يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا لَا تُقَدِّمُوا بَيْنَ يَدَيِ اللَّهِ وَرَسُولِهِ ۖ وَاتَّقُوا اللَّهَ ۚ إِنَّ اللَّهَ سَمِيعٌ عَلِيمٌ (1) Eyin ti e gbagbo ni ododo, eyin ko gbodo gbawaju mo Allahu ati Ojise Re lowo. Ki e si beru Allahu. Dajudaju Allahu ni Olugbo, Onimo |
يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا لَا تَرْفَعُوا أَصْوَاتَكُمْ فَوْقَ صَوْتِ النَّبِيِّ وَلَا تَجْهَرُوا لَهُ بِالْقَوْلِ كَجَهْرِ بَعْضِكُمْ لِبَعْضٍ أَن تَحْبَطَ أَعْمَالُكُمْ وَأَنتُمْ لَا تَشْعُرُونَ (2) Eyin ti e gbagbo ni ododo, e ma se gbe ohun yin ga bori ohun Anabi (sollalahu 'alayhi wa sallam). Ki e si ma se fi ohun ariwo ba a soro gege bi apa kan yin se n fi ohun ariwo ba apa kan soro nitori ki awon ise yin ma baa baje, eyin ko si nii fura |
إِنَّ الَّذِينَ يَغُضُّونَ أَصْوَاتَهُمْ عِندَ رَسُولِ اللَّهِ أُولَٰئِكَ الَّذِينَ امْتَحَنَ اللَّهُ قُلُوبَهُمْ لِلتَّقْوَىٰ ۚ لَهُم مَّغْفِرَةٌ وَأَجْرٌ عَظِيمٌ (3) Dajudaju awon t’o n re ohun won nile lodo Ojise Allahu, awon wonyen ni awon ti Allahu ti gbidanwo okan won fun iberu (Re). Aforijin ati esan nla wa fun won |
إِنَّ الَّذِينَ يُنَادُونَكَ مِن وَرَاءِ الْحُجُرَاتِ أَكْثَرُهُمْ لَا يَعْقِلُونَ (4) Dajudaju awon t’o n pe o lati eyin awon yara, opolopo won ni ko se laakaye |
وَلَوْ أَنَّهُمْ صَبَرُوا حَتَّىٰ تَخْرُجَ إِلَيْهِمْ لَكَانَ خَيْرًا لَّهُمْ ۚ وَاللَّهُ غَفُورٌ رَّحِيمٌ (5) Ti o ba je pe dajudaju won se suuru titi o maa fi jade si won ni, iba dara julo fun won. Allahu si ni Alaforijin, Asake-orun |
يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا إِن جَاءَكُمْ فَاسِقٌ بِنَبَإٍ فَتَبَيَّنُوا أَن تُصِيبُوا قَوْمًا بِجَهَالَةٍ فَتُصْبِحُوا عَلَىٰ مَا فَعَلْتُمْ نَادِمِينَ (6) Eyin ti e gbagbo ni ododo, ti obileje kan ba mu iro kan wa ba yin, e se pelepele lati mo ododo (nipa oro naa) nitori ki e ma baa se awon eniyan kan ni suta pelu aimo. Leyin naa, ki e ma baa di alabaamo lori ohun ti e se |
وَاعْلَمُوا أَنَّ فِيكُمْ رَسُولَ اللَّهِ ۚ لَوْ يُطِيعُكُمْ فِي كَثِيرٍ مِّنَ الْأَمْرِ لَعَنِتُّمْ وَلَٰكِنَّ اللَّهَ حَبَّبَ إِلَيْكُمُ الْإِيمَانَ وَزَيَّنَهُ فِي قُلُوبِكُمْ وَكَرَّهَ إِلَيْكُمُ الْكُفْرَ وَالْفُسُوقَ وَالْعِصْيَانَ ۚ أُولَٰئِكَ هُمُ الرَّاشِدُونَ (7) Ki e si mo pe dajudaju Ojise Allahu wa laarin yin. Ti o ba je pe o n tele yin nibi opolopo ninu oro (t’o n sele) ni, dajudaju eyin iba ti ko o sinu idaamu. Sugbon Allahu je ki e nifee si igbagbo ododo. O se e ni oso sinu okan yin. O si je ki e korira aigbagbo, iwa buruku ati iyapa ase. Awon wonyen ni awon olumona |
