Quran with Yoruba translation - Surah An-Nahl ayat 21 - النَّحل - Page - Juz 14
﴿أَمۡوَٰتٌ غَيۡرُ أَحۡيَآءٖۖ وَمَا يَشۡعُرُونَ أَيَّانَ يُبۡعَثُونَ ﴾
[النَّحل: 21]
﴿أموات غير أحياء وما يشعرون أيان يبعثون﴾ [النَّحل: 21]
Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni Òkú (ni wọ́n), wọn kì í ṣe alààyè. Wọn kò sì mọ àkókò tí A óò gbé wọn dìde. wọn kì í ṣe alààyè.” kò sọ ikú Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) di ohun t’ó ti ṣẹlẹ̀. Ṣebí àwọn mọlāika kan wà lára n̄ǹkan tí àwọn ènìyàn ń jọ́sìn fún lẹ́yìn Allāhu. Ṣé òkú ni àwọn mọlaika náà ni tàbí alààyè? A ò kúkú tí ì gbọ́ ikú mọlaika kan kan rí. Bákan náà aṣ-Ṣatọ̄n ar-Rọjīm jẹ́ ọ̀kan pàtàkì nínú ohun tí àwọn ènìyàn ń jọ́sìn fún. Ṣé òkú ni Ṣaetọ̄n náà ni tàbí alààyè? Rárá bí Allāhu ṣe fẹ́.” Kò wá sí ẹ̀rí tààrà kan kan t’ó fi rinlẹ̀ pé Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) ti kú bí kò ṣe āyah onípọ́nna èyí tí a ti ṣe àlàyé lórí rẹ̀ ṣíwájú nínú ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah āli-’Imrọ̄n 3:55. Dípò kí á rí āyah kan tàbí hadīth kan tààrà lórí ikú Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) hadīth t’ó ń fi ìpadàbọ̀ rẹ̀ rinlẹ̀ l’à ń rí. Ẹni tí kò ì kú l’ó sì lè padà wá sílé ayé. ” nínú āyah náà kì í ṣe ìtúmọ̀ àdámọ́. Ìdí ni pé ère tí kò sí ẹ̀mí lára rẹ̀ ni àwọn òrìṣà náà. Ipò òkú ẹni tí kò lè sọ̀rọ̀ |