إِذَا الشَّمْسُ كُوِّرَتْ (1) Nigba ti Won ba ka oorun korobojo danu |
وَإِذَا النُّجُومُ انكَدَرَتْ (2) ati nigba ti awon irawo ba ja bo kaakiri |
وَإِذَا الْجِبَالُ سُيِّرَتْ (3) ati nigba ti Won ba mu awon apata rin (kuro ni aye won, ti won ku won danu) |
وَإِذَا الْعِشَارُ عُطِّلَتْ (4) ati nigba ti won ba pa awon rakunmi aboyun ti |
وَإِذَا الْوُحُوشُ حُشِرَتْ (5) ati nigba ti Won ba ko awon eranko jo |
وَإِذَا الْبِحَارُ سُجِّرَتْ (6) ati nigba ti Won ba mu awon agbami odo gbina |
وَإِذَا النُّفُوسُ زُوِّجَتْ (7) ati nigba ti Won ba so awon emi po mora won, (eni rere pelu eni rere, eni ibi pelu eni ibi) |
وَإِذَا الْمَوْءُودَةُ سُئِلَتْ (8) ati nigba ti omobinrin ti won bo mole laaye ba beere pe |
بِأَيِّ ذَنبٍ قُتِلَتْ (9) ese wo ni won pa oun fun |
وَإِذَا الصُّحُفُ نُشِرَتْ (10) ati nigba ti Won ba si awon takada (ise eda) sile |
وَإِذَا السَّمَاءُ كُشِطَتْ (11) ati nigba ti Won ba ka sanmo kuro loke |
وَإِذَا الْجَحِيمُ سُعِّرَتْ (12) ati nigba ti won ba mu ina Jehim jo fofo |
وَإِذَا الْجَنَّةُ أُزْلِفَتْ (13) ati nigba ti Won ba sun Ogba Idera mo (awon onigbagbo ododo) |
عَلِمَتْ نَفْسٌ مَّا أَحْضَرَتْ (14) (nigba naa ni) emi (kookan) yoo mo ohun ti o mu wa (ninu ise ire ati ise ibi) |
فَلَا أُقْسِمُ بِالْخُنَّسِ (15) Nitori naa, Emi (Allahu) n bura pelu awon irawo t’o n yo ni ale, t’o n wookun ni osan |
الْجَوَارِ الْكُنَّسِ (16) (iyen) awon irawo t’o n rin lo rin bo, t’o n wookun si ibuwo won |
وَاللَّيْلِ إِذَا عَسْعَسَ (17) Mo tun bura pelu ale nigba ti o ba lo |
وَالصُّبْحِ إِذَا تَنَفَّسَ (18) Mo tun bura pelu owuro nigba ti o ba mole |
إِنَّهُ لَقَوْلُ رَسُولٍ كَرِيمٍ (19) Dajudaju (al-Ƙur’an) ni oro (ti A fi ran Jibril) Ojise, alapon-onle |
ذِي قُوَّةٍ عِندَ ذِي الْعَرْشِ مَكِينٍ (20) alagbara, eni pataki ni odo Eni t’O ni Ite-ola |
مُّطَاعٍ ثَمَّ أَمِينٍ (21) eni ti won n tele ase re nibe yen (ninu sanmo), olufokantan |
وَمَا صَاحِبُكُم بِمَجْنُونٍ (22) Ati pe eni yin (Anabi Muhammad s.a.w.) ki i se were |
وَلَقَدْ رَآهُ بِالْأُفُقِ الْمُبِينِ (23) O kuku ri i ninu ofurufu kedere |
وَمَا هُوَ عَلَى الْغَيْبِ بِضَنِينٍ (24) Ati pe ki i se ahun (tabi eni-afurasi) lori iro ikoko (ti A fi ranse si i) |
وَمَا هُوَ بِقَوْلِ شَيْطَانٍ رَّجِيمٍ (25) Al-Ƙur’an ki i si se oro (ti A fi ran) Esu, eni eko |
فَأَيْنَ تَذْهَبُونَ (26) Nitori naa, ibo l’e n lo |
إِنْ هُوَ إِلَّا ذِكْرٌ لِّلْعَالَمِينَ (27) Ki si ni al-Ƙur’an bi ko se iranti fun gbogbo eda |
لِمَن شَاءَ مِنكُمْ أَن يَسْتَقِيمَ (28) (O wa) fun eni ti o ba fe ninu yin lati duro deede |
وَمَا تَشَاءُونَ إِلَّا أَن يَشَاءَ اللَّهُ رَبُّ الْعَالَمِينَ (29) Eyin ko si nii fe (lati duro deede) ayafi ti Allahu ba fe, Oluwa gbogbo eda |