طسم (1) To sin mim |
تِلْكَ آيَاتُ الْكِتَابِ الْمُبِينِ (2) Iwonyi ni awon ayah Tira t’o n yanju oro eda |
لَعَلَّكَ بَاخِعٌ نَّفْسَكَ أَلَّا يَكُونُوا مُؤْمِنِينَ (3) Nitori ki ni o se maa para re pe won ko je onigbagbo ododo |
إِن نَّشَأْ نُنَزِّلْ عَلَيْهِم مِّنَ السَّمَاءِ آيَةً فَظَلَّتْ أَعْنَاقُهُمْ لَهَا خَاضِعِينَ (4) Ti A ba fe, A maa so ami kan kale fun won lati sanmo. Awon orun won ko si nii ye teriba fun un |
وَمَا يَأْتِيهِم مِّن ذِكْرٍ مِّنَ الرَّحْمَٰنِ مُحْدَثٍ إِلَّا كَانُوا عَنْهُ مُعْرِضِينَ (5) Ko si iranti kan ti o maa de ba won ni titun lati odo Ajoke-aye afi ki won je olugbunri kuro nibe |
فَقَدْ كَذَّبُوا فَسَيَأْتِيهِمْ أَنبَاءُ مَا كَانُوا بِهِ يَسْتَهْزِئُونَ (6) Dajudaju won ti pe (ayah Wa) niro. Nitori naa, awon iro ohun ti won n fi se yeye n bo wa ba won |
أَوَلَمْ يَرَوْا إِلَى الْأَرْضِ كَمْ أَنبَتْنَا فِيهَا مِن كُلِّ زَوْجٍ كَرِيمٍ (7) Se won ko ri ile pe meloo meloo ninu gbogbo orisirisi nnkan alapon-onle ti A mu hu jade lati inu re |
إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَآيَةً ۖ وَمَا كَانَ أَكْثَرُهُم مُّؤْمِنِينَ (8) Dajudaju ami wa ninu iyen. Sibesibe opolopo won ko je onigbagbo ododo |
وَإِنَّ رَبَّكَ لَهُوَ الْعَزِيزُ الرَّحِيمُ (9) Dajudaju Oluwa re, Oun ma ni Alagbara, Asake-orun |
وَإِذْ نَادَىٰ رَبُّكَ مُوسَىٰ أَنِ ائْتِ الْقَوْمَ الظَّالِمِينَ (10) (Ranti) nigba ti Oluwa re pe (Anabi) Musa pe: "Lo ba ijo alabosi |
قَوْمَ فِرْعَوْنَ ۚ أَلَا يَتَّقُونَ (11) ijo Fir‘aon (ki o si so fun won) pe 'Se won ko nii beru (Allahu) ni |
قَالَ رَبِّ إِنِّي أَخَافُ أَن يُكَذِّبُونِ (12) O so pe: "Oluwa mi, dajudaju emi n beru pe won maa pe mi ni opuro |
وَيَضِيقُ صَدْرِي وَلَا يَنطَلِقُ لِسَانِي فَأَرْسِلْ إِلَىٰ هَارُونَ (13) O si maa je inira fun mi (ti won ba pe mi ni opuro). Ahon mi ko si ja gaaraga. Nitori naa, ranse si Harun |
وَلَهُمْ عَلَيَّ ذَنبٌ فَأَخَافُ أَن يَقْتُلُونِ (14) Ati pe mo ni ese kan lorun lodo won. Nitori naa, mo n beru pe won maa pa mi |
قَالَ كَلَّا ۖ فَاذْهَبَا بِآيَاتِنَا ۖ إِنَّا مَعَكُم مُّسْتَمِعُونَ (15) (Allahu) so pe: "Rara (won ko le pa o). Nitori naa, ki eyin mejeeji mu awon ami (ise iyanu) Wa lo (ba won). Dajudaju Awa n be pelu yin; A n gbo (oro yin) |
فَأْتِيَا فِرْعَوْنَ فَقُولَا إِنَّا رَسُولُ رَبِّ الْعَالَمِينَ (16) Eyin mejeeji, e lo ba Fir‘aon. Ki e so fun un pe: 'Dajudaju awa ni Ojise Oluwa gbogbo eda |
أَنْ أَرْسِلْ مَعَنَا بَنِي إِسْرَائِيلَ (17) (A n so fun o) pe ki o je ki awon omo ’Isro’il maa ba wa lo |
قَالَ أَلَمْ نُرَبِّكَ فِينَا وَلِيدًا وَلَبِثْتَ فِينَا مِنْ عُمُرِكَ سِنِينَ (18) (Fir‘aon) wi pe: “Se ki i se ni aarin wa ni a ti to o ni kekere ni, ti o si gbe ni odo wa fun odun pupo ninu isemi aye re |
وَفَعَلْتَ فَعْلَتَكَ الَّتِي فَعَلْتَ وَأَنتَ مِنَ الْكَافِرِينَ (19) O si se ise owo re ti o se (si wa). Iwo si wa ninu awon alaimoore.” |
قَالَ فَعَلْتُهَا إِذًا وَأَنَا مِنَ الضَّالِّينَ (20) (Anabi Musa) so pe: "Mo se e nigba naa nigba ti mo wa ninu awon alaimokan ni |
فَفَرَرْتُ مِنكُمْ لَمَّا خِفْتُكُمْ فَوَهَبَ لِي رَبِّي حُكْمًا وَجَعَلَنِي مِنَ الْمُرْسَلِينَ (21) Mo si sa fun yin nigba ti mo beru yin. Nitori naa, Allahu ti ta mi lore ipo Anabi. O si se mi ni (okan) ninu awon Ojise |
وَتِلْكَ نِعْمَةٌ تَمُنُّهَا عَلَيَّ أَنْ عَبَّدتَّ بَنِي إِسْرَائِيلَ (22) Ati pe iyen ni idera ti o n se iregun re le mi lori. Pe o so awon omo ’Isro’il di eru (nko) |
قَالَ فِرْعَوْنُ وَمَا رَبُّ الْعَالَمِينَ (23) Fir‘aon wi pe: “Ki ni Oluwa gbogbo eda?” |
قَالَ رَبُّ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ وَمَا بَيْنَهُمَا ۖ إِن كُنتُم مُّوقِنِينَ (24) (Anabi Musa) so pe: “(Allahu ni) |
