إِذَا وَقَعَتِ الْوَاقِعَةُ (1) Nigba ti Isele (Ajinde) ba sele |
لَيْسَ لِوَقْعَتِهَا كَاذِبَةٌ (2) ko si iro kan nipa isele re-E |
خَافِضَةٌ رَّافِعَةٌ (3) o maa mu (awon kan) wale (sinu Ina), o si maa gbe (awon kan) soke (ninu Ogba Idera) |
إِذَا رُجَّتِ الْأَرْضُ رَجًّا (4) Nigba ti won ba mi ile titi ni mimititi |
وَبُسَّتِ الْجِبَالُ بَسًّا (5) ati nigba ti Won ba fo awon apata ni fifo womuwomu |
فَكَانَتْ هَبَاءً مُّنبَثًّا (6) won si maa di eruku afedanu - E |
وَكُنتُمْ أَزْوَاجًا ثَلَاثَةً (7) eyin si maa je orisi meta |
فَأَصْحَابُ الْمَيْمَنَةِ مَا أَصْحَابُ الْمَيْمَنَةِ (8) ijo osi ati ijo asiwaju. Amo ninu surah al-Balad; 90:18-19 ati surah az-Zalzalah; 99:6-8 Allahu (subhanahu wa ta'ala) pin won si ijo meji. Ijo meji kuku ni gbogbo eda ni orun 8 Awon ero owo otun, ki ni (o maa ti dara to fun) awon ero owo otun |
وَأَصْحَابُ الْمَشْأَمَةِ مَا أَصْحَابُ الْمَشْأَمَةِ (9) Awon ero owo osi, ki ni (o maa ti buru to fun) awon ero owo osi |
وَالسَّابِقُونَ السَّابِقُونَ (10) Awon asiwaju si ni awon asiwaju |
أُولَٰئِكَ الْمُقَرَّبُونَ (11) Awon wonyen ni alasun-unmo (Allahu) |
فِي جَنَّاتِ النَّعِيمِ (12) ninu Ogba Idera |
ثُلَّةٌ مِّنَ الْأَوَّلِينَ (13) Won po ninu awon eni akoko |
وَقَلِيلٌ مِّنَ الْآخِرِينَ (14) Won si kere ninu awon eni Ikeyin |
عَلَىٰ سُرُرٍ مَّوْضُونَةٍ (15) (Won yoo wa) lori ite ti won fi goolu hun |
مُّتَّكِئِينَ عَلَيْهَا مُتَقَابِلِينَ (16) Won yoo rogboku sori re, won si maa doju kora won |
يَطُوفُ عَلَيْهِمْ وِلْدَانٌ مُّخَلَّدُونَ (17) Awon odokunrin ti ko nii darugbo yo si maa lo bo laaarin won |
بِأَكْوَابٍ وَأَبَارِيقَ وَكَأْسٍ مِّن مَّعِينٍ (18) pelu awon ife omi, ohun iromi fenfe ati ife oti aladun |
لَّا يُصَدَّعُونَ عَنْهَا وَلَا يُنزِفُونَ (19) Ko nii fo won lori; ko si nii mu won hunrira |
وَفَاكِهَةٍ مِّمَّا يَتَخَيَّرُونَ (20) Eso ti won yoo maa sesa ninu re (tun wa fun won) |
وَلَحْمِ طَيْرٍ مِّمَّا يَشْتَهُونَ (21) Ati eran eye, eyi ti won n fe (yo wa fun won) |
وَحُورٌ عِينٌ (22) Awon obinrin eleyinju ege (tun wa fun won) |
كَأَمْثَالِ اللُّؤْلُؤِ الْمَكْنُونِ (23) Won da bi okuta olowo-iyebiye ti won fi pamo |
جَزَاءً بِمَا كَانُوا يَعْمَلُونَ (24) (Iwonyi ni) esan fun ohun ti won n se nise |
