الم (1) ’Alif lam mim |
غُلِبَتِ الرُّومُ (2) Won segun Romu |
فِي أَدْنَى الْأَرْضِ وَهُم مِّن بَعْدِ غَلَبِهِمْ سَيَغْلِبُونَ (3) ni awon ile t’o wa nitosi (erekusu Larubawa). Leyin isegun won, awon naa maa segun won |
فِي بِضْعِ سِنِينَ ۗ لِلَّهِ الْأَمْرُ مِن قَبْلُ وَمِن بَعْدُ ۚ وَيَوْمَئِذٍ يَفْرَحُ الْمُؤْمِنُونَ (4) ni odun mewaa (si igba naa). Ti Allahu ni ase ni isaaju ati ni ikeyin. Ni ojo yen, awon onigbagbo ododo maa dunnu |
بِنَصْرِ اللَّهِ ۚ يَنصُرُ مَن يَشَاءُ ۖ وَهُوَ الْعَزِيزُ الرَّحِيمُ (5) si aranse Allahu. O n saranse fun eni ti O ba fe. Oun si ni Alagbara, Asake-orun |
وَعْدَ اللَّهِ ۖ لَا يُخْلِفُ اللَّهُ وَعْدَهُ وَلَٰكِنَّ أَكْثَرَ النَّاسِ لَا يَعْلَمُونَ (6) (Eyi je) adehun Allahu. Allahu ko si nii yapa adehun Re, sugbon opolopo awon eniyan ko mo |
يَعْلَمُونَ ظَاهِرًا مِّنَ الْحَيَاةِ الدُّنْيَا وَهُمْ عَنِ الْآخِرَةِ هُمْ غَافِلُونَ (7) Won nimo nipa gbangba ninu oro isemi aye (yii). Afonu-fora si ni won nipa Ojo Ikeyin |
أَوَلَمْ يَتَفَكَّرُوا فِي أَنفُسِهِم ۗ مَّا خَلَقَ اللَّهُ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضَ وَمَا بَيْنَهُمَا إِلَّا بِالْحَقِّ وَأَجَلٍ مُّسَمًّى ۗ وَإِنَّ كَثِيرًا مِّنَ النَّاسِ بِلِقَاءِ رَبِّهِمْ لَكَافِرُونَ (8) Se won ko ronu nipa oro ara won ni? Allahu ko seda awon sanmo, ile ati nnkan t’o wa laaarin awon mejeeji bi ko se pelu ododo ati fun gbedeke akoko kan. Dajudaju opolopo ninu awon eniyan ma ni alaigbagbo ninu ipade Oluwa won |
أَوَلَمْ يَسِيرُوا فِي الْأَرْضِ فَيَنظُرُوا كَيْفَ كَانَ عَاقِبَةُ الَّذِينَ مِن قَبْلِهِمْ ۚ كَانُوا أَشَدَّ مِنْهُمْ قُوَّةً وَأَثَارُوا الْأَرْضَ وَعَمَرُوهَا أَكْثَرَ مِمَّا عَمَرُوهَا وَجَاءَتْهُمْ رُسُلُهُم بِالْبَيِّنَاتِ ۖ فَمَا كَانَ اللَّهُ لِيَظْلِمَهُمْ وَلَٰكِن كَانُوا أَنفُسَهُمْ يَظْلِمُونَ (9) Se won ko rin kiri lori ile ki won wo bi ikangun awon t’o siwaju won se ri? Won ni agbara ju won lo. Won fi ile dako. Won si lo ile fun ohun ti o po ju bi (awon ara Mokkah) se lo o. Awon Ojise won si mu awon eri t’o yanju wa ba won. Nitori naa, Allahu ko sabosi si won, sugbon emi ara won ni won n sabosi si |
ثُمَّ كَانَ عَاقِبَةَ الَّذِينَ أَسَاءُوا السُّوأَىٰ أَن كَذَّبُوا بِآيَاتِ اللَّهِ وَكَانُوا بِهَا يَسْتَهْزِئُونَ (10) Leyin naa, aburu je atubotan awon t’o saburu nitori pe won pe awon ayah Allahu niro. Won si n fi se yeye |
اللَّهُ يَبْدَأُ الْخَلْقَ ثُمَّ يُعِيدُهُ ثُمَّ إِلَيْهِ تُرْجَعُونَ (11) Allahu n pile eda dida. Leyin naa, O maa da a pada (sipo alaaye). Leyin naa, odo Re ni won yoo da yin pada si |
