إِذَا جَاءَكَ الْمُنَافِقُونَ قَالُوا نَشْهَدُ إِنَّكَ لَرَسُولُ اللَّهِ ۗ وَاللَّهُ يَعْلَمُ إِنَّكَ لَرَسُولُهُ وَاللَّهُ يَشْهَدُ إِنَّ الْمُنَافِقِينَ لَكَاذِبُونَ (1) Nigba ti awon sobe-selu musulumi ba wa si odo re, won a wi pe: “A n jerii pe dajudaju iwo, Ojise Allahu ni o.” Allahu si mo pe dajudaju iwo, Ojise Re ni o. Allahu si n jerii pe dajudaju awon sobe-selu musulumi, opuro ni won |
اتَّخَذُوا أَيْمَانَهُمْ جُنَّةً فَصَدُّوا عَن سَبِيلِ اللَّهِ ۚ إِنَّهُمْ سَاءَ مَا كَانُوا يَعْمَلُونَ (2) Won fi awon ibura won se aabo (fun emi ara won), won si seri awon eniyan kuro loju ona (esin) Allahu; dajudaju ohun ti won n se nise buru |
ذَٰلِكَ بِأَنَّهُمْ آمَنُوا ثُمَّ كَفَرُوا فَطُبِعَ عَلَىٰ قُلُوبِهِمْ فَهُمْ لَا يَفْقَهُونَ (3) (Won se) iyen nitori pe won gbagbo, leyin naa won sai gbagbo. Nitori naa, A ti fi edidi di okan won; won ