Quran with Yoruba translation - Surah At-Taubah ayat 37 - التوبَة - Page - Juz 10
﴿إِنَّمَا ٱلنَّسِيٓءُ زِيَادَةٞ فِي ٱلۡكُفۡرِۖ يُضَلُّ بِهِ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ يُحِلُّونَهُۥ عَامٗا وَيُحَرِّمُونَهُۥ عَامٗا لِّيُوَاطِـُٔواْ عِدَّةَ مَا حَرَّمَ ٱللَّهُ فَيُحِلُّواْ مَا حَرَّمَ ٱللَّهُۚ زُيِّنَ لَهُمۡ سُوٓءُ أَعۡمَٰلِهِمۡۗ وَٱللَّهُ لَا يَهۡدِي ٱلۡقَوۡمَ ٱلۡكَٰفِرِينَ ﴾
[التوبَة: 37]
﴿إنما النسيء زيادة في الكفر يضل به الذين كفروا يحلونه عاما ويحرمونه﴾ [التوبَة: 37]
Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni Àlékún nínú àìgbàgbọ́ ni dídájọ́ sí àwọn oṣù ọ̀wọ̀ (láti ọwọ́ àwọn ọ̀ṣẹbọ). Wọ́n ń fi kó ìṣìnà bá àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ (nípa pé) wọ́n ń ṣe oṣù ọ̀wọ̀ kan ní oṣù ẹ̀tọ́ (fún ogun jíjà) nínú ọdún kan, wọ́n sì ń bu ọ̀wọ̀ fún oṣù (tí kì í ṣe oṣù ọ̀wọ̀) nínú ọdún (mìíràn, wọn kò sì níí jagun nínú rẹ̀) nítorí kí wọ́n lè yọ òǹkà oṣù tí Allāhu ṣe ní ọ̀wọ̀ síra wọn. Wọ́n sì tipasẹ̀ bẹ́ẹ̀ ṣe ní ẹ̀tọ́ ohun tí Allāhu ṣe ní èèwọ̀. Wọ́n ṣe iṣẹ́ aburú wọn ní ọ̀ṣọ́ fún wọn. Allāhu kò níí fi ọ̀nà mọ ìjọ aláìgbàgbọ́ |