يُسَبِّحُ لِلَّهِ مَا فِي السَّمَاوَاتِ وَمَا فِي الْأَرْضِ الْمَلِكِ الْقُدُّوسِ الْعَزِيزِ الْحَكِيمِ (1) Ohunkohun t’o wa ninu awon sanmo ati ohunkohun to wa ninu ile n se afomo fun Allahu, Oba eda, Eni-Mimo julo, Alagbara, Ologbon |
هُوَ الَّذِي بَعَثَ فِي الْأُمِّيِّينَ رَسُولًا مِّنْهُمْ يَتْلُو عَلَيْهِمْ آيَاتِهِ وَيُزَكِّيهِمْ وَيُعَلِّمُهُمُ الْكِتَابَ وَالْحِكْمَةَ وَإِن كَانُوا مِن قَبْلُ لَفِي ضَلَالٍ مُّبِينٍ (2) Oun ni Eni ti O gbe dide laaarin awon alaimoonkomoonka (alainitira) Ojise kan lara won. O n ke awon ayah Re fun won. O n fo won mo (ninu ese). O si n ko won ni Tira ati ogbon ijinle (iyen, sunnah), bi o tile je pe teletele won ti wa ninu isina ponnbele |
وَآخَرِينَ مِنْهُمْ لَمَّا يَلْحَقُوا بِهِمْ ۚ وَهُوَ الْعَزِيزُ الْحَكِيمُ (3) (Ise jije re tun wa fun) awon miiran ti won maa wa ninu awon (omoleyin re), amo ti won ko ti i rin kan won. (Allahu) Oun ni Alagbara, Ologbon |
ذَٰلِكَ فَضْلُ اللَّهِ يُؤْتِيهِ مَن يَشَاءُ ۚ وَاللَّهُ ذُو الْفَضْلِ الْعَظِيمِ (4) Iyen ni oore ajulo Allahu. O n fun eni ti O ba fe. Allahu si ni Oloore-ajulo nla |
مَثَلُ الَّذِينَ حُمِّلُوا التَّوْرَاةَ ثُمَّ لَمْ يَحْمِلُوهَا كَمَثَلِ الْحِمَارِ يَحْمِلُ أَسْفَارًا ۚ بِئْسَ مَثَلُ الْقَوْمِ الَّذِينَ كَذَّبُوا بِآيَاتِ اللَّهِ ۚ وَاللَّهُ لَا يَهْدِي الْقَوْمَ الظَّالِمِينَ (5) Apejuwe ijo ti A fun ni Taorah, leyin naa ti won ko tele e, o da bi apejuwe ketekete ti o ru eru awon tira. Aburu ni apejuwe awon t’o pe awon ayah Allahu niro. Allahu ko si nii fi ona mo ijo alabosi |
قُلْ يَا أَيُّهَا الَّذِينَ هَادُوا إِن زَعَمْتُمْ أَنَّكُمْ أَوْلِيَاءُ لِلَّهِ مِن دُونِ النَّاسِ فَتَمَنَّوُا الْمَوْتَ إِن كُنتُمْ صَادِقِينَ (6) So pe: "Eyin yehudi, ti e ba lero pe dajudaju eyin ni ore Allahu dipo awon eniyan (yooku), e toro iku nigba naa ti e ba je olododo |
وَلَا يَتَمَنَّوْنَهُ أَبَدًا بِمَا قَدَّمَتْ أَيْدِيهِمْ ۚ وَاللَّهُ عَلِيمٌ بِالظَّالِمِينَ (7) Won ko nii toro re laelae nitori ohun ti owo won ti ti siwaju. Allahu si ni Onimo nipa awon alabosi |
قُلْ إِنَّ الْمَوْتَ الَّذِي تَفِرُّونَ مِنْهُ فَإِنَّهُ مُلَاقِيكُمْ ۖ ثُمَّ تُرَدُّونَ إِلَىٰ عَالِمِ الْغَيْبِ وَالشَّهَادَةِ فَيُنَبِّئُكُم بِمَا كُنتُمْ تَعْمَلُونَ (8) So pe: "Dajudaju iku ti e n sa fun, dajudaju o maa pade yin. Leyin naa, won yoo da yin pada si odo Onimo-ikoko ati gbangba. O si maa fun yin ni iro ohun ti e n se nise |
يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا إِذَا نُودِيَ لِلصَّلَاةِ مِن يَوْمِ الْجُمُعَةِ فَاسْعَوْا إِلَىٰ ذِكْرِ اللَّهِ وَذَرُوا الْبَيْعَ ۚ ذَٰلِكُمْ خَيْرٌ لَّكُمْ إِن كُنتُمْ تَعْلَمُونَ (9) Eyin ti e gbagbo ni ododo, nigba ti won ba pe irun ni ojo Jum‘ah, e yara lo sibi iranti Allahu, ki e si pa kata-kara ti. Iyen loore julo fun yin ti e ba mo |
فَإِذَا قُضِيَتِ الصَّلَاةُ فَانتَشِرُوا فِي الْأَرْضِ وَابْتَغُوا مِن فَضْلِ اللَّهِ وَاذْكُرُوا اللَّهَ كَثِيرًا لَّعَلَّكُمْ تُفْلِحُونَ (10) Nigba ti won ba si pari irun, e tuka si ori ile, ki e si maa wa ninu oore Allahu. E ranti Allahu ni opolopo nitori ki e le jere |
وَإِذَا رَأَوْا تِجَارَةً أَوْ لَهْوًا انفَضُّوا إِلَيْهَا وَتَرَكُوكَ قَائِمًا ۚ قُلْ مَا عِندَ اللَّهِ خَيْرٌ مِّنَ اللَّهْوِ وَمِنَ التِّجَارَةِ ۚ وَاللَّهُ خَيْرُ الرَّازِقِينَ (11) Nigba ti won ba ri oja kan tabi iranu kan, won yoo da lo sibe. Won yo si fi o sile lori iduro. So pe: "Nnkan ti o wa ni odo Allahu l’oore ju iranu ati oja lo. Allahu si l’oore julo ninu awon olupese |