قَالَ لِمَنْ حَوْلَهُ أَلَا تَسْتَمِعُونَ (25) (Fir‘aon) wi fun awon t’o wa ni ayika re pe: “Se e e gbo oro (t’o n so ni)?” |
قَالَ رَبُّكُمْ وَرَبُّ آبَائِكُمُ الْأَوَّلِينَ (26) (Anabi Musa) so pe: “(Allahu ni) Oluwa yin ati Oluwa awon baba yin, awon eni akoko.” |
قَالَ إِنَّ رَسُولَكُمُ الَّذِي أُرْسِلَ إِلَيْكُمْ لَمَجْنُونٌ (27) (Fir‘aon) wi pe: “Dajudaju Ojise yin eyi ti won ran si yin, were ma ni.” |
قَالَ رَبُّ الْمَشْرِقِ وَالْمَغْرِبِ وَمَا بَيْنَهُمَا ۖ إِن كُنتُمْ تَعْقِلُونَ (28) (Anabi Musa) so pe: “(Allahu ni) Oluwa ibuyo oorun, ibuwo oorun ati ohunkohun t’o n be laaarin awon mejeeji, ti e ba maa n se laakaye.” |
قَالَ لَئِنِ اتَّخَذْتَ إِلَٰهًا غَيْرِي لَأَجْعَلَنَّكَ مِنَ الْمَسْجُونِينَ (29) (Fir‘aon) wi pe: “Dajudaju ti o ba fi le josin fun olohun kan yato si mi, dajudaju mo maa so o di ara awon elewon.” |
قَالَ أَوَلَوْ جِئْتُكَ بِشَيْءٍ مُّبِينٍ (30) (Anabi Musa) so pe: “Ti o ba je pe mo mu kini kan t’o yanju wa fun o nko?” |
قَالَ فَأْتِ بِهِ إِن كُنتَ مِنَ الصَّادِقِينَ (31) (Fir‘aon) wi pe: “Mu un wa nigba naa ti iwo ba wa ninu awon olododo.” |
فَأَلْقَىٰ عَصَاهُ فَإِذَا هِيَ ثُعْبَانٌ مُّبِينٌ (32) Nitori naa, o ju opa re sile, o si di ejo ponnbele |
وَنَزَعَ يَدَهُ فَإِذَا هِيَ بَيْضَاءُ لِلنَّاظِرِينَ (33) O tun fa owo re yo sita, o si di funfun fun awon oluworan |
قَالَ لِلْمَلَإِ حَوْلَهُ إِنَّ هَٰذَا لَسَاحِرٌ عَلِيمٌ (34) (Fir‘aon) wi fun awon ijoye ti won wa ni ayika re pe: “Dajudaju eyi ni onimo nipa idan pipa |
يُرِيدُ أَن يُخْرِجَكُم مِّنْ أَرْضِكُم بِسِحْرِهِ فَمَاذَا تَأْمُرُونَ (35) O fe ko yin kuro lori ile yin ni. Ki ni ohun ti e maa mu wa ni imoran?” |
قَالُوا أَرْجِهْ وَأَخَاهُ وَابْعَثْ فِي الْمَدَائِنِ حَاشِرِينَ (36) Won wi pe: "Da oun ati arakunrin re duro na, ki o si ran awon akonijo si awon ilu |
يَأْتُوكَ بِكُلِّ سَحَّارٍ عَلِيمٍ (37) (pe) ki gbogbo onimo nipa idan pipa wa ba o |
فَجُمِعَ السَّحَرَةُ لِمِيقَاتِ يَوْمٍ مَّعْلُومٍ (38) Won si ko awon opidan jo ni asiko ti won fi adehun si ni ojo ti (gbogbo ilu) ti mo |
وَقِيلَ لِلنَّاسِ هَلْ أَنتُم مُّجْتَمِعُونَ (39) Won si wi fun awon eniyan pe: "Se eyin maa ko jo (sibe) bi |
لَعَلَّنَا نَتَّبِعُ السَّحَرَةَ إِن كَانُوا هُمُ الْغَالِبِينَ (40) Nitori ki a le tele awon opidan ti o ba je pe awon ni olubori |
فَلَمَّا جَاءَ السَّحَرَةُ قَالُوا لِفِرْعَوْنَ أَئِنَّ لَنَا لَأَجْرًا إِن كُنَّا نَحْنُ الْغَالِبِينَ (41) Nigba ti awon opidan de, won wi fun Fir‘aon pe: “Nje owo-oya kan wa fun wa, ti o ba je pe awa gan-an la je olubori?” |
قَالَ نَعَمْ وَإِنَّكُمْ إِذًا لَّمِنَ الْمُقَرَّبِينَ (42) (Fir‘aon) wi pe: “Bee ni, dajudaju nigba naa e maa wa ninu awon alasun-unmo (mi).” |
قَالَ لَهُم مُّوسَىٰ أَلْقُوا مَا أَنتُم مُّلْقُونَ (43) (Anabi) Musa so fun won pe: “E ju ohun ti e fe ju sile.” |
فَأَلْقَوْا حِبَالَهُمْ وَعِصِيَّهُمْ وَقَالُوا بِعِزَّةِ فِرْعَوْنَ إِنَّا لَنَحْنُ الْغَالِبُونَ (44) Won si ju awon okun won ati opa won sile. Won wi pe: “Pelu ogo Fir‘aon, dajudaju awa, awa ni olubori.” |
فَأَلْقَىٰ مُوسَىٰ عَصَاهُ فَإِذَا هِيَ تَلْقَفُ مَا يَأْفِكُونَ (45) Nigba naa, (Anabi) Musa ju opa re sile. O si n gbe ohun ti won pa niro kale mi kalokalo |
فَأُلْقِيَ السَّحَرَةُ سَاجِدِينَ (46) Nitori naa, ise iyanu (Anabi Musa) mu awon opidan wo lule, ti won fori kanle (fun Allahu) |
قَالُوا آمَنَّا بِرَبِّ الْعَالَمِينَ (47) Won so pe: "A gbagbo ninu Oluwa gbogbo eda |
رَبِّ مُوسَىٰ وَهَارُونَ (48) Oluwa (Anabi) Musa ati Harun |
