×

سورة الأحقاف باللغة اليوربا

ترجمات القرآنباللغة اليوربا ⬅ سورة الأحقاف

ترجمة معاني سورة الأحقاف باللغة اليوربا - Yoruba

القرآن باللغة اليوربا - سورة الأحقاف مترجمة إلى اللغة اليوربا، Surah Ahqaf in Yoruba. نوفر ترجمة دقيقة سورة الأحقاف باللغة اليوربا - Yoruba, الآيات 35 - رقم السورة 46 - الصفحة 502.

بسم الله الرحمن الرحيم

حم (1)
Ha mim
تَنزِيلُ الْكِتَابِ مِنَ اللَّهِ الْعَزِيزِ الْحَكِيمِ (2)
Tira naa sokale lati odo Allahu, Alagbara, Ologbon
مَا خَلَقْنَا السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضَ وَمَا بَيْنَهُمَا إِلَّا بِالْحَقِّ وَأَجَلٍ مُّسَمًّى ۚ وَالَّذِينَ كَفَرُوا عَمَّا أُنذِرُوا مُعْرِضُونَ (3)
A o seda awon sanmo ati ile, ati ohunkohun t’o wa laaarin mejeeji bi ko se pelu ododo ati fun gbedeke akoko kan. Awon t’o sai gbagbo yo si maa gbunri kuro nibi ohun ti A fi sekilo fun won
قُلْ أَرَأَيْتُم مَّا تَدْعُونَ مِن دُونِ اللَّهِ أَرُونِي مَاذَا خَلَقُوا مِنَ الْأَرْضِ أَمْ لَهُمْ شِرْكٌ فِي السَّمَاوَاتِ ۖ ائْتُونِي بِكِتَابٍ مِّن قَبْلِ هَٰذَا أَوْ أَثَارَةٍ مِّنْ عِلْمٍ إِن كُنتُمْ صَادِقِينَ (4)
So pe: "E so fun mi nipa nnkan ti e n pe leyin Allahu; e fi won han mi na, ki ni won seda ninu (ohun t’o wa lori) ile. Tabi won ni ipin kan (pelu Allahu) ninu (iseda) awon sanmo? E mu Tira kan wa fun mi t’o siwaju (al-Ƙur’an) yii tabi oripa kan ninu imo ti e ba je olododo
وَمَنْ أَضَلُّ مِمَّن يَدْعُو مِن دُونِ اللَّهِ مَن لَّا يَسْتَجِيبُ لَهُ إِلَىٰ يَوْمِ الْقِيَامَةِ وَهُمْ عَن دُعَائِهِمْ غَافِلُونَ (5)
Ta l’o si sina ju eni ti o n pe leyin Allahu, eni ti ko le je ipe re titi di Ojo Ajinde! Ati pe won ko ni oye si pipe ti won n pe won
وَإِذَا حُشِرَ النَّاسُ كَانُوا لَهُمْ أَعْدَاءً وَكَانُوا بِعِبَادَتِهِمْ كَافِرِينَ (6)
Nigba ti A ba si ko awon eniyan jo (fun Ajinde), awon orisa yoo di ota fun awon aborisa. Won si maa tako ijosin ti won se fun won
وَإِذَا تُتْلَىٰ عَلَيْهِمْ آيَاتُنَا بَيِّنَاتٍ قَالَ الَّذِينَ كَفَرُوا لِلْحَقِّ لَمَّا جَاءَهُمْ هَٰذَا سِحْرٌ مُّبِينٌ (7)
Nigba ti won ba n ke awon ayah Wa t’o yanju fun won, awon t’o sai gbagbo yo si maa so isokuso si ododo nigba ti o de ba won pe: "Eyi ni idan ponnbele
