Quran with Yoruba translation - Surah Al-An‘am ayat 35 - الأنعَام - Page - Juz 7
﴿وَإِن كَانَ كَبُرَ عَلَيۡكَ إِعۡرَاضُهُمۡ فَإِنِ ٱسۡتَطَعۡتَ أَن تَبۡتَغِيَ نَفَقٗا فِي ٱلۡأَرۡضِ أَوۡ سُلَّمٗا فِي ٱلسَّمَآءِ فَتَأۡتِيَهُم بِـَٔايَةٖۚ وَلَوۡ شَآءَ ٱللَّهُ لَجَمَعَهُمۡ عَلَى ٱلۡهُدَىٰۚ فَلَا تَكُونَنَّ مِنَ ٱلۡجَٰهِلِينَ ﴾
[الأنعَام: 35]
﴿وإن كان كبر عليك إعراضهم فإن استطعت أن تبتغي نفقا في الأرض﴾ [الأنعَام: 35]
Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni Tí ó bá sì jẹ́ pé gbígbúnrí wọn lágbára lára rẹ, nígbà náà tí o bá lágbára láti wá ihò kan sínú (àjà) ilẹ̀, tàbí àkàbà kan sínú sánmọ̀ (ṣe bẹ́ẹ̀) kí o lè mú àmì kan wá fún wọn. Àti pé tí ó bá jẹ́ pé Allāhu bá fẹ́, dájúdájú ìbá kó wọn jọ sínú ìmọ̀nà (’Islām). Nítorí náà, o ò gbọdọ̀ wà lára àwọn aláìmọ̀kan |