Quran with Yoruba translation - Surah At-Taubah ayat 120 - التوبَة - Page - Juz 11
﴿مَا كَانَ لِأَهۡلِ ٱلۡمَدِينَةِ وَمَنۡ حَوۡلَهُم مِّنَ ٱلۡأَعۡرَابِ أَن يَتَخَلَّفُواْ عَن رَّسُولِ ٱللَّهِ وَلَا يَرۡغَبُواْ بِأَنفُسِهِمۡ عَن نَّفۡسِهِۦۚ ذَٰلِكَ بِأَنَّهُمۡ لَا يُصِيبُهُمۡ ظَمَأٞ وَلَا نَصَبٞ وَلَا مَخۡمَصَةٞ فِي سَبِيلِ ٱللَّهِ وَلَا يَطَـُٔونَ مَوۡطِئٗا يَغِيظُ ٱلۡكُفَّارَ وَلَا يَنَالُونَ مِنۡ عَدُوّٖ نَّيۡلًا إِلَّا كُتِبَ لَهُم بِهِۦ عَمَلٞ صَٰلِحٌۚ إِنَّ ٱللَّهَ لَا يُضِيعُ أَجۡرَ ٱلۡمُحۡسِنِينَ ﴾
[التوبَة: 120]
﴿ما كان لأهل المدينة ومن حولهم من الأعراب أن يتخلفوا عن رسول﴾ [التوبَة: 120]
Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni Kò lẹ́tọ̀ọ́ fún àwọn ará ìlú Mọdīnah àti ẹni tí ó wà ní àyíká wọn nínú àwọn Lárúbáwá oko láti sá sẹ́yìn fún Òjíṣẹ́ Allāhu (nípa ogun ẹ̀sìn. Kò sì lẹ́tọ̀ọ́ fún wọn) láti fẹ́ràn ẹ̀mí ara wọn ju ẹ̀mí rẹ̀. Ìyẹn nítorí pé dájúdájú òǹgbẹ, ìnira tàbí ebi kan kò níí ṣẹlẹ̀ sí wọn lójú ogun lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu, tàbí wọn kò níí tẹ ọ̀nà kan tí ń bí àwọn aláìgbàgbọ́ nínú, tàbí ọwọ́ wọn kò níí ba kiní kan lára ọ̀tá àfi kí Á fi kọ iṣẹ́ rere sílẹ̀ fún wọn. Dájúdájú Allāhu kò níí fi ẹ̀san àwọn olùṣe-rere ráre |