Quran with Yoruba translation - Surah al-‘Imran ayat 167 - آل عِمران - Page - Juz 4
﴿وَلِيَعۡلَمَ ٱلَّذِينَ نَافَقُواْۚ وَقِيلَ لَهُمۡ تَعَالَوۡاْ قَٰتِلُواْ فِي سَبِيلِ ٱللَّهِ أَوِ ٱدۡفَعُواْۖ قَالُواْ لَوۡ نَعۡلَمُ قِتَالٗا لَّٱتَّبَعۡنَٰكُمۡۗ هُمۡ لِلۡكُفۡرِ يَوۡمَئِذٍ أَقۡرَبُ مِنۡهُمۡ لِلۡإِيمَٰنِۚ يَقُولُونَ بِأَفۡوَٰهِهِم مَّا لَيۡسَ فِي قُلُوبِهِمۡۚ وَٱللَّهُ أَعۡلَمُ بِمَا يَكۡتُمُونَ ﴾
[آل عِمران: 167]
﴿وليعلم الذين نافقوا وقيل لهم تعالوا قاتلوا في سبيل الله أو ادفعوا﴾ [آل عِمران: 167]
Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni (Ó tún rí bẹ́ẹ̀) nítorí kí Ó lè ṣàfi hàn àwọn t’ó ṣọ̀bẹ-ṣèlu (nínú àwọn mùsùlùmí). (Àwọn onígbàgbọ́ òdodo) sì sọ fún wọn pé: “Ẹ máa bọ̀, kí á lọ jagun fún ẹ̀sìn Allāhu tàbí ẹ wá dáàbò bo ẹ̀mí ara yín.” Wọ́n wí pé: “Àwa ìbá mọ ogun-ún jà àwa ìbá tẹ̀lé yín.” Wọ́n súnmọ́ àìgbàgbọ́ ní ọjọ́ yẹn ju ìgbàgbọ́ lọ. Wọ́n ń fi ẹnu wọn sọ ohun tí kò sí nínú ọkàn wọn. Allāhu sì nímọ̀ jùlọ nípa ohun tí wọ́n ń fi pamọ́ |