قَالَ آمَنتُمْ لَهُ قَبْلَ أَنْ آذَنَ لَكُمْ ۖ إِنَّهُ لَكَبِيرُكُمُ الَّذِي عَلَّمَكُمُ السِّحْرَ فَلَسَوْفَ تَعْلَمُونَ ۚ لَأُقَطِّعَنَّ أَيْدِيَكُمْ وَأَرْجُلَكُم مِّنْ خِلَافٍ وَلَأُصَلِّبَنَّكُمْ أَجْمَعِينَ (49) Fir‘aon wi pe: “E gba A gbo siwaju ki ng to yonda fun yin! Dajudaju oun ni agba yin ti o ko yin ni idan pipa. Laipe e n bo wa mo. Dajudaju mo maa ge owo yin ati ese yin ni ipasipayo. Leyin naa, dajudaju mo maa kan gbogbo yin mogi.” |
قَالُوا لَا ضَيْرَ ۖ إِنَّا إِلَىٰ رَبِّنَا مُنقَلِبُونَ (50) (Awon opidan) so pe: “Ko si inira fun wa! Dajudaju awa yo si fabo si odo Oluwa wa |
إِنَّا نَطْمَعُ أَن يَغْفِرَ لَنَا رَبُّنَا خَطَايَانَا أَن كُنَّا أَوَّلَ الْمُؤْمِنِينَ (51) Dajudaju awa n reti pe Oluwa wa yoo se aforijin awon asise wa fun wa nitori pe awa je eni akoko (ti o je) onigbagbo ododo.” |
۞ وَأَوْحَيْنَا إِلَىٰ مُوسَىٰ أَنْ أَسْرِ بِعِبَادِي إِنَّكُم مُّتَّبَعُونَ (52) A fi imisi ranse si (Anabi) Musa pe: “Mu awon erusin Mi rin ni oru (nitori pe) dajudaju won yoo lepa yin.” |
فَأَرْسَلَ فِرْعَوْنُ فِي الْمَدَائِنِ حَاشِرِينَ (53) Fir‘aon si ran awon akonijo sinu awon ilu (lati so pe) |
إِنَّ هَٰؤُلَاءِ لَشِرْذِمَةٌ قَلِيلُونَ (54) Dajudaju awon (omo ’Isro’il) wonyi, ijo perete die ni won |
وَإِنَّهُمْ لَنَا لَغَائِظُونَ (55) Ati pe dajudaju won ti se ohun t’o n bi wa ninu |
وَإِنَّا لَجَمِيعٌ حَاذِرُونَ (56) Dajudaju gbogbo wa ni ki a si wa tifura-tifura |
فَأَخْرَجْنَاهُم مِّن جَنَّاتٍ وَعُيُونٍ (57) Nitori naa, A mu (ijo Fir‘aon) jade kuro ninu awon ogba oko ati iseleru omi |
وَكُنُوزٍ وَمَقَامٍ كَرِيمٍ (58) ati awon apoti-oro ati ibujokoo aponle |
كَذَٰلِكَ وَأَوْرَثْنَاهَا بَنِي إِسْرَائِيلَ (59) Bayen (loro ri). A si jogun re fun awon omo ’Isro’il |
فَأَتْبَعُوهُم مُّشْرِقِينَ (60) Won si lepa won ni asiko ti oorun yo |
فَلَمَّا تَرَاءَى الْجَمْعَانِ قَالَ أَصْحَابُ مُوسَىٰ إِنَّا لَمُدْرَكُونَ (61) Nigba ti ijo mejeeji rira won, awon ijo (Anabi) Musa so pe: “Dajudaju won yoo le wa ba.” |
قَالَ كَلَّا ۖ إِنَّ مَعِيَ رَبِّي سَيَهْدِينِ (62) (Anabi) Musa so pe: “Rara, dajudaju Oluwa mi n be pelu mi. O si maa fi ona mo mi.” |
فَأَوْحَيْنَا إِلَىٰ مُوسَىٰ أَنِ اضْرِب بِّعَصَاكَ الْبَحْرَ ۖ فَانفَلَقَ فَكَانَ كُلُّ فِرْقٍ كَالطَّوْدِ الْعَظِيمِ (63) A si fi imisi ranse si (Anabi) Musa pe: “Fi opa re na agbami okun.” (O fi na a). O si pin (si ona mejila). Ipin kookan si da bi apata nla |
وَأَزْلَفْنَا ثَمَّ الْآخَرِينَ (64) A si mu ijo keji (iyen, ijo Fir‘aon) sunmo ibe yen |
وَأَنجَيْنَا مُوسَىٰ وَمَن مَّعَهُ أَجْمَعِينَ (65) A gba (Anabi) Musa ati gbogbo awon t’o n be pelu re la patapata |
ثُمَّ أَغْرَقْنَا الْآخَرِينَ (66) Leyin naa, A te ijo keji ri (sinu agbami) |
إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَآيَةً ۖ وَمَا كَانَ أَكْثَرُهُم مُّؤْمِنِينَ (67) Dajudaju ami wa ninu iyen. Sibesibe opolopo won ko je onigbagbo ododo |
وَإِنَّ رَبَّكَ لَهُوَ الْعَزِيزُ الرَّحِيمُ (68) Dajudaju Oluwa re, Oun ma ni Alagbara, Asake-orun |
وَاتْلُ عَلَيْهِمْ نَبَأَ إِبْرَاهِيمَ (69) Ka iroyin (Anabi) ’Ibrohim fun won |
إِذْ قَالَ لِأَبِيهِ وَقَوْمِهِ مَا تَعْبُدُونَ (70) Nigba ti o so fun baba re ati awon eniyan re pe: “Ki ni nnkan ti e n josin fun na?” |
قَالُوا نَعْبُدُ أَصْنَامًا فَنَظَلُّ لَهَا عَاكِفِينَ (71) Won wi pe: “A n josin fun awon ere kan ni. A o si nii ye taku ti won lorun.” |
قَالَ هَلْ يَسْمَعُونَكُمْ إِذْ تَدْعُونَ (72) (Anabi ’Ibrohim) so pe: “Nje won n gbo oro yin nigba ti e ba n pe won |
أَوْ يَنفَعُونَكُمْ أَوْ يَضُرُّونَ (73) Tabi (se) won le se yin ni oore tabi won le fi inira kan yin?” |
قَالُوا بَلْ وَجَدْنَا آبَاءَنَا كَذَٰلِكَ يَفْعَلُونَ (74) Won wi pe: “Rara o! A ba awon baba wa, ti won n se bee ni” |
قَالَ أَفَرَأَيْتُم مَّا كُنتُمْ تَعْبُدُونَ (75) (Anabi ’Ibrohim) so pe: " E so fun mi, ki ni nnkan ti e n josin fun |