لَا يَسْمَعُونَ فِيهَا لَغْوًا وَلَا تَأْثِيمًا (25) Won ko nii gbo isokuso ati oro ese ninu Ogba Idera |
إِلَّا قِيلًا سَلَامًا سَلَامًا (26) Ayafi oro alaafia, alaafia |
وَأَصْحَابُ الْيَمِينِ مَا أَصْحَابُ الْيَمِينِ (27) Awon ero owo otun, ki ni (o maa ti dara to fun) awon ero owo otun |
فِي سِدْرٍ مَّخْضُودٍ (28) (Won yoo wa) ni idi igi ti ko ni egun |
وَطَلْحٍ مَّنضُودٍ (29) ati ogede t’o so jigbinni |
وَظِلٍّ مَّمْدُودٍ (30) ati iboji t’o gbooro |
وَمَاءٍ مَّسْكُوبٍ (31) ati omi t’o n san lai dawo duro |
وَفَاكِهَةٍ كَثِيرَةٍ (32) ati opolopo eso |
لَّا مَقْطُوعَةٍ وَلَا مَمْنُوعَةٍ (33) ti ko nii ja (ni odo won), ko si nii deewo (fun won) |
وَفُرُشٍ مَّرْفُوعَةٍ (34) (Won maa wa lori) ite ti won gbe soke |
إِنَّا أَنشَأْنَاهُنَّ إِنشَاءً (35) Dajudaju Awa tun (awon obinrin won) da ni eda otun |
فَجَعَلْنَاهُنَّ أَبْكَارًا (36) A si se won ni wundia |
عُرُبًا أَتْرَابًا (37) ololufe oko. Won si dogba ni ojo ori |
لِّأَصْحَابِ الْيَمِينِ (38) (Won wa) fun awon ero owo otun |
ثُلَّةٌ مِّنَ الْأَوَّلِينَ (39) Won po ninu awon eni akoko |
وَثُلَّةٌ مِّنَ الْآخِرِينَ (40) Won tun po ninu awon eni Ikeyin |
وَأَصْحَابُ الشِّمَالِ مَا أَصْحَابُ الشِّمَالِ (41) Awon ero owo osi, ki ni (o maa ti buru to fun) awon ero owo osi |
فِي سَمُومٍ وَحَمِيمٍ (42) (Won yoo wa) ninu ategun gbigbona ati omi gbigbona |
وَظِلٍّ مِّن يَحْمُومٍ (43) ati ni abe iboji eleeefin dudu |
لَّا بَارِدٍ وَلَا كَرِيمٍ (44) ko tutu, ko si dara |
إِنَّهُمْ كَانُوا قَبْلَ ذَٰلِكَ مُتْرَفِينَ (45) Dajudaju won ti je onigbedemuke siwaju iyen |
وَكَانُوا يُصِرُّونَ عَلَى الْحِنثِ الْعَظِيمِ (46) Won si maa n sorikunkun lori ese nla |
وَكَانُوا يَقُولُونَ أَئِذَا مِتْنَا وَكُنَّا تُرَابًا وَعِظَامًا أَإِنَّا لَمَبْعُوثُونَ (47) Won si maa n wi pe: "Se nigba ti a ba di oku, ti a si di erupe ati egungun, nje Won yoo tun gbe wa dide ni |
أَوَآبَاؤُنَا الْأَوَّلُونَ (48) Se ati awon baba wa, awon eni akoko |
قُلْ إِنَّ الْأَوَّلِينَ وَالْآخِرِينَ (49) So pe: "Dajudaju awon eni akoko ati awon eni Ikeyin |
لَمَجْمُوعُونَ إِلَىٰ مِيقَاتِ يَوْمٍ مَّعْلُومٍ (50) dajudaju A oo ko won jo papo ni akoko ojo kan ti A ti mo |
ثُمَّ إِنَّكُمْ أَيُّهَا الضَّالُّونَ الْمُكَذِّبُونَ (51) Leyin naa, dajudaju eyin olusina, olupe-ododo-niro |
