الر ۚ تِلْكَ آيَاتُ الْكِتَابِ الْحَكِيمِ (1) ’Alif Lam Ro. Iwonyi ni awon ayah Tira ogbon |
أَكَانَ لِلنَّاسِ عَجَبًا أَنْ أَوْحَيْنَا إِلَىٰ رَجُلٍ مِّنْهُمْ أَنْ أَنذِرِ النَّاسَ وَبَشِّرِ الَّذِينَ آمَنُوا أَنَّ لَهُمْ قَدَمَ صِدْقٍ عِندَ رَبِّهِمْ ۗ قَالَ الْكَافِرُونَ إِنَّ هَٰذَا لَسَاحِرٌ مُّبِينٌ (2) Se o je kayefi fun awon eniyan pe A fi imisi ranse si arakunrin kan ninu won, pe: “Se ikilo fun awon eniyan, ki o si fun awon t’o gbagbo ni iro idunnu pe esan rere (ise ti won se) siwaju ti wa ni odo Oluwa won.”? Awon alaigbagbo wi pe: “Dajudaju opidan ponnbele ma ni (Anabi) yii.” |
إِنَّ رَبَّكُمُ اللَّهُ الَّذِي خَلَقَ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضَ فِي سِتَّةِ أَيَّامٍ ثُمَّ اسْتَوَىٰ عَلَى الْعَرْشِ ۖ يُدَبِّرُ الْأَمْرَ ۖ مَا مِن شَفِيعٍ إِلَّا مِن بَعْدِ إِذْنِهِ ۚ ذَٰلِكُمُ اللَّهُ رَبُّكُمْ فَاعْبُدُوهُ ۚ أَفَلَا تَذَكَّرُونَ (3) Dajudaju Oluwa yin ni Allahu, Eni ti O seda awon sanmo ati ile fun ojo mefa. Leyin naa, O gunwa si ori Ite-ola. O n seto oro (eda). Ko si olusipe kan afi leyin iyonda Re. Iyen ni Allahu, Oluwa yin. Nitori naa, e josin fun Un. Se e o nii lo iranti ni |
إِلَيْهِ مَرْجِعُكُمْ جَمِيعًا ۖ وَعْدَ اللَّهِ حَقًّا ۚ إِنَّهُ يَبْدَأُ الْخَلْقَ ثُمَّ يُعِيدُهُ لِيَجْزِيَ الَّذِينَ آمَنُوا وَعَمِلُوا الصَّالِحَاتِ بِالْقِسْطِ ۚ وَالَّذِينَ كَفَرُوا لَهُمْ شَرَابٌ مِّنْ حَمِيمٍ وَعَذَابٌ أَلِيمٌ بِمَا كَانُوا يَكْفُرُونَ (4) Odo Re ni ibupadasi gbogbo yin. (O je) adehun Allahu ni ododo. Dajudaju Oun l’O n pile dida eda. Leyin naa, O maa da a pada (sodo Re) nitori ki O le fi deede san esan fun awon t’o gbagbo ni ododo, ti won si se ise rere. Awon t’o si sai gbagbo, ohun mimu gbigbona ati iya eleta-elero n be fun won nitori pe won sai gbagbo |
هُوَ الَّذِي جَعَلَ الشَّمْسَ ضِيَاءً وَالْقَمَرَ نُورًا وَقَدَّرَهُ مَنَازِلَ لِتَعْلَمُوا عَدَدَ السِّنِينَ وَالْحِسَابَ ۚ مَا خَلَقَ اللَّهُ ذَٰلِكَ إِلَّا بِالْحَقِّ ۚ يُفَصِّلُ الْآيَاتِ لِقَوْمٍ يَعْلَمُونَ (5) (Allahu) Oun ni Eni ti O se oorun ni itansan. (O se) osupa ni imole. O si diwon (irisi) re sinu awon ibuso nitori ki e le mo onka awon odun ati isiro (ojo). Allahu ko da iyen bi ko se pelu ododo. O n salaye awon ayah fun ijo t’o nimo |
إِنَّ فِي اخْتِلَافِ اللَّيْلِ وَالنَّهَارِ وَمَا خَلَقَ اللَّهُ فِي السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ لَآيَاتٍ لِّقَوْمٍ يَتَّقُونَ (6) Dajudaju awon ami wa ninu itelentele ati iyato oru ati osan ati ohun ti Allahu da sinu awon sanmo ati ile; (ami wa ninu won) fun ijo t’o n beru (Allahu) |
إِنَّ الَّذِينَ لَا يَرْجُونَ لِقَاءَنَا وَرَضُوا بِالْحَيَاةِ الدُّنْيَا وَاطْمَأَنُّوا بِهَا وَالَّذِينَ هُمْ عَنْ آيَاتِنَا غَافِلُونَ (7) Dajudaju awon ti ko reti ipade Wa (ni orun), ti won yonu si isemi aye, ti okan won si bale dodo si (isemi aye yii) ati awon afonu-fora nipa awon ayah Wa |
أُولَٰئِكَ مَأْوَاهُمُ النَّارُ بِمَا كَانُوا يَكْسِبُونَ (8) awon wonyen, ibugbe won ni Ina nitori ohun ti won n se nise |
إِنَّ الَّذِينَ آمَنُوا وَعَمِلُوا الصَّالِحَاتِ يَهْدِيهِمْ رَبُّهُم بِإِيمَانِهِمْ ۖ تَجْرِي مِن تَحْتِهِمُ الْأَنْهَارُ فِي جَنَّاتِ النَّعِيمِ (9) Dajudaju awon t’o gbagbo ni ododo, ti won si se awon ise rere, Oluwa won yoo fi igbagbo ododo won to won sona. Awon odo yo si maa san ni isale odo won ninu Ogba Idera |
دَعْوَاهُمْ فِيهَا سُبْحَانَكَ اللَّهُمَّ وَتَحِيَّتُهُمْ فِيهَا سَلَامٌ ۚ وَآخِرُ دَعْوَاهُمْ أَنِ الْحَمْدُ لِلَّهِ رَبِّ الْعَالَمِينَ (10) Adua won ninu re ni “mimo ni fun O, Allahu”. Ikini won ninu re ni “alaafia”. Ipari adua won si ni pe “gbogbo ope n je ti Allahu, Oluwa gbogbo eda” |
۞ وَلَوْ يُعَجِّلُ اللَّهُ لِلنَّاسِ الشَّرَّ اسْتِعْجَالَهُم بِالْخَيْرِ لَقُضِيَ إِلَيْهِمْ أَجَلُهُمْ ۖ فَنَذَرُ الَّذِينَ لَا يَرْجُونَ لِقَاءَنَا فِي طُغْيَانِهِمْ يَعْمَهُونَ (11) Ti o ba je pe Allahu n kanju mu aburu ba awon eniyan (nipase epe enu won, gege bi O se n) tete mu oore ba won (nipase adua), A iba ti mu opin ba isemi won. Nitori naa, A maa fi awon ti ko reti ipade Wa sile sinu agbere won, ti won yoo maa pa ridarida |
وَإِذَا مَسَّ الْإِنسَانَ الضُّرُّ دَعَانَا لِجَنبِهِ أَوْ قَاعِدًا أَوْ قَائِمًا فَلَمَّا كَشَفْنَا عَنْهُ ضُرَّهُ مَرَّ كَأَن لَّمْ يَدْعُنَا إِلَىٰ ضُرٍّ مَّسَّهُ ۚ كَذَٰلِكَ زُيِّنَ لِلْمُسْرِفِينَ مَا كَانُوا يَعْمَلُونَ (12) Nigba ti inira ba kan eniyan, o maa pe Wa lori idubule re tabi ni ijokoo tabi ni inaro. Nigba ti A ba mu inira re kuro fun un, o maa te siwaju (ninu aigbagbo) bi eni pe ko pe Wa si inira ti o mu un. Bayen ni won se ni oso fun awon alakoyo ohun ti won n se nise |
