Quran with Yoruba translation - Surah At-Taubah ayat 74 - التوبَة - Page - Juz 10
﴿يَحۡلِفُونَ بِٱللَّهِ مَا قَالُواْ وَلَقَدۡ قَالُواْ كَلِمَةَ ٱلۡكُفۡرِ وَكَفَرُواْ بَعۡدَ إِسۡلَٰمِهِمۡ وَهَمُّواْ بِمَا لَمۡ يَنَالُواْۚ وَمَا نَقَمُوٓاْ إِلَّآ أَنۡ أَغۡنَىٰهُمُ ٱللَّهُ وَرَسُولُهُۥ مِن فَضۡلِهِۦۚ فَإِن يَتُوبُواْ يَكُ خَيۡرٗا لَّهُمۡۖ وَإِن يَتَوَلَّوۡاْ يُعَذِّبۡهُمُ ٱللَّهُ عَذَابًا أَلِيمٗا فِي ٱلدُّنۡيَا وَٱلۡأٓخِرَةِۚ وَمَا لَهُمۡ فِي ٱلۡأَرۡضِ مِن وَلِيّٖ وَلَا نَصِيرٖ ﴾
[التوبَة: 74]
﴿يحلفون بالله ما قالوا ولقد قالوا كلمة الكفر وكفروا بعد إسلامهم وهموا﴾ [التوبَة: 74]
Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni Wọ́n ń fi Allāhu búra pé àwọn kò sọ̀rọ̀ (burúkú). Wọ́n sì kúkú ti sọ ọ̀rọ̀ àìgbàgbọ́, wọ́n sì ṣàì gbàgbọ́ lẹ́yìn tí wọ́n ti gba ’Islām. Wọ́n tún gbèròkérò sí n̄ǹkan tí ọwọ́ wọn kò níí bà. Wọn kò tako kiní kan bí kò ṣe nítorí pé Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ rọ àwọn (Sọhābah) lọ́rọ̀ nínú ọlá Rẹ̀. Tí wọ́n bá ronú pìwàdà, ó máa dára fún wọn. Tí wọ́n bá sì kọ̀yìn (si yín), Allāhu yóò jẹ wọ́n níyà ẹlẹ́ta-eléro ní ayé àti ní ọ̀run. Kò sì níí sí aláàbò àti alárànṣe kan fún wọn lórí ilẹ̀ ayé |