وَيَوْمَ تَقُومُ السَّاعَةُ يُبْلِسُ الْمُجْرِمُونَ (12) Ni ojo ti Akoko naa maa sele, awon elese yo soreti nu |
وَلَمْ يَكُن لَّهُم مِّن شُرَكَائِهِمْ شُفَعَاءُ وَكَانُوا بِشُرَكَائِهِمْ كَافِرِينَ (13) Ati pe ko nii si awon olusipe fun won ninu awon orisa won. Won si maa je alatako orisa won |
وَيَوْمَ تَقُومُ السَّاعَةُ يَوْمَئِذٍ يَتَفَرَّقُونَ (14) Ni ojo ti Akoko naa maa sele, ni ojo yen ni won yoo pinya si otooto |
فَأَمَّا الَّذِينَ آمَنُوا وَعَمِلُوا الصَّالِحَاتِ فَهُمْ فِي رَوْضَةٍ يُحْبَرُونَ (15) Ni ti awon t’o gbagbo ni ododo, ti won si se ise rere, won yoo wa ni aye t’o rewa julo ninu Ogba Idera, ti won yo si maa dunnu |
وَأَمَّا الَّذِينَ كَفَرُوا وَكَذَّبُوا بِآيَاتِنَا وَلِقَاءِ الْآخِرَةِ فَأُولَٰئِكَ فِي الْعَذَابِ مُحْضَرُونَ (16) Ni ti awon t’o sai gbagbo, ti won si pe awon ayah Wa ati ipade Ojo Ikeyin niro, awon wonyen ni won yoo ko wa sinu Ina |
فَسُبْحَانَ اللَّهِ حِينَ تُمْسُونَ وَحِينَ تُصْبِحُونَ (17) Nitori naa, e se afomo fun Allahu nigba ti e ba wa ni ale ati nigba ti e ba wa ni owuro |
وَلَهُ الْحَمْدُ فِي السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ وَعَشِيًّا وَحِينَ تُظْهِرُونَ (18) TiRe si ni ope ninu awon sanmo ati lori ile ni asale ati nigba ti e ba wa ni osan |
يُخْرِجُ الْحَيَّ مِنَ الْمَيِّتِ وَيُخْرِجُ الْمَيِّتَ مِنَ الْحَيِّ وَيُحْيِي الْأَرْضَ بَعْدَ مَوْتِهَا ۚ وَكَذَٰلِكَ تُخْرَجُونَ (19) (Allahu) n yo alaaye jade lati ara oku. O n yo oku jade lati ara alaaye. O n ta ile ji leyin ti ile ti ku. Bayen ni A oo se mu eyin naa jade |
وَمِنْ آيَاتِهِ أَنْ خَلَقَكُم مِّن تُرَابٍ ثُمَّ إِذَا أَنتُم بَشَرٌ تَنتَشِرُونَ (20) O wa ninu awon ami Re pe, O seda yin lati ara erupe. Leyin naa, nigba naa eyin di abara ti e n fonka (lori ile aye) |
وَمِنْ آيَاتِهِ أَنْ خَلَقَ لَكُم مِّنْ أَنفُسِكُمْ أَزْوَاجًا لِّتَسْكُنُوا إِلَيْهَا وَجَعَلَ بَيْنَكُم مَّوَدَّةً وَرَحْمَةً ۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَآيَاتٍ لِّقَوْمٍ يَتَفَكَّرُونَ (21) O wa ninu awon ami Re pe, O seda awon aya fun yin lati ara yin nitori ki e le ri ifayabale lodo won. O si fi ife ati ike si aarin yin. Dajudaju awon ami wa ninu iyen fun ijo t’o larojinle |
وَمِنْ آيَاتِهِ خَلْقُ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ وَاخْتِلَافُ أَلْسِنَتِكُمْ وَأَلْوَانِكُمْ ۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَآيَاتٍ لِّلْعَالِمِينَ (22) O wa ninu awon ami Re, dida awon sanmo ati ile ati okan-o-jokan awon ede yin ati awon awo ara yin. Dajudaju awon ami wa ninu iyen fun awon onimo |