أَنتُمْ وَآبَاؤُكُمُ الْأَقْدَمُونَ (76) eyin ati awon baba yin isaaju |
فَإِنَّهُمْ عَدُوٌّ لِّي إِلَّا رَبَّ الْعَالَمِينَ (77) Dajudaju awon ni ota fun mi ayafi Oluwa gbogbo eda |
الَّذِي خَلَقَنِي فَهُوَ يَهْدِينِ (78) (Oun ni) Eni ti O seda mi. Nitori naa, O maa fi ona mo mi |
وَالَّذِي هُوَ يُطْعِمُنِي وَيَسْقِينِ (79) Eni t’O n fun mi ni jije, t’O n fun mi ni mimu |
وَإِذَا مَرِضْتُ فَهُوَ يَشْفِينِ (80) Ati pe nigba ti ara mi ko ba ya, Oun l’O n wo mi san |
وَالَّذِي يُمِيتُنِي ثُمَّ يُحْيِينِ (81) Eni ti O maa pa mi, leyin naa, O maa so mi di alaaye |
وَالَّذِي أَطْمَعُ أَن يَغْفِرَ لِي خَطِيئَتِي يَوْمَ الدِّينِ (82) Eni ti mo ni ireti si pe O maa fori awon asise mi jin mi ni Ojo Esan |
رَبِّ هَبْ لِي حُكْمًا وَأَلْحِقْنِي بِالصَّالِحِينَ (83) Oluwa mi, ta mi ni ore ipo Anabi. Da mi po mo awon eni rere |
وَاجْعَل لِّي لِسَانَ صِدْقٍ فِي الْآخِرِينَ (84) Je ki awon t’o n bo leyin (mi) maa soro mi pelu daadaa |
وَاجْعَلْنِي مِن وَرَثَةِ جَنَّةِ النَّعِيمِ (85) Se mi ni okan ninu awon olujogun Ogba Idera |
وَاغْفِرْ لِأَبِي إِنَّهُ كَانَ مِنَ الضَّالِّينَ (86) Ki O si forijin baba mi. Dajudaju o je okan ninu awon olusina |
وَلَا تُخْزِنِي يَوْمَ يُبْعَثُونَ (87) Ma se doju ti mi ni ojo ti won yoo gbe eda dide |
يَوْمَ لَا يَنفَعُ مَالٌ وَلَا بَنُونَ (88) Ojo ti dukia kan tabi awon omo ko nii sanfaani |
إِلَّا مَنْ أَتَى اللَّهَ بِقَلْبٍ سَلِيمٍ (89) Ayafi eni ti o ba de odo Allahu pelu okan mimo |
وَأُزْلِفَتِ الْجَنَّةُ لِلْمُتَّقِينَ (90) A maa mu Ogba Idera sunmo awon oluberu (Allahu) |
وَبُرِّزَتِ الْجَحِيمُ لِلْغَاوِينَ (91) Won si maa fi ina Jehim han awon olusina |
وَقِيلَ لَهُمْ أَيْنَ مَا كُنتُمْ تَعْبُدُونَ (92) won yo si so fun won pe: “Nibo ni nnkan ti e n josin fun wa?” |
مِن دُونِ اللَّهِ هَلْ يَنصُرُونَكُمْ أَوْ يَنتَصِرُونَ (93) (Nnkan ti e n josin fun) leyin Allahu, se won le ran yin lowo tabi se won le ran ara won lowo |
فَكُبْكِبُوا فِيهَا هُمْ وَالْغَاوُونَ (94) Won si maa taari gbogbo won sinu Ina; awon ati esu won |
وَجُنُودُ إِبْلِيسَ أَجْمَعُونَ (95) ati awon omo ogun ’Iblis patapata |
قَالُوا وَهُمْ فِيهَا يَخْتَصِمُونَ (96) (Awon alaigbagbo), nigba ti won ba n ba ara won jiyan ninu Ina, won a wi pe |
تَاللَّهِ إِن كُنَّا لَفِي ضَلَالٍ مُّبِينٍ (97) A fi Allahu bura, dajudaju awa kuku ti wa ninu isina ponnbele |
إِذْ نُسَوِّيكُم بِرَبِّ الْعَالَمِينَ (98) nigba ti a fi yin se akegbe fun Oluwa gbogbo eda |
وَمَا أَضَلَّنَا إِلَّا الْمُجْرِمُونَ (99) Ko si ohun ti o si wa lona bi ko se awon (esu) elese |
فَمَا لَنَا مِن شَافِعِينَ (100) Ko si si awon olusipe kan fun wa |
وَلَا صَدِيقٍ حَمِيمٍ (101) Ko tun si ore imule kan (fun wa) |
فَلَوْ أَنَّ لَنَا كَرَّةً فَنَكُونَ مِنَ الْمُؤْمِنِينَ (102) Ti o ba je pe ipada si ile aye wa fun wa ni, nigba naa awa iba wa ninu awon onigbagbo ododo |
إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَآيَةً ۖ وَمَا كَانَ أَكْثَرُهُم مُّؤْمِنِينَ (103) Dajudaju ami wa ninu iyen. Sibesibe opolopo won ni ko si je onigbagbo ododo |
وَإِنَّ رَبَّكَ لَهُوَ الْعَزِيزُ الرَّحِيمُ (104) Dajudaju Oluwa re, Oun ma ni Alagbara, Asake-orun |
كَذَّبَتْ قَوْمُ نُوحٍ الْمُرْسَلِينَ (105) Ijo (Anabi) Nuh pe awon Ojise ni opuro |
إِذْ قَالَ لَهُمْ أَخُوهُمْ نُوحٌ أَلَا تَتَّقُونَ (106) Nigba ti arakunrin won, (Anabi) Nuh, so pe: “Se e o nii beru (Allahu) ni |
إِنِّي لَكُمْ رَسُولٌ أَمِينٌ (107) Dajudaju emi ni Ojise olufokantan fun yin |
فَاتَّقُوا اللَّهَ وَأَطِيعُونِ (108) Nitori naa, e beru Allahu, ki e si tele mi |
وَمَا أَسْأَلُكُمْ عَلَيْهِ مِنْ أَجْرٍ ۖ إِنْ أَجْرِيَ إِلَّا عَلَىٰ رَبِّ الْعَالَمِينَ (109) Emi ko si beere owo-oya kan ni owo yin lori re. Ko si esan mi lodo eni kan afi lodo Oluwa gbogbo eda |
