| الر ۚ تِلْكَ آيَاتُ الْكِتَابِ وَقُرْآنٍ مُّبِينٍ (1) ’Alif lam ro. Iwonyi ni awon ayah Tira naa ati (awon ayah) al-Ƙur’an t’o n yanju oro eda
 | 
| رُّبَمَا يَوَدُّ الَّذِينَ كَفَرُوا لَوْ كَانُوا مُسْلِمِينَ (2) O see se ki awon t’o sai gbagbo nifee si pe awon iba si ti je musulumi (nile aye)
 | 
| ذَرْهُمْ يَأْكُلُوا وَيَتَمَتَّعُوا وَيُلْهِهِمُ الْأَمَلُ ۖ فَسَوْفَ يَعْلَمُونَ (3) Fi won sile, ki won je, ki won gbadun, ki ireti (emi gigun) ko airoju raaye ba won (lati sesin); laipe won maa mo
 | 
| وَمَا أَهْلَكْنَا مِن قَرْيَةٍ إِلَّا وَلَهَا كِتَابٌ مَّعْلُومٌ (4) A ko pa ilu kan run ri afi ki o ni akosile ti A ti mo
 | 
| مَّا تَسْبِقُ مِنْ أُمَّةٍ أَجَلَهَا وَمَا يَسْتَأْخِرُونَ (5) Ko si ijo kan (ti o parun) siwaju akoko re (ninu Laohul-Mahfuuth); won ko si nii sun un siwaju fun won
 | 
| وَقَالُوا يَا أَيُّهَا الَّذِي نُزِّلَ عَلَيْهِ الذِّكْرُ إِنَّكَ لَمَجْنُونٌ (6) Won wi pe: “Iwo ti Won so al-Ƙur’an kale fun, dajudaju were ni e
 | 
| لَّوْ مَا تَأْتِينَا بِالْمَلَائِكَةِ إِن كُنتَ مِنَ الصَّادِقِينَ (7) Ki ni ko je ki iwo mu awon molaika wa ba wa, ti iwo ba wa ninu awon olododo?”
 | 
| مَا نُنَزِّلُ الْمَلَائِكَةَ إِلَّا بِالْحَقِّ وَمَا كَانُوا إِذًا مُّنظَرِينَ (8) A o nii so molaika kale bi ko se pelu ododo. Won ko si nii lo won lara mo nigba naa (ti awon molaika ba sokale)
 | 
| إِنَّا نَحْنُ نَزَّلْنَا الذِّكْرَ وَإِنَّا لَهُ لَحَافِظُونَ (9) Dajudaju Awa l’A so Tira Iranti kale (iyen al-Ƙur’an). Dajudaju Awa si ni Oluso re
 | 
| وَلَقَدْ أَرْسَلْنَا مِن قَبْلِكَ فِي شِيَعِ الْأَوَّلِينَ (10) Dajudaju siwaju re A ti ran (awon Ojise) nise si awon ijo, awon eni akoko
 | 
| وَمَا يَأْتِيهِم مِّن رَّسُولٍ إِلَّا كَانُوا بِهِ يَسْتَهْزِئُونَ (11) Ojise kan ko si nii de ba won afi ki won fi se yeye
 | 
| كَذَٰلِكَ نَسْلُكُهُ فِي قُلُوبِ الْمُجْرِمِينَ (12) Bayen ni A se n fi (aisan) sinu okan awon elese
 | 
| لَا يُؤْمِنُونَ بِهِ ۖ وَقَدْ خَلَتْ سُنَّةُ الْأَوَّلِينَ (13) Won ko nii gba Anabi (sollalahu 'alayhi wa sallam) gbo; ise (Allahu lori) awon eni akoko kuku ti re koja
 | 
| وَلَوْ فَتَحْنَا عَلَيْهِم بَابًا مِّنَ السَّمَاءِ فَظَلُّوا فِيهِ يَعْرُجُونَ (14) Ti o ba je pe A si ilekun kan sile fun won lati inu sanmo, ti won ko si ye gbabe gunke lo (sinu sanmo)
 | 
| لَقَالُوا إِنَّمَا سُكِّرَتْ أَبْصَارُنَا بَلْ نَحْنُ قَوْمٌ مَّسْحُورُونَ (15) dajudaju won a wi pe: “Won kuku lo isiju fun wa ni. Nse ni won n dan wa.”
