سَبَّحَ لِلَّهِ مَا فِي السَّمَاوَاتِ وَمَا فِي الْأَرْضِ ۖ وَهُوَ الْعَزِيزُ الْحَكِيمُ (1) Ohunkohun t’o wa ninu awon sanmo ati ohunkohun t’o wa ninu ile n safomo fun Allahu. Oun si ni Alagbara, Ologbon |
يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا لِمَ تَقُولُونَ مَا لَا تَفْعَلُونَ (2) Eyin ti e gbagbo ni ododo, nitori ki ni e se n so ohun ti e o nii se nise |
كَبُرَ مَقْتًا عِندَ اللَّهِ أَن تَقُولُوا مَا لَا تَفْعَلُونَ (3) O je ohun ibinu t’o tobi ni odo Allahu pe ki e so ohun ti e o nii se |
إِنَّ اللَّهَ يُحِبُّ الَّذِينَ يُقَاتِلُونَ فِي سَبِيلِهِ صَفًّا كَأَنَّهُم بُنْيَانٌ مَّرْصُوصٌ (4) Dajudaju Allahu feran awon t’o n jagun fun esin Re (ti won to ni) owoowo bi eni pe ogiri ile ti won le po mora won ni won |
وَإِذْ قَالَ مُوسَىٰ لِقَوْمِهِ يَا قَوْمِ لِمَ تُؤْذُونَنِي وَقَد تَّعْلَمُونَ أَنِّي رَسُولُ اللَّهِ إِلَيْكُمْ ۖ فَلَمَّا زَاغُوا أَزَاغَ اللَّهُ قُلُوبَهُمْ ۚ وَاللَّهُ لَا يَهْدِي الْقَوْمَ الْفَاسِقِينَ (5) (Ranti) nigba ti (Anabi) Musa so fun ijo re pe: "Eyin ijo mi, nitori ki ni e oo se fi inira kan mi. E si kuku mo pe dajudaju Ojise Allahu ni emi je si yin." Nigba ti won si ye (kuro nibi ododo), Allahu ye okan won. Allahu ko si nii fi ona mo ijo obileje |
وَإِذْ قَالَ عِيسَى ابْنُ مَرْيَمَ يَا بَنِي إِسْرَائِيلَ إِنِّي رَسُولُ اللَّهِ إِلَيْكُم مُّصَدِّقًا لِّمَا بَيْنَ يَدَيَّ مِنَ التَّوْرَاةِ وَمُبَشِّرًا بِرَسُولٍ يَأْتِي مِن بَعْدِي اسْمُهُ أَحْمَدُ ۖ فَلَمَّا جَاءَهُم بِالْبَيِّنَاتِ قَالُوا هَٰذَا سِحْرٌ مُّبِينٌ (6) (Ranti) nigba ti ‘Isa omo Moryam so pe: "Eyin omo ’Isro’il, dajudaju emi ni Ojise Allahu si yin. Mo n fi ohun t’o je ododo rinle nipa eyi t’o siwaju mi ninu Taorah. Mo si n mu iro-idunnu wa nipa Ojise kan t’o n bo leyin mi. Oruko re ni ’Ahmod." Nigba ti o ba si wa ba won pelu awon eri t’o yanju, won a wi pe: "Idan ponnbele ni eyi |
وَمَنْ أَظْلَمُ مِمَّنِ افْتَرَىٰ عَلَى اللَّهِ الْكَذِبَ وَهُوَ يُدْعَىٰ إِلَى الْإِسْلَامِ ۚ وَاللَّهُ لَا يَهْدِي الْقَوْمَ الظَّالِمِينَ (7) Ta si ni o sabosi t’o tayo eni ti o da adapa iro mo Allahu, ti won si n pe e sinu ’Islam! Allahu ko si nii fi ona mo ijo alabosi |
يُرِيدُونَ لِيُطْفِئُوا نُورَ اللَّهِ بِأَفْوَاهِهِمْ وَاللَّهُ مُتِمُّ نُورِهِ وَلَوْ كَرِهَ الْكَافِرُونَ (8) Won n gbero lati fi (oro) enu won pa imole Allahu. Allahu yo si mu imole Re tan kari, awon alaigbagbo ibaa korira re |