وَلَقَدْ أَهْلَكْنَا الْقُرُونَ مِن قَبْلِكُمْ لَمَّا ظَلَمُوا ۙ وَجَاءَتْهُمْ رُسُلُهُم بِالْبَيِّنَاتِ وَمَا كَانُوا لِيُؤْمِنُوا ۚ كَذَٰلِكَ نَجْزِي الْقَوْمَ الْمُجْرِمِينَ (13) A kuku ti pa awon iran kan re siwaju yin nigba ti won se abosi. Awon Ojise won mu awon eri t’o yanju wa ba won. Won ko si gbagbo. Bayen ni A se n san ijo elese ni esan |
ثُمَّ جَعَلْنَاكُمْ خَلَائِفَ فِي الْأَرْضِ مِن بَعْدِهِمْ لِنَنظُرَ كَيْفَ تَعْمَلُونَ (14) Leyin naa, A se yin ni arole lori ile leyin won nitori ki A le wo bi eyin naa yoo se maa se |
وَإِذَا تُتْلَىٰ عَلَيْهِمْ آيَاتُنَا بَيِّنَاتٍ ۙ قَالَ الَّذِينَ لَا يَرْجُونَ لِقَاءَنَا ائْتِ بِقُرْآنٍ غَيْرِ هَٰذَا أَوْ بَدِّلْهُ ۚ قُلْ مَا يَكُونُ لِي أَنْ أُبَدِّلَهُ مِن تِلْقَاءِ نَفْسِي ۖ إِنْ أَتَّبِعُ إِلَّا مَا يُوحَىٰ إِلَيَّ ۖ إِنِّي أَخَافُ إِنْ عَصَيْتُ رَبِّي عَذَابَ يَوْمٍ عَظِيمٍ (15) Nigba ti won ba n ke awon ayah Wa, t’o yanju fun won, awon ti ko reti ipade Wa (ni orun) yoo maa wi pe: “Mu Ƙur’an kan wa yato si eyi tabi ki o yi i pada.” So pe: “Ko letoo fun mi lati yi i pada lati odo ara mi. Emi ko tele kini kan ayafi ohun ti Won fi ranse si mi ni imisi. Dajudaju emi n paya iya Ojo nla ti mo ba fi le yapa Oluwa mi.” |
قُل لَّوْ شَاءَ اللَّهُ مَا تَلَوْتُهُ عَلَيْكُمْ وَلَا أَدْرَاكُم بِهِ ۖ فَقَدْ لَبِثْتُ فِيكُمْ عُمُرًا مِّن قَبْلِهِ ۚ أَفَلَا تَعْقِلُونَ (16) So pe: “Ti o ba je pe Allahu ba fe ni, emi iba ti le ke al-Ƙur’an fun yin, ati pe Allahu iba ti fi imo re mo yin. Mo kuku ti lo awon odun kan laaarin yin siwaju (isokale) re, se e o se laakaye ni?” |
فَمَنْ أَظْلَمُ مِمَّنِ افْتَرَىٰ عَلَى اللَّهِ كَذِبًا أَوْ كَذَّبَ بِآيَاتِهِ ۚ إِنَّهُ لَا يُفْلِحُ الْمُجْرِمُونَ (17) Nitori naa, ta l’o sabosi ju eni t’o da adapa iro mo Allahu tabi t’o pe awon ayah Re niro? Dajudaju awon odaran ko nii jere |
وَيَعْبُدُونَ مِن دُونِ اللَّهِ مَا لَا يَضُرُّهُمْ وَلَا يَنفَعُهُمْ وَيَقُولُونَ هَٰؤُلَاءِ شُفَعَاؤُنَا عِندَ اللَّهِ ۚ قُلْ أَتُنَبِّئُونَ اللَّهَ بِمَا لَا يَعْلَمُ فِي السَّمَاوَاتِ وَلَا فِي الْأَرْضِ ۚ سُبْحَانَهُ وَتَعَالَىٰ عَمَّا يُشْرِكُونَ (18) Won n josin fun ohun ti ko le ko inira ba won, ti ko si le se won ni anfaani leyin Allahu. Won si n wi pe: “Awon wonyi ni olusipe wa lodo Allahu.” So pe: “Se e maa fun Allahu ni iro ohun ti ko mo ninu awon sanmo ati ile ni?” Mimo ni fun Un, O ga tayo nnkan ti won n fi sebo si I |
وَمَا كَانَ النَّاسُ إِلَّا أُمَّةً وَاحِدَةً فَاخْتَلَفُوا ۚ وَلَوْلَا كَلِمَةٌ سَبَقَتْ مِن رَّبِّكَ لَقُضِيَ بَيْنَهُمْ فِيمَا فِيهِ يَخْتَلِفُونَ (19) Ki ni awon eniyan je (ni ipile) bi ko se ijo eyo kan (ijo ’Islam). Leyin naa ni won yapa enu. Ti ko ba je pe oro kan t’o ti siwaju lodo Oluwa re, Awa iba ti yanju ohun ti won n yapa enu si laaarin ara won |
وَيَقُولُونَ لَوْلَا أُنزِلَ عَلَيْهِ آيَةٌ مِّن رَّبِّهِ ۖ فَقُلْ إِنَّمَا الْغَيْبُ لِلَّهِ فَانتَظِرُوا إِنِّي مَعَكُم مِّنَ الْمُنتَظِرِينَ (20) Won n wi pe: “Ki ni ko je ki ami kan sokale fun un lati odo Oluwa re?” Nitori naa, so pe: “Ti Allahu ni ikoko. Nitori naa, e maa reti. Dajudaju emi naa wa pelu yin ninu awon olureti.” |
وَإِذَا أَذَقْنَا النَّاسَ رَحْمَةً مِّن بَعْدِ ضَرَّاءَ مَسَّتْهُمْ إِذَا لَهُم مَّكْرٌ فِي آيَاتِنَا ۚ قُلِ اللَّهُ أَسْرَعُ مَكْرًا ۚ إِنَّ رُسُلَنَا يَكْتُبُونَ مَا تَمْكُرُونَ (21) Nigba ti A ba fun awon eniyan ni idera kan towo leyin ti inira ti fowo ba won, nigba naa ni won maa dete si awon ayah Wa. So pe: “Allahu yara julo nibi ete. Dajudaju awon Ojise Wa n se akosile ohun ti e n da lete.” |
هُوَ الَّذِي يُسَيِّرُكُمْ فِي الْبَرِّ وَالْبَحْرِ ۖ حَتَّىٰ إِذَا كُنتُمْ فِي الْفُلْكِ وَجَرَيْنَ بِهِم بِرِيحٍ طَيِّبَةٍ وَفَرِحُوا بِهَا جَاءَتْهَا رِيحٌ عَاصِفٌ وَجَاءَهُمُ الْمَوْجُ مِن كُلِّ مَكَانٍ وَظَنُّوا أَنَّهُمْ أُحِيطَ بِهِمْ ۙ دَعَوُا اللَّهَ مُخْلِصِينَ لَهُ الدِّينَ لَئِنْ أَنجَيْتَنَا مِنْ هَٰذِهِ لَنَكُونَنَّ مِنَ الشَّاكِرِينَ (22) (Allahu) Oun ni Eni ti O mu yin rin lori ile ati ni oju omi, titi di igba ti e ba wa ninu oko oju-omi, ti ategun t’o dara si n tuko won lo, inu won yo si maa dun si i. (Amo) ategun lile ko lu u, igbi omi de ba won ni gbogbo aye, won si lero pe dajudaju won ti fi (adanwo) yi awon po, won si pe Allahu pelu sise afomo-adua fun Un pe: “Dajudaju ti O ba fi le gba wa la nibi eyi, dajudaju a maa wa ninu awon oludupe.” |
فَلَمَّا أَنجَاهُمْ إِذَا هُمْ يَبْغُونَ فِي الْأَرْضِ بِغَيْرِ الْحَقِّ ۗ يَا أَيُّهَا النَّاسُ إِنَّمَا بَغْيُكُمْ عَلَىٰ أَنفُسِكُم ۖ مَّتَاعَ الْحَيَاةِ الدُّنْيَا ۖ ثُمَّ إِلَيْنَا مَرْجِعُكُمْ فَنُنَبِّئُكُم بِمَا كُنتُمْ تَعْمَلُونَ (23) Sugbon nigba ti O gba won la tan igba naa ni won tun n se ibaje kiri lori ile lai letoo. Eyin eniyan, dajudaju ibaje yin n be lori yin. (Ibaje yin si je) igbadun isemi aye. Leyin naa, odo Wa ni ibupadasi yin. A si maa fun yin ni iro ohun ti e n se nise |
