fún ẹnì kọ̀ọ̀kan àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé ìjìyà àti pípa han àwọn mùsùlùmí ni èèmọ̀ ìfojú-egbò-rìn. Mọ̀ dájú pé kò sí Ànábì kan nínú àwọn Ànábì Ọlọ́hun (ahm.s.w.) tí kò mọ̀ pé tí ó bá jẹ́ pé ìtúmọ̀ tí àwọn kristiẹni fún āyah náà l’ó bá jẹ́ òdodo “èmi kò sì mọ n̄ǹkan tí Allāhu máa ṣe fún èmi àti ẹ̀yin” ni ìbá jẹ́ àgbékalẹ̀ rẹ̀. Bákan náà iṣẹ́ tí Ànábì (sollalāhu 'alayhi wa sallam) jẹ́ fáyé kò yàtọ̀ sí ti àwọn t’ó ṣíwájú rẹ̀ nínú àwọn Òjíṣẹ́ Allāhu (ahm.s.w). Bákan náà āyah náà ń pè wá síbi ìdúró ṣinṣin àti àtẹ̀mọra lásìkò ìnira àwọn aláìgbàgbọ́ |