| يَا أَيُّهَا الْمُدَّثِّرُ (1) Iwo oludasobora
 | 
| قُمْ فَأَنذِرْ (2) Dide ki o sekilo
 | 
| وَرَبَّكَ فَكَبِّرْ (3) Oluwa re si ni ki o gbe titobi fun
 | 
| وَثِيَابَكَ فَطَهِّرْ (4) Aso re ni ki o fo mo
 | 
| وَالرُّجْزَ فَاهْجُرْ (5) Orisa ni ki o jinna si
 | 
| وَلَا تَمْنُن تَسْتَكْثِرُ (6) Ma se tore nitori ki o le ri pupo gba
 | 
| وَلِرَبِّكَ فَاصْبِرْ (7) Oluwa re ni ki o se suuru fun
 | 
| فَإِذَا نُقِرَ فِي النَّاقُورِ (8) Nigba ti won ba fon fere oniwo fun ajinde
 | 
| فَذَٰلِكَ يَوْمَئِذٍ يَوْمٌ عَسِيرٌ (9) iyen, ni ojo yen, ni ojo inira
 | 
| عَلَى الْكَافِرِينَ غَيْرُ يَسِيرٍ (10) ti ko nii rorun fun awon alaigbagbo
 | 
| ذَرْنِي وَمَنْ خَلَقْتُ وَحِيدًا (11) Fi Mi da eni ti Mo da ni oun nikan
 | 
| وَجَعَلْتُ لَهُ مَالًا مَّمْدُودًا (12) Mo si fun un ni opolopo dukia
 | 
| وَبَنِينَ شُهُودًا (13) ati awon omokunrin t’o n be pelu re
 | 
| وَمَهَّدتُّ لَهُ تَمْهِيدًا (14) Mo si se aye nirorun fun un gan-an
 | 
| ثُمَّ يَطْمَعُ أَنْ أَزِيدَ (15) Leyin naa, o tun n jerankan pe ki Ng se alekun
 | 
| كَلَّا ۖ إِنَّهُ كَانَ لِآيَاتِنَا عَنِيدًا (16) Rara o! Dajudaju o je alatako si awon ayah Wa
 | 
| سَأُرْهِقُهُ صَعُودًا (17) Emi yoo la iya ponkeponke bo o lorun (ninu Ina)
 | 
| إِنَّهُ فَكَّرَ وَقَدَّرَ (18) Dajudaju o ronu (lodi nipa al-Ƙur’an). O si pinnu (oro kan ninu emi re)
 | 
| فَقُتِلَ كَيْفَ قَدَّرَ (19) Won si sebi le e nipa bi o se pinnu
 | 
| ثُمَّ قُتِلَ كَيْفَ قَدَّرَ (20) Leyin naa, Won tun sebi le e nipa bi o se pinnu
 | 
| ثُمَّ نَظَرَ (21) Leyin naa, o wo sun
 | 
| ثُمَّ عَبَسَ وَبَسَرَ (22) Leyin naa, o faju ro, o si diju magbari
 | 
| ثُمَّ أَدْبَرَ وَاسْتَكْبَرَ (23) Leyin naa, o peyin da, o si segberaga
 | 
| فَقَالَ إِنْ هَٰذَا إِلَّا سِحْرٌ يُؤْثَرُ (24) O si wi pe: "Ki ni eyi bi ko se idan atowodowo
 | 
| إِنْ هَٰذَا إِلَّا قَوْلُ الْبَشَرِ (25) Ki ni eyi bi ko se oro abara
 | 
| سَأُصْلِيهِ سَقَرَ (26) Emi yoo fi sinu ina Saƙor
 | 
| وَمَا أَدْرَاكَ مَا سَقَرُ (27) Ki l’o mu o mo ohun t’o n je ina Saƙor
 | 
| لَا تُبْقِي وَلَا تَذَرُ (28) (Saƙor) ko nii se e ku, ko si nii pa a ti
 | 
| لَوَّاحَةٌ لِّلْبَشَرِ (29) O maa jo awo ara di dudu
 | 
| عَلَيْهَا تِسْعَةَ عَشَرَ (30) (Awon molaika) mokandinlogun ni eso re
 | 
| وَمَا جَعَلْنَا أَصْحَابَ النَّارِ إِلَّا مَلَائِكَةً ۙ وَمَا جَعَلْنَا عِدَّتَهُمْ إِلَّا فِتْنَةً لِّلَّذِينَ كَفَرُوا لِيَسْتَيْقِنَ الَّذِينَ أُوتُوا الْكِتَابَ وَيَزْدَادَ الَّذِينَ آمَنُوا إِيمَانًا ۙ وَلَا يَرْتَابَ الَّذِينَ أُوتُوا الْكِتَابَ وَالْمُؤْمِنُونَ ۙ وَلِيَقُولَ الَّذِينَ فِي قُلُوبِهِم مَّرَضٌ وَالْكَافِرُونَ مَاذَا أَرَادَ اللَّهُ بِهَٰذَا مَثَلًا ۚ كَذَٰلِكَ يُضِلُّ اللَّهُ مَن يَشَاءُ وَيَهْدِي مَن يَشَاءُ ۚ وَمَا يَعْلَمُ جُنُودَ رَبِّكَ إِلَّا هُوَ ۚ وَمَا هِيَ إِلَّا ذِكْرَىٰ لِلْبَشَرِ (31) Awa ko se eni kan ni eso Ina afi awon molaika. Awa ko si se onka won (bee) bi ko se (nitori ki o le je) adanwo fun awon t’o sai gbagbo, ati nitori ki awon ti A fun ni Tira le ni amodaju ati nitori ki awon ti won gbagbo ni ododo le lekun ni igbagbo ododo. (O ri bee) nitori ki awon ti A fun ni Tira ati awon onigbagbo ododo ma baa seyemeji ati nitori ki awon ti arun wa ninu okan won ati awon alaigbagbo le wi pe: "Ki ni Allahu gba lero pelu apejuwe yii?" Bayen ni Allahu se n si eni ti O ba fe lona, O si n to eni ti O ba fe sona. Ko si si eni ti o mo awon omo ogun Oluwa re afi Oun naa. (Ina Saƙor) ko si je kini kan bi ko se iranti fun abara
 | 
| كَلَّا وَالْقَمَرِ (32) E gbo! Allahu bura pelu osupa
 | 
| وَاللَّيْلِ إِذْ أَدْبَرَ (33) O tun bura pelu ale nigba ti o ba lo
 | 
| وَالصُّبْحِ إِذَا أَسْفَرَ (34) O tun bura pelu owuro nigba ti ojumo ba mo
 | 
| إِنَّهَا لَإِحْدَى الْكُبَرِ (35) Dajudaju (ina Saƙor) ni okan ninu (awon adanwo) t’o tobi
 | 
| نَذِيرًا لِّلْبَشَرِ (36) (O je) ikilo fun abara
 | 
| لِمَن شَاءَ مِنكُمْ أَن يَتَقَدَّمَ أَوْ يَتَأَخَّرَ (37) Fun eni ti o ba fe ninu yin lati te siwaju tabi lati fa seyin
 | 
| كُلُّ نَفْسٍ بِمَا كَسَبَتْ رَهِينَةٌ (38) Emi kookan ni oniduuro fun ohun t’o se nise
 | 
| إِلَّا أَصْحَابَ الْيَمِينِ (39) Ayafi awon ero owo otun
 | 
| فِي جَنَّاتٍ يَتَسَاءَلُونَ (40) Won yoo maa bira won leere oro ninu awon Ogba Idera
 | 
| عَنِ الْمُجْرِمِينَ (41) nipa awon elese pe
 | 
| مَا سَلَكَكُمْ فِي سَقَرَ (42) Ki ni o mu yin wo inu ina Saƙor
 | 
| قَالُوا لَمْ نَكُ مِنَ الْمُصَلِّينَ (43) Won yoo wi pe: "Awa ko si ninu awon olukirun ni
 | 
| وَلَمْ نَكُ نُطْعِمُ الْمِسْكِينَ (44) Awa ko si si ninu awon t’o n bo awon mekunnu
 | 
| وَكُنَّا نَخُوضُ مَعَ الْخَائِضِينَ (45) Awa si maa n so isokuso pelu awon onisokuso
 | 
| وَكُنَّا نُكَذِّبُ بِيَوْمِ الدِّينِ (46) Ati pe awa maa n pe Ojo esan niro
 | 
| حَتَّىٰ أَتَانَا الْيَقِينُ (47) titi iku fi de ba wa
 | 
| فَمَا تَنفَعُهُمْ شَفَاعَةُ الشَّافِعِينَ (48) Ipe awon olusipe ko si nii se won ni anfaani
 | 
| فَمَا لَهُمْ عَنِ التَّذْكِرَةِ مُعْرِضِينَ (49) Ki lo mu won na ti won n gbunri kuro nibi iranti
 | 
| كَأَنَّهُمْ حُمُرٌ مُّسْتَنفِرَةٌ (50) bi eni pe awon ni ketekete t’o n sa lo
 | 
| فَرَّتْ مِن قَسْوَرَةٍ (51) t’o sa fun kinihun
 | 
| بَلْ يُرِيدُ كُلُّ امْرِئٍ مِّنْهُمْ أَن يُؤْتَىٰ صُحُفًا مُّنَشَّرَةً (52) Rara, nse ni enikookan ninu won n fe ki A fun oun naa ni Tira ti o maa see te han awon eniyan (bii ti al-Ƙur’an)
 | 
| كَلَّا ۖ بَل لَّا يَخَافُونَ الْآخِرَةَ (53) Rara. Won ko paya orun ni
 | 
| كَلَّا إِنَّهُ تَذْكِرَةٌ (54) E gbo! Dajudaju al-Ƙur’an ni iranti
 | 
| فَمَن شَاءَ ذَكَرَهُ (55) Nitori naa, eni ti o ba fe ko ranti re
 | 
| وَمَا يَذْكُرُونَ إِلَّا أَن يَشَاءَ اللَّهُ ۚ هُوَ أَهْلُ التَّقْوَىٰ وَأَهْلُ الْمَغْفِرَةِ (56) Won ko si nii ranti (al-Ƙur’an) afi ti Allahu ba fe. (Allahu) Oun l’a gbodo beru. Oun l’o si laforijin
 |