 | 
| وَلَقَدْ جَعَلْنَا فِي السَّمَاءِ بُرُوجًا وَزَيَّنَّاهَا لِلنَّاظِرِينَ (16) A kuku fi awon ibuso (irawo) sinu sanmo (aye). A si se e ni oso fun awon oluworan
 | 
| وَحَفِظْنَاهَا مِن كُلِّ شَيْطَانٍ رَّجِيمٍ (17) A si fi aabo bo imisi sanmo lodo gbogbo esu, eni eko
 | 
| إِلَّا مَنِ اسْتَرَقَ السَّمْعَ فَأَتْبَعَهُ شِهَابٌ مُّبِينٌ (18) Afi (esu) ti o ba ji oro gbo. Nigba naa si ni ogunna ponnbele yo tele e lati eyin
 | 
| وَالْأَرْضَ مَدَدْنَاهَا وَأَلْقَيْنَا فِيهَا رَوَاسِيَ وَأَنبَتْنَا فِيهَا مِن كُلِّ شَيْءٍ مَّوْزُونٍ (19) Ile, A te e perese. A si ju awon apata t’o duro gbagidi sinu re. A si mu gbogbo nnkan ti o ni odiwon hu jade lati inu re
 | 
| وَجَعَلْنَا لَكُمْ فِيهَا مَعَايِشَ وَمَن لَّسْتُمْ لَهُ بِرَازِقِينَ (20) A se ona ije-imu sinu (ile aye) fun eyin ati awon ti eyin ko le pese fun
 | 
| وَإِن مِّن شَيْءٍ إِلَّا عِندَنَا خَزَائِنُهُ وَمَا نُنَزِّلُهُ إِلَّا بِقَدَرٍ مَّعْلُومٍ (21) Ko si si kini kan afi ki ile-oro re wa lodo Wa. Awa ko si nii so o kale afi pelu odiwon ti A ti mo
 | 
| وَأَرْسَلْنَا الرِّيَاحَ لَوَاقِحَ فَأَنزَلْنَا مِنَ السَّمَاءِ مَاءً فَأَسْقَيْنَاكُمُوهُ وَمَا أَنتُمْ لَهُ بِخَازِنِينَ (22) Ati pe A ran ategun lati ko esujo jo. A si so omi kale lati sanmo. Nitori naa, A fun yin mu. Eyin si ko ni e ko omi ojo jo (soju sanmo)
 | 
| وَإِنَّا لَنَحْنُ نُحْيِي وَنُمِيتُ وَنَحْنُ الْوَارِثُونَ (23) Dajudaju Awa, Awa ma l’A n so (eda) di alaaye. A si n so o di oku. Awa si ni A oo jogun (eda)
 | 
| وَلَقَدْ عَلِمْنَا الْمُسْتَقْدِمِينَ مِنكُمْ وَلَقَدْ عَلِمْنَا الْمُسْتَأْخِرِينَ (24) Ati pe dajudaju A mo awon olugbawaju ninu yin. Dajudaju A si mo awon olugbeyin
 | 
| وَإِنَّ رَبَّكَ هُوَ يَحْشُرُهُمْ ۚ إِنَّهُ حَكِيمٌ عَلِيمٌ (25) Dajudaju Oluwa re, Oun l’O maa ko won jo. Dajudaju Oun ni Ologbon, Onimo
 | 
| وَلَقَدْ خَلَقْنَا الْإِنسَانَ مِن صَلْصَالٍ مِّنْ حَمَإٍ مَّسْنُونٍ (26) Dajudaju A seda eniyan lati ara amo t’o n dun koko, t’o ti pawoda
 | 
| وَالْجَانَّ خَلَقْنَاهُ مِن قَبْلُ مِن نَّارِ السَّمُومِ (27) Ati pe alujannu, A seda re siwaju (eniyan) lati ara ina alategun gbigbona ti ko ni eefin
 | 
| وَإِذْ قَالَ رَبُّكَ لِلْمَلَائِكَةِ إِنِّي خَالِقٌ بَشَرًا مِّن صَلْصَالٍ مِّنْ حَمَإٍ مَّسْنُونٍ (28) (Ranti) nigba ti Oluwa re so fun awon molaika pe: “Dajudaju Emi yoo se eda abara kan lati ara amo t’o n dun koko, t’o ti pawoda
 | 