لَآكِلُونَ مِن شَجَرٍ مِّن زَقُّومٍ (52) dajudaju eyin maa je ninu igi zaƙƙum (igi iwo) |
فَمَالِئُونَ مِنْهَا الْبُطُونَ (53) Ikun yin si maa kun bamubamu fun (jije) igi naa |
فَشَارِبُونَ عَلَيْهِ مِنَ الْحَمِيمِ (54) Eyin yo si maa mu omi gbigbona le e lori |
فَشَارِبُونَ شُرْبَ الْهِيمِ (55) Eyin yoo maa mu un ni imumi rakunmi ti ongbe n gbe |
هَٰذَا نُزُلُهُمْ يَوْمَ الدِّينِ (56) Eyi ni nnkan alejo won ni Ojo esan |
نَحْنُ خَلَقْنَاكُمْ فَلَوْلَا تُصَدِّقُونَ (57) Awa l’A seda yin. Ki ni ko je ki e gbagbo lododo |
أَفَرَأَيْتُم مَّا تُمْنُونَ (58) E so fun Mi nipa ato ti e n da jade (sinu apoluke) |
أَأَنتُمْ تَخْلُقُونَهُ أَمْ نَحْنُ الْخَالِقُونَ (59) se eyin le seda re ni tabi Awa l’A seda re |
نَحْنُ قَدَّرْنَا بَيْنَكُمُ الْمَوْتَ وَمَا نَحْنُ بِمَسْبُوقِينَ (60) Awa l’A yan kadara (ojo) iku fun gbogbo yin. Awa ko si le kagara |
عَلَىٰ أَن نُّبَدِّلَ أَمْثَالَكُمْ وَنُنشِئَكُمْ فِي مَا لَا تَعْلَمُونَ (61) lati fi iru yin paaro yin, ki a si tun yin da sinu ohun ti e ko mo |
وَلَقَدْ عَلِمْتُمُ النَّشْأَةَ الْأُولَىٰ فَلَوْلَا تَذَكَّرُونَ (62) E kuku mo iseda akoko, e o se lo iranti |
أَفَرَأَيْتُم مَّا تَحْرُثُونَ (63) E so fun Mi nipa nnkan ti e n gbin sinu ile |
أَأَنتُمْ تَزْرَعُونَهُ أَمْ نَحْنُ الزَّارِعُونَ (64) se eyin l’e n je ki o hu jade ni tabi Awa l’A n je ki o hu jade |
لَوْ نَشَاءُ لَجَعَلْنَاهُ حُطَامًا فَظَلْتُمْ تَفَكَّهُونَ (65) Ti A ba fe ni, Awa iba so o di gbigbe, eyin yo si maa seemo (ti e oo maa ka abamo) |
إِنَّا لَمُغْرَمُونَ (66) (Eyin yo si wi pe:) "Dajudaju awa ti di onigbese |
بَلْ نَحْنُ مَحْرُومُونَ (67) (Awon miiran yo si wi pe:) "Rara o! Won se ikore oko ni eewo fun wa ni |
أَفَرَأَيْتُمُ الْمَاءَ الَّذِي تَشْرَبُونَ (68) E so fun mi nipa omi ti e n mu |
أَأَنتُمْ أَنزَلْتُمُوهُ مِنَ الْمُزْنِ أَمْ نَحْنُ الْمُنزِلُونَ (69) se eyin l’e n so o kale lati inu esujo ni tabi Awa l’A n so o kale |
لَوْ نَشَاءُ جَعَلْنَاهُ أُجَاجًا فَلَوْلَا تَشْكُرُونَ (70) Ti A ba fe ni, Awa iba se e ni omi t’o moro. E o se maa dupe |
أَفَرَأَيْتُمُ النَّارَ الَّتِي تُورُونَ (71) E so fun Mi nipa ina ti e n da |
أَأَنتُمْ أَنشَأْتُمْ شَجَرَتَهَا أَمْ نَحْنُ الْمُنشِئُونَ (72) se eyin l’e seda igi re ni tabi Awa ni Aseda |
