إِذَا السَّمَاءُ انفَطَرَتْ (1) Nigba ti sanmo ba fa ya perepere |
وَإِذَا الْكَوَاكِبُ انتَثَرَتْ (2) ati nigba ti awon irawo ba ja bo kaakiri |
وَإِذَا الْبِحَارُ فُجِّرَتْ (3) ati nigba ti awon ibudo ba san jara won |
وَإِذَا الْقُبُورُ بُعْثِرَتْ (4) ati (nigba ti A ba ta ile soke), ti A si mu awon oku jade (laaye) lati inu awon saree |
عَلِمَتْ نَفْسٌ مَّا قَدَّمَتْ وَأَخَّرَتْ (5) (nigba naa ni) emi kookan yoo mo ohun ti o ti siwaju (ninu ise re) ati ohun ti o fi seyin (ninu oripa ise re) |
يَا أَيُّهَا الْإِنسَانُ مَا غَرَّكَ بِرَبِّكَ الْكَرِيمِ (6) Iwo eniyan, ki ni o tan o je nipa Oluwa re, Alapon-onle |
الَّذِي خَلَقَكَ فَسَوَّاكَ فَعَدَلَكَ (7) Eni t’O seda re? O seda re ni pipe. O si mu o dogba jale leeyan |
فِي أَيِّ صُورَةٍ مَّا شَاءَ رَكَّبَكَ (8) O to eya ara re papo sinu eyikeyii aworan ti O fe |
كَلَّا بَلْ تُكَذِّبُونَ بِالدِّينِ (9) Ni ti ododo, nse l’e n pe Ojo esan niro |
وَإِنَّ عَلَيْكُمْ لَحَافِظِينَ (10) Dajudaju awon eso si wa ni odo yin |
كِرَامًا كَاتِبِينَ (11) (Won je) alapon-onle, onkowe-ise eda |
يَعْلَمُونَ مَا تَفْعَلُونَ (12) Won mo ohun ti e n se nise |
إِنَّ الْأَبْرَارَ لَفِي نَعِيمٍ (13) Dajudaju awon eni rere yoo kuku wa ninu igbadun |
وَإِنَّ الْفُجَّارَ لَفِي جَحِيمٍ (14) Dajudaju awon eni ibi yo si kuku wa ninu ina Jehim |
يَصْلَوْنَهَا يَوْمَ الدِّينِ (15) Won yoo wo inu re ni Ojo esan |
وَمَا هُمْ عَنْهَا بِغَائِبِينَ (16) Won ko si nii kuro ninu re |
وَمَا أَدْرَاكَ مَا يَوْمُ الدِّينِ (17) Ki si ni o mu o mo ohun t’o n je Ojo esan |
ثُمَّ مَا أَدْرَاكَ مَا يَوْمُ الدِّينِ (18) Leyin naa, ki ni o mu o mo ohun t’o n je Ojo esan |
يَوْمَ لَا تَمْلِكُ نَفْسٌ لِّنَفْسٍ شَيْئًا ۖ وَالْأَمْرُ يَوْمَئِذٍ لِّلَّهِ (19) (Ojo esan ni) ojo ti emi kan ko nii kapa kini kan fun emi kan. Gbogbo ase ojo yen si n je ti Allahu |