Quran with Yoruba translation - Surah Al-Fath ayat 25 - الفَتح - Page - Juz 26
﴿هُمُ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ وَصَدُّوكُمۡ عَنِ ٱلۡمَسۡجِدِ ٱلۡحَرَامِ وَٱلۡهَدۡيَ مَعۡكُوفًا أَن يَبۡلُغَ مَحِلَّهُۥۚ وَلَوۡلَا رِجَالٞ مُّؤۡمِنُونَ وَنِسَآءٞ مُّؤۡمِنَٰتٞ لَّمۡ تَعۡلَمُوهُمۡ أَن تَطَـُٔوهُمۡ فَتُصِيبَكُم مِّنۡهُم مَّعَرَّةُۢ بِغَيۡرِ عِلۡمٖۖ لِّيُدۡخِلَ ٱللَّهُ فِي رَحۡمَتِهِۦ مَن يَشَآءُۚ لَوۡ تَزَيَّلُواْ لَعَذَّبۡنَا ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ مِنۡهُمۡ عَذَابًا أَلِيمًا ﴾
[الفَتح: 25]
﴿هم الذين كفروا وصدوكم عن المسجد الحرام والهدي معكوفا أن يبلغ محله﴾ [الفَتح: 25]
Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni Àwọn (ọ̀ṣẹbọ) ni àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́, tí wọ́n ṣẹ yín lórí kúrò ní Mọ́sálásí Haram, tí wọ́n tún de ẹran ọrẹ mọ́lẹ̀ kí ó má lè dé àyè rẹ̀. Tí kì í bá ṣe ti àwọn ọkùnrin (tí wọ́n ti di) onígbàgbọ́ òdodo àti àwọn obìnrin (tí wọ́n ti di) onígbàgbọ́ òdodo (nínú ìlú Mọkkah), tí ẹ̀yin kò sì mọ̀ wọ́n, kí ẹ̀yin má lọ pa wọ́n, kí ẹ̀yin má lọ fara kó ẹ̀ṣẹ̀ láti ara wọn nípasẹ̀ àìmọ̀, (Allāhu ìbá tí ko yín lọ́wọ́ ró fún wọn. Allāhu ko yín lọ́wọ́ ró fún wọn sẹ́) nítorí kí Ó lè fi ẹni tí ó bá fẹ́ sínú ìkẹ́ Rẹ̀. Tí ó bá jẹ́ pé wọ́n wà ní ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni (onígbàgbọ́ òdodo lọ́tọ̀, aláìgbàgbọ́ lọ́tọ̀), Àwa ìbá jẹ àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ nínú wọn ní ìyà ẹlẹ́ta-eléro |