عَبَسَ وَتَوَلَّىٰ (1) (Anabi s.a.w.) faju ro, o si peyin da |
أَن جَاءَهُ الْأَعْمَىٰ (2) nitori pe afoju wa ba a |
وَمَا يُدْرِيكَ لَعَلَّهُ يَزَّكَّىٰ (3) Ki si l’o maa fi mo o pe o see se ki o safomo (ara re kuro ninu aigbagbo) |
أَوْ يَذَّكَّرُ فَتَنفَعَهُ الذِّكْرَىٰ (4) tabi ki o gbo iranti, ki iranti naa si se e ni anfaani |
أَمَّا مَنِ اسْتَغْنَىٰ (5) Ni ti eni ti o ka ara re kun oloro |
فَأَنتَ لَهُ تَصَدَّىٰ (6) oun ni iwo teti si |
وَمَا عَلَيْكَ أَلَّا يَزَّكَّىٰ (7) Ko si si ese fun o bi ko ba se afomo (ara re kuro ninu aigbagbo) |
وَأَمَّا مَن جَاءَكَ يَسْعَىٰ (8) Ni ti eni ti o si wa ba o, t’o n yara gaga (si iranti, iyen afoju) |
وَهُوَ يَخْشَىٰ (9) ti o si n paya (Allahu) |
فَأَنتَ عَنْهُ تَلَهَّىٰ (10) iwo ko si kobi ara si i |
كَلَّا إِنَّهَا تَذْكِرَةٌ (11) Rara (ko to bee). Dajudaju al-Ƙur’an ni iranti |
فَمَن شَاءَ ذَكَرَهُ (12) Nitori naa, eni ti o ba fe ki o ranti re |
فِي صُحُفٍ مُّكَرَّمَةٍ (13) (Al-Ƙur’an) wa ninu awon takada alapon-onle |
مَّرْفُوعَةٍ مُّطَهَّرَةٍ (14) A gbe e ga, A si se e ni mimo |
بِأَيْدِي سَفَرَةٍ (15) ni owo awon onkotia (iyen, awon molaika) |
كِرَامٍ بَرَرَةٍ (16) awon alapon-onle, awon eni rere |
قُتِلَ الْإِنسَانُ مَا أَكْفَرَهُ (17) Won ti fi eniyan gegun-un (nipa) bi o se je alaimoore julo |
مِنْ أَيِّ شَيْءٍ خَلَقَهُ (18) Ki si ni Allahu fi seda re |
مِن نُّطْفَةٍ خَلَقَهُ فَقَدَّرَهُ (19) Ninu ato l’O ti seda re. O si pebubu (eya-ara) re |
ثُمَّ السَّبِيلَ يَسَّرَهُ (20) Leyin naa, O se ona atiwaye ni irorun fun un |
ثُمَّ أَمَاتَهُ فَأَقْبَرَهُ (21) Leyin naa, O maa pa a. O si maa fi sinu saree |
ثُمَّ إِذَا شَاءَ أَنشَرَهُ (22) Leyin naa, nigba ti Allahu ba fe, O maa gbe e dide |
كَلَّا لَمَّا يَقْضِ مَا أَمَرَهُ (23) E gbo, eniyan ko ti i se nnkan ti Allahu pa lase fun un |
فَلْيَنظُرِ الْإِنسَانُ إِلَىٰ طَعَامِهِ (24) Nitori naa, ki eniyan woye si ounje re |
أَنَّا صَبَبْنَا الْمَاءَ صَبًّا (25) Dajudaju Awa n ro ojo ni pupo |
ثُمَّ شَقَقْنَا الْأَرْضَ شَقًّا (26) Leyin naa, A mu ile san kankan |
فَأَنبَتْنَا فِيهَا حَبًّا (27) A si mu koro eso hu jade lati inu re |
وَعِنَبًا وَقَضْبًا (28) ati eso ajara ati kannafuru |
وَزَيْتُونًا وَنَخْلًا (29) ati igi ororo Zaetun ati dabinu |
وَحَدَائِقَ غُلْبًا (30) ati awon ogba t’o kun fun igi |
وَفَاكِهَةً وَأَبًّا (31) ati awon eso (miiran) pelu ewe ti eranko n je, (A mu won hu jade) |
مَّتَاعًا لَّكُمْ وَلِأَنْعَامِكُمْ (32) (Won je nnkan) igbadun fun eyin ati awon eran-osin yin |
فَإِذَا جَاءَتِ الصَّاخَّةُ (33) Nigba ti fifon sinu iwo nigba keji ba sele |
يَوْمَ يَفِرُّ الْمَرْءُ مِنْ أَخِيهِ (34) ni ojo ti eniyan yoo sa fun arakunrin re |
وَأُمِّهِ وَأَبِيهِ (35) ati iya re pelu baba re |
وَصَاحِبَتِهِ وَبَنِيهِ (36) ati iyawo re pelu awon omo re |
لِكُلِّ امْرِئٍ مِّنْهُمْ يَوْمَئِذٍ شَأْنٌ يُغْنِيهِ (37) Eni kookan won ni ojo yen l’o ti ni oran t’o maa to o o ran |
وُجُوهٌ يَوْمَئِذٍ مُّسْفِرَةٌ (38) Awon oju kan lojo yen yoo mole |
ضَاحِكَةٌ مُّسْتَبْشِرَةٌ (39) Won yo maa rerin-in, won yo si maa dunnu |
وَوُجُوهٌ يَوْمَئِذٍ عَلَيْهَا غَبَرَةٌ (40) Awon oju kan lojo yen ni eruku yo si bo mole |
تَرْهَقُهَا قَتَرَةٌ (41) Okunkun yo si bo won mole |
أُولَٰئِكَ هُمُ الْكَفَرَةُ الْفَجَرَةُ (42) Awon wonyen, awon ni alaigbagbo, elese |