تَبَارَكَ الَّذِي بِيَدِهِ الْمُلْكُ وَهُوَ عَلَىٰ كُلِّ شَيْءٍ قَدِيرٌ (1) Ibukun ni fun Eni ti ijoba wa ni Owo Re. Oun si ni Alagbara lori gbogbo nnkan |
الَّذِي خَلَقَ الْمَوْتَ وَالْحَيَاةَ لِيَبْلُوَكُمْ أَيُّكُمْ أَحْسَنُ عَمَلًا ۚ وَهُوَ الْعَزِيزُ الْغَفُورُ (2) Eni ti O da iku ati isemi nitori ki o le dan yin wo; ewo ninu yin l’o maa se ise rere julo. Oun si ni Alagbara, Alaforijin |
الَّذِي خَلَقَ سَبْعَ سَمَاوَاتٍ طِبَاقًا ۖ مَّا تَرَىٰ فِي خَلْقِ الرَّحْمَٰنِ مِن تَفَاوُتٍ ۖ فَارْجِعِ الْبَصَرَ هَلْ تَرَىٰ مِن فُطُورٍ (3) Eni ti O da awon sanmo meje ni ipele ipele. O o le ri aigunrege kan lara eda Ajoke-aye. Nitori naa, wo o pada, nje o ri oju sisan kan (lara sanmo) |
ثُمَّ ارْجِعِ الْبَصَرَ كَرَّتَيْنِ يَنقَلِبْ إِلَيْكَ الْبَصَرُ خَاسِئًا وَهُوَ حَسِيرٌ (4) Leyin naa, wo o pada ni ee meji, ki oju re pada si odo re pelu iyepere. O si maa kaaare |
وَلَقَدْ زَيَّنَّا السَّمَاءَ الدُّنْيَا بِمَصَابِيحَ وَجَعَلْنَاهَا رُجُومًا لِّلشَّيَاطِينِ ۖ وَأَعْتَدْنَا لَهُمْ عَذَابَ السَّعِيرِ (5) Dajudaju A ti fi (awon irawo t’o n tanmole bi) atupa se sanmo ile aye ni oso. A tun se won ni eta-irawo ti won n ju mo awon esu. A si pese iya Ina t’o n jo fofo sile de won |
وَلِلَّذِينَ كَفَرُوا بِرَبِّهِمْ عَذَابُ جَهَنَّمَ ۖ وَبِئْسَ الْمَصِيرُ (6) Iya ina Jahanamo si wa fun awon t’o sai gbagbo. Ikangun naa si buru |
إِذَا أُلْقُوا فِيهَا سَمِعُوا لَهَا شَهِيقًا وَهِيَ تَفُورُ (7) Nigba ti won ba ju won sinu re, won yoo maa gbo kikun re, ti o si maa ru soke |
تَكَادُ تَمَيَّزُ مِنَ الْغَيْظِ ۖ كُلَّمَا أُلْقِيَ فِيهَا فَوْجٌ سَأَلَهُمْ خَزَنَتُهَا أَلَمْ يَأْتِكُمْ نَذِيرٌ (8) Ina maa fee pinra re lati ara ibinu. Igbakigba ti won ba ju ijo kan sinu re, awon eso Ina yoo maa bi won leere pe: "Nje olukilo kan ko wa ba yin bi |
قَالُوا بَلَىٰ قَدْ جَاءَنَا نَذِيرٌ فَكَذَّبْنَا وَقُلْنَا مَا نَزَّلَ اللَّهُ مِن شَيْءٍ إِنْ أَنتُمْ إِلَّا فِي ضَلَالٍ كَبِيرٍ (9) Won yoo wi pe: "Rara, dajudaju olukilo kan ti wa ba wa, sugbon a pe e ni opuro. A si wi pe Allahu ko so nnkan kan kale. Ki ni eyin bi ko se pe e wa ninu isina t’o tobi |
