| وَالشَّمْسِ وَضُحَاهَا (1) (Allahu) bura pelu oorun ati iyaleta re
 | 
| وَالْقَمَرِ إِذَا تَلَاهَا (2) O tun bura pelu osupa nigba ti o ba (yo) tele (oorun)
 | 
| وَالنَّهَارِ إِذَا جَلَّاهَا (3) O tun bura pelu osan nigba ti o ba mu imole ba okunkun oru
 | 
| وَاللَّيْلِ إِذَا يَغْشَاهَا (4) O tun bura pelu ale nigba ti o ba bo osan mole
 | 
| وَالسَّمَاءِ وَمَا بَنَاهَا (5) O tun bura pelu sanmo ati Eni ti O mo on
 | 
| وَالْأَرْضِ وَمَا طَحَاهَا (6) O tun bura pelu ile ati Eni ti O te e kale
 | 
| وَنَفْسٍ وَمَا سَوَّاهَا (7) O tun bura pelu emi (eniyan) ati Eni ti O se (orikee re) dogba
 | 
| فَأَلْهَمَهَا فُجُورَهَا وَتَقْوَاهَا (8) O si fi ese (ti emi le da) ati iberu re mo on
 | 
| قَدْ أَفْلَحَ مَن زَكَّاهَا (9) Enikeni ti o ba safomo (emi ara) re (nibi ese), o ma ti jere
 | 
| وَقَدْ خَابَ مَن دَسَّاهَا (10) Enikeni ti o ba fi (iwa ese) ba emi (ara) re je, o ma ti padanu
 | 
| كَذَّبَتْ ثَمُودُ بِطَغْوَاهَا (11) Ijo Thamud pe ododo niro nipa itayo enu-ala won
 | 
| إِذِ انبَعَثَ أَشْقَاهَا (12) (Ranti) nigba ti eni ti ori re buru julo ninu won sare dide (lati gun rakunmi pa)
 | 
| فَقَالَ لَهُمْ رَسُولُ اللَّهِ نَاقَةَ اللَّهِ وَسُقْيَاهَا (13) Nigba naa, Ojise Allahu so fun won pe: "(E fi) abo rakunmi Allahu ati omi re (sile)
 | 
| فَكَذَّبُوهُ فَعَقَرُوهَا فَدَمْدَمَ عَلَيْهِمْ رَبُّهُم بِذَنبِهِمْ فَسَوَّاهَا (14) Won pe e niro. Won si gun (rakunmi) pa. Nitori naa, Oluwa won pa won re nitori ese won. O si fi iparun naa kari won
 | 
| وَلَا يَخَافُ عُقْبَاهَا (15) (Eni t’o gun rakunmi pa) ko si paya ikangun oro won
 |