Quran with Yoruba translation - Surah Yunus ayat 61 - يُونس - Page - Juz 11
﴿وَمَا تَكُونُ فِي شَأۡنٖ وَمَا تَتۡلُواْ مِنۡهُ مِن قُرۡءَانٖ وَلَا تَعۡمَلُونَ مِنۡ عَمَلٍ إِلَّا كُنَّا عَلَيۡكُمۡ شُهُودًا إِذۡ تُفِيضُونَ فِيهِۚ وَمَا يَعۡزُبُ عَن رَّبِّكَ مِن مِّثۡقَالِ ذَرَّةٖ فِي ٱلۡأَرۡضِ وَلَا فِي ٱلسَّمَآءِ وَلَآ أَصۡغَرَ مِن ذَٰلِكَ وَلَآ أَكۡبَرَ إِلَّا فِي كِتَٰبٖ مُّبِينٍ ﴾
[يُونس: 61]
﴿وما تكون في شأن وما تتلو منه من قرآن ولا تعملون من﴾ [يُونس: 61]
Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni Ìwọ kò níí wà nínú ìṣe kan, ìwọ kò sì níí ké (āyah kan) nínú al-Ƙur’ān, ẹ̀yin kò níí ṣe iṣẹ́ kan àfi kí Àwa jẹ́ Ẹlẹ́rìí lórí yín nígbà tí ẹ bá ń ṣe é. Kiní kan kò pamọ́ fún Olúwa rẹ; tí ó mọ ní òdiwọ̀n iná-igún nínú ilẹ̀ àti nínú sánmọ̀, kí ó tún kéré jú ìyẹn lọ tàbí kí ó tóbi jù ú lọ àfi kí ó wà nínú àkọsílẹ̀ t’ó yanjú |