| هَلْ أَتَاكَ حَدِيثُ الْغَاشِيَةِ (1) Nje oro nipa ohun t’o maa bo eda mole ti de odo re
 | 
| وُجُوهٌ يَوْمَئِذٍ خَاشِعَةٌ (2) Awon oju kan yoo wale (ni ti iyepere) ni ojo yen
 | 
| عَامِلَةٌ نَّاصِبَةٌ (3) Onise asekudorogbo (ni won nile aye)
 | 
| تَصْلَىٰ نَارًا حَامِيَةً (4) Won maa wo inu Ina t’o gbona janjan (ni orun)
 | 
| تُسْقَىٰ مِنْ عَيْنٍ آنِيَةٍ (5) Won si maa fun (won) ni omi gbigbona mu
 | 
| لَّيْسَ لَهُمْ طَعَامٌ إِلَّا مِن ضَرِيعٍ (6) Ko si ounje kan fun won ayafi igi elegun-un gbigbe
 | 
| لَّا يُسْمِنُ وَلَا يُغْنِي مِن جُوعٍ (7) Ko nii mu won sanra. Ko si nii ro won loro ninu ebi
 | 
| وُجُوهٌ يَوْمَئِذٍ نَّاعِمَةٌ (8) Awon oju kan yo si kun fun igbadun ni ojo yen
 | 
| لِّسَعْيِهَا رَاضِيَةٌ (9) nitori pe (o) yonu si (esan) ise re
 | 
| فِي جَنَّةٍ عَالِيَةٍ (10) (O maa) wa ninu Ogba Idera giga
 | 
| لَّا تَسْمَعُ فِيهَا لَاغِيَةً (11) Won ko nii gbo isokuso ninu re
 | 
| فِيهَا عَيْنٌ جَارِيَةٌ (12) Omi iseleru t’o n san wa ninu re
 | 
| فِيهَا سُرُرٌ مَّرْفُوعَةٌ (13) Awon ibusun ti won gbe soke wa ninu re
 | 
| وَأَكْوَابٌ مَّوْضُوعَةٌ (14) ati awon ife imumi ti won gbe kale (si arowoto won)
 | 
| وَنَمَارِقُ مَصْفُوفَةٌ (15) ati awon irori ti won to si egbe ara won
 | 
| وَزَرَابِيُّ مَبْثُوثَةٌ (16) ati awon ite ateeka
 | 
| أَفَلَا يَنظُرُونَ إِلَى الْإِبِلِ كَيْفَ خُلِقَتْ (17) Nitori naa, se won ko wo rakunmi, bi A ti seda re ni
 | 
| وَإِلَى السَّمَاءِ كَيْفَ رُفِعَتْ (18) ati sanmo, bi A ti se gbe e soke
 | 
| وَإِلَى الْجِبَالِ كَيْفَ نُصِبَتْ (19) ati apata, bi A ti se gbe e naro (sinu ile)
 | 
| وَإِلَى الْأَرْضِ كَيْفَ سُطِحَتْ (20) ati ile, bi A ti se te e sile ni gbansasa
 | 
| فَذَكِّرْ إِنَّمَا أَنتَ مُذَكِّرٌ (21) Nitori naa, seranti. Iwo kuku ni oluseranti
 | 
| لَّسْتَ عَلَيْهِم بِمُصَيْطِرٍ (22) Iwo ki i se ajeni-nipa lori won
 | 
| إِلَّا مَن تَوَلَّىٰ وَكَفَرَ (23) afi eni ti o ba peyinda (si ododo), ti o si sai gbagbo
 | 
| فَيُعَذِّبُهُ اللَّهُ الْعَذَابَ الْأَكْبَرَ (24) Allahu si maa je e niya t’o tobi julo
 | 
| إِنَّ إِلَيْنَا إِيَابَهُمْ (25) Dajudaju odo Wa ni abo won wa
 | 
| ثُمَّ إِنَّ عَلَيْنَا حِسَابَهُم (26) Leyin naa, dajudaju Awa l’A maa se isiro-ise won
 |