وَقَالُوا لَوْ كُنَّا نَسْمَعُ أَوْ نَعْقِلُ مَا كُنَّا فِي أَصْحَابِ السَّعِيرِ (10) Won tun wi pe: "Ti o ba je pe a gboran ni tabi pe a se laakaye ni, awa ko nii wa ninu ero inu Ina jijo |
فَاعْتَرَفُوا بِذَنبِهِمْ فَسُحْقًا لِّأَصْحَابِ السَّعِيرِ (11) Won si jewo ese won. Nitori naa, ijinna si ike Allahu yo wa fun awon ero inu Ina t’o n jo fofo |
إِنَّ الَّذِينَ يَخْشَوْنَ رَبَّهُم بِالْغَيْبِ لَهُم مَّغْفِرَةٌ وَأَجْرٌ كَبِيرٌ (12) Dajudaju awon t’o n paya Oluwa won ni ikoko, aforijin ati esan t’o tobi n be fun won |
وَأَسِرُّوا قَوْلَكُمْ أَوِ اجْهَرُوا بِهِ ۖ إِنَّهُ عَلِيمٌ بِذَاتِ الصُّدُورِ (13) E wi oro yin ni jeeje tabi e wi i soke, dajudaju Oun ni Onimo nipa ohun t’o wa ninu awon igba-aya eda |
أَلَا يَعْلَمُ مَنْ خَلَقَ وَهُوَ اللَّطِيفُ الْخَبِيرُ (14) Se (Allahu) ko mo eni t’O da ni? Oun si ni Alaaanu, Alamotan |
هُوَ الَّذِي جَعَلَ لَكُمُ الْأَرْضَ ذَلُولًا فَامْشُوا فِي مَنَاكِبِهَا وَكُلُوا مِن رِّزْقِهِ ۖ وَإِلَيْهِ النُّشُورُ (15) Oun ni Eni ti O ro ile fun yin. Nitori naa, e rin ni awon agbegbe re kaakiri, ki e si je ninu arisiki Re. Odo Re si ni ajinde eda wa |
أَأَمِنتُم مَّن فِي السَّمَاءِ أَن يَخْسِفَ بِكُمُ الْأَرْضَ فَإِذَا هِيَ تَمُورُ (16) Se e fokanbale si Eni ti O wa ni (oke) sanmo pe ko le je ki ile gbe yin mi? Nigba naa, ile yo si maa mi titi |
أَمْ أَمِنتُم مَّن فِي السَّمَاءِ أَن يُرْسِلَ عَلَيْكُمْ حَاصِبًا ۖ فَسَتَعْلَمُونَ كَيْفَ نَذِيرِ (17) Tabi e fokanbale si Eni ti O wa ni (oke) sanmo pe ko le fi okuta ina ranse si yin ni? Nigba naa, e si maa mo bi ikilo Mi ti ri |
وَلَقَدْ كَذَّبَ الَّذِينَ مِن قَبْلِهِمْ فَكَيْفَ كَانَ نَكِيرِ (18) Awon t’o siwaju won kuku pe ododo niro. Bawo si ni bi Mo se (fi iya) ko (aburu fun won) ti ri |
أَوَلَمْ يَرَوْا إِلَى الطَّيْرِ فَوْقَهُمْ صَافَّاتٍ وَيَقْبِضْنَ ۚ مَا يُمْسِكُهُنَّ إِلَّا الرَّحْمَٰنُ ۚ إِنَّهُ بِكُلِّ شَيْءٍ بَصِيرٌ (19) Se won ko ri awon eye ti o wa ni oke won, ti (won) n na iye apa (won), ti won si n pa a mora? Kini kan ko mu won duro (sinu ofurufu) afi Ajoke-aye. Dajudaju Oun si ni Oluriran nipa gbogbo nnkan |
أَمَّنْ هَٰذَا الَّذِي هُوَ جُندٌ لَّكُمْ يَنصُرُكُم مِّن دُونِ الرَّحْمَٰنِ ۚ إِنِ الْكَافِرُونَ إِلَّا فِي غُرُورٍ (20) Ta ni eni ti o maa je omo ogun fun yin, ti o maa ran yin lowo leyin Ajoke-aye? (Ninu) ki ni awon alaigbagbo wa bi ko se ninu etan |