وَمِنْ آيَاتِهِ مَنَامُكُم بِاللَّيْلِ وَالنَّهَارِ وَابْتِغَاؤُكُم مِّن فَضْلِهِ ۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَآيَاتٍ لِّقَوْمٍ يَسْمَعُونَ (23) Ninu awon ami Re ni oorun yin ni ale ati ni osan ati wiwa ti e n wa ninu oore Re (fun ije-imu). Dajudaju awon ami wa ninu iyen fun ijo t’o n gboro |
وَمِنْ آيَاتِهِ يُرِيكُمُ الْبَرْقَ خَوْفًا وَطَمَعًا وَيُنَزِّلُ مِنَ السَّمَاءِ مَاءً فَيُحْيِي بِهِ الْأَرْضَ بَعْدَ مَوْتِهَا ۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَآيَاتٍ لِّقَوْمٍ يَعْقِلُونَ (24) Ninu awon ami Re tun ni fifi monamona han yin ni ti eru ati ireti. O si n so omi kale lati sanmo. O n fi ta ile ji leyin ti ile ti ku. Dajudaju awon ami wa ninu iyen fun ijo t’o n se laakaye |
وَمِنْ آيَاتِهِ أَن تَقُومَ السَّمَاءُ وَالْأَرْضُ بِأَمْرِهِ ۚ ثُمَّ إِذَا دَعَاكُمْ دَعْوَةً مِّنَ الْأَرْضِ إِذَا أَنتُمْ تَخْرُجُونَ (25) Ati pe ninu awon ami Re ni pe sanmo ati ile duro pelu ase Re. Leyin naa, nigba ti O ba pe yin ni ipe kan nigba naa ni eyin yoo maa jade lati inu ile |
وَلَهُ مَن فِي السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ ۖ كُلٌّ لَّهُ قَانِتُونَ (26) TiRe ni awon t’o wa ninu awon sanmo ati ile. Eni kookan ni olutele-ase Re |
وَهُوَ الَّذِي يَبْدَأُ الْخَلْقَ ثُمَّ يُعِيدُهُ وَهُوَ أَهْوَنُ عَلَيْهِ ۚ وَلَهُ الْمَثَلُ الْأَعْلَىٰ فِي السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ ۚ وَهُوَ الْعَزِيزُ الْحَكِيمُ (27) Oun ni Eni ti O n bere eda dida. Leyin naa, O maa da a pada (sipo alaaye fun ajinde). O si rorun julo fun Un (lati se bee). TiRe ni iroyin t’o ga julo ninu awon sanmo ati ile. Oun si ni Alagbara, Ologbon |
ضَرَبَ لَكُم مَّثَلًا مِّنْ أَنفُسِكُمْ ۖ هَل لَّكُم مِّن مَّا مَلَكَتْ أَيْمَانُكُم مِّن شُرَكَاءَ فِي مَا رَزَقْنَاكُمْ فَأَنتُمْ فِيهِ سَوَاءٌ تَخَافُونَهُمْ كَخِيفَتِكُمْ أَنفُسَكُمْ ۚ كَذَٰلِكَ نُفَصِّلُ الْآيَاتِ لِقَوْمٍ يَعْقِلُونَ (28) (Allahu) sakawe kan fun yin nipa ara yin. Nje e ni akegbe ninu awon eru yin lori ohun ti A fun yin ni arisiki, ti e jo maa pin (dukia naa) ni dogbadogba, ti e o si maa paya won gege bi won se n paya eyin naa? Bayen ni A se n s’alaye awon ayah fun ijo t’o n se laakaye |
بَلِ اتَّبَعَ الَّذِينَ ظَلَمُوا أَهْوَاءَهُم بِغَيْرِ عِلْمٍ ۖ فَمَن يَهْدِي مَنْ أَضَلَّ اللَّهُ ۖ وَمَا لَهُم مِّن نَّاصِرِينَ (29) Nse ni awon t’o sabosi tele ife-inu won lai si imo kan (fun won). Ta si ni o le fi ona mo eni ti Allahu ba si lona? Ko si nii si awon alaranse fun won |