نَحْنُ جَعَلْنَاهَا تَذْكِرَةً وَمَتَاعًا لِّلْمُقْوِينَ (73) Awa se ina aye ni iranti (fun Ina orun) ati nnkan elo fun awon onirin-ajo |
فَسَبِّحْ بِاسْمِ رَبِّكَ الْعَظِيمِ (74) Nitori naa, safomo fun oruko Oluwa re, Atobi |
۞ فَلَا أُقْسِمُ بِمَوَاقِعِ النُّجُومِ (75) Mo n bura pelu awon ibuso irawo |
وَإِنَّهُ لَقَسَمٌ لَّوْ تَعْلَمُونَ عَظِيمٌ (76) Dajudaju ibura nla ni, ti e ba mo |
إِنَّهُ لَقُرْآنٌ كَرِيمٌ (77) Dajudaju (al-Ƙur’an) ni nnkan kike alapon-onle |
فِي كِتَابٍ مَّكْنُونٍ (78) (t’o wa) ninu Tira aabo (ninu Laohul-Mahfuth) |
لَّا يَمَسُّهُ إِلَّا الْمُطَهَّرُونَ (79) Ko si eni to le fowo kan an (ni odo Allahu) afi awon eni mimo (iyen, awon molaika) |
تَنزِيلٌ مِّن رَّبِّ الْعَالَمِينَ (80) Won so al-Ƙur’an kale lati odo Oluwa gbogbo eda |
أَفَبِهَٰذَا الْحَدِيثِ أَنتُم مُّدْهِنُونَ (81) Nitori naa, se oro (al-Ƙur’an) yii l’e n pe niro |
وَتَجْعَلُونَ رِزْقَكُمْ أَنَّكُمْ تُكَذِّبُونَ (82) E si n so idupe arisiki yin di pe dajudaju e n pe ododo niro |
فَلَوْلَا إِذَا بَلَغَتِ الْحُلْقُومَ (83) Ki ni o maa ti ri (fun yin) nigba ti emi (yin) ba de ona ofun |
وَأَنتُمْ حِينَئِذٍ تَنظُرُونَ (84) ti eyin yo si maa woran nigba yen |
وَنَحْنُ أَقْرَبُ إِلَيْهِ مِنكُمْ وَلَٰكِن لَّا تُبْصِرُونَ (85) Awa si sunmo on ju eyin lo, sugbon eyin ko riran |
فَلَوْلَا إِن كُنتُمْ غَيْرَ مَدِينِينَ (86) Eyin ko se je eni ti A o nii gbesan lara re |
تَرْجِعُونَهَا إِن كُنتُمْ صَادِقِينَ (87) ki e si da (emi ti o fe bo) pada, ti e ba je olododo |
فَأَمَّا إِن كَانَ مِنَ الْمُقَرَّبِينَ (88) Ni ti eni ti o ba wa ninu awon alasun-unmo (Wa) |
فَرَوْحٌ وَرَيْحَانٌ وَجَنَّتُ نَعِيمٍ (89) isinmi, ese t’o dara ati Ogba Idera (ni tire) |
وَأَمَّا إِن كَانَ مِنْ أَصْحَابِ الْيَمِينِ (90) Ni ti eni ti o ba wa ninu awon ero owo otun |
فَسَلَامٌ لَّكَ مِنْ أَصْحَابِ الْيَمِينِ (91) alaafia ni fun o laaarin awon ero owo otun |
وَأَمَّا إِن كَانَ مِنَ الْمُكَذِّبِينَ الضَّالِّينَ (92) Ni ti eni ti o ba wa ninu awon olupe-ododo-niro, awon olusina |
فَنُزُلٌ مِّنْ حَمِيمٍ (93) nnkan alejo (won) ni omi gbigbona |
وَتَصْلِيَةُ جَحِيمٍ (94) ati wiwo inu ina Jehim |
إِنَّ هَٰذَا لَهُوَ حَقُّ الْيَقِينِ (95) Dajudaju eyi, ohun ni ododo t’o daju |
فَسَبِّحْ بِاسْمِ رَبِّكَ الْعَظِيمِ (96) Nitori naa, safomo fun oruko Oluwa re, Atobi |