أَمَّنْ هَٰذَا الَّذِي يَرْزُقُكُمْ إِنْ أَمْسَكَ رِزْقَهُ ۚ بَل لَّجُّوا فِي عُتُوٍّ وَنُفُورٍ (21) Ta ni eni ti o maa pese fun yin ti O ba da arisiki Re duro? Nse ni won n sori kunkun si i ninu igberaga ati sisa fun ododo |
أَفَمَن يَمْشِي مُكِبًّا عَلَىٰ وَجْهِهِ أَهْدَىٰ أَمَّن يَمْشِي سَوِيًّا عَلَىٰ صِرَاطٍ مُّسْتَقِيمٍ (22) Nje eni t’o n rin ni idojubole l’o mona julo ni tabi eni t’o n rin san an loju ona taara |
قُلْ هُوَ الَّذِي أَنشَأَكُمْ وَجَعَلَ لَكُمُ السَّمْعَ وَالْأَبْصَارَ وَالْأَفْئِدَةَ ۖ قَلِيلًا مَّا تَشْكُرُونَ (23) So pe: "Oun ni Eni ti O seda yin. O si se igboro, iriran ati awon okan fun yin. Ope ti e n da si kere pupo |
قُلْ هُوَ الَّذِي ذَرَأَكُمْ فِي الْأَرْضِ وَإِلَيْهِ تُحْشَرُونَ (24) So pe: "Oun ni Eni ti O da yin si ori ile. Odo Re si ni won yoo ko yin jo si |
وَيَقُولُونَ مَتَىٰ هَٰذَا الْوَعْدُ إِن كُنتُمْ صَادِقِينَ (25) Won n wi pe: "Igba wo ni adehun yii yoo se ti e ba je olododo |
قُلْ إِنَّمَا الْعِلْمُ عِندَ اللَّهِ وَإِنَّمَا أَنَا نَذِيرٌ مُّبِينٌ (26) So pe: "Odo Allahu nikan ni imo (nipa) re wa. Emi kan je olukilo ponnbele ni |
فَلَمَّا رَأَوْهُ زُلْفَةً سِيئَتْ وُجُوهُ الَّذِينَ كَفَرُوا وَقِيلَ هَٰذَا الَّذِي كُنتُم بِهِ تَدَّعُونَ (27) Nigba ti won ba ri i t’o sunmo, oju awon t’o sai gbagbo yoo koro wa fun ibanuje. A o si so fun won pe: "Eyi ni ohun ti e n pe |
قُلْ أَرَأَيْتُمْ إِنْ أَهْلَكَنِيَ اللَّهُ وَمَن مَّعِيَ أَوْ رَحِمَنَا فَمَن يُجِيرُ الْكَافِرِينَ مِنْ عَذَابٍ أَلِيمٍ (28) So pe: " E so fun mi, ti Allahu ba pa emi ati awon t’o wa pelu mi re, tabi ti O ba ke wa (se e le di I lowo ni?) Nitori naa, ta ni o maa gba awon alaigbagbo la ninu iya eleta-elero |
قُلْ هُوَ الرَّحْمَٰنُ آمَنَّا بِهِ وَعَلَيْهِ تَوَكَّلْنَا ۖ فَسَتَعْلَمُونَ مَنْ هُوَ فِي ضَلَالٍ مُّبِينٍ (29) So pe: "Oun ni Ajoke-aye. Awa gba A gbo. Oun si la gbarale. Laipe e maa mo ta ni o wa ninu isina ponnbele |
قُلْ أَرَأَيْتُمْ إِنْ أَصْبَحَ مَاؤُكُمْ غَوْرًا فَمَن يَأْتِيكُم بِمَاءٍ مَّعِينٍ (30) So pe: " E so fun mi, ti omi yin ba gbe wa, ta ni eni ti o maa mu omi iseleru wa ba yin |