فَأَقِمْ وَجْهَكَ لِلدِّينِ حَنِيفًا ۚ فِطْرَتَ اللَّهِ الَّتِي فَطَرَ النَّاسَ عَلَيْهَا ۚ لَا تَبْدِيلَ لِخَلْقِ اللَّهِ ۚ ذَٰلِكَ الدِّينُ الْقَيِّمُ وَلَٰكِنَّ أَكْثَرَ النَّاسِ لَا يَعْلَمُونَ (30) Nitori naa, doju re ko esin naa, (ki o je) oluduro-deede-ninu-esin, esin adamo Allahu eyi ti O da mo awon eniyan. Ko si si iyipada fun eda Allahu. Iyen ni esin t’o feserinle, sugbon opolopo awon eniyan ko mo |
۞ مُنِيبِينَ إِلَيْهِ وَاتَّقُوهُ وَأَقِيمُوا الصَّلَاةَ وَلَا تَكُونُوا مِنَ الْمُشْرِكِينَ (31) (E je) oluseri si odo Allahu (nipa ironupiwada). E paya Re. E kirun. E ma se wa ninu awon osebo |
مِنَ الَّذِينَ فَرَّقُوا دِينَهُمْ وَكَانُوا شِيَعًا ۖ كُلُّ حِزْبٍ بِمَا لَدَيْهِمْ فَرِحُونَ (32) (E ma se wa) ninu awon t’o da esin won si kelekele, ti won si di ijo-ijo. Ijo kookan si n yo si ohun ti o wa lodo won |
وَإِذَا مَسَّ النَّاسَ ضُرٌّ دَعَوْا رَبَّهُم مُّنِيبِينَ إِلَيْهِ ثُمَّ إِذَا أَذَاقَهُم مِّنْهُ رَحْمَةً إِذَا فَرِيقٌ مِّنْهُم بِرَبِّهِمْ يُشْرِكُونَ (33) Nigba ti inira kan ba fowo ba eniyan, won yoo pe Oluwa won, ti won yoo maa seri pada sodo Re. Leyin naa, nigba ti (Allahu) ba fun won ni ike kan to wo lati odo Re, nigba naa ni igun kan ninu won yoo maa sebo si Oluwa won |
لِيَكْفُرُوا بِمَا آتَيْنَاهُمْ ۚ فَتَمَتَّعُوا فَسَوْفَ تَعْلَمُونَ (34) nitori ki won le sai moore si ohun ti (Allahu) fun won. E maa jaye lo. Nitori naa, laipe e maa mo |
أَمْ أَنزَلْنَا عَلَيْهِمْ سُلْطَانًا فَهُوَ يَتَكَلَّمُ بِمَا كَانُوا بِهِ يُشْرِكُونَ (35) Tabi A so eri kan kale fun won, t’o n soro nipa nnkan ti won n so di akegbe Re |
وَإِذَا أَذَقْنَا النَّاسَ رَحْمَةً فَرِحُوا بِهَا ۖ وَإِن تُصِبْهُمْ سَيِّئَةٌ بِمَا قَدَّمَتْ أَيْدِيهِمْ إِذَا هُمْ يَقْنَطُونَ (36) Nigba ti A ba fi ike kan to eniyan lenu wo, won yoo dunnu si i. Ti aburu kan ba si kan won nipa ohun ti owo won ti siwaju, nigba naa ni won yoo soreti nu |
أَوَلَمْ يَرَوْا أَنَّ اللَّهَ يَبْسُطُ الرِّزْقَ لِمَن يَشَاءُ وَيَقْدِرُ ۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَآيَاتٍ لِّقَوْمٍ يُؤْمِنُونَ (37) Se won ko ri i pe dajudaju Allahu l’O n te oro sile fun eni ti O ba fe, (O si n) diwon re (fun eni ti O ba fe)? Dajudaju awon ami wa ninu iyen fun ijo t’o gbagbo |
فَآتِ ذَا الْقُرْبَىٰ حَقَّهُ وَالْمِسْكِينَ وَابْنَ السَّبِيلِ ۚ ذَٰلِكَ خَيْرٌ لِّلَّذِينَ يُرِيدُونَ وَجْهَ اللَّهِ ۖ وَأُولَٰئِكَ هُمُ الْمُفْلِحُونَ (38) Nitori naa, fun ebi ni eto re. (Fun) mekunnu ati onirin-ajo ti agara da (ni nnkan). Iyen loore julo fun awon t’o n fe Oju rere Allahu. Awon wonyen, awon si ni olujere |