فَضْلًا مِّنَ اللَّهِ وَنِعْمَةً ۚ وَاللَّهُ عَلِيمٌ حَكِيمٌ (8) (Eyi je) oore ajulo ati idera lati odo Allahu. Allahu si ni Onimo, Ologbon |
وَإِن طَائِفَتَانِ مِنَ الْمُؤْمِنِينَ اقْتَتَلُوا فَأَصْلِحُوا بَيْنَهُمَا ۖ فَإِن بَغَتْ إِحْدَاهُمَا عَلَى الْأُخْرَىٰ فَقَاتِلُوا الَّتِي تَبْغِي حَتَّىٰ تَفِيءَ إِلَىٰ أَمْرِ اللَّهِ ۚ فَإِن فَاءَتْ فَأَصْلِحُوا بَيْنَهُمَا بِالْعَدْلِ وَأَقْسِطُوا ۖ إِنَّ اللَّهَ يُحِبُّ الْمُقْسِطِينَ (9) Ti igun meji ninu awon onigbagbo ododo ba n ba ara won ja, e se atunse laaarin awon mejeeji. Ti okan ninu awon mejeeji ba si koja enu-ala lori ikeji, e ba eyi ti o koja enu-ala ja titi o fi maa seri pada sibi ase Allahu. Ti o ba si seri pada, e se atunse laaarin awon mejeeji pelu deede. Ki e si se eto. Dajudaju Allahu feran awon oluse-eto |
إِنَّمَا الْمُؤْمِنُونَ إِخْوَةٌ فَأَصْلِحُوا بَيْنَ أَخَوَيْكُمْ ۚ وَاتَّقُوا اللَّهَ لَعَلَّكُمْ تُرْحَمُونَ (10) Omo iya (esin) ni awon onigbagbo ododo. Nitori naa, e satunse laaarin awon omo iya yin mejeeji. Ki e si beru Allahu nitori ki A le ke yin |
يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا لَا يَسْخَرْ قَوْمٌ مِّن قَوْمٍ عَسَىٰ أَن يَكُونُوا خَيْرًا مِّنْهُمْ وَلَا نِسَاءٌ مِّن نِّسَاءٍ عَسَىٰ أَن يَكُنَّ خَيْرًا مِّنْهُنَّ ۖ وَلَا تَلْمِزُوا أَنفُسَكُمْ وَلَا تَنَابَزُوا بِالْأَلْقَابِ ۖ بِئْسَ الِاسْمُ الْفُسُوقُ بَعْدَ الْإِيمَانِ ۚ وَمَن لَّمْ يَتُبْ فَأُولَٰئِكَ هُمُ الظَّالِمُونَ (11) Eyin ti e gbagbo ni ododo, awon eniyan kan ko gbodo fi awon eniyan kan se yeye. O le je pe awon (ti won so di oniyeye) dara ju awon (t’o n se yeye). Awon obinrin kan (ko si gbodo fi) awon obinrin kan (se yeye). O le je pe awon (ti won so di oniyeye) dara ju awon (t’o n se yeye). E ma se bura yin. E ma pe’ra yin loriki buruku leyin igbagbo ododo. Enikeni ti ko ba ronu piwada, awon wonyen ni awon alabosi |
يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا اجْتَنِبُوا كَثِيرًا مِّنَ الظَّنِّ إِنَّ بَعْضَ الظَّنِّ إِثْمٌ ۖ وَلَا تَجَسَّسُوا وَلَا يَغْتَب بَّعْضُكُم بَعْضًا ۚ أَيُحِبُّ أَحَدُكُمْ أَن يَأْكُلَ لَحْمَ أَخِيهِ مَيْتًا فَكَرِهْتُمُوهُ ۚ وَاتَّقُوا اللَّهَ ۚ إِنَّ اللَّهَ تَوَّابٌ رَّحِيمٌ (12) Eyin ti e gbagbo ni ododo, e jinna si opolopo aroso. Dajudaju apa kan aroso ni ese. E ma se topinpin ara yin. Ki apa kan yin ma se soro apa kan leyin. Se okan ninu yin nifee si lati je eran-ara omo iya re t’o ti ku ni? E si korira re. E beru Allahu. Dajudaju Allahu ni Olugba-ironupiwada, Asake-orun |