| فَإِذَا سَوَّيْتُهُ وَنَفَخْتُ فِيهِ مِن رُّوحِي فَقَعُوا لَهُ سَاجِدِينَ (29) Nigba ti Mo ba se e t’o gun rege tan, ti Mo fe emi si i (lara) ninu emi Mi (ti Mo da), nigba naa e doju bole fun un ni oluforikanle-kini
 | 
| فَسَجَدَ الْمَلَائِكَةُ كُلُّهُمْ أَجْمَعُونَ (30) Nitori naa, awon molaika, gbogbo won patapata si fori kanle ki i
 | 
| إِلَّا إِبْلِيسَ أَبَىٰ أَن يَكُونَ مَعَ السَّاجِدِينَ (31) Ayafi ’Iblis. O ko lati wa ninu awon oluforikanle naa
 | 
| قَالَ يَا إِبْلِيسُ مَا لَكَ أَلَّا تَكُونَ مَعَ السَّاجِدِينَ (32) (Allahu) so pe: "’Iblis, ki l’o di o lowo lati wa ninu awon oluforikanle
 | 
| قَالَ لَمْ أَكُن لِّأَسْجُدَ لِبَشَرٍ خَلَقْتَهُ مِن صَلْصَالٍ مِّنْ حَمَإٍ مَّسْنُونٍ (33) O wi pe: "Emi ko nii fori kanle ki abara kan ti O seda re lati ara amo t’o n dun koko, t’o ti pawoda
 | 
| قَالَ فَاخْرُجْ مِنْهَا فَإِنَّكَ رَجِيمٌ (34) (Allahu) so pe: "Nitori naa, jade kuro ninu re. Dajudaju, iwo ni eni-eko
 | 
| وَإِنَّ عَلَيْكَ اللَّعْنَةَ إِلَىٰ يَوْمِ الدِّينِ (35) Ati pe, dajudaju egun n be lori re titi di Ojo esan
 | 
| قَالَ رَبِّ فَأَنظِرْنِي إِلَىٰ يَوْمِ يُبْعَثُونَ (36) O wi pe: “Oluwa mi, lo mi lara titi di Ojo Ajinde.”
 | 
| قَالَ فَإِنَّكَ مِنَ الْمُنظَرِينَ (37) (Allahu) so pe: "Dajudaju iwo wa lara awon ti A oo lo lara
 | 
| إِلَىٰ يَوْمِ الْوَقْتِ الْمَعْلُومِ (38) titi di ojo akoko ti A ti mo
 | 
| قَالَ رَبِّ بِمَا أَغْوَيْتَنِي لَأُزَيِّنَنَّ لَهُمْ فِي الْأَرْضِ وَلَأُغْوِيَنَّهُمْ أَجْمَعِينَ (39) O wi pe: "Oluwa mi, fun wi pe O ti se mi ni eni anu, dajudaju emi yoo se (aburu) ni oso fun won lori ile. Dajudaju emi yo si ko gbogbo won sinu anu
 | 
| إِلَّا عِبَادَكَ مِنْهُمُ الْمُخْلَصِينَ (40) afi awon erusin Re, awon eni esa ninu won
 | 
| قَالَ هَٰذَا صِرَاطٌ عَلَيَّ مُسْتَقِيمٌ (41) (Allahu) so pe: "(Idurosinsin loju) ona taara, Owo Mi ni eyi wa
 | 
| إِنَّ عِبَادِي لَيْسَ لَكَ عَلَيْهِمْ سُلْطَانٌ إِلَّا مَنِ اتَّبَعَكَ مِنَ الْغَاوِينَ (42) Dajudaju awon erusin Mi, ko si agbara kan fun o lori won, ayafi eni ti o ba tele o ninu awon eni anu
 | 
| وَإِنَّ جَهَنَّمَ لَمَوْعِدُهُمْ أَجْمَعِينَ (43) Ati pe dajudaju ina Jahanamo ni adehun fun gbogbo won
 | 
| لَهَا سَبْعَةُ أَبْوَابٍ لِّكُلِّ بَابٍ مِّنْهُمْ جُزْءٌ مَّقْسُومٌ (44) Awon oju ona meje n be fun (ina). Atunpin tun wa fun oju-ona kookan
 | 
| إِنَّ الْمُتَّقِينَ فِي جَنَّاتٍ وَعُيُونٍ (45) Dajudaju awon oluberu (Allahu) maa wa ninu awon Ogba Idera pelu awon odo (t’o n san nisale re)
 | 
| ادْخُلُوهَا بِسَلَامٍ آمِنِينَ (46) (A maa so pe): “E wo inu re pelu alaafia ni olufayabale.”
