Quran with Yoruba translation - Surah Al-‘Ankabut ayat 45 - العَنكبُوت - Page - Juz 21
﴿ٱتۡلُ مَآ أُوحِيَ إِلَيۡكَ مِنَ ٱلۡكِتَٰبِ وَأَقِمِ ٱلصَّلَوٰةَۖ إِنَّ ٱلصَّلَوٰةَ تَنۡهَىٰ عَنِ ٱلۡفَحۡشَآءِ وَٱلۡمُنكَرِۗ وَلَذِكۡرُ ٱللَّهِ أَكۡبَرُۗ وَٱللَّهُ يَعۡلَمُ مَا تَصۡنَعُونَ ﴾
[العَنكبُوت: 45]
﴿اتل ما أوحي إليك من الكتاب وأقم الصلاة إن الصلاة تنهى عن﴾ [العَنكبُوت: 45]
Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni Ké ohun tí A fi ránṣẹ́ sí ọ nínú Tírà. Kí o sì kírun. Dájúdájú ìrun kíkí ń kọ ìwà ìbàjẹ́ àti aburú. Àti pé ìrántí Allāhu tóbi jùlọ. Allāhu sì mọ ohun tí ẹ̀ ń ṣe. bí ìrun kíkí ṣe ní ẹ̀san bẹ́ẹ̀ náà ló tún jẹ́ ohun t’ó ń mú olùkírun jìnnà sí ìwà aburú ààwẹ̀ gbígbà àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ẹnikẹ́ni tí ó bá pa ìrun kíkí àti ààwẹ̀ gbígbà tì nípasẹ̀ fífún gbólóhùn yìí ní ìtúmọ̀ òdì ó ti kó ìparun bá ẹ̀mí ara rẹ̀ ní ìbámu sí sūrah al-Muddaththir; 74: 42-43. Kí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) là wá nínú èyí |