إِنَّمَا مَثَلُ الْحَيَاةِ الدُّنْيَا كَمَاءٍ أَنزَلْنَاهُ مِنَ السَّمَاءِ فَاخْتَلَطَ بِهِ نَبَاتُ الْأَرْضِ مِمَّا يَأْكُلُ النَّاسُ وَالْأَنْعَامُ حَتَّىٰ إِذَا أَخَذَتِ الْأَرْضُ زُخْرُفَهَا وَازَّيَّنَتْ وَظَنَّ أَهْلُهَا أَنَّهُمْ قَادِرُونَ عَلَيْهَا أَتَاهَا أَمْرُنَا لَيْلًا أَوْ نَهَارًا فَجَعَلْنَاهَا حَصِيدًا كَأَن لَّمْ تَغْنَ بِالْأَمْسِ ۚ كَذَٰلِكَ نُفَصِّلُ الْآيَاتِ لِقَوْمٍ يَتَفَكَّرُونَ (24) Apejuwe isemi aye da bi omi kan ti A sokale lati sanmo, ti awon irugbin ninu ohun ti eniyan ati awon eran-osin n je si gba a sara, titi di igba ti ile yoo fi loraa. O si mu oso (ara) re jade. Awon t’o ni i si lero pe awon ni alagbara lori re, (nigba naa ni) ase Wa de ba a ni oru tabi ni osan. A si so o di oko ti won fa tu danu bi eni pe ko si nibe rara ri ni ana. Bayen ni A se n salaye awon ayah fun ijo alarojinle |
وَاللَّهُ يَدْعُو إِلَىٰ دَارِ السَّلَامِ وَيَهْدِي مَن يَشَاءُ إِلَىٰ صِرَاطٍ مُّسْتَقِيمٍ (25) Allahu n pepe si ile Alaafia. O si n to eni ti O ba fe si ona taara (’Islam) |
۞ لِّلَّذِينَ أَحْسَنُوا الْحُسْنَىٰ وَزِيَادَةٌ ۖ وَلَا يَرْهَقُ وُجُوهَهُمْ قَتَرٌ وَلَا ذِلَّةٌ ۚ أُولَٰئِكَ أَصْحَابُ الْجَنَّةِ ۖ هُمْ فِيهَا خَالِدُونَ (26) Rere ati alekun (oore) wa fun awon t’o se rere. Eruku tabi iyepere kan ko nii bo won loju mole. Awon wonyen ni ero inu Ogba Idera. Olusegbere ni won ninu re |
وَالَّذِينَ كَسَبُوا السَّيِّئَاتِ جَزَاءُ سَيِّئَةٍ بِمِثْلِهَا وَتَرْهَقُهُمْ ذِلَّةٌ ۖ مَّا لَهُم مِّنَ اللَّهِ مِنْ عَاصِمٍ ۖ كَأَنَّمَا أُغْشِيَتْ وُجُوهُهُمْ قِطَعًا مِّنَ اللَّيْلِ مُظْلِمًا ۚ أُولَٰئِكَ أَصْحَابُ النَّارِ ۖ هُمْ فِيهَا خَالِدُونَ (27) Awon t’o si s’ise aburu, esan aburu bi iru re (ni esan won). Iyepere si maa bo won mole. Ko si alaabo kan fun won lodo Allahu. (Won maa da bi) eni pe won fi apa kan oru t’o sokunkun bo won loju pa. Awon wonyen ni ero inu Ina. Olusegbere ni won ninu re |
وَيَوْمَ نَحْشُرُهُمْ جَمِيعًا ثُمَّ نَقُولُ لِلَّذِينَ أَشْرَكُوا مَكَانَكُمْ أَنتُمْ وَشُرَكَاؤُكُمْ ۚ فَزَيَّلْنَا بَيْنَهُمْ ۖ وَقَالَ شُرَكَاؤُهُم مَّا كُنتُمْ إِيَّانَا تَعْبُدُونَ (28) Ati pe (ranti) Ojo ti A oo ko gbogbo won jo, leyin naa A oo so fun awon t’o ba Allahu wa akegbe pe: “E duro pa si aye yin, eyin ati awon orisa yin.” Nitori naa, A ya won si otooto. Awon orisa won si wi pe: “Awa ko ni e n josin fun |
فَكَفَىٰ بِاللَّهِ شَهِيدًا بَيْنَنَا وَبَيْنَكُمْ إِن كُنَّا عَنْ عِبَادَتِكُمْ لَغَافِلِينَ (29) Nitori naa, Allahu to ni Elerii laaarin awa ati eyin pe awa je alaimo nipa ijosin yin (ti e se fun wa).” |
هُنَالِكَ تَبْلُو كُلُّ نَفْسٍ مَّا أَسْلَفَتْ ۚ وَرُدُّوا إِلَى اللَّهِ مَوْلَاهُمُ الْحَقِّ ۖ وَضَلَّ عَنْهُم مَّا كَانُوا يَفْتَرُونَ (30) Nibe yen, emi kookan maa da ohun t’o se siwaju mo. Won yo si da won pada sodo Allahu, Oluwa won, Ododo. Ohun ti won si n da ni adapa iro si maa dofo mo won lowo |
قُلْ مَن يَرْزُقُكُم مِّنَ السَّمَاءِ وَالْأَرْضِ أَمَّن يَمْلِكُ السَّمْعَ وَالْأَبْصَارَ وَمَن يُخْرِجُ الْحَيَّ مِنَ الْمَيِّتِ وَيُخْرِجُ الْمَيِّتَ مِنَ الْحَيِّ وَمَن يُدَبِّرُ الْأَمْرَ ۚ فَسَيَقُولُونَ اللَّهُ ۚ فَقُلْ أَفَلَا تَتَّقُونَ (31) So pe: “Ta ni O n pese fun yin lati inu sanmo ati ile? Ta ni O ni ikapa lori igboro ati iriran? Ta ni O n mu alaaye jade lati ara oku, ti O tun n mu oku jade lati ara alaaye? Ta si ni O n se eto oro (eda)?” Won yoo wi pe: "Allahu" Nigba naa, so pe: "Se e o nii beru (Re) ni |
فَذَٰلِكُمُ اللَّهُ رَبُّكُمُ الْحَقُّ ۖ فَمَاذَا بَعْدَ الْحَقِّ إِلَّا الضَّلَالُ ۖ فَأَنَّىٰ تُصْرَفُونَ (32) Iyen ni Allahu, Oluwa yin, Ododo. Ki si ni o n be leyin Ododo bi ko se isina? Nitori naa, bawo ni won se n seri yin kuro nibi ododo |
كَذَٰلِكَ حَقَّتْ كَلِمَتُ رَبِّكَ عَلَى الَّذِينَ فَسَقُوا أَنَّهُمْ لَا يُؤْمِنُونَ (33) Bayen ni oro Oluwa re se wa si imuse lori awon t’o sebaje pe dajudaju won ko nii gbagbo |
قُلْ هَلْ مِن شُرَكَائِكُم مَّن يَبْدَأُ الْخَلْقَ ثُمَّ يُعِيدُهُ ۚ قُلِ اللَّهُ يَبْدَأُ الْخَلْقَ ثُمَّ يُعِيدُهُ ۖ فَأَنَّىٰ تُؤْفَكُونَ (34) So pe: "Nje o wa ninu awon orisa yin eni ti o le pile dida eda, leyin naa, ti o maa da a pada (si ipile re leyin iku)?" So pe: "Allahu l’O n pile dida eda. Leyin naa, O maa da a pada (si ipile re leyin iku). Nitori naa, bawo ni won se n seri yin kuro nibi ododo |
