Quran with Yoruba translation - Surah Al-A‘raf ayat 53 - الأعرَاف - Page - Juz 8
﴿هَلۡ يَنظُرُونَ إِلَّا تَأۡوِيلَهُۥۚ يَوۡمَ يَأۡتِي تَأۡوِيلُهُۥ يَقُولُ ٱلَّذِينَ نَسُوهُ مِن قَبۡلُ قَدۡ جَآءَتۡ رُسُلُ رَبِّنَا بِٱلۡحَقِّ فَهَل لَّنَا مِن شُفَعَآءَ فَيَشۡفَعُواْ لَنَآ أَوۡ نُرَدُّ فَنَعۡمَلَ غَيۡرَ ٱلَّذِي كُنَّا نَعۡمَلُۚ قَدۡ خَسِرُوٓاْ أَنفُسَهُمۡ وَضَلَّ عَنۡهُم مَّا كَانُواْ يَفۡتَرُونَ ﴾
[الأعرَاف: 53]
﴿هل ينظرون إلا تأويله يوم يأتي تأويله يقول الذين نسوه من قبل﴾ [الأعرَاف: 53]
Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni Kí ni wọ́n ń retí bí kò ṣe ìmúṣẹ ọ̀rọ̀ Rẹ̀? Lọ́jọ́ tí ìmúṣẹ ọ̀rọ̀ Rẹ̀ bá dé, àwọn t’ó gbàgbé rẹ̀ ṣíwájú yóò wí pé: “Dájúdájú àwọn Òjíṣẹ́ Olúwa wa ti mú òdodo wá. Nítorí náà, ǹjẹ́ a lè rí àwọn olùṣìpẹ̀, kí wọ́n wá ṣìpẹ̀ fún wa tàbí kí wọ́n dá wa padà sílé ayé, kí á lè ṣe iṣẹ́ mìíràn yàtọ̀ sí èyí tí a máa ń ṣe?” Dájúdájú wọ́n ti ṣe ẹ̀mí wọn lófò. Ohun tí wọ́n sì ń dá ní àdápa irọ́ ti di òfò mọ́ wọn lọ́wọ́ |