Quran with Yoruba translation - Surah Al-hadid ayat 4 - الحدِيد - Page - Juz 27
﴿هُوَ ٱلَّذِي خَلَقَ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضَ فِي سِتَّةِ أَيَّامٖ ثُمَّ ٱسۡتَوَىٰ عَلَى ٱلۡعَرۡشِۖ يَعۡلَمُ مَا يَلِجُ فِي ٱلۡأَرۡضِ وَمَا يَخۡرُجُ مِنۡهَا وَمَا يَنزِلُ مِنَ ٱلسَّمَآءِ وَمَا يَعۡرُجُ فِيهَاۖ وَهُوَ مَعَكُمۡ أَيۡنَ مَا كُنتُمۡۚ وَٱللَّهُ بِمَا تَعۡمَلُونَ بَصِيرٞ ﴾
[الحدِيد: 4]
﴿هو الذي خلق السموات والأرض في ستة أيام ثم استوى على العرش﴾ [الحدِيد: 4]
Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni Òun ni Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ fún ọjọ́ mẹ́fà. Lẹ́yìn náà, Ó gúnwà sí orí Ìtẹ́-ọlá. Ó mọ n̄ǹkan t’ó ń wọ inú ilẹ̀ àti n̄ǹkan t’ó ń jáde láti inú rẹ̀, àti n̄ǹkan t’ó ń sọ̀kalẹ̀ láti inú sánmọ̀ àti n̄ǹkan t’ó ń gùnkè sínú rẹ̀. Àti pé Ó wà pẹ̀lú yín ní ibikíbi tí ẹ bá wà (pẹ̀lú ìmọ̀ Rẹ̀). Allāhu sì ni Olùríran nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́ |