 | 
| وَنَزَعْنَا مَا فِي صُدُورِهِم مِّنْ غِلٍّ إِخْوَانًا عَلَىٰ سُرُرٍ مُّتَقَابِلِينَ (47) A si maa yo ohun ti n be ninu okan won t’o je inunibini kuro; (won yoo di) omo-iya (ara won. Won yoo wa) lori ibusun, ti won yoo koju sira won
 | 
| لَا يَمَسُّهُمْ فِيهَا نَصَبٌ وَمَا هُم مِّنْهَا بِمُخْرَجِينَ (48) Wahala kan ko nii ba won ninu re. Won ko si nii mu won jade kuro ninu re
 | 
| ۞ نَبِّئْ عِبَادِي أَنِّي أَنَا الْغَفُورُ الرَّحِيمُ (49) Fun awon erusin Mi ni iro pe dajudaju Emi ni Alaforijin, Asake-orun
 | 
| وَأَنَّ عَذَابِي هُوَ الْعَذَابُ الْأَلِيمُ (50) Ati pe dajudaju iya Mi ni iya eleta-elero
 | 
| وَنَبِّئْهُمْ عَن ضَيْفِ إِبْرَاهِيمَ (51) Fun won ni iro nipa alejo (Anabi) ’Ibrohim
 | 
| إِذْ دَخَلُوا عَلَيْهِ فَقَالُوا سَلَامًا قَالَ إِنَّا مِنكُمْ وَجِلُونَ (52) (Ranti) nigba ti won wole to o, won si so pe: “Alaafia”. O so pe: “Dajudaju eru yin n ba awa.”
 | 
| قَالُوا لَا تَوْجَلْ إِنَّا نُبَشِّرُكَ بِغُلَامٍ عَلِيمٍ (53) Won so pe: "Ma se beru. Dajudaju awa yoo fun o ni iro idunnu (nipa bibi) omokunrin onimimo kan
 | 
| قَالَ أَبَشَّرْتُمُونِي عَلَىٰ أَن مَّسَّنِيَ الْكِبَرُ فَبِمَ تُبَشِّرُونَ (54) O so pe: "Se e n fun mi ni iro idunnu (nipa bibi omo) nigba ti ogbo ti de si mi? Iro idunnu wo ni e n fun mi na
 | 
| قَالُوا بَشَّرْنَاكَ بِالْحَقِّ فَلَا تَكُن مِّنَ الْقَانِطِينَ (55) Won so pe: “A n fun o ni iro idunnu pelu ododo. Nitori naa, ma se wa lara awon olujakanmuna.”
 | 
| قَالَ وَمَن يَقْنَطُ مِن رَّحْمَةِ رَبِّهِ إِلَّا الضَّالُّونَ (56) O so pe: “Ko ma si eni ti o maa jakanmuna ninu ike Oluwa Re bi ko se awon olusina.”
 | 
| قَالَ فَمَا خَطْبُكُمْ أَيُّهَا الْمُرْسَلُونَ (57) O so pe: “Ki tun ni oro ti e ba wa, eyin Ojise?”
 | 
| قَالُوا إِنَّا أُرْسِلْنَا إِلَىٰ قَوْمٍ مُّجْرِمِينَ (58) Won so pe: "Dajudaju Won ran wa nise si ijo elese ni
 | 
| إِلَّا آلَ لُوطٍ إِنَّا لَمُنَجُّوهُمْ أَجْمَعِينَ (59) Afi ara ile (Anabi) Lut. Dajudaju awa yoo gba won la patapata
 | 
| إِلَّا امْرَأَتَهُ قَدَّرْنَا ۙ إِنَّهَا لَمِنَ الْغَابِرِينَ (60) Afi iyawo re; A ti ko kadara re (pe) dajudaju o maa wa ninu awon t’o maa seku leyin sinu iparun
 | 
| فَلَمَّا جَاءَ آلَ لُوطٍ الْمُرْسَلُونَ (61) Nigba ti awon Ojise de odo ara ile (Anabi) Lut
 | 
| قَالَ إِنَّكُمْ قَوْمٌ مُّنكَرُونَ (62) (Anabi Lut) so pe: “Dajudaju eyin je ajoji eniyan.”
 | 
| قَالُوا بَلْ جِئْنَاكَ بِمَا كَانُوا فِيهِ يَمْتَرُونَ (63) Won so pe: “Rara, a wa sodo re nitori ohun ti won n seyemeji nipa re
 | 
| وَأَتَيْنَاكَ بِالْحَقِّ وَإِنَّا لَصَادِقُونَ (64) A mu ododo wa ba o ni. Ati pe dajudaju olododo ni awa
 | 
| فَأَسْرِ بِأَهْلِكَ بِقِطْعٍ مِّنَ اللَّيْلِ وَاتَّبِعْ أَدْبَارَهُمْ وَلَا يَلْتَفِتْ مِنكُمْ أَحَدٌ وَامْضُوا حَيْثُ تُؤْمَرُونَ (65) Nitori naa, mu ara ile re jade ni apa kan oru. Ki o si tele won leyin. Eni kan ninu yin ko si gbodo siju wo eyin wo. Ki e si lo si aye ti won n pa lase fun yin
 | 
| وَقَضَيْنَا إِلَيْهِ ذَٰلِكَ الْأَمْرَ أَنَّ دَابِرَ هَٰؤُلَاءِ مَقْطُوعٌ مُّصْبِحِينَ (66) A si je ki idajo oro yii han si i pe dajudaju A maa pa awon (elese) wonyi run patapata nigba ti won ba mojumo
 | 
| وَجَاءَ أَهْلُ الْمَدِينَةِ يَسْتَبْشِرُونَ (67) Awon ara ilu naa de, won si n yo sese
 | 
| قَالَ إِنَّ هَٰؤُلَاءِ ضَيْفِي فَلَا تَفْضَحُونِ (68) (Anabi Lut) so pe: “Dajudaju awon wonyi ni alejo mi. Nitori naa, e ma se doju ti mi
 | 
| وَاتَّقُوا اللَّهَ وَلَا تُخْزُونِ (69) Ki e beru Allahu. Ki e si ma se yepere mi
 | 
| قَالُوا أَوَلَمْ نَنْهَكَ عَنِ الْعَالَمِينَ (70) Won wi pe: “Nje awa ko ti ko fun o (nipa gbigba alejo) awon eda?”
 | 
| قَالَ هَٰؤُلَاءِ بَنَاتِي إِن كُنتُمْ فَاعِلِينَ (71) O so pe: “Awon omobinrin mi niwonyi, ti e ba ni nnkan ti e fe (fi won) se.”
 | 
| لَعَمْرُكَ إِنَّهُمْ لَفِي سَكْرَتِهِمْ يَعْمَهُونَ (72) (Allahu so pe): “Mo fi isemi iwo (Anabi Muhammad) bura; dajudaju won kuku wa ninu idaamu opolo, ti won n pa ridarida.”
 | 
| فَأَخَذَتْهُمُ الصَّيْحَةُ مُشْرِقِينَ (73) Nitori naa, ohun igbe mu won nigba ti oorun owuro yo si won
 | 
| فَجَعَلْنَا عَالِيَهَا سَافِلَهَا وَأَمْطَرْنَا عَلَيْهِمْ حِجَارَةً مِّن سِجِّيلٍ (74) A si so oke ilu won di isale re (ilu won doju bole). A tun ro ojo okuta amo (sisun) le won lori
 | 
| إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَآيَاتٍ لِّلْمُتَوَسِّمِينَ (75) Dajudaju awon ami wa ninu iyen fun awon alariiwoye
 | 
| وَإِنَّهَا لَبِسَبِيلٍ مُّقِيمٍ (76) Dajudaju (ilu naa) kuku wa loju ona (ti e n to lo to bo)
 | 
| إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَآيَةً لِّلْمُؤْمِنِينَ (77) Dajudaju ami wa ninu iyen fun awon onigbagbo ododo
 | 
| وَإِن كَانَ أَصْحَابُ الْأَيْكَةِ لَظَالِمِينَ (78) Awon ara ’Aekah naa je alabosi
 | 
| فَانتَقَمْنَا مِنْهُمْ وَإِنَّهُمَا لَبِإِمَامٍ مُّبِينٍ (79) A si gbesan lara won. Dajujaju awon ilu mejeeji l’o kuku wa loju ona gbangba (ti e n to lo to bo)
 | 
| وَلَقَدْ كَذَّبَ أَصْحَابُ الْحِجْرِ الْمُرْسَلِينَ (80) Dajudaju awon ara Iho apata pe awon Ojise ni opuro
 | 
