سَبِّحِ اسْمَ رَبِّكَ الْأَعْلَى (1) Safomo fun oruko Oluwa re, Eni giga julo |
الَّذِي خَلَقَ فَسَوَّىٰ (2) Eni ti O da eda. O si se (orikee-rikee re) ni dogbadogba |
وَالَّذِي قَدَّرَ فَهَدَىٰ (3) Eni ti O yan kadara (fun eda). O si to o sona |
وَالَّذِي أَخْرَجَ الْمَرْعَىٰ (4) Eni ti O mu koriko tutu (hu) jade |
فَجَعَلَهُ غُثَاءً أَحْوَىٰ (5) O si so o di gbigbe t’o dudu |
سَنُقْرِئُكَ فَلَا تَنسَىٰ (6) Awa yoo maa ke (al-Ƙur’an) fun o. Iwo ko si nii gbagbe |
إِلَّا مَا شَاءَ اللَّهُ ۚ إِنَّهُ يَعْلَمُ الْجَهْرَ وَمَا يَخْفَىٰ (7) Ayafi ohun ti Allahu ba fe. Dajudaju O mo gbangba ati ohun t’o pamo |
وَنُيَسِّرُكَ لِلْيُسْرَىٰ (8) Awa yo si se ise rere ni irorun fun o |
فَذَكِّرْ إِن نَّفَعَتِ الذِّكْرَىٰ (9) Nitori naa, seranti ni aye ti iranti ti wulo |
سَيَذَّكَّرُ مَن يَخْشَىٰ (10) Eni ti o maa paya (Allahu) maa lo iranti |
وَيَتَجَنَّبُهَا الْأَشْقَى (11) Olori-buruku si maa takete si i |
الَّذِي يَصْلَى النَّارَ الْكُبْرَىٰ (12) (Oun si ni) eni ti o maa wo inu Ina t’o tobi |
ثُمَّ لَا يَمُوتُ فِيهَا وَلَا يَحْيَىٰ (13) Leyin naa, ko nii ku sinu re, ko si nii semi (alaafia) |
قَدْ أَفْلَحَ مَن تَزَكَّىٰ (14) Dajudaju eni ti o ba safomo (okan re) ti jere |
وَذَكَرَ اسْمَ رَبِّهِ فَصَلَّىٰ (15) O tun ranti oruko Oluwa re, o si kirun |
بَلْ تُؤْثِرُونَ الْحَيَاةَ الدُّنْيَا (16) Rara, nse l’e n gbe ajulo fun isemi aye |
وَالْآخِرَةُ خَيْرٌ وَأَبْقَىٰ (17) Orun si loore julo, o si maa wa titi laelae |
إِنَّ هَٰذَا لَفِي الصُّحُفِ الْأُولَىٰ (18) Dajudaju eyi wa ninu awon takada akoko |
صُحُفِ إِبْرَاهِيمَ وَمُوسَىٰ (19) takada (Anabi) ’Ibrohim ati (Anabi) Musa |