وَمَا آتَيْتُم مِّن رِّبًا لِّيَرْبُوَ فِي أَمْوَالِ النَّاسِ فَلَا يَرْبُو عِندَ اللَّهِ ۖ وَمَا آتَيْتُم مِّن زَكَاةٍ تُرِيدُونَ وَجْهَ اللَّهِ فَأُولَٰئِكَ هُمُ الْمُضْعِفُونَ (39) Ohunkohun ti e ba fun (awon eniyan) ni ebun, nitori ki o le di ele lati ara dukia awon eniyan, ko le lekun ni odo Allahu. Ohunkohun ti e ba si (fun awon eniyan) ni Zakah, ti e n fe oju rere Allahu, awon wonyen ni A maa fun ni adipele esan |
اللَّهُ الَّذِي خَلَقَكُمْ ثُمَّ رَزَقَكُمْ ثُمَّ يُمِيتُكُمْ ثُمَّ يُحْيِيكُمْ ۖ هَلْ مِن شُرَكَائِكُم مَّن يَفْعَلُ مِن ذَٰلِكُم مِّن شَيْءٍ ۚ سُبْحَانَهُ وَتَعَالَىٰ عَمَّا يُشْرِكُونَ (40) Allahu, Eni ti O seda yin, leyin naa, O fun yin ni arisiki, leyin naa, O maa so yin di oku, leyin naa, O maa so yin di alaaye. Nje o wa ninu awon orisa yin eni ti o le se nnkan kan ninu iyen? Mimo ni fun Un. O ga tayo nnkan ti won n fi sebo si I |
ظَهَرَ الْفَسَادُ فِي الْبَرِّ وَالْبَحْرِ بِمَا كَسَبَتْ أَيْدِي النَّاسِ لِيُذِيقَهُم بَعْضَ الَّذِي عَمِلُوا لَعَلَّهُمْ يَرْجِعُونَ (41) Ibaje han lori ile ati loju omi nipase ohun ti owo awon eniyan se nise (aburu) nitori ki (Allahu) le fi (iya) apa kan eyi ti won se nise (aburu) to won lenu wo nitori ki won le seri pada (nibi aburu) |
قُلْ سِيرُوا فِي الْأَرْضِ فَانظُرُوا كَيْفَ كَانَ عَاقِبَةُ الَّذِينَ مِن قَبْلُ ۚ كَانَ أَكْثَرُهُم مُّشْرِكِينَ (42) So pe: “E rin lori ile, ki e wo bi atubotan awon t’o siwaju se ri! Opolopo won ni won je osebo.” |
فَأَقِمْ وَجْهَكَ لِلدِّينِ الْقَيِّمِ مِن قَبْلِ أَن يَأْتِيَ يَوْمٌ لَّا مَرَدَّ لَهُ مِنَ اللَّهِ ۖ يَوْمَئِذٍ يَصَّدَّعُونَ (43) Nitori naa, doju re ko esin t’o feserinle siwaju ki ojo kan to de, ti ko si nnkan ti o le ye e lodo Allahu. Ni ojo yen ni awon eniyan yoo pinya si (ero Ogba Idera ati ero Ina) |
مَن كَفَرَ فَعَلَيْهِ كُفْرُهُ ۖ وَمَنْ عَمِلَ صَالِحًا فَلِأَنفُسِهِمْ يَمْهَدُونَ (44) Enikeni ti o ba sai gbagbo, ori ara re ni (iya) aigbagbo re wa. Enikeni ti o ba si se ise rere, emi ara won ni won n te ite (Ogba Idera) sile fun |
لِيَجْزِيَ الَّذِينَ آمَنُوا وَعَمِلُوا الصَّالِحَاتِ مِن فَضْلِهِ ۚ إِنَّهُ لَا يُحِبُّ الْكَافِرِينَ (45) nitori ki (Allahu) le san esan rere ninu oore ajulo Re fun awon t’o gbagbo ni ododo, ti won si se ise rere. Dajudaju (Allahu) ko nifee awon alaigbagbo |
وَمِنْ آيَاتِهِ أَن يُرْسِلَ الرِّيَاحَ مُبَشِّرَاتٍ وَلِيُذِيقَكُم مِّن رَّحْمَتِهِ وَلِتَجْرِيَ الْفُلْكُ بِأَمْرِهِ وَلِتَبْتَغُوا مِن فَضْلِهِ وَلَعَلَّكُمْ تَشْكُرُونَ (46) Ninu awon ami Re ni pe, O n ran ategun ni iro idunnu. Ati pe nitori ki (Allahu) le fun yin to wo ninu ike Re; ati nitori ki oko oju-omi le rin loju-omi pelu ase Re; ati nitori ki e le wa ninu oore Re; ati nitori ki e le dupe |