قُلْ هَلْ مِن شُرَكَائِكُم مَّن يَهْدِي إِلَى الْحَقِّ ۚ قُلِ اللَّهُ يَهْدِي لِلْحَقِّ ۗ أَفَمَن يَهْدِي إِلَى الْحَقِّ أَحَقُّ أَن يُتَّبَعَ أَمَّن لَّا يَهِدِّي إِلَّا أَن يُهْدَىٰ ۖ فَمَا لَكُمْ كَيْفَ تَحْكُمُونَ (35) So pe: "Nje o wa ninu awon orisa yin eni t’o n fini mona sibi ododo?" So pe: “Allahu l’O n fini mona sibi ododo. Nigba naa, se Eni t’O n fini mona sibi ododo l’o letoo julo si pe ki won maa tele ni tabi eni ti ko le da ona mo funra re afi ti A ba fi mona?” Nitori naa, ki l’o n se yin ti e fi n dajo bayii |
وَمَا يَتَّبِعُ أَكْثَرُهُمْ إِلَّا ظَنًّا ۚ إِنَّ الظَّنَّ لَا يُغْنِي مِنَ الْحَقِّ شَيْئًا ۚ إِنَّ اللَّهَ عَلِيمٌ بِمَا يَفْعَلُونَ (36) Opolopo won ko si ri kini kan tele bi ko se aroso. Dajudaju aroso ko si le roro kini kan niwaju ododo. Dajudaju Allahu ni Onimo nipa ohun ti won n se nise |
وَمَا كَانَ هَٰذَا الْقُرْآنُ أَن يُفْتَرَىٰ مِن دُونِ اللَّهِ وَلَٰكِن تَصْدِيقَ الَّذِي بَيْنَ يَدَيْهِ وَتَفْصِيلَ الْكِتَابِ لَا رَيْبَ فِيهِ مِن رَّبِّ الْعَالَمِينَ (37) Al-Ƙur’an yii ki i se nnkan ti o se e dahun (lati odo elomiiran) leyin Allahu, sugbon o n jerii si eyi t’o je ododo ninu eyi t’o siwaju re, o n se alaye (awon) Tira naa. Ko si iyemeji ninu re. (O wa) lati odo Oluwa gbogbo eda |
أَمْ يَقُولُونَ افْتَرَاهُ ۖ قُلْ فَأْتُوا بِسُورَةٍ مِّثْلِهِ وَادْعُوا مَنِ اسْتَطَعْتُم مِّن دُونِ اللَّهِ إِن كُنتُمْ صَادِقِينَ (38) Tabi won n wi pe: "O hun un ni? So pe: "E mu surah kan bi iru re wa. Ki e si pe enikeni ti e ba le pe leyin Allahu, ti e ba je olododo |
بَلْ كَذَّبُوا بِمَا لَمْ يُحِيطُوا بِعِلْمِهِ وَلَمَّا يَأْتِهِمْ تَأْوِيلُهُ ۚ كَذَٰلِكَ كَذَّبَ الَّذِينَ مِن قَبْلِهِمْ ۖ فَانظُرْ كَيْفَ كَانَ عَاقِبَةُ الظَّالِمِينَ (39) Ko ri bee, won pe ohun ti won ko ni imo re niro ni. Ati pe imuse oro Re ko ti i de ba won (ni won fi pe e niro). Bayen ni awon t’o siwaju won se pe (oro Allahu) niro. Nitori naa, wo bi atubotan awon alabosi se ri |
وَمِنْهُم مَّن يُؤْمِنُ بِهِ وَمِنْهُم مَّن لَّا يُؤْمِنُ بِهِ ۚ وَرَبُّكَ أَعْلَمُ بِالْمُفْسِدِينَ (40) O si n be ninu won eni t’o gba a gbo ni ododo. O tun n be ninu won eni ti ko gba a gbo. Oluwa re si ni Onimo-julo nipa awon obileje |
وَإِن كَذَّبُوكَ فَقُل لِّي عَمَلِي وَلَكُمْ عَمَلُكُمْ ۖ أَنتُم بَرِيئُونَ مِمَّا أَعْمَلُ وَأَنَا بَرِيءٌ مِّمَّا تَعْمَلُونَ (41) Ti won ba pe o ni opuro, so pe: “Temi ni ise mi. Tiyin ni ise yin. Eyin yowo yose ninu ohun ti mo n se nise. Emi naa si yowo yose ninu ohun ti e n se nise.” |
وَمِنْهُم مَّن يَسْتَمِعُونَ إِلَيْكَ ۚ أَفَأَنتَ تُسْمِعُ الصُّمَّ وَلَوْ كَانُوا لَا يَعْقِلُونَ (42) O si wa ninu won, awon t’o n teti si o. Se iwo l’o maa mu aditi gboro ni, bi o tile je pe won ki i se laakaye |
وَمِنْهُم مَّن يَنظُرُ إِلَيْكَ ۚ أَفَأَنتَ تَهْدِي الْعُمْيَ وَلَوْ كَانُوا لَا يُبْصِرُونَ (43) O tun n be ninu won eni t’o n wo o. Se iwo l’o maa fi afoju mona ni, bi o tile je pe won ki i riran |
إِنَّ اللَّهَ لَا يَظْلِمُ النَّاسَ شَيْئًا وَلَٰكِنَّ النَّاسَ أَنفُسَهُمْ يَظْلِمُونَ (44) Dajudaju Allahu ko nii fi kini kan sabosi si eniyan. Sugbon eniyan n sabosi si emi ara won |
وَيَوْمَ يَحْشُرُهُمْ كَأَن لَّمْ يَلْبَثُوا إِلَّا سَاعَةً مِّنَ النَّهَارِ يَتَعَارَفُونَ بَيْنَهُمْ ۚ قَدْ خَسِرَ الَّذِينَ كَذَّبُوا بِلِقَاءِ اللَّهِ وَمَا كَانُوا مُهْتَدِينَ (45) Ati pe (ranti) Ojo ti (Allahu) yoo ko won jo afi bi eni pe won ko gbe ile aye ju akoko kan ninu osan. Won yo si dara won mo. Dajudaju awon t’o pe ipade Allahu niro ti sofo; won ko si je olumona |
وَإِمَّا نُرِيَنَّكَ بَعْضَ الَّذِي نَعِدُهُمْ أَوْ نَتَوَفَّيَنَّكَ فَإِلَيْنَا مَرْجِعُهُمْ ثُمَّ اللَّهُ شَهِيدٌ عَلَىٰ مَا يَفْعَلُونَ (46) O see se ki A fi apa kan eyi ti A se ni ileri fun won han o tabi ki A ti gba emi re (siwaju asiko naa), odo Wa kuku ni ibupadasi won. Leyin naa, Allahu ni Arinu-rode ohun ti won n se nise |
وَلِكُلِّ أُمَّةٍ رَّسُولٌ ۖ فَإِذَا جَاءَ رَسُولُهُمْ قُضِيَ بَيْنَهُم بِالْقِسْطِ وَهُمْ لَا يُظْلَمُونَ (47) Ojise ti wa fun ijo kookan. Nitori naa, nigba ti Ojise won ba de, A oo sedajo laaarin won pelu deede; A o si nii sabosi si won |
وَيَقُولُونَ مَتَىٰ هَٰذَا الْوَعْدُ إِن كُنتُمْ صَادِقِينَ (48) Won n wi pe: “Igba wo ni adehun yii yoo se ti e ba je olododo?” |
قُل لَّا أَمْلِكُ لِنَفْسِي ضَرًّا وَلَا نَفْعًا إِلَّا مَا شَاءَ اللَّهُ ۗ لِكُلِّ أُمَّةٍ أَجَلٌ ۚ إِذَا جَاءَ أَجَلُهُمْ فَلَا يَسْتَأْخِرُونَ سَاعَةً ۖ وَلَا يَسْتَقْدِمُونَ (49) So pe: “Emi ko ni ikapa inira tabi oore kan fun emi ara mi afi ohun ti Allahu ba fe. Gbedeke akoko ti wa fun ijo kookan. Nigba ti akoko naa ba de, won ko nii sun un siwaju di akoko kan, won ko si nii fa a seyin.” |