أَمْ يَقُولُونَ افْتَرَاهُ ۖ قُلْ إِنِ افْتَرَيْتُهُ فَلَا تَمْلِكُونَ لِي مِنَ اللَّهِ شَيْئًا ۖ هُوَ أَعْلَمُ بِمَا تُفِيضُونَ فِيهِ ۖ كَفَىٰ بِهِ شَهِيدًا بَيْنِي وَبَيْنَكُمْ ۖ وَهُوَ الْغَفُورُ الرَّحِيمُ (8)
Tabi won n wi pe: "O da (al-Ƙur’an) hun funra re ni." So pe: "Ti mo ba hun un funra mi, e o ni ikapa kini kan fun mi ni odo Allahu (nibi iya Re). Oun ni Onimo-julo nipa isokuso ti e n so nipa re. O (si) to ni Elerii laaarin emi ati eyin. Oun ni Alaforijin, Asake-orun
قُلْ مَا كُنتُ بِدْعًا مِّنَ الرُّسُلِ وَمَا أَدْرِي مَا يُفْعَلُ بِي وَلَا بِكُمْ ۖ إِنْ أَتَّبِعُ إِلَّا مَا يُوحَىٰ إِلَيَّ وَمَا أَنَا إِلَّا نَذِيرٌ مُّبِينٌ (9)
So pe: "Emi ki i se akoko ninu awon Ojise. Emi ko si mo nnkan ti won maa se fun emi ati eyin. Emi ko tele kini kan ayafi ohun ti Won fi ranse si mi ni imisi. Emi ko si je kini kan bi ko se olukilo ponnbele." won wa labe ijoba awon osebo ninu ilu Mokkah alapon-onle. Won si bere si nii yowo kowo si awon omoleyin Anabi (sollalahu 'alayhi wa sallam). Lasiko naa ipo ole ni awon musulumi wa ninu ilu naa. Ko si ohun t’o wa le fi won lokan bale sinu ’Islam tayo ki Anabi (sollalahu 'alayhi wa sallam) je ki o di mimo fun eni kookan awon omoleyin re pe ijiya ati pipa han awon musulumi ni eemo ifoju-egbo-rin. Mo daju pe ko si Anabi kan ninu awon Anabi Olohun (ahm.s.w.) ti ko mo pe ti o ba je pe itumo ti awon kristieni fun ayah naa l’o ba je ododo “emi ko si mo nnkan ti Allahu maa se fun emi ati eyin” ni iba je agbekale re. Bakan naa ise ti Anabi (sollalahu 'alayhi wa sallam) je faye ko yato si ti awon t’o siwaju re ninu awon Ojise Allahu (ahm.s.w). Bakan naa ayah naa n pe wa sibi iduro sinsin ati atemora lasiko inira awon alaigbagbo
قُلْ أَرَأَيْتُمْ إِن كَانَ مِنْ عِندِ اللَّهِ وَكَفَرْتُم بِهِ وَشَهِدَ شَاهِدٌ مِّن بَنِي إِسْرَائِيلَ عَلَىٰ مِثْلِهِ فَآمَنَ وَاسْتَكْبَرْتُمْ ۖ إِنَّ اللَّهَ لَا يَهْدِي الْقَوْمَ الظَّالِمِينَ (10)
So pe: " E so fun mi, ti o ba je pe lati odo Allahu ni (al-Ƙur’an) ti wa, ti e si sai gbagbo ninu re, ti elerii kan ninu awon omo ’Isro’il si jerii lori iru re, ti o si gba a gbo, (amo) ti eyin segberaga si i, (se e o ti sabosi bayen bi?). Dajudaju Allahu ko nii fi ona mo ijo alabosi
وَقَالَ الَّذِينَ كَفَرُوا لِلَّذِينَ آمَنُوا لَوْ كَانَ خَيْرًا مَّا سَبَقُونَا إِلَيْهِ ۚ وَإِذْ لَمْ يَهْتَدُوا بِهِ فَسَيَقُولُونَ هَٰذَا إِفْكٌ قَدِيمٌ (11)
Awon t’o sai gbagbo wi fun awon t’o gbagbo pe: "Ti o ba je pe al-Ƙur’an je oore ni, won ko nii siwaju wa debe." Nigba ti awon osebo ko ti tele imona re, ni won n wi pe: "Iro ijoun ni eyi
وَمِن قَبْلِهِ كِتَابُ مُوسَىٰ إِمَامًا وَرَحْمَةً ۚ وَهَٰذَا كِتَابٌ مُّصَدِّقٌ لِّسَانًا عَرَبِيًّا لِّيُنذِرَ الَّذِينَ ظَلَمُوا وَبُشْرَىٰ لِلْمُحْسِنِينَ (12)
Tira (Anabi) Musa si ti wa siwaju re, ti o je tira ti won n tele, o si je ike (fun won. Al-Ƙur’an) yii tun ni Tira kan t’o n jerii si ododo ni ede Larubawa nitori ki o le sekilo fun awon t’o sabosi, (o si je) iro idunnu fun awon oluse-rere
إِنَّ الَّذِينَ قَالُوا رَبُّنَا اللَّهُ ثُمَّ اسْتَقَامُوا فَلَا خَوْفٌ عَلَيْهِمْ وَلَا هُمْ يَحْزَنُونَ (13)
Dajudaju awon t’o so pe: "Allahu ni Oluwa wa", leyin naa, ti won duro sinsin, ko nii si ipaya fun won. Won ko si nii banuje
أُولَٰئِكَ أَصْحَابُ الْجَنَّةِ خَالِدِينَ فِيهَا جَزَاءً بِمَا كَانُوا يَعْمَلُونَ (14)
Awon wonyen ni ero inu Ogba Idera. Olusegbere ni won ninu re. (O je) esan nitori ohun ti won n se nise
وَوَصَّيْنَا الْإِنسَانَ بِوَالِدَيْهِ إِحْسَانًا ۖ حَمَلَتْهُ أُمُّهُ كُرْهًا وَوَضَعَتْهُ كُرْهًا ۖ وَحَمْلُهُ وَفِصَالُهُ ثَلَاثُونَ شَهْرًا ۚ حَتَّىٰ إِذَا بَلَغَ أَشُدَّهُ وَبَلَغَ أَرْبَعِينَ سَنَةً قَالَ رَبِّ أَوْزِعْنِي أَنْ أَشْكُرَ نِعْمَتَكَ الَّتِي أَنْعَمْتَ عَلَيَّ وَعَلَىٰ وَالِدَيَّ وَأَنْ أَعْمَلَ صَالِحًا تَرْضَاهُ وَأَصْلِحْ لِي فِي ذُرِّيَّتِي ۖ إِنِّي تُبْتُ إِلَيْكَ وَإِنِّي مِنَ الْمُسْلِمِينَ (15)
A pa a ni ase fun eniyan pe ki o maa se daadaa si awon obi re mejeeji. Iya re ni oyun re pelu wahala. O si bi i pelu wahala. Oyun re ati gbigba omu lenu re je ogbon osu. (O si n to o) titi o fi dagba, ti o fi di omo ogoji odun, o si so pe: "Oluwa mi, fi mo mi ki ng maa dupe idera Re, eyi ti O fi se idera fun mi ati fun awon obi mi mejeeji, ki ng si maa se ise rere, eyi ti O yonu si. Ki O si se rere fun mi lori awon aromodomo mi. Dajudaju emi ti ronu piwada si odo Re. Dajudaju emi si wa ninu awon musulumi
أُولَٰئِكَ الَّذِينَ نَتَقَبَّلُ عَنْهُمْ أَحْسَنَ مَا عَمِلُوا وَنَتَجَاوَزُ عَن سَيِّئَاتِهِمْ فِي أَصْحَابِ الْجَنَّةِ ۖ وَعْدَ الصِّدْقِ الَّذِي كَانُوا يُوعَدُونَ (16)
Awon wonyen ni awon ti A maa gba ise rere ti won se nise, A si maa se amojukuro nibi awon aburu ise won; won maa wa ninu awon ero inu Ogba Idera. (O je) adehun ododo ti A n se ni adehun fun won
وَالَّذِي قَالَ لِوَالِدَيْهِ أُفٍّ لَّكُمَا أَتَعِدَانِنِي أَنْ أُخْرَجَ وَقَدْ خَلَتِ الْقُرُونُ مِن قَبْلِي وَهُمَا يَسْتَغِيثَانِ اللَّهَ وَيْلَكَ آمِنْ إِنَّ وَعْدَ اللَّهِ حَقٌّ فَيَقُولُ مَا هَٰذَا إِلَّا أَسَاطِيرُ الْأَوَّلِينَ (17)
Eni ti o so fun awon obi re mejeeji pe: "Sio eyin mejeeji! Se eyin yoo maa seleri fun mi pe Won yoo mu mi jade (laaye lati inu saree), sebi awon iran kan ti re koja lo siwaju mi (ti Won ko ti i mu won jade lati inu saree won)." Awon (obi re) mejeeji si n toro igbala ni odo Allahu (fun omo yii. Won si so pe): "Egbe ni fun o! (O je) gbagbo ni ododo. Dajudaju adehun Allahu ni ododo." (Omo naa si) wi pe: "Eyi ko je kini kan bi ko se akosile alo awon eni akoko
أُولَٰئِكَ الَّذِينَ حَقَّ عَلَيْهِمُ الْقَوْلُ فِي أُمَمٍ قَدْ خَلَتْ مِن قَبْلِهِم مِّنَ الْجِنِّ وَالْإِنسِ ۖ إِنَّهُمْ كَانُوا خَاسِرِينَ (18)
Awon (alaigbagbo) wonyen ni awon ti oro naa ti ko le lori ninu awon ijo kan ti o ti re koja siwaju won ninu awon alujannu ati eniyan. Dajudaju won je eni ofo
وَلِكُلٍّ دَرَجَاتٌ مِّمَّا عَمِلُوا ۖ وَلِيُوَفِّيَهُمْ أَعْمَالَهُمْ وَهُمْ لَا يُظْلَمُونَ (19)
Awon ipo yoo wa fun eni kookan nipa ise ti won se nise. Ati pe (eyi ri bee) nitori ki (Allahu) le san won ni esan ise won. Awa ko si nii sabosi si won
وَيَوْمَ يُعْرَضُ الَّذِينَ كَفَرُوا عَلَى النَّارِ أَذْهَبْتُمْ طَيِّبَاتِكُمْ فِي حَيَاتِكُمُ الدُّنْيَا وَاسْتَمْتَعْتُم بِهَا فَالْيَوْمَ تُجْزَوْنَ عَذَابَ الْهُونِ بِمَا كُنتُمْ تَسْتَكْبِرُونَ فِي الْأَرْضِ بِغَيْرِ الْحَقِّ وَبِمَا كُنتُمْ تَفْسُقُونَ (20)
Ni ojo ti won maa dari awon t’o sai gbagbo ko Ina, (won maa so fun won pe:) "E ti lo igbadun yin tan ninu isemi aye? E si ti je igbadun aye? Nitori naa, ni oni, won maa san yin ni esan abuku iya nitori pe e n segberaga ni ori ile lai letoo ati nitori pe e n sebaje
۞ وَاذْكُرْ أَخَا عَادٍ إِذْ أَنذَرَ قَوْمَهُ بِالْأَحْقَافِ وَقَدْ خَلَتِ النُّذُرُ مِن بَيْنِ يَدَيْهِ وَمِنْ خَلْفِهِ أَلَّا تَعْبُدُوا إِلَّا اللَّهَ إِنِّي أَخَافُ عَلَيْكُمْ عَذَابَ يَوْمٍ عَظِيمٍ (21)
