وَالْفَجْرِ (1) Allahu bura pelu afemojumo |
وَلَيَالٍ عَشْرٍ (2) O tun bura pelu awon oru mewaa kan |
وَالشَّفْعِ وَالْوَتْرِ (3) O tun bura pelu meji ati eyo |
وَاللَّيْلِ إِذَا يَسْرِ (4) O tun bura pelu oru nigba ti o ba lo (ti o ba de) |
هَلْ فِي ذَٰلِكَ قَسَمٌ لِّذِي حِجْرٍ (5) Nje ibura wa ninu iyen fun onilaakaye |
أَلَمْ تَرَ كَيْفَ فَعَلَ رَبُّكَ بِعَادٍ (6) Se o o ri bi Oluwa re ti se oro ara ‘Ad |
إِرَمَ ذَاتِ الْعِمَادِ (7) (iyen awon iran) ’Irom, awon omiran |
الَّتِي لَمْ يُخْلَقْ مِثْلُهَا فِي الْبِلَادِ (8) awon ti A o da iru won mo sinu ilu |
وَثَمُودَ الَّذِينَ جَابُوا الصَّخْرَ بِالْوَادِ (9) Ati awon Thamud ti won gbe (ile igbe) sinu apata ninu afonifoji |
وَفِرْعَوْنَ ذِي الْأَوْتَادِ (10) ati Fir‘aon eleekan (iya) |
الَّذِينَ طَغَوْا فِي الْبِلَادِ (11) (Awon wonyi ni) awon t’o tayo enu-ala ninu ilu |
فَأَكْثَرُوا فِيهَا الْفَسَادَ (12) Won si se ibaje pupo sinu re |
فَصَبَّ عَلَيْهِمْ رَبُّكَ سَوْطَ عَذَابٍ (13) Oluwa re si rojo iya le won lori |
إِنَّ رَبَّكَ لَبِالْمِرْصَادِ (14) Dajudaju Oluwa re wa ni ibuso (ise eda) |
فَأَمَّا الْإِنسَانُ إِذَا مَا ابْتَلَاهُ رَبُّهُ فَأَكْرَمَهُ وَنَعَّمَهُ فَيَقُولُ رَبِّي أَكْرَمَنِ (15) Nitori naa, ni ti eniyan, nigba ti Oluwa re ba dan an wo, ti O pon on le, ti O si se idera fun un, nigba naa o maa wi pe: "Oluwa mi ti pon mi le |
وَأَمَّا إِذَا مَا ابْتَلَاهُ فَقَدَرَ عَلَيْهِ رِزْقَهُ فَيَقُولُ رَبِّي أَهَانَنِ (16) Sugbon nigba ti O ba dan an wo, ti O gan arisiki re le e lowo, nigba naa o maa wi pe: "Oluwa mi ti yepere mi |
كَلَّا ۖ بَل لَّا تُكْرِمُونَ الْيَتِيمَ (17) Rara, ko ri bee. Amo, eyin ko saponle omo-orukan |
وَلَا تَحَاضُّونَ عَلَىٰ طَعَامِ الْمِسْكِينِ (18) Ati pe eyin ko gbera yin longbe lati fun mekunnu ni ounje |
وَتَأْكُلُونَ التُّرَاثَ أَكْلًا لَّمًّا (19) E tun n je ogun ni ijekuje |
وَتُحِبُّونَ الْمَالَ حُبًّا جَمًّا (20) Ati pe e nifee si dukia ni ife pupo |
كَلَّا إِذَا دُكَّتِ الْأَرْضُ دَكًّا دَكًّا (21) Rara, (ko ye ko ri bee). Nigba ti won ba mi ile titi ni mimi titi (t’o run womuwomu, ti ko si koto, ti ko si gelemo) |
وَجَاءَ رَبُّكَ وَالْمَلَكُ صَفًّا صَفًّا (22) (ti) Oluwa re de pelu awon molaika ni owoowo owoowo |
وَجِيءَ يَوْمَئِذٍ بِجَهَنَّمَ ۚ يَوْمَئِذٍ يَتَذَكَّرُ الْإِنسَانُ وَأَنَّىٰ لَهُ الذِّكْرَىٰ (23) ni ojo yen ni won maa mu ina Jahanamo wa. Ni ojo yen, eniyan yoo ranti (oro ara re). Bawo si ni iranti naa se le wulo fun un |
يَقُولُ يَا لَيْتَنِي قَدَّمْتُ لِحَيَاتِي (24) O maa wi pe: "Yee, emi iba ti ti (ise rere) siwaju fun isemi mi |
فَيَوْمَئِذٍ لَّا يُعَذِّبُ عَذَابَهُ أَحَدٌ (25) Ni ojo yen, eni kan ko le fi iya je (eda) bi iru iya (ti) Allahu (yoo fi je e) |
وَلَا يُوثِقُ وَثَاقَهُ أَحَدٌ (26) Eni kan ko si le de (eda) ni igbekun bi iru igbekun (ti) Allahu (yoo fi de e) |
يَا أَيَّتُهَا النَّفْسُ الْمُطْمَئِنَّةُ (27) Iwo emi olufokanbale |
ارْجِعِي إِلَىٰ رَبِّكِ رَاضِيَةً مَّرْضِيَّةً (28) pada si odo Oluwa re ni oluyonu, eni iyonu |
فَادْخُلِي فِي عِبَادِي (29) Nitori naa, wole saaarin awon erusin Mi |
وَادْخُلِي جَنَّتِي (30) Wo inu Ogba Idera Mi |