قُلْ أَرَأَيْتُمْ إِنْ أَتَاكُمْ عَذَابُهُ بَيَاتًا أَوْ نَهَارًا مَّاذَا يَسْتَعْجِلُ مِنْهُ الْمُجْرِمُونَ (50) So pe: "E so fun mi, ti iya Re ba de ba yin ni oru tabi ni osan? Ewo ninu re ni awon elese n wa pelu ikanju?” |
أَثُمَّ إِذَا مَا وَقَعَ آمَنتُم بِهِ ۚ آلْآنَ وَقَدْ كُنتُم بِهِ تَسْتَعْجِلُونَ (51) Se leyin igba ti o ba sele tan ni e maa gba a gbo? Se nisinsin yii (ni e oo gba a gbo), ti e si kuku ti n wa a pelu ikanju |
ثُمَّ قِيلَ لِلَّذِينَ ظَلَمُوا ذُوقُوا عَذَابَ الْخُلْدِ هَلْ تُجْزَوْنَ إِلَّا بِمَا كُنتُمْ تَكْسِبُونَ (52) Leyin naa, A oo so fun awon t’o sabosi pe: “E to iya gbere wo.” Se A oo san yin ni esan kan bi ko se ohun ti e n se nise |
۞ وَيَسْتَنبِئُونَكَ أَحَقٌّ هُوَ ۖ قُلْ إِي وَرَبِّي إِنَّهُ لَحَقٌّ ۖ وَمَا أَنتُم بِمُعْجِزِينَ (53) Won si n beere fun iro re lodo re pe, “se ododo ni?” So pe: “Bee ni. Mo fi Oluwa mi bura. Dajudaju ododo ni. Eyin ko si nii mori bo.” |
وَلَوْ أَنَّ لِكُلِّ نَفْسٍ ظَلَمَتْ مَا فِي الْأَرْضِ لَافْتَدَتْ بِهِ ۗ وَأَسَرُّوا النَّدَامَةَ لَمَّا رَأَوُا الْعَذَابَ ۖ وَقُضِيَ بَيْنَهُم بِالْقِسْطِ ۚ وَهُمْ لَا يُظْلَمُونَ (54) Ati pe ti o ba je pe gbogbo nnkan ti n be lori ile je ti emi kookan t’o sabosi, iba fi serapada (fun emi ara won nibi iya). Won yoo fi igbe abamo pamo nigba ti won ba ri Iya. A o se idajo laaarin won pelu deede; Won ko si nii sabosi si won |
أَلَا إِنَّ لِلَّهِ مَا فِي السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ ۗ أَلَا إِنَّ وَعْدَ اللَّهِ حَقٌّ وَلَٰكِنَّ أَكْثَرَهُمْ لَا يَعْلَمُونَ (55) Gbo, dajudaju ti Allahu ni ohunkohun t’o wa ninu awon sanmo ati ile. Gbo! Dajudaju adehun Allahu ni ododo, sugbon opolopo won ko nimo |
هُوَ يُحْيِي وَيُمِيتُ وَإِلَيْهِ تُرْجَعُونَ (56) O n so eda di alaaye. O si n so eda di oku. Odo Re si ni won yoo da yin pada si |
يَا أَيُّهَا النَّاسُ قَدْ جَاءَتْكُم مَّوْعِظَةٌ مِّن رَّبِّكُمْ وَشِفَاءٌ لِّمَا فِي الصُّدُورِ وَهُدًى وَرَحْمَةٌ لِّلْمُؤْمِنِينَ (57) Eyin eniyan, isiti kan lati odo Oluwa yin ti de ba yin. Iwosan ni fun nnkan t’o wa ninu awon igba-aya eda. Imona ati ike ni fun awon onigbagbo ododo |
قُلْ بِفَضْلِ اللَّهِ وَبِرَحْمَتِهِ فَبِذَٰلِكَ فَلْيَفْرَحُوا هُوَ خَيْرٌ مِّمَّا يَجْمَعُونَ (58) So pe: “Pelu ajulo oore Allahu (iyen, al-Ƙur’an) ati aanu Re (iyen, ’Islam), nitori iyen ni ki won maa fi dunnu; o si loore julo si ohun ti awon (alaigbagbo) n ko jo (ninu oore aye).” |
قُلْ أَرَأَيْتُم مَّا أَنزَلَ اللَّهُ لَكُم مِّن رِّزْقٍ فَجَعَلْتُم مِّنْهُ حَرَامًا وَحَلَالًا قُلْ آللَّهُ أَذِنَ لَكُمْ ۖ أَمْ عَلَى اللَّهِ تَفْتَرُونَ (59) So pe: “E so fun mi nipa awon nnkan ti Allahu sokale fun yin ninu arisiki, ti eyin funra yin se awon kan ni eewo ati eto. Se Allahu l’O yonda fun yin ni tabi e n da adapa iro mo Allahu?” |
وَمَا ظَنُّ الَّذِينَ يَفْتَرُونَ عَلَى اللَّهِ الْكَذِبَ يَوْمَ الْقِيَامَةِ ۗ إِنَّ اللَّهَ لَذُو فَضْلٍ عَلَى النَّاسِ وَلَٰكِنَّ أَكْثَرَهُمْ لَا يَشْكُرُونَ (60) Ki ni ero-okan awon t’o n da adapa iro mo Allahu ni Ojo Ajinde na? Dajudaju Allahu ni Olola-julo lori awon eniyan, sugbon opolopo won ni ki i dupe (fun Un) |
وَمَا تَكُونُ فِي شَأْنٍ وَمَا تَتْلُو مِنْهُ مِن قُرْآنٍ وَلَا تَعْمَلُونَ مِنْ عَمَلٍ إِلَّا كُنَّا عَلَيْكُمْ شُهُودًا إِذْ تُفِيضُونَ فِيهِ ۚ وَمَا يَعْزُبُ عَن رَّبِّكَ مِن مِّثْقَالِ ذَرَّةٍ فِي الْأَرْضِ وَلَا فِي السَّمَاءِ وَلَا أَصْغَرَ مِن ذَٰلِكَ وَلَا أَكْبَرَ إِلَّا فِي كِتَابٍ مُّبِينٍ (61) Iwo ko nii wa ninu ise kan, iwo ko si nii ke (ayah kan) ninu al-Ƙur’an, eyin ko nii se ise kan afi ki Awa je Elerii lori yin nigba ti e ba n se e. Kini kan ko pamo fun Oluwa re; ti o mo ni odiwon ina-igun ninu ile ati ninu sanmo, ki o tun kere ju iyen lo tabi ki o tobi ju u lo afi ki o wa ninu akosile t’o yanju |
أَلَا إِنَّ أَوْلِيَاءَ اللَّهِ لَا خَوْفٌ عَلَيْهِمْ وَلَا هُمْ يَحْزَنُونَ (62) Gbo, dajudaju awon ore Allahu, ko nii si iberu (iya orun) fun won, won ko si nii banuje (lori oore aye) |
الَّذِينَ آمَنُوا وَكَانُوا يَتَّقُونَ (63) (Awon ni) awon t’o gbagbo lododo, won si maa n beru (Allahu) |
لَهُمُ الْبُشْرَىٰ فِي الْحَيَاةِ الدُّنْيَا وَفِي الْآخِرَةِ ۚ لَا تَبْدِيلَ لِكَلِمَاتِ اللَّهِ ۚ ذَٰلِكَ هُوَ الْفَوْزُ الْعَظِيمُ (64) Ti won ni iro idunnu ninu isemi aye (yii) ati ni Ojo Ikeyin. Ko si iyipada kan fun awon oro Allahu. Iyen, ohun ni erenje nla |
وَلَا يَحْزُنكَ قَوْلُهُمْ ۘ إِنَّ الْعِزَّةَ لِلَّهِ جَمِيعًا ۚ هُوَ السَّمِيعُ الْعَلِيمُ (65) Ma se je ki oro (enu) won ba o ninu je. Dajudaju gbogbo agbara patapata n je ti Allahu. Oun ni Olugbo, Onimo |
أَلَا إِنَّ لِلَّهِ مَن فِي السَّمَاوَاتِ وَمَن فِي الْأَرْضِ ۗ وَمَا يَتَّبِعُ الَّذِينَ يَدْعُونَ مِن دُونِ اللَّهِ شُرَكَاءَ ۚ إِن يَتَّبِعُونَ إِلَّا الظَّنَّ وَإِنْ هُمْ إِلَّا يَخْرُصُونَ (66) Gbo, dajudaju ti Allahu ni enikeni t’o n be ninu awon sanmo ati enikeni t’o n be lori ile. Ki ni awon t’o n pe awon orisa leyin Allahu n tele na? Won ko tele (kini kan) bi ko se aroso. Won ko si se kini kan bi ko se pe won n paro |
هُوَ الَّذِي جَعَلَ لَكُمُ اللَّيْلَ لِتَسْكُنُوا فِيهِ وَالنَّهَارَ مُبْصِرًا ۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَآيَاتٍ لِّقَوْمٍ يَسْمَعُونَ (67) Oun ni Eni t’O se oru fun yin nitori ki e le sinmi ninu re. (O se) osan ni (asiko) ti e oo riran (kedere). Dajudaju awon ami wa ninu iyen fun ijo t’o n gboro (ododo) |
قَالُوا اتَّخَذَ اللَّهُ وَلَدًا ۗ سُبْحَانَهُ ۖ هُوَ الْغَنِيُّ ۖ لَهُ مَا فِي السَّمَاوَاتِ وَمَا فِي الْأَرْضِ ۚ إِنْ عِندَكُم مِّن سُلْطَانٍ بِهَٰذَا ۚ أَتَقُولُونَ عَلَى اللَّهِ مَا لَا تَعْلَمُونَ (68) Won wi pe: “Allahu so eda di omo.” - Mimo ni fun Un. Oun ni Oluroro. TiRe ni ohunkohun t’o wa ninu awon sanmo ati ohunkohun t’o wa ninu ile. – Ko si eri kan lodo yin fun eyi. Se e fe safiti ohun ti e o nimo nipa re sodo Allahu ni |
قُلْ إِنَّ الَّذِينَ يَفْتَرُونَ عَلَى اللَّهِ الْكَذِبَ لَا يُفْلِحُونَ (69) So pe: “Dajudaju awon t’o n da adapa iro mo Allahu, won ko nii jere.” |
مَتَاعٌ فِي الدُّنْيَا ثُمَّ إِلَيْنَا مَرْجِعُهُمْ ثُمَّ نُذِيقُهُمُ الْعَذَابَ الشَّدِيدَ بِمَا كَانُوا يَكْفُرُونَ (70) Igbadun bin-intin (le wa fun won) nile aye. Leyin naa, odo Wa ni ibupadasi won. Leyin naa, A oo fun won ni iya lile to wo nitori pe won n sai gbagbo |
۞ وَاتْلُ عَلَيْهِمْ نَبَأَ نُوحٍ إِذْ قَالَ لِقَوْمِهِ يَا قَوْمِ إِن كَانَ كَبُرَ عَلَيْكُم مَّقَامِي وَتَذْكِيرِي بِآيَاتِ اللَّهِ فَعَلَى اللَّهِ تَوَكَّلْتُ فَأَجْمِعُوا أَمْرَكُمْ وَشُرَكَاءَكُمْ ثُمَّ لَا يَكُنْ أَمْرُكُمْ عَلَيْكُمْ غُمَّةً ثُمَّ اقْضُوا إِلَيَّ وَلَا تُنظِرُونِ (71) Ka iroyin (Anabi) Nuh fun won. Nigba ti o so fun ijo re pe: “Eyin eniyan mi, ti o ba je pe iduro mi (pelu yin) ati bi mo se n fi awon ayah Allahu se isiti fun yin ba lagbara lara yin, nigba naa Allahu ni mo gbarale. Nitori naa, e pa imoran yin po, (ki e si ke pe) awon orisa yin. Leyin naa, ki ipinnu oro yin ma se wa ni bonkele laaarin yin. Leyin naa, ki e yanju oro mi. Ki e si ma se lo mi lara mo |
فَإِن تَوَلَّيْتُمْ فَمَا سَأَلْتُكُم مِّنْ أَجْرٍ ۖ إِنْ أَجْرِيَ إِلَّا عَلَى اللَّهِ ۖ وَأُمِرْتُ أَنْ أَكُونَ مِنَ الْمُسْلِمِينَ (72) Ti e ba si koyin (si iranti), emi ko kuku toro owo-oya kan lowo yin. Ko si esan kan fun mi (nibi kan) bi ko se lodo Allahu. Won si ti pa mi lase pe ki ng wa ninu awon musulumi.” |
فَكَذَّبُوهُ فَنَجَّيْنَاهُ وَمَن مَّعَهُ فِي الْفُلْكِ وَجَعَلْنَاهُمْ خَلَائِفَ وَأَغْرَقْنَا الَّذِينَ كَذَّبُوا بِآيَاتِنَا ۖ فَانظُرْ كَيْفَ كَانَ عَاقِبَةُ الْمُنذَرِينَ (73) Nigba naa, won pe e ni opuro. Nitori naa, A gba a la, oun ati awon t’o n be pelu re ninu oko oju-omi. A si se won ni arole (lori ile). A si te awon t’o pe ayah Wa niro ri sinu agbami. Nitori naa, wo bi ikangun awon eni-akilo-fun se ri |
ثُمَّ بَعَثْنَا مِن بَعْدِهِ رُسُلًا إِلَىٰ قَوْمِهِمْ فَجَاءُوهُم بِالْبَيِّنَاتِ فَمَا كَانُوا لِيُؤْمِنُوا بِمَا كَذَّبُوا بِهِ مِن قَبْلُ ۚ كَذَٰلِكَ نَطْبَعُ عَلَىٰ قُلُوبِ الْمُعْتَدِينَ (74) Leyin naa, A gbe awon Ojise kan dide si awon ijo won. Won si mu awon eri t’o yanju wa ba won. Awon naa ko kuku gbagbo ninu ohun ti (ijo Anabi Nuh) pe niro siwaju (won, iyen ni pe, iru kan-un ni won). Bayen ni A se n fi edidi bo okan awon alakoyo |
ثُمَّ بَعَثْنَا مِن بَعْدِهِم مُّوسَىٰ وَهَارُونَ إِلَىٰ فِرْعَوْنَ وَمَلَئِهِ بِآيَاتِنَا فَاسْتَكْبَرُوا وَكَانُوا قَوْمًا مُّجْرِمِينَ (75) Leyin naa, leyin won A fi awon ami Wa ran (Anabi) Musa ati Harun nise si Fir‘aon ati awon ijoye re. Nigba naa, won segberaga. Won si je ijo elese |
فَلَمَّا جَاءَهُمُ الْحَقُّ مِنْ عِندِنَا قَالُوا إِنَّ هَٰذَا لَسِحْرٌ مُّبِينٌ (76) Nigba ti ododo de ba won lati odo Wa, won wi pe: “Dajudaju eyi ni idan ponnbele.” |
قَالَ مُوسَىٰ أَتَقُولُونَ لِلْحَقِّ لَمَّا جَاءَكُمْ ۖ أَسِحْرٌ هَٰذَا وَلَا يُفْلِحُ السَّاحِرُونَ (77) (Anabi) Musa so pe: "Se nnkan ti eyin yoo maa wi nipa ododo ni pe idan ni nigba ti o de ba yin? Se idan si ni eyi bi? Awon opidan ko si nii jere |
قَالُوا أَجِئْتَنَا لِتَلْفِتَنَا عَمَّا وَجَدْنَا عَلَيْهِ آبَاءَنَا وَتَكُونَ لَكُمَا الْكِبْرِيَاءُ فِي الْأَرْضِ وَمَا نَحْنُ لَكُمَا بِمُؤْمِنِينَ (78) Won wi pe: “Se o wa ba wa nitori ki o le seri wa kuro nibi ohun ti a ba awon baba wa lori re (ninu iborisa) ati nitori ki titobi si le je teyin mejeeji lori ile? Awa ko si nii gba eyin mejeeji gbo.” |
وَقَالَ فِرْعَوْنُ ائْتُونِي بِكُلِّ سَاحِرٍ عَلِيمٍ (79) Fir‘aon wi pe: “E lo mu gbogbo awon onimo nipa idan pipa wa fun mi.” |
فَلَمَّا جَاءَ السَّحَرَةُ قَالَ لَهُم مُّوسَىٰ أَلْقُوا مَا أَنتُم مُّلْقُونَ (80) Nigba ti awon opidan si de, (Anabi) Musa so fun won pe: “E ju ohun ti e maa ju sile.” |
فَلَمَّا أَلْقَوْا قَالَ مُوسَىٰ مَا جِئْتُم بِهِ السِّحْرُ ۖ إِنَّ اللَّهَ سَيُبْطِلُهُ ۖ إِنَّ اللَّهَ لَا يُصْلِحُ عَمَلَ الْمُفْسِدِينَ (81) Nigba ti won ju u sile, (Anabi) Musa so pe: “Idan ni ohun ti e mu wa. Dajudaju Allahu si maa ba a je. Dajudaju Allahu ko si nii satunse ise awon obileje |
وَيُحِقُّ اللَّهُ الْحَقَّ بِكَلِمَاتِهِ وَلَوْ كَرِهَ الْمُجْرِمُونَ (82) Allahu si maa mu ododo se pelu awon oro Re, awon elese ibaa korira re |
فَمَا آمَنَ لِمُوسَىٰ إِلَّا ذُرِّيَّةٌ مِّن قَوْمِهِ عَلَىٰ خَوْفٍ مِّن فِرْعَوْنَ وَمَلَئِهِمْ أَن يَفْتِنَهُمْ ۚ وَإِنَّ فِرْعَوْنَ لَعَالٍ فِي الْأَرْضِ وَإِنَّهُ لَمِنَ الْمُسْرِفِينَ (83) Nitori naa, ko si eni t’o gba (Anabi) Musa gbo afi awon aromodomo kan ninu awon eniyan re pelu iberu-bojo (won) si Fir‘aon ati awon ijoye won pe o maa fooro awon. Dajudaju Fir‘aon kuku segberaga lori ile. Ati pe, dajudaju o wa ninu awon alakoyo |
وَقَالَ مُوسَىٰ يَا قَوْمِ إِن كُنتُمْ آمَنتُم بِاللَّهِ فَعَلَيْهِ تَوَكَّلُوا إِن كُنتُم مُّسْلِمِينَ (84) (Anabi) Musa so pe: “Eyin eniyan mi, ti e ba je eni t’o gbagbo ninu Allahu, Oun naa ni ki e gbarale ti e ba je musulumi.” |
فَقَالُوا عَلَى اللَّهِ تَوَكَّلْنَا رَبَّنَا لَا تَجْعَلْنَا فِتْنَةً لِّلْقَوْمِ الظَّالِمِينَ (85) Nitori naa, won so pe: "Allahu la gbarale. Oluwa wa, ma se wa ni adanwo fun ijo alabosi |
وَنَجِّنَا بِرَحْمَتِكَ مِنَ الْقَوْمِ الْكَافِرِينَ (86) Ki O si fi aanu Re gba wa la lowo ijo alaigbagbo |
وَأَوْحَيْنَا إِلَىٰ مُوسَىٰ وَأَخِيهِ أَن تَبَوَّآ لِقَوْمِكُمَا بِمِصْرَ بُيُوتًا وَاجْعَلُوا بُيُوتَكُمْ قِبْلَةً وَأَقِيمُوا الصَّلَاةَ ۗ وَبَشِّرِ الْمُؤْمِنِينَ (87) A si ranse si (Anabi) Musa ati arakunrin re pe: “Ki eyin mejeeji mu awon ibugbe fun awon eniyan yin si ilu Misro. Ki e si so ibugbe yin di ibukirun. Ki e si maa kirun. Ati pe, fun awon onigbagbo ododo ni iro idunnu.” |
وَقَالَ مُوسَىٰ رَبَّنَا إِنَّكَ آتَيْتَ فِرْعَوْنَ وَمَلَأَهُ زِينَةً وَأَمْوَالًا فِي الْحَيَاةِ الدُّنْيَا رَبَّنَا لِيُضِلُّوا عَن سَبِيلِكَ ۖ رَبَّنَا اطْمِسْ عَلَىٰ أَمْوَالِهِمْ وَاشْدُدْ عَلَىٰ قُلُوبِهِمْ فَلَا يُؤْمِنُوا حَتَّىٰ يَرَوُا الْعَذَابَ الْأَلِيمَ (88) (Anabi) Musa so pe: "Oluwa wa, dajudaju Iwo l’O fun Fir‘aon ati awon ijoye re ni oso ati dukia ninu isemi aye. Oluwa wa, (O fun won) nitori ki won le seri awon eniyan kuro loju ona (esin) Re. Oluwa wa, pa dukia won re, ki O si mu okan won le, ki won ma gbagbo mo titi won fi maa ri iya eleta-elero |
قَالَ قَدْ أُجِيبَت دَّعْوَتُكُمَا فَاسْتَقِيمَا وَلَا تَتَّبِعَانِّ سَبِيلَ الَّذِينَ لَا يَعْلَمُونَ (89) (Allahu) so pe: "Dajudaju Mo ti gba adua eyin mejeeji. Nitori naa, ki eyin mejeeji duro sinsin. E ma se tele oju ona awon ti ko nimo |
۞ وَجَاوَزْنَا بِبَنِي إِسْرَائِيلَ الْبَحْرَ فَأَتْبَعَهُمْ فِرْعَوْنُ وَجُنُودُهُ بَغْيًا وَعَدْوًا ۖ حَتَّىٰ إِذَا أَدْرَكَهُ الْغَرَقُ قَالَ آمَنتُ أَنَّهُ لَا إِلَٰهَ إِلَّا الَّذِي آمَنَتْ بِهِ بَنُو إِسْرَائِيلَ وَأَنَا مِنَ الْمُسْلِمِينَ (90) A mu awon omo ’Isro’il la agbami odo ja. Fir‘aon ati awon omo ogun re si gba to won leyin, ni ti abosi ati itayo enu-ala, titi iteri sinu agbami okun fi ba a. O si wi pe: “Mo gbagbo pe dajudaju ko si olohun ti ijosin to si afi Eni ti awon omo ’Isro’il gbagbo. Mo si wa ninu awon musulumi.” |
آلْآنَ وَقَدْ عَصَيْتَ قَبْلُ وَكُنتَ مِنَ الْمُفْسِدِينَ (91) Se nisinsin yii, ti iwo ti yapa siwaju, ti o si wa ninu awon obileje |
فَالْيَوْمَ نُنَجِّيكَ بِبَدَنِكَ لِتَكُونَ لِمَنْ خَلْفَكَ آيَةً ۚ وَإِنَّ كَثِيرًا مِّنَ النَّاسِ عَنْ آيَاتِنَا لَغَافِلُونَ (92) Nitori naa, ni oni ni A oo gbe oku re jade si ori ile tente nitori ki o le je ami (feyikogbon) fun awon t’o n bo leyin re. Dajudaju opolopo ninu awon eniyan ma ni afonu-fora nipa awon ayah Wa |
وَلَقَدْ بَوَّأْنَا بَنِي إِسْرَائِيلَ مُبَوَّأَ صِدْقٍ وَرَزَقْنَاهُم مِّنَ الطَّيِّبَاتِ فَمَا اخْتَلَفُوا حَتَّىٰ جَاءَهُمُ الْعِلْمُ ۚ إِنَّ رَبَّكَ يَقْضِي بَيْنَهُمْ يَوْمَ الْقِيَامَةِ فِيمَا كَانُوا فِيهِ يَخْتَلِفُونَ (93) A kuku se ibugbe fun awon omo ’Isro’il ni ibugbe alapon-onle. A si pese fun won ninu awon nnkan daadaa. Nigba naa, won ko yapa enu (si ’Islam) titi imo fi de ba won. Dajudaju Oluwa re yoo sedajo laaarin won ni Ojo Ajinde nipa ohun ti won n yapa enu si |