Seranti arakunrin (ijo) ‘Ad. Nigba ti o sekilo fun awon eniyan re t’o n gbe ninu yanrin ti ategun kojo bi oke. Awon olukilo si ti re koja siwaju re ati leyin re. (O si so pe:) "Eyin ko gbodo josin fun kini kan ayafi Allahu. Dajudaju emi n paya iya ojo nla kan fun yin
قَالُوا أَجِئْتَنَا لِتَأْفِكَنَا عَنْ آلِهَتِنَا فَأْتِنَا بِمَا تَعِدُنَا إِن كُنتَ مِنَ الصَّادِقِينَ (22)
Won wi pe: "Se iwo wa ba wa lati se wa lori kuro nibi awon orisa wa ni? Mu ohun ti o n se ileri re fun wa wa ti iwo ba wa ninu awon olododo
قَالَ إِنَّمَا الْعِلْمُ عِندَ اللَّهِ وَأُبَلِّغُكُم مَّا أُرْسِلْتُ بِهِ وَلَٰكِنِّي أَرَاكُمْ قَوْمًا تَجْهَلُونَ (23)
O so pe: "Imo (nipa re) wa ni odo Allahu nikan soso. Emi yo si je ise ti Won fi ran mi de opin fun yin, sugbon emi n ri eyin ni ijo alaimokan
فَلَمَّا رَأَوْهُ عَارِضًا مُّسْتَقْبِلَ أَوْدِيَتِهِمْ قَالُوا هَٰذَا عَارِضٌ مُّمْطِرُنَا ۚ بَلْ هُوَ مَا اسْتَعْجَلْتُم بِهِ ۖ رِيحٌ فِيهَا عَذَابٌ أَلِيمٌ (24)
Nigba ti won ri iya naa ni esujo regede, t’o n wo bo wa sinu awon koto ilu won, won wi pe: "Eyi ni esujo regede, ti o maa rojo fun wa." Ko si ri bee, ohun ti e n wa pelu ikanju ni. Ategun ti iya eleta-elero wa ninu re ni
تُدَمِّرُ كُلَّ شَيْءٍ بِأَمْرِ رَبِّهَا فَأَصْبَحُوا لَا يُرَىٰ إِلَّا مَسَاكِنُهُمْ ۚ كَذَٰلِكَ نَجْزِي الْقَوْمَ الْمُجْرِمِينَ (25)
O n pa gbogbo nnkan re pelu ase Oluwa re. Nigba naa, won di eni ti won ko ri mo afi awon ibugbe won. Bayen ni A se n san ijo elese ni esan
وَلَقَدْ مَكَّنَّاهُمْ فِيمَا إِن مَّكَّنَّاكُمْ فِيهِ وَجَعَلْنَا لَهُمْ سَمْعًا وَأَبْصَارًا وَأَفْئِدَةً فَمَا أَغْنَىٰ عَنْهُمْ سَمْعُهُمْ وَلَا أَبْصَارُهُمْ وَلَا أَفْئِدَتُهُم مِّن شَيْءٍ إِذْ كَانُوا يَجْحَدُونَ بِآيَاتِ اللَّهِ وَحَاقَ بِهِم مَّا كَانُوا بِهِ يَسْتَهْزِئُونَ (26)
A kuku fun won ni ipo ti A o fun eyin. A si fun won ni igboro, awon iriran ati awon okan. Amo igboro won ati awon iriran won pelu awon okan won ko ro won loro kan kan nibi iya nitori pe won n se atako si awon ayah Allahu. Ati pe ohun ti won n fi se yeye si diya t’o yi won po
وَلَقَدْ أَهْلَكْنَا مَا حَوْلَكُم مِّنَ الْقُرَىٰ وَصَرَّفْنَا الْآيَاتِ لَعَلَّهُمْ يَرْجِعُونَ (27)
Awa kuku ti pa re ninu awon ilu ti o wa ni ayika yin. Awa si ti salaye awon ayah naa ni orisirisi ona nitori ki won le seri pada (sibi ododo)
فَلَوْلَا نَصَرَهُمُ الَّذِينَ اتَّخَذُوا مِن دُونِ اللَّهِ قُرْبَانًا آلِهَةً ۖ بَلْ ضَلُّوا عَنْهُمْ ۚ وَذَٰلِكَ إِفْكُهُمْ وَمَا كَانُوا يَفْتَرُونَ (28)
Awon olohun ti won so di ohun ti o maa mu won sunmo (igbala) leyin Allahu ko se ran won lowo mo? Rara (ko le si aranse fun won)! Won ti dofo mo won lowo. Iyen si ni (olohun) iro won ati ohun ti won n da ni adapa iro
وَإِذْ صَرَفْنَا إِلَيْكَ نَفَرًا مِّنَ الْجِنِّ يَسْتَمِعُونَ الْقُرْآنَ فَلَمَّا حَضَرُوهُ قَالُوا أَنصِتُوا ۖ فَلَمَّا قُضِيَ وَلَّوْا إِلَىٰ قَوْمِهِم مُّنذِرِينَ (29)
(Ranti) nigba ti A dari ijo kan ninu awon alujannu si o, ti won n teti gbo al-Ƙur’an. Nigba ti won de sibe, won so pe: "E dake (fun al-Ƙur’an)." Nigba ti won si pari (kike re tan), won pada si odo ijo won, ti won n sekilo (fun won)
قَالُوا يَا قَوْمَنَا إِنَّا سَمِعْنَا كِتَابًا أُنزِلَ مِن بَعْدِ مُوسَىٰ مُصَدِّقًا لِّمَا بَيْنَ يَدَيْهِ يَهْدِي إِلَى الْحَقِّ وَإِلَىٰ طَرِيقٍ مُّسْتَقِيمٍ (30)
Won so pe: "Eyin ijo wa, dajudaju awa gbo (nipa) Tira kan ti won sokale leyin (Anabi) Musa, ti o n fi ohun t’o je ododo rinle nipa eyi t’o wa siwaju re, ti o si n toni si ona ododo ati ona taara
يَا قَوْمَنَا أَجِيبُوا دَاعِيَ اللَّهِ وَآمِنُوا بِهِ يَغْفِرْ لَكُم مِّن ذُنُوبِكُمْ وَيُجِرْكُم مِّنْ عَذَابٍ أَلِيمٍ (31)
Eyin ijo wa, e je ipe olupepe Allahu. Ki e si gba a gbo ni ododo. (Allahu) yo si fori awon ese yin jin yin. O si maa yo yin kuro ninu iya eleta-elero
وَمَن لَّا يُجِبْ دَاعِيَ اللَّهِ فَلَيْسَ بِمُعْجِزٍ فِي الْأَرْضِ وَلَيْسَ لَهُ مِن دُونِهِ أَوْلِيَاءُ ۚ أُولَٰئِكَ فِي ضَلَالٍ مُّبِينٍ (32)
Enikeni ti ko ba si jepe olupepe Allahu, ko le mori bo mo (Allahu) lowo lori ile. Ko si si alaabo kan fun un leyin Allahu. Awon wonyen si wa ninu isina ponnbele
أَوَلَمْ يَرَوْا أَنَّ اللَّهَ الَّذِي خَلَقَ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضَ وَلَمْ يَعْيَ بِخَلْقِهِنَّ بِقَادِرٍ عَلَىٰ أَن يُحْيِيَ الْمَوْتَىٰ ۚ بَلَىٰ إِنَّهُ عَلَىٰ كُلِّ شَيْءٍ قَدِيرٌ (33)
Se won ko ri i pe dajudaju Allahu, Eni ti O da awon sanmo ati ile, ti ko si kaaare nipa iseda won, (se ko) ni agbara lati so awon oku di alaaye ni? Rara, (O lagbara lati se bee). Dajudaju O n je Alagbara lori gbogbo nnkan