وَلَقَدْ أَرْسَلْنَا مِن قَبْلِكَ رُسُلًا إِلَىٰ قَوْمِهِمْ فَجَاءُوهُم بِالْبَيِّنَاتِ فَانتَقَمْنَا مِنَ الَّذِينَ أَجْرَمُوا ۖ وَكَانَ حَقًّا عَلَيْنَا نَصْرُ الْمُؤْمِنِينَ (47) Dajudaju A ti ran awon Ojise kan nise siwaju re si awon ijo won. Won si wa ba won pelu awon eri t’o yanju. A si gbesan lara awon t’o dese. O si je eto fun wa lati se aranse fun awon onigbagbo ododo |
اللَّهُ الَّذِي يُرْسِلُ الرِّيَاحَ فَتُثِيرُ سَحَابًا فَيَبْسُطُهُ فِي السَّمَاءِ كَيْفَ يَشَاءُ وَيَجْعَلُهُ كِسَفًا فَتَرَى الْوَدْقَ يَخْرُجُ مِنْ خِلَالِهِ ۖ فَإِذَا أَصَابَ بِهِ مَن يَشَاءُ مِنْ عِبَادِهِ إِذَا هُمْ يَسْتَبْشِرُونَ (48) Allahu ni Eni t’O n fi awon ategun ranse. (Ategun naa) si maa tu esujo soke. (Allahu) yo si te (esujo) sile s’oju sanmo bi O ba se fe. O si maa da a kelekele (si oju sanmo). O si maa ri ojo ti o ma maa jade laaarin re. Nigba ti O ba si ro (ojo naa) fun eni ti O ba fe ninu awon erusin Re, nigba naa won yo si maa dunnu |
وَإِن كَانُوا مِن قَبْلِ أَن يُنَزَّلَ عَلَيْهِم مِّن قَبْلِهِ لَمُبْلِسِينَ (49) Bi o tile je pe siwaju ki O to so o kale fun won, won ti soreti nu siwaju re |
فَانظُرْ إِلَىٰ آثَارِ رَحْمَتِ اللَّهِ كَيْفَ يُحْيِي الْأَرْضَ بَعْدَ مَوْتِهَا ۚ إِنَّ ذَٰلِكَ لَمُحْيِي الْمَوْتَىٰ ۖ وَهُوَ عَلَىٰ كُلِّ شَيْءٍ قَدِيرٌ (50) Nitori naa, woye si awon oripa ike Allahu, (wo) bi (Allahu) se n ta ile ji leyin ti ile ti ku. Dajudaju (Allahu) yii ni O kuku maa so awon oku di alaaye. Oun si ni Alagbara lori gbogbo nnkan |
وَلَئِنْ أَرْسَلْنَا رِيحًا فَرَأَوْهُ مُصْفَرًّا لَّظَلُّوا مِن بَعْدِهِ يَكْفُرُونَ (51) Dajudaju ti A ba ran ategun kan (si won), ki won si ri (nnkan ogbin won) ni pipon (jijona), dajudaju won yo si maa sai moore lo leyin re |
فَإِنَّكَ لَا تُسْمِعُ الْمَوْتَىٰ وَلَا تُسْمِعُ الصُّمَّ الدُّعَاءَ إِذَا وَلَّوْا مُدْبِرِينَ (52) Dajudaju iwo ko l’o maa mu awon oku gboro. O o si nii mu awon aditi gbo ipe nigba ti won ba keyin si o, ti won n lo |
وَمَا أَنتَ بِهَادِ الْعُمْيِ عَن ضَلَالَتِهِمْ ۖ إِن تُسْمِعُ إِلَّا مَن يُؤْمِنُ بِآيَاتِنَا فَهُم مُّسْلِمُونَ (53) Iwo ko l’o maa fi ona mo awon afoju nibi isina won. Ko si eni ti o maa mu gbo oro afi eni ti o ba gba awon ayah Wa gbo. Awon si ni (musulumi) olujupa-juse-sile fun Allahu. Allahu (subhanahu wa ta'ala) l’O n sise iyanu. Ko si si Anabi tabi Ojise Olohun kan ti Allahu ko fun ni ise iyanu kan tabi omiran se ni ibamu si igba eni