وَالنَّازِعَاتِ غَرْقًا (1) Allahu bura pelu awon molaika t’o n fi ona ele gba emi awon alaigbagbo |
وَالنَّاشِطَاتِ نَشْطًا (2) O tun bura pelu awon molaika t’o n fi ona ero gba emi awon onigbagbo ododo |
وَالسَّابِحَاتِ سَبْحًا (3) O tun bura pelu awon molaika t’o n yara gaga nibi ase Re |
فَالسَّابِقَاتِ سَبْقًا (4) O tun bura pelu awon molaika t’o maa siwaju emi awon onigbagbo ododo wonu Ogba Idera taara |
فَالْمُدَبِّرَاتِ أَمْرًا (5) O tun bura pelu awon molaika t’o n seto ile aye |
يَوْمَ تَرْجُفُ الرَّاجِفَةُ (6) Ni ojo ti ifon akoko fun opin aye maa mi gbogbo aye titi pelu ohun igbe |
تَتْبَعُهَا الرَّادِفَةُ (7) Ifon keji fun Ajinde si maa tele e |
قُلُوبٌ يَوْمَئِذٍ وَاجِفَةٌ (8) Awon okan yoo maa gbon pepe ni ojo yen |
أَبْصَارُهَا خَاشِعَةٌ (9) Oju won yo si wale ni ti iyepere |
يَقُولُونَ أَإِنَّا لَمَرْدُودُونَ فِي الْحَافِرَةِ (10) Won yoo wi pe: "Se Won tun maa da wa pada si ibere isemi (bii taye ni) |
أَإِذَا كُنَّا عِظَامًا نَّخِرَةً (11) Se nigba ti a ti di eegun t’o kefun tan |
قَالُوا تِلْكَ إِذًا كَرَّةٌ خَاسِرَةٌ (12) Won wi pe: "Idapada ofo niyen nigba naa (fun eni t’o pe e niro) |
فَإِنَّمَا هِيَ زَجْرَةٌ وَاحِدَةٌ (13) Nitori naa, igbe eyo kan si ni |
فَإِذَا هُم بِالسَّاهِرَةِ (14) Nigba naa ni won yoo bara won lori ile gbansasa |
هَلْ أَتَاكَ حَدِيثُ مُوسَىٰ (15) Nje oro (Anabi) Musa ti de odo re |
إِذْ نَادَاهُ رَبُّهُ بِالْوَادِ الْمُقَدَّسِ طُوًى (16) (Ranti) nigba ti Oluwa re pe e ni afonifoji mimo, Tuwa |
اذْهَبْ إِلَىٰ فِرْعَوْنَ إِنَّهُ طَغَىٰ (17) Lo ba Fir‘aon, dajudaju o ti tayo enu-ala |
فَقُلْ هَل لَّكَ إِلَىٰ أَن تَزَكَّىٰ (18) Ki o si so pe: "Nje o maa safomo ara re (kuro ninu aigbagbo) bi |
وَأَهْدِيَكَ إِلَىٰ رَبِّكَ فَتَخْشَىٰ (19) Ki emi si fi ona mo o de odo Oluwa re. Nitori naa, ki o paya (Re) |
فَأَرَاهُ الْآيَةَ الْكُبْرَىٰ (20) O si fi ami t’o tobi han an |
فَكَذَّبَ وَعَصَىٰ (21) (Amo) o pe e lopuro. O si yapa re |
ثُمَّ أَدْبَرَ يَسْعَىٰ (22) Leyin naa, o keyin si i. O si n sise (tako o) |
فَحَشَرَ فَنَادَىٰ (23) O ko (awon eniyan) jo, o si ke gbajari |
فَقَالَ أَنَا رَبُّكُمُ الْأَعْلَىٰ (24) O si wi pe: "Emi ni oluwa yin, eni giga julo |