فَاتَّقُوا اللَّهَ وَأَطِيعُونِ (110) Nitori naa, e beru Allahu, ki e si tele mi.” |
۞ قَالُوا أَنُؤْمِنُ لَكَ وَاتَّبَعَكَ الْأَرْذَلُونَ (111) Won wi pe: “Se ki a gba o gbo nigba ti o je pe awon eniyan yepere l’o n tele o!?” |
قَالَ وَمَا عِلْمِي بِمَا كَانُوا يَعْمَلُونَ (112) O so pe: “Emi ko nimo si ohun ti won n se (leyin mi) |
إِنْ حِسَابُهُمْ إِلَّا عَلَىٰ رَبِّي ۖ لَوْ تَشْعُرُونَ (113) Ko si isiro-ise won lodo eni kan bi ko se lodo Oluwa mi, ti o ba je pe e ba fura |
وَمَا أَنَا بِطَارِدِ الْمُؤْمِنِينَ (114) Emi ko si nii le awon onigbagbo ododo danu |
إِنْ أَنَا إِلَّا نَذِيرٌ مُّبِينٌ (115) Emi ko si je kini kan bi ko se olukilo ponnbele.” |
قَالُوا لَئِن لَّمْ تَنتَهِ يَا نُوحُ لَتَكُونَنَّ مِنَ الْمَرْجُومِينَ (116) Won wi pe: “Dajudaju ti iwo Nuh ko ba jawo (nibi ipepe re) dajudaju o maa wa ninu awon ti a maa ju loko.” |
قَالَ رَبِّ إِنَّ قَوْمِي كَذَّبُونِ (117) O so pe: “Oluwa mi, dajudaju awon eniyan mi ti pe mi ni opuro |
فَافْتَحْ بَيْنِي وَبَيْنَهُمْ فَتْحًا وَنَجِّنِي وَمَن مَّعِيَ مِنَ الْمُؤْمِنِينَ (118) Nitori naa, sedajo taara laaarin emi ati awon. Ki o si la emi ati awon t’o wa pelu mi ninu awon onigbagbo ododo.” |
فَأَنجَيْنَاهُ وَمَن مَّعَهُ فِي الْفُلْكِ الْمَشْحُونِ (119) A la oun ati awon t’o wa pelu re ninu oko oju-omi t’o kun keke |
ثُمَّ أَغْرَقْنَا بَعْدُ الْبَاقِينَ (120) Leyin naa, A te awon t’o seku ri sinu omi |
إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَآيَةً ۖ وَمَا كَانَ أَكْثَرُهُم مُّؤْمِنِينَ (121) Dajudaju ami wa ninu iyen. Opolopo won ni ko si je onigbagbo ododo |
وَإِنَّ رَبَّكَ لَهُوَ الْعَزِيزُ الرَّحِيمُ (122) Dajudaju Oluwa re, Oun ma ni Alagbara, Asake-orun |
كَذَّبَتْ عَادٌ الْمُرْسَلِينَ (123) Awon iran ‘Ad pe awon Ojise ni opuro |
إِذْ قَالَ لَهُمْ أَخُوهُمْ هُودٌ أَلَا تَتَّقُونَ (124) Nigba ti arakunrin won, (Anabi) Hud, so pe: “Se e o nii beru (Allahu) ni |
إِنِّي لَكُمْ رَسُولٌ أَمِينٌ (125) Dajudaju emi ni Ojise olufokantan fun yin |
فَاتَّقُوا اللَّهَ وَأَطِيعُونِ (126) Nitori naa, e beru Allahu, ki e si tele mi |
وَمَا أَسْأَلُكُمْ عَلَيْهِ مِنْ أَجْرٍ ۖ إِنْ أَجْرِيَ إِلَّا عَلَىٰ رَبِّ الْعَالَمِينَ (127) Emi ko si beere owo-oya kan ni owo yin lori re. Ko si esan mi lodo eni kan afi lodo Oluwa gbogbo eda |
أَتَبْنُونَ بِكُلِّ رِيعٍ آيَةً تَعْبَثُونَ (128) Se e oo maa ko ile nla nla si awon aye giga (ki e le) maa fi awon olurekoja sefe |
وَتَتَّخِذُونَ مَصَانِعَ لَعَلَّكُمْ تَخْلُدُونَ (129) E si n ko awon ile nla nla bi eni pe e maa se gbere (nile aye yii) |
وَإِذَا بَطَشْتُم بَطَشْتُمْ جَبَّارِينَ (130) Nigba ti e ba si gba (eniyan mu lati fiya je won), e n gba won mu ni igbamu alailoju-aanu |
فَاتَّقُوا اللَّهَ وَأَطِيعُونِ (131) Nitori naa, e beru Allahu, ki e si tele mi |
وَاتَّقُوا الَّذِي أَمَدَّكُم بِمَا تَعْلَمُونَ (132) E beru Eni ti O ran yin lowo pelu ohun ti e mo |
أَمَدَّكُم بِأَنْعَامٍ وَبَنِينَ (133) O ran yin lowo pelu awon eran-osin ati awon omo |
وَجَنَّاتٍ وَعُيُونٍ (134) ati awon ogba oko pelu awon iseleru omi |
إِنِّي أَخَافُ عَلَيْكُمْ عَذَابَ يَوْمٍ عَظِيمٍ (135) Dajudaju emi n paya iya ojo nla fun yin.” |
قَالُوا سَوَاءٌ عَلَيْنَا أَوَعَظْتَ أَمْ لَمْ تَكُن مِّنَ الْوَاعِظِينَ (136) Won wi pe: “Bakan naa ni fun wa; yala o kilo fun wa tabi o o si ninu awon olukilo |
إِنْ هَٰذَا إِلَّا خُلُقُ الْأَوَّلِينَ (137) Eyi ko je kini kan bi ko se iwa awon eni akoko |
وَمَا نَحْنُ بِمُعَذَّبِينَ (138) Won ko si nii je wa niya.” |
فَكَذَّبُوهُ فَأَهْلَكْنَاهُمْ ۗ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَآيَةً ۖ وَمَا كَانَ أَكْثَرُهُم مُّؤْمِنِينَ (139) Nitori naa, won pe e ni opuro. A si pa won run. Dajudaju ami wa ninu iyen. Opolopo won ni ko si je onigbagbo ododo |