وَيَوْمَ يُعْرَضُ الَّذِينَ كَفَرُوا عَلَى النَّارِ أَلَيْسَ هَٰذَا بِالْحَقِّ ۖ قَالُوا بَلَىٰ وَرَبِّنَا ۚ قَالَ فَذُوقُوا الْعَذَابَ بِمَا كُنتُمْ تَكْفُرُونَ (34)
(Ranti) ojo ti won maa dari awon t’o sai gbagbo lo sori Ina, (won si maa so fun won pe:) "Se eyi ki i se ododo bi?" Won yoo wi pe: "Rara, (ododo ni) Oluwa wa." (Allahu maa) so pe: "Nitori naa, e to iya wo nitori pe eyin je alaigbagbo
فَاصْبِرْ كَمَا صَبَرَ أُولُو الْعَزْمِ مِنَ الرُّسُلِ وَلَا تَسْتَعْجِل لَّهُمْ ۚ كَأَنَّهُمْ يَوْمَ يَرَوْنَ مَا يُوعَدُونَ لَمْ يَلْبَثُوا إِلَّا سَاعَةً مِّن نَّهَارٍ ۚ بَلَاغٌ ۚ فَهَلْ يُهْلَكُ إِلَّا الْقَوْمُ الْفَاسِقُونَ (35)
Nitori naa, se suuru gege bi awon onipinnu okan ninu awon Ojise ti se suuru. Ma se ba won wa iya pelu ikanju. Ni ojo ti won ba ri ohun ti A n se ni adehun fun won, won yoo da bi eni pe won ko gbe ile aye (yii) tayo akoko kan ninu osan. Al-Ƙur’an yii si ni ijise dopin. Ta ni o si maa parun bi ko se ijo obileje
❮ السورة السابقة السورة التـالية ❯

قراءة المزيد من سور القرآن الكريم :

1- الفاتحة2- البقرة3- آل عمران
4- النساء5- المائدة6- الأنعام
7- الأعراف8- الأنفال9- التوبة
10- يونس11- هود12- يوسف
13- الرعد14- إبراهيم15- الحجر
16- النحل17- الإسراء18- الكهف
19- مريم20- طه21- الأنبياء
22- الحج23- المؤمنون24- النور
25- الفرقان26- الشعراء27- النمل
28- القصص29- العنكبوت30- الروم
31- لقمان32- السجدة33- الأحزاب
34- سبأ35- فاطر36- يس
37- الصافات38- ص39- الزمر
40- غافر41- فصلت42- الشورى
43- الزخرف44- الدخان45- الجاثية
46- الأحقاف47- محمد48- الفتح
49- الحجرات50- ق51- الذاريات
52- الطور53- النجم54- القمر
55- الرحمن56- الواقعة57- الحديد
58- المجادلة59- الحشر60- الممتحنة
61- الصف62- الجمعة63- المنافقون
64- التغابن65- الطلاق66- التحريم
67- الملك68- القلم69- الحاقة
70- المعارج71- نوح72- الجن
73- المزمل74- المدثر75- القيامة
76- الإنسان77- المرسلات78- النبأ
79- النازعات80- عبس81- التكوير
82- الإنفطار83- المطففين84- الانشقاق
85- البروج86- الطارق87- الأعلى
88- الغاشية89- الفجر90- البلد
91- الشمس92- الليل93- الضحى
94- الشرح95- التين96- العلق
97- القدر98- البينة99- الزلزلة
100- العاديات101- القارعة102- التكاثر
103- العصر104- الهمزة105- الفيل
106- قريش107- الماعون108- الكوثر
109- الكافرون110- النصر111- المسد
112- الإخلاص113- الفلق114- الناس