| وَآتَيْنَاهُمْ آيَاتِنَا فَكَانُوا عَنْهَا مُعْرِضِينَ (81) A si fun won ni awon ami Wa. Amo won gbunri kuro nibe
 | 
| وَكَانُوا يَنْحِتُونَ مِنَ الْجِبَالِ بُيُوتًا آمِنِينَ (82) Won maa n gbe awon ile igbe ifayabale sinu awon apata
 | 
| فَأَخَذَتْهُمُ الصَّيْحَةُ مُصْبِحِينَ (83) Ohun igbe si mu won nigba ti won mojumo
 | 
| فَمَا أَغْنَىٰ عَنْهُم مَّا كَانُوا يَكْسِبُونَ (84) Ohun ti won n se nise ko si ro won loro (nibi iya)
 | 
| وَمَا خَلَقْنَا السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضَ وَمَا بَيْنَهُمَا إِلَّا بِالْحَقِّ ۗ وَإِنَّ السَّاعَةَ لَآتِيَةٌ ۖ فَاصْفَحِ الصَّفْحَ الْجَمِيلَ (85) A ko seda awon sanmo, ile ati nnkan t’o wa laaarin awon mejeeji bi ko se pelu ododo. Dajudaju Akoko naa maa de. Nitori naa, samojukuro ni amojukuro t’o rewa
 | 
| إِنَّ رَبَّكَ هُوَ الْخَلَّاقُ الْعَلِيمُ (86) Dajudaju Oluwa re ni Eledaa, Onimo
 | 
| وَلَقَدْ آتَيْنَاكَ سَبْعًا مِّنَ الْمَثَانِي وَالْقُرْآنَ الْعَظِيمَ (87) Dajudaju A fun o ni Sab‘u Mothani (iyen, surah al-Fatihah) ati al-Ƙur’an t’o tobi
 | 
| لَا تَمُدَّنَّ عَيْنَيْكَ إِلَىٰ مَا مَتَّعْنَا بِهِ أَزْوَاجًا مِّنْهُمْ وَلَا تَحْزَنْ عَلَيْهِمْ وَاخْفِضْ جَنَاحَكَ لِلْمُؤْمِنِينَ (88) Iwo ko gbodo siju re wo ohun ti A fi se igbadun aye lorisirisi fun awon kan ninu won. Ma se banuje nitori won. Ki o si re apa re nile fun awon onigbagbo ododo
 | 
| وَقُلْ إِنِّي أَنَا النَّذِيرُ الْمُبِينُ (89) Ki o si so pe: “Dajudaju emi ni olukilo ponnbele.”
 | 
| كَمَا أَنزَلْنَا عَلَى الْمُقْتَسِمِينَ (90) Gege bi A se so (iya) kale fun awon t’o n pin ododo mo iro
 | 
| الَّذِينَ جَعَلُوا الْقُرْآنَ عِضِينَ (91) awon ti won so al-Ƙur’an di ipinkupin-in
 | 
| فَوَرَبِّكَ لَنَسْأَلَنَّهُمْ أَجْمَعِينَ (92) Oluwa re fi Ara Re bura fun o pe, A maa bi gbogbo won ni ibeere
 | 
| عَمَّا كَانُوا يَعْمَلُونَ (93) nipa ohun ti won n se nise
 | 
| فَاصْدَعْ بِمَا تُؤْمَرُ وَأَعْرِضْ عَنِ الْمُشْرِكِينَ (94) Nitori naa, kede nnkan ti A pa lase fun o. Ki o si seri kuro lodo awon osebo
 | 
| إِنَّا كَفَيْنَاكَ الْمُسْتَهْزِئِينَ (95) Dajudaju Awa yoo to o (nibi aburu) awon oniyeye
 | 
| الَّذِينَ يَجْعَلُونَ مَعَ اللَّهِ إِلَٰهًا آخَرَ ۚ فَسَوْفَ يَعْلَمُونَ (96) awon t’o n mu olohun miiran mo Allahu. Laipe won maa mo
 | 
| وَلَقَدْ نَعْلَمُ أَنَّكَ يَضِيقُ صَدْرُكَ بِمَا يَقُولُونَ (97) Awa kuku ti mo pe dajudaju ohun ti won n wi n ko inira ba o
 | 
| فَسَبِّحْ بِحَمْدِ رَبِّكَ وَكُن مِّنَ السَّاجِدِينَ (98) Nitori naa, se afomo pelu idupe fun Oluwa re. Ki o si wa ninu awon oluforikanle (fun Un)
 | 
| وَاعْبُدْ رَبَّكَ حَتَّىٰ يَأْتِيَكَ الْيَقِينُ (99) Josin fun Oluwa re titi amodaju (iyen, iku) yoo fi de ba o
 |