هُوَ الَّذِي أَرْسَلَ رَسُولَهُ بِالْهُدَىٰ وَدِينِ الْحَقِّ لِيُظْهِرَهُ عَلَى الدِّينِ كُلِّهِ وَلَوْ كَرِهَ الْمُشْرِكُونَ (9) (Allahu) Oun ni Eni ti O fi imona ati esin ododo (’Islam) ran Ojise Re nitori ki O le fi bori esin (miiran), gbogbo re patapata, awon osebo ibaa korira re |
يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا هَلْ أَدُلُّكُمْ عَلَىٰ تِجَارَةٍ تُنجِيكُم مِّنْ عَذَابٍ أَلِيمٍ (10) Eyin ti e gbagbo ni ododo, se ki Ng toka yin si okowo kan ti o maa gba yin la ninu iya eleta-elero |
تُؤْمِنُونَ بِاللَّهِ وَرَسُولِهِ وَتُجَاهِدُونَ فِي سَبِيلِ اللَّهِ بِأَمْوَالِكُمْ وَأَنفُسِكُمْ ۚ ذَٰلِكُمْ خَيْرٌ لَّكُمْ إِن كُنتُمْ تَعْلَمُونَ (11) E gbagbo ninu Allahu ati Ojise Re, e jagun soju ona (esin) Allahu pelu awon dukia yin ati emi yin. Iyen loore julo fun yin ti e ba mo |
يَغْفِرْ لَكُمْ ذُنُوبَكُمْ وَيُدْخِلْكُمْ جَنَّاتٍ تَجْرِي مِن تَحْتِهَا الْأَنْهَارُ وَمَسَاكِنَ طَيِّبَةً فِي جَنَّاتِ عَدْنٍ ۚ ذَٰلِكَ الْفَوْزُ الْعَظِيمُ (12) (Allahu) maa fori ese yin jin yin. O si maa mu yin wo inu awon Ogba Idera, ti awon odo n san ni isale re ati awon ibugbe t’o dara ninu awon Ogba Idera gbere. Iyen ni erenje nla |
وَأُخْرَىٰ تُحِبُّونَهَا ۖ نَصْرٌ مِّنَ اللَّهِ وَفَتْحٌ قَرِيبٌ ۗ وَبَشِّرِ الْمُؤْمِنِينَ (13) Ati nnkan miiran ti e tun nifee si; (iyen,) aranse lati odo Allahu ati isegun t’o sunmo. Ki o si fun awon onigbagbo ododo ni iro idunnu |
يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا كُونُوا أَنصَارَ اللَّهِ كَمَا قَالَ عِيسَى ابْنُ مَرْيَمَ لِلْحَوَارِيِّينَ مَنْ أَنصَارِي إِلَى اللَّهِ ۖ قَالَ الْحَوَارِيُّونَ نَحْنُ أَنصَارُ اللَّهِ ۖ فَآمَنَت طَّائِفَةٌ مِّن بَنِي إِسْرَائِيلَ وَكَفَرَت طَّائِفَةٌ ۖ فَأَيَّدْنَا الَّذِينَ آمَنُوا عَلَىٰ عَدُوِّهِمْ فَأَصْبَحُوا ظَاهِرِينَ (14) Eyin ti e gbagbo ni ododo, e je alaranse fun esin Allahu gege bi (Anabi) ‘Isa omo Moryam se so fun awon omoleyin re pe: "Ta ni o maa se iranlowo fun mi nipa esin Allahu?" Awon omoleyin re so pe: "Awa ni alaranse fun esin Allahu." Igun kan ninu awon omo ’Isro’il gba a gbo ni ododo nigba naa, igun kan si sai gbagbo ninu re. A si fun awon t’o gbagbo lagbara lori awon ota won; won si di olubori |