فَأَخَذَهُ اللَّهُ نَكَالَ الْآخِرَةِ وَالْأُولَىٰ (25) Nitori naa, Allahu gba a mu pelu iya ikeyin ati akoko (nipa oro enu re ikeyin yii ati akoko) |
إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَعِبْرَةً لِّمَن يَخْشَىٰ (26) Dajudaju ariwoye wa ninu iyen fun eni t’o n paya (Allahu) |
أَأَنتُمْ أَشَدُّ خَلْقًا أَمِ السَّمَاءُ ۚ بَنَاهَا (27) Se eyin le lagbara julo ni iseda ni tabi sanmo ti Allahu mo |
رَفَعَ سَمْكَهَا فَسَوَّاهَا (28) Allahu gbe aja re ga soke. O si se e ni pipe t’o gun rege |
وَأَغْطَشَ لَيْلَهَا وَأَخْرَجَ ضُحَاهَا (29) O se oru re ni dudu. O si fa iyaleta re yo jade |
وَالْأَرْضَ بَعْدَ ذَٰلِكَ دَحَاهَا (30) Ati ile, O te e perese leyin iyen |
أَخْرَجَ مِنْهَا مَاءَهَا وَمَرْعَاهَا (31) O mu omi re ati irugbin re jade lati inu re |
وَالْجِبَالَ أَرْسَاهَا (32) Ati awon apata, O fi idi won mule sinsin |
مَتَاعًا لَّكُمْ وَلِأَنْعَامِكُمْ (33) Igbadun ni fun yin ati fun awon eran-osin yin |
فَإِذَا جَاءَتِ الطَّامَّةُ الْكُبْرَىٰ (34) Sugbon nigba ti iparun nla ba de |
يَوْمَ يَتَذَكَّرُ الْإِنسَانُ مَا سَعَىٰ (35) ni ojo ti eniyan yoo ranti ohun t’o se nise |
وَبُرِّزَتِ الْجَحِيمُ لِمَن يَرَىٰ (36) Won si maa fi Ina han kedere fun (gbogbo) eni t’o riran |
فَأَمَّا مَن طَغَىٰ (37) Nitori naa, ni ti eni t’o ba tayo enu-ala |
وَآثَرَ الْحَيَاةَ الدُّنْيَا (38) ti o tun gbe ajulo fun isemi aye |
فَإِنَّ الْجَحِيمَ هِيَ الْمَأْوَىٰ (39) dajudaju ina Jehim, ohun ni ibugbe (re) |
وَأَمَّا مَنْ خَافَ مَقَامَ رَبِّهِ وَنَهَى النَّفْسَ عَنِ الْهَوَىٰ (40) Ni ti eni ti o ba paya iduro niwaju Oluwa re, ti o tun ko ife-inu fun emi (ara re) |
فَإِنَّ الْجَنَّةَ هِيَ الْمَأْوَىٰ (41) dajudaju Ogba Idera, ohun ni ibugbe (re) |
يَسْأَلُونَكَ عَنِ السَّاعَةِ أَيَّانَ مُرْسَاهَا (42) Won n bi o leere nipa Akoko naa pe: "Igba wo l’o maa sele |
فِيمَ أَنتَ مِن ذِكْرَاهَا (43) Ona wo ni iwo le fi ni (imo) iranti re na |
إِلَىٰ رَبِّكَ مُنتَهَاهَا (44) Odo Oluwa re ni opin imo nipa re wa |
إِنَّمَا أَنتَ مُنذِرُ مَن يَخْشَاهَا (45) Iwo kuku ni olukilo fun eni t’o n paya re |
كَأَنَّهُمْ يَوْمَ يَرَوْنَهَا لَمْ يَلْبَثُوا إِلَّا عَشِيَّةً أَوْ ضُحَاهَا (46) Ni ojo ti won maa ri i, won maa da bi eni pe won ko lo tayo irole tabi iyaleta (ojo) kan lo (nile aye) |