يَا أَيُّهَا النَّاسُ إِنَّا خَلَقْنَاكُم مِّن ذَكَرٍ وَأُنثَىٰ وَجَعَلْنَاكُمْ شُعُوبًا وَقَبَائِلَ لِتَعَارَفُوا ۚ إِنَّ أَكْرَمَكُمْ عِندَ اللَّهِ أَتْقَاكُمْ ۚ إِنَّ اللَّهَ عَلِيمٌ خَبِيرٌ (13) Eyin eniyan, dajudaju Awa seda yin lati ara okunrin ati obinrin. A si se yin ni orile-ede orile-ede ati iran-iran nitori ki e le dara yin mo. Dajudaju alapon-onle julo ninu yin lodo Allahu ni eni t’o beru (Re) julo. Dajudaju Allahu ni Onimo, Alamotan |
۞ قَالَتِ الْأَعْرَابُ آمَنَّا ۖ قُل لَّمْ تُؤْمِنُوا وَلَٰكِن قُولُوا أَسْلَمْنَا وَلَمَّا يَدْخُلِ الْإِيمَانُ فِي قُلُوبِكُمْ ۖ وَإِن تُطِيعُوا اللَّهَ وَرَسُولَهُ لَا يَلِتْكُم مِّنْ أَعْمَالِكُمْ شَيْئًا ۚ إِنَّ اللَّهَ غَفُورٌ رَّحِيمٌ (14) Awon Larubawa oko so pe: "A gbagbo ni ododo." So pe: "Eyin ko gbagbo ni ododo." Sugbon e so pe: "A gba ’Islam." niwon igba ti igbagbo ododo ko ti i wo’nu okan yin. Ti e ba tele (ase) Allahu ati Ojise Re, (Allahu) ko nii din kini kan ku fun yin ninu (esan) awon ise yin. Dajudaju Allahu ni Alaforijin, Asake-orun |
إِنَّمَا الْمُؤْمِنُونَ الَّذِينَ آمَنُوا بِاللَّهِ وَرَسُولِهِ ثُمَّ لَمْ يَرْتَابُوا وَجَاهَدُوا بِأَمْوَالِهِمْ وَأَنفُسِهِمْ فِي سَبِيلِ اللَّهِ ۚ أُولَٰئِكَ هُمُ الصَّادِقُونَ (15) Awon onigbagbo ododo ni awon t’o gbagbo ninu Allahu ati Ojise Re, leyin naa ti won ko seyemeji, ti won si fi dukia won ati emi won jagun fun esin Allahu. Awon wonyen, awon ni olododo |
قُلْ أَتُعَلِّمُونَ اللَّهَ بِدِينِكُمْ وَاللَّهُ يَعْلَمُ مَا فِي السَّمَاوَاتِ وَمَا فِي الْأَرْضِ ۚ وَاللَّهُ بِكُلِّ شَيْءٍ عَلِيمٌ (16) So pe: "Se e maa ko Allahu ni esin yin ni?" Allahu si mo ohunkohun t’o wa ninu awon sanmo ati ohunkohun t’o wa ninu ile. Allahu si ni Onimo nipa gbogbo nnkan |
يَمُنُّونَ عَلَيْكَ أَنْ أَسْلَمُوا ۖ قُل لَّا تَمُنُّوا عَلَيَّ إِسْلَامَكُم ۖ بَلِ اللَّهُ يَمُنُّ عَلَيْكُمْ أَنْ هَدَاكُمْ لِلْإِيمَانِ إِن كُنتُمْ صَادِقِينَ (17) Won n seregun lori re pe won gba ’Islam. So pe: "E ma fi ’Islam yin seregun lori mi.” Bee ni! Allahu l’O maa seregun lori yin pe O fi yin mona sibi igbagbo ododo ti e ba je olododo |
إِنَّ اللَّهَ يَعْلَمُ غَيْبَ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ ۚ وَاللَّهُ بَصِيرٌ بِمَا تَعْمَلُونَ (18) Dajudaju Allahu mo ikoko awon sanmo ati ile. Ati pe Allahu ni Oluriran nipa ohun ti e n se nise |