kookan won. Bee si ni eyikeyii ise iyanu ti o ba towo Anabi tabi Ojise kan waye ko so Anabi tabi Ojise naa di oluwa ati olugbala. Allahu nikan soso ni Oluwa ati Olugbala aye ati orun. Nitori naa fun alekun lori awon ise iyanu Anabi ‘Isa omo Moryam ('alaehi-ssolatu wa-ssalam) ti Allahu ba fe. Allahu si ni Alagbara lori gbogbo nnkan. Amo awon kristieni gege bi isesi won bi o se n wu u to ati bi o se n jerankan to ni pe ki gbogbo awon eniyan re gbagbo ninu Allahu. Amo won ko gbagbo |
۞ اللَّهُ الَّذِي خَلَقَكُم مِّن ضَعْفٍ ثُمَّ جَعَلَ مِن بَعْدِ ضَعْفٍ قُوَّةً ثُمَّ جَعَلَ مِن بَعْدِ قُوَّةٍ ضَعْفًا وَشَيْبَةً ۚ يَخْلُقُ مَا يَشَاءُ ۖ وَهُوَ الْعَلِيمُ الْقَدِيرُ (54) Allahu, Eni ti O seda yin lati (ara nnkan) lile, leyin naa, leyin lile O fun (yin ni) agbara, leyin naa, leyin agbara, O tun fi lile ati ogbo (si yin lara). O n da ohunkohun ti O ba fe. Oun si ni Onimo, Alagbara |
وَيَوْمَ تَقُومُ السَّاعَةُ يُقْسِمُ الْمُجْرِمُونَ مَا لَبِثُوا غَيْرَ سَاعَةٍ ۚ كَذَٰلِكَ كَانُوا يُؤْفَكُونَ (55) Ati pe ni ojo ti Akoko naa ba sele (iyen, ojo Ajinde), awon elese yoo maa bura pe awon ko gbe (ile aye) ju akoko kan lo.” Bayen ni won se maa n f’iro tanra won je |
وَقَالَ الَّذِينَ أُوتُوا الْعِلْمَ وَالْإِيمَانَ لَقَدْ لَبِثْتُمْ فِي كِتَابِ اللَّهِ إِلَىٰ يَوْمِ الْبَعْثِ ۖ فَهَٰذَا يَوْمُ الْبَعْثِ وَلَٰكِنَّكُمْ كُنتُمْ لَا تَعْلَمُونَ (56) Awon ti A fun ni imo ati igbagbo ododo yoo so pe: “Dajudaju ninu akosile ti Allahu, e ti gbe ile aye titi Ojo Ajinde (fi to). Nitori naa, eyi ni Ojo Ajinde, sugbon eyin ko mo.” |
فَيَوْمَئِذٍ لَّا يَنفَعُ الَّذِينَ ظَلَمُوا مَعْذِرَتُهُمْ وَلَا هُمْ يُسْتَعْتَبُونَ (57) Nitori naa ni ojo yen, awon t’o sabosi, awawi won ko nii se won ni anfaani. Won ko si nii fun won ni aye lati se ohun ti won yoo fi ri iyonu Allahu |
وَلَقَدْ ضَرَبْنَا لِلنَّاسِ فِي هَٰذَا الْقُرْآنِ مِن كُلِّ مَثَلٍ ۚ وَلَئِن جِئْتَهُم بِآيَةٍ لَّيَقُولَنَّ الَّذِينَ كَفَرُوا إِنْ أَنتُمْ إِلَّا مُبْطِلُونَ (58) A kuku ti fi orisirisi akawe lele ninu al-Ƙur’an yii fun awon eniyan. Dajudaju ti o ba mu ayah kan wa fun won, dajudaju awon t’o sai gbagbo yoo wi pe: “Eyin (musulumi) ko je kini kan tayo opuro.” |
كَذَٰلِكَ يَطْبَعُ اللَّهُ عَلَىٰ قُلُوبِ الَّذِينَ لَا يَعْلَمُونَ (59) Bayen ni Allahu se n fi edidi di okan awon ti ko nimo |
فَاصْبِرْ إِنَّ وَعْدَ اللَّهِ حَقٌّ ۖ وَلَا يَسْتَخِفَّنَّكَ الَّذِينَ لَا يُوقِنُونَ (60) Nitori naa, se suuru. Dajudaju adehun Allahu ni ododo. Ma se je ki awon ti ko mo amodaju (nipa Ojo esan) so o dope |