وَإِنَّ رَبَّكَ لَهُوَ الْعَزِيزُ الرَّحِيمُ (140) Dajudaju Oluwa re, Oun ma ni Alagbara, Asake-orun |
كَذَّبَتْ ثَمُودُ الْمُرْسَلِينَ (141) Awon iran Thamud pe awon Ojise ni opuro |
إِذْ قَالَ لَهُمْ أَخُوهُمْ صَالِحٌ أَلَا تَتَّقُونَ (142) Nigba ti arakunrin won, (Anabi) Solih, so pe: “Se e o nii beru (Allahu) ni |
إِنِّي لَكُمْ رَسُولٌ أَمِينٌ (143) Dajudaju emi ni Ojise olufokantan fun yin |
فَاتَّقُوا اللَّهَ وَأَطِيعُونِ (144) Nitori naa, e beru Allahu, ki e si tele mi |
وَمَا أَسْأَلُكُمْ عَلَيْهِ مِنْ أَجْرٍ ۖ إِنْ أَجْرِيَ إِلَّا عَلَىٰ رَبِّ الْعَالَمِينَ (145) Emi ko si beere owo-oya kan ni owo yin lori re. Ko si esan mi lodo eni kan afi lodo Oluwa gbogbo eda |
أَتُتْرَكُونَ فِي مَا هَاهُنَا آمِنِينَ (146) Se ki won fi yin sile sibi nnkan ti o wa (nile aye) nibi yii (ninu igbadun aye, ki e je) olufokanbale |
فِي جَنَّاتٍ وَعُيُونٍ (147) ninu awon ogba oko ati iseleru omi |
وَزُرُوعٍ وَنَخْلٍ طَلْعُهَا هَضِيمٌ (148) ati oko irugbin pelu igi dabinu ti ogomo re tutu |
وَتَنْحِتُونَ مِنَ الْجِبَالِ بُيُوتًا فَارِهِينَ (149) E si n gbe awon ile sinu awon apata (gege bi) akose-mose |
فَاتَّقُوا اللَّهَ وَأَطِيعُونِ (150) Nitori naa, e beru Allahu, ki e si tele mi |
وَلَا تُطِيعُوا أَمْرَ الْمُسْرِفِينَ (151) Ki e si ma se tele ase awon alaseju |
الَّذِينَ يُفْسِدُونَ فِي الْأَرْضِ وَلَا يُصْلِحُونَ (152) awon t’o n sebaje lori ile, ti won ko si se rere.” |
قَالُوا إِنَّمَا أَنتَ مِنَ الْمُسَحَّرِينَ (153) Won wi pe: “Iwo kuku wa ninu awon eleedi |
مَا أَنتَ إِلَّا بَشَرٌ مِّثْلُنَا فَأْتِ بِآيَةٍ إِن كُنتَ مِنَ الصَّادِقِينَ (154) Iwo ko si je kini kan bi ko se abara bi iru wa. Nitori naa, mu ami kan wa ti o ba wa ninu awon olododo.” |
قَالَ هَٰذِهِ نَاقَةٌ لَّهَا شِرْبٌ وَلَكُمْ شِرْبُ يَوْمٍ مَّعْلُومٍ (155) O so pe: “Eyi ni abo rakunmi kan. Omi wa fun ohun, omi si wa fun eyin naa ni ojo ti a ti mo |
وَلَا تَمَسُّوهَا بِسُوءٍ فَيَأْخُذَكُمْ عَذَابُ يَوْمٍ عَظِيمٍ (156) E ma se fi aburu kan kan an nitori ki iya ojo nla ma baa je yin.” |
فَعَقَرُوهَا فَأَصْبَحُوا نَادِمِينَ (157) Won si gun un pa. Nitori naa, won si di alabaamo |
فَأَخَذَهُمُ الْعَذَابُ ۗ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَآيَةً ۖ وَمَا كَانَ أَكْثَرُهُم مُّؤْمِنِينَ (158) Iya naa je won. Dajudaju ami wa ninu iyen. Opolopo won ni ko si je onigbagbo ododo |
وَإِنَّ رَبَّكَ لَهُوَ الْعَزِيزُ الرَّحِيمُ (159) Dajudaju Oluwa re, Oun ma ni Alagbara, Asake-orun |
كَذَّبَتْ قَوْمُ لُوطٍ الْمُرْسَلِينَ (160) Ijo Lut pe awon Ojise ni opuro |
إِذْ قَالَ لَهُمْ أَخُوهُمْ لُوطٌ أَلَا تَتَّقُونَ (161) Nigba ti arakunrin won, (Anabi) Lut, so pe: “Se e o nii beru (Allahu) ni |
إِنِّي لَكُمْ رَسُولٌ أَمِينٌ (162) Dajudaju emi ni Ojise olufokantan fun yin |
فَاتَّقُوا اللَّهَ وَأَطِيعُونِ (163) Nitori naa, e beru Allahu, ki e si tele mi |
وَمَا أَسْأَلُكُمْ عَلَيْهِ مِنْ أَجْرٍ ۖ إِنْ أَجْرِيَ إِلَّا عَلَىٰ رَبِّ الْعَالَمِينَ (164) Emi ko si beere owo-oya kan ni owo yin lori re. Ko si esan mi lodo eni kan afi lodo Oluwa gbogbo eda |
أَتَأْتُونَ الذُّكْرَانَ مِنَ الْعَالَمِينَ (165) Se awon okunrin ninu eda ni eyin okunrin yoo lo maa ba (fun adun ibalopo) |
وَتَذَرُونَ مَا خَلَقَ لَكُمْ رَبُّكُم مِّنْ أَزْوَاجِكُم ۚ بَلْ أَنتُمْ قَوْمٌ عَادُونَ (166) E si n pa ohun ti Oluwa yin da fun yin ti ninu awon iyawo yin! Ani se, ijo alakoyo ni eyin.” |
قَالُوا لَئِن لَّمْ تَنتَهِ يَا لُوطُ لَتَكُونَنَّ مِنَ الْمُخْرَجِينَ (167) Won wi pe: “Ti iwo Lut ko ba jawo (nibi ipepe re) dajudaju o maa wa ninu awon ti a maa le jade kuro ninu ilu.” |
قَالَ إِنِّي لِعَمَلِكُم مِّنَ الْقَالِينَ (168) O so pe: "Dajudaju emi wa ninu awon olubinu si ise (aburu) owo yin |
رَبِّ نَجِّنِي وَأَهْلِي مِمَّا يَعْمَلُونَ (169) Oluwa mi, la emi ati awon eniyan mi nibi ohun ti won n se nise (aburu) |
فَنَجَّيْنَاهُ وَأَهْلَهُ أَجْمَعِينَ (170) Nitori naa, A la oun ati awon eniyan re patapata |
إِلَّا عَجُوزًا فِي الْغَابِرِينَ (171) Afi arugbobinrin kan ti o wa ninu awon t’o se ku leyin (laaarin awon ti A pare) |
ثُمَّ دَمَّرْنَا الْآخَرِينَ (172) Leyin naa, A pa awon yooku run |
وَأَمْطَرْنَا عَلَيْهِم مَّطَرًا ۖ فَسَاءَ مَطَرُ الْمُنذَرِينَ (173) A ro ojo le won lori taara. Ojo awon ti A kilo fun si buru |
إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَآيَةً ۖ وَمَا كَانَ أَكْثَرُهُم مُّؤْمِنِينَ (174) Dajudaju ami wa ninu iyen. Opolopo won ni ko si je onigbagbo ododo |
وَإِنَّ رَبَّكَ لَهُوَ الْعَزِيزُ الرَّحِيمُ (175) Dajudaju Oluwa re, Oun ma ni Alagbara, Asake-orun |
كَذَّبَ أَصْحَابُ الْأَيْكَةِ الْمُرْسَلِينَ (176) Awon ara ’Aekah pe awon Ojise ni opuro |
إِذْ قَالَ لَهُمْ شُعَيْبٌ أَلَا تَتَّقُونَ (177) Nigba ti arakunrin won, (Anabi) Su‘aeb, so pe: “Se eyin ko nii beru (Allahu) ni |
إِنِّي لَكُمْ رَسُولٌ أَمِينٌ (178) Dajudaju emi ni Ojise olufokantan fun yin |
فَاتَّقُوا اللَّهَ وَأَطِيعُونِ (179) Nitori naa, e beru Allahu, ki e si tele mi |
وَمَا أَسْأَلُكُمْ عَلَيْهِ مِنْ أَجْرٍ ۖ إِنْ أَجْرِيَ إِلَّا عَلَىٰ رَبِّ الْعَالَمِينَ (180) Emi ko si beere owo-oya kan ni owo yin lori re. Ko si esan mi lodo eni kan afi lodo Oluwa gbogbo eda |
۞ أَوْفُوا الْكَيْلَ وَلَا تَكُونُوا مِنَ الْمُخْسِرِينَ (181) E won osuwon kun. Ki e si ma se wa ninu awon oludosuwonku |
وَزِنُوا بِالْقِسْطَاسِ الْمُسْتَقِيمِ (182) E fi iwon t’o to won nnkan |
وَلَا تَبْخَسُوا النَّاسَ أَشْيَاءَهُمْ وَلَا تَعْثَوْا فِي الْأَرْضِ مُفْسِدِينَ (183) E ma se din nnkan awon eniyan ku. Ki e si ma se huwa aburu lori ile ni ti obileje |
وَاتَّقُوا الَّذِي خَلَقَكُمْ وَالْجِبِلَّةَ الْأَوَّلِينَ (184) Ki e si beru Eni ti O da yin ati awon iran akoko.” |
قَالُوا إِنَّمَا أَنتَ مِنَ الْمُسَحَّرِينَ (185) Won wi pe: “Iwo kuku wa ninu awon eleedi |
وَمَا أَنتَ إِلَّا بَشَرٌ مِّثْلُنَا وَإِن نَّظُنُّكَ لَمِنَ الْكَاذِبِينَ (186) Iwo ko si je kini kan bi ko se abara bi iru wa. Ati pe a o ro o si kini kan bi ko se pe o wa ninu awon opuro |
فَأَسْقِطْ عَلَيْنَا كِسَفًا مِّنَ السَّمَاءِ إِن كُنتَ مِنَ الصَّادِقِينَ (187) Nitori naa, je ki apa kan ninu sanmo ya lu wa mole, ti o ba wa ninu awon olododo.” |
قَالَ رَبِّي أَعْلَمُ بِمَا تَعْمَلُونَ (188) O so pe: “Oluwa mi nimo julo nipa ohun ti e n se nise |
فَكَذَّبُوهُ فَأَخَذَهُمْ عَذَابُ يَوْمِ الظُّلَّةِ ۚ إِنَّهُ كَانَ عَذَابَ يَوْمٍ عَظِيمٍ (189) Won si pe e ni opuro. Nitori naa, iya ojo esujo si je won. Dajudaju o je iya ojo nla |
إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَآيَةً ۖ وَمَا كَانَ أَكْثَرُهُم مُّؤْمِنِينَ (190) Dajudaju ami wa ninu iyen. Opolopo won ni ko si je onigbagbo ododo |
وَإِنَّ رَبَّكَ لَهُوَ الْعَزِيزُ الرَّحِيمُ (191) Dajudaju Oluwa re, Oun ma ni Alagbara, Asake-orun |
وَإِنَّهُ لَتَنزِيلُ رَبِّ الْعَالَمِينَ (192) Dajudaju al-Ƙur’an, won so o kale ni lati odo Oluwa gbogbo eda |
نَزَلَ بِهِ الرُّوحُ الْأَمِينُ (193) Molaika Jibril, olufokantan l’o so o kale |
عَلَىٰ قَلْبِكَ لِتَكُونَ مِنَ الْمُنذِرِينَ (194) sinu okan re nitori ki o le wa ninu awon olukilo |
بِلِسَانٍ عَرَبِيٍّ مُّبِينٍ (195) pelu ede Larubawa ponnbele |
وَإِنَّهُ لَفِي زُبُرِ الْأَوَّلِينَ (196) Dajudaju (oro nipa re) ti wa ninu ipin-ipin Tira awon eni akoko |