فَإِن كُنتَ فِي شَكٍّ مِّمَّا أَنزَلْنَا إِلَيْكَ فَاسْأَلِ الَّذِينَ يَقْرَءُونَ الْكِتَابَ مِن قَبْلِكَ ۚ لَقَدْ جَاءَكَ الْحَقُّ مِن رَّبِّكَ فَلَا تَكُونَنَّ مِنَ الْمُمْتَرِينَ (94) Ti o ba wa ninu iyemeji nipa nnkan ti A sokale fun o (pe oruko re ati asotele nipa re wa ninu Taorat ati ’Injil), bi awon t’o n ka Tira siwaju re leere wo. Dajudaju ododo ti de ba o lati odo Oluwa re. Nitori naa, o o gbodo wa lara awon oniyemeji |
وَلَا تَكُونَنَّ مِنَ الَّذِينَ كَذَّبُوا بِآيَاتِ اللَّهِ فَتَكُونَ مِنَ الْخَاسِرِينَ (95) O o gbodo wa lara awon t’o pe awon ayah Allahu niro, nitori ki o ma baa wa lara awon eni ofo |
إِنَّ الَّذِينَ حَقَّتْ عَلَيْهِمْ كَلِمَتُ رَبِّكَ لَا يُؤْمِنُونَ (96) Dajudaju awon ti oro Oluwa re ti ko le lori, won ko nii gbagbo |
وَلَوْ جَاءَتْهُمْ كُلُّ آيَةٍ حَتَّىٰ يَرَوُا الْعَذَابَ الْأَلِيمَ (97) gbogbo ayah ibaa de ba won, titi won maa fi ri iya eleta-elero |
فَلَوْلَا كَانَتْ قَرْيَةٌ آمَنَتْ فَنَفَعَهَا إِيمَانُهَا إِلَّا قَوْمَ يُونُسَ لَمَّا آمَنُوا كَشَفْنَا عَنْهُمْ عَذَابَ الْخِزْيِ فِي الْحَيَاةِ الدُّنْيَا وَمَتَّعْنَاهُمْ إِلَىٰ حِينٍ (98) Ko kuku si ilu kan, t’o gbagbo (lasiko iya), ti igbagbo re si se e ni anfaani afi ijo (Anabi) Yunus. Nigba ti won gbagbo, A mu abuku iya kuro fun won ninu isemi aye. A si je ki won je igbadun aye fun igba die |
وَلَوْ شَاءَ رَبُّكَ لَآمَنَ مَن فِي الْأَرْضِ كُلُّهُمْ جَمِيعًا ۚ أَفَأَنتَ تُكْرِهُ النَّاسَ حَتَّىٰ يَكُونُوا مُؤْمِنِينَ (99) Ti o ba je pe Oluwa re ba fe, awon ti n be lori ile iba gbagbo, gbogbo won patapata. Nitori naa, se iwo l’o maa je won nipa ni titi won yoo fi di onigbagbo ododo |
وَمَا كَانَ لِنَفْسٍ أَن تُؤْمِنَ إِلَّا بِإِذْنِ اللَّهِ ۚ وَيَجْعَلُ الرِّجْسَ عَلَى الَّذِينَ لَا يَعْقِلُونَ (100) Emi kan ko le gbagbo afi pelu ase Allahu. O si maa fi iya je awon ti ko se laakaye |
قُلِ انظُرُوا مَاذَا فِي السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ ۚ وَمَا تُغْنِي الْآيَاتُ وَالنُّذُرُ عَن قَوْمٍ لَّا يُؤْمِنُونَ (101) So pe: "E woye si nnkan ti n be ninu sanmo ati ile. Awon ayah ati ikilo ko si nii ro ijo alaigbagbo loro |
فَهَلْ يَنتَظِرُونَ إِلَّا مِثْلَ أَيَّامِ الَّذِينَ خَلَوْا مِن قَبْلِهِمْ ۚ قُلْ فَانتَظِرُوا إِنِّي مَعَكُم مِّنَ الْمُنتَظِرِينَ (102) Nitori naa, se won tun n reti (nnkan miiran) ni bi ko se (iparun) iru ti igba awon t’o re koja lo siwaju won. So pe: “E maa reti nigba naa. Dajudaju emi naa wa pelu yin ninu awon olureti.” |
ثُمَّ نُنَجِّي رُسُلَنَا وَالَّذِينَ آمَنُوا ۚ كَذَٰلِكَ حَقًّا عَلَيْنَا نُنجِ الْمُؤْمِنِينَ (103) Leyin naa, A oo gba awon Ojise Wa ati awon t’o gbagbo la. Bayen ni o se je ojuse Wa lati gba awon onigbagbo ododo la |
قُلْ يَا أَيُّهَا النَّاسُ إِن كُنتُمْ فِي شَكٍّ مِّن دِينِي فَلَا أَعْبُدُ الَّذِينَ تَعْبُدُونَ مِن دُونِ اللَّهِ وَلَٰكِنْ أَعْبُدُ اللَّهَ الَّذِي يَتَوَفَّاكُمْ ۖ وَأُمِرْتُ أَنْ أَكُونَ مِنَ الْمُؤْمِنِينَ (104) So pe: “Eyin eniyan, ti e ba wa ninu iyemeji nipa esin mi. Nigba naa, emi ko nii josin fun awon ti e n josin fun leyin Allahu. Sugbon emi yoo maa josin fun Allahu, Eni ti O maa gba emi yin. Won si pa mi ni ase pe ki ng wa ninu awon onigbagbo ododo |
وَأَنْ أَقِمْ وَجْهَكَ لِلدِّينِ حَنِيفًا وَلَا تَكُونَنَّ مِنَ الْمُشْرِكِينَ (105) (Won tun pa mi lase pe): “Doju re ko esin naa, (ki o je) oluduro-deede-ninu-esin. Iwo ko si gbodo wa ninu awon osebo |
وَلَا تَدْعُ مِن دُونِ اللَّهِ مَا لَا يَنفَعُكَ وَلَا يَضُرُّكَ ۖ فَإِن فَعَلْتَ فَإِنَّكَ إِذًا مِّنَ الظَّالِمِينَ (106) Ati pe ma se pe leyin Allahu nnkan ti ko le se o ni anfaani, ti ko si le ko inira ba o. Ti o ba se bee nigba naa, dajudaju iwo ti wa ninu awon alabosi.” |
وَإِن يَمْسَسْكَ اللَّهُ بِضُرٍّ فَلَا كَاشِفَ لَهُ إِلَّا هُوَ ۖ وَإِن يُرِدْكَ بِخَيْرٍ فَلَا رَادَّ لِفَضْلِهِ ۚ يُصِيبُ بِهِ مَن يَشَاءُ مِنْ عِبَادِهِ ۚ وَهُوَ الْغَفُورُ الرَّحِيمُ (107) Ti Allahu ba mu inira ba o, ko si eni ti o le mu un kuro afi Oun. Ti O ba si gbero oore kan pelu re, ko si eni ti o le da oore Re pada. O n soore fun eni ti O ba fe ninu awon erusin Re. Oun ni Alaforijin, Asake-orun |
قُلْ يَا أَيُّهَا النَّاسُ قَدْ جَاءَكُمُ الْحَقُّ مِن رَّبِّكُمْ ۖ فَمَنِ اهْتَدَىٰ فَإِنَّمَا يَهْتَدِي لِنَفْسِهِ ۖ وَمَن ضَلَّ فَإِنَّمَا يَضِلُّ عَلَيْهَا ۖ وَمَا أَنَا عَلَيْكُم بِوَكِيلٍ (108) So pe: "Eyin eniyan, dajudaju ododo ti de ba yin lati odo Oluwa yin. Nitori naa, enikeni ti o ba mona, o mona fun emi ara re. Enikeni ti o ba si sina, o sina fun emi ara re. Emi si ko ni oluso fun yin |
وَاتَّبِعْ مَا يُوحَىٰ إِلَيْكَ وَاصْبِرْ حَتَّىٰ يَحْكُمَ اللَّهُ ۚ وَهُوَ خَيْرُ الْحَاكِمِينَ (109) Tele ohun ti A fi ranse si o ninu imisi. Ki o si se suuru titi Allahu yoo fi se idajo. Oun si loore julo ninu awon oludajo |