أَوَلَمْ يَكُن لَّهُمْ آيَةً أَن يَعْلَمَهُ عُلَمَاءُ بَنِي إِسْرَائِيلَ (197) Se ko je ami kan fun won pe awon onimo (ninu) awon omo ’Isro’il nimo (si asoole nipa) re (ninu tira owo won) |
وَلَوْ نَزَّلْنَاهُ عَلَىٰ بَعْضِ الْأَعْجَمِينَ (198) Ti o ba je pe A so o kale fun apa kan awon elede miiran ni |
فَقَرَأَهُ عَلَيْهِم مَّا كَانُوا بِهِ مُؤْمِنِينَ (199) ti o si ke e fun won, won ko nii gba a gbo ni ododo |
كَذَٰلِكَ سَلَكْنَاهُ فِي قُلُوبِ الْمُجْرِمِينَ (200) Bayen ni A se mu (atako) wo inu okan awon elese |
لَا يُؤْمِنُونَ بِهِ حَتَّىٰ يَرَوُا الْعَذَابَ الْأَلِيمَ (201) Won ko nii gba a gbo ni ododo titi won yoo fi ri iya eleta-elero |
فَيَأْتِيَهُم بَغْتَةً وَهُمْ لَا يَشْعُرُونَ (202) (Iya naa) yoo de ba won ni ojiji; won ko si nii fura |
فَيَقُولُوا هَلْ نَحْنُ مُنظَرُونَ (203) Nigba naa ni won yoo wi pe: "Nje won le lo wa lara bi |
أَفَبِعَذَابِنَا يَسْتَعْجِلُونَ (204) Se iya Wa ni won n wa pelu ikanju |
أَفَرَأَيْتَ إِن مَّتَّعْنَاهُمْ سِنِينَ (205) So fun Mi ti A ba fun won ni igbadun aye fun odun gbooro |
ثُمَّ جَاءَهُم مَّا كَانُوا يُوعَدُونَ (206) Leyin naa, ki ohun ti A n se ni adehun fun won de ba won |
مَا أَغْنَىٰ عَنْهُم مَّا كَانُوا يُمَتَّعُونَ (207) Ohun ti A se ni igbadun fun won ko si nii ro won loro |
وَمَا أَهْلَكْنَا مِن قَرْيَةٍ إِلَّا لَهَا مُنذِرُونَ (208) A o si pa ilu kan run afi ki won ti ni awon olukilo |
ذِكْرَىٰ وَمَا كُنَّا ظَالِمِينَ (209) Iranti (de fun won se). Ati pe Awa ki i se alabosi |
وَمَا تَنَزَّلَتْ بِهِ الشَّيَاطِينُ (210) Ki i se awon esu ni won so (al-Ƙur’an) kale |
وَمَا يَنبَغِي لَهُمْ وَمَا يَسْتَطِيعُونَ (211) Ko ye fun won. Won ko si lagbara re |
إِنَّهُمْ عَنِ السَّمْعِ لَمَعْزُولُونَ (212) Dajudaju A ti mu won takete si gbigbo re (lati oju sanmo) |
فَلَا تَدْعُ مَعَ اللَّهِ إِلَٰهًا آخَرَ فَتَكُونَ مِنَ الْمُعَذَّبِينَ (213) Nitori naa, ma se pe olohun miiran mo Allahu, nitori ki iwo ma baa wa ninu awon ti A maa je niya |
وَأَنذِرْ عَشِيرَتَكَ الْأَقْرَبِينَ (214) Ki o si kilo fun awon ebi re, t’o sunmo julo |
وَاخْفِضْ جَنَاحَكَ لِمَنِ اتَّبَعَكَ مِنَ الْمُؤْمِنِينَ (215) Ki o si re apa re nile fun awon t’o tele o ninu awon onigbagbo ododo |
فَإِنْ عَصَوْكَ فَقُلْ إِنِّي بَرِيءٌ مِّمَّا تَعْمَلُونَ (216) Ti won ba si yapa (ase) re, so pe: “Dajudaju emi yowo yose ninu ohun ti e n se (nise aburu).” |
وَتَوَكَّلْ عَلَى الْعَزِيزِ الرَّحِيمِ (217) Ki o si gbarale Alagbara, Asake-orun |
الَّذِي يَرَاكَ حِينَ تَقُومُ (218) Eni t’O n ri o nigba ti o n dide naro (fun irun kiki) |
وَتَقَلُّبَكَ فِي السَّاجِدِينَ (219) ati iyirapada re (fun rukuu ati iforikanle) laaarin awon oluforikanle |
إِنَّهُ هُوَ السَّمِيعُ الْعَلِيمُ (220) Dajudaju Oun ma ni Olugbo, Onimo |
هَلْ أُنَبِّئُكُمْ عَلَىٰ مَن تَنَزَّلُ الشَّيَاطِينُ (221) Se ki ng so eni ti awon esu n sokale wa ba |
تَنَزَّلُ عَلَىٰ كُلِّ أَفَّاكٍ أَثِيمٍ (222) Won n sokale wa ba gbogbo awon opuro, elese |
يُلْقُونَ السَّمْعَ وَأَكْثَرُهُمْ كَاذِبُونَ (223) (Awon esu) n deti (si iro sanmo). Opolopo won si ni opuro |
وَالشُّعَرَاءُ يَتَّبِعُهُمُ الْغَاوُونَ (224) Awon elewi, awon olusina l’o n tele won |
أَلَمْ تَرَ أَنَّهُمْ فِي كُلِّ وَادٍ يَهِيمُونَ (225) Se o o ri i pe gbogbo ogbun oro ni won n tenu bo ni |
وَأَنَّهُمْ يَقُولُونَ مَا لَا يَفْعَلُونَ (226) Ati pe dajudaju won n so ohun ti won ko nii se |
إِلَّا الَّذِينَ آمَنُوا وَعَمِلُوا الصَّالِحَاتِ وَذَكَرُوا اللَّهَ كَثِيرًا وَانتَصَرُوا مِن بَعْدِ مَا ظُلِمُوا ۗ وَسَيَعْلَمُ الَّذِينَ ظَلَمُوا أَيَّ مُنقَلَبٍ يَنقَلِبُونَ (227) Afi awon t’o gbagbo ni ododo, ti won se ise rere, ti won ranti Allahu ni opolopo, ti won si jaja gbara leyin ti won ti sabosi si won. Awon t’o sabosi si maa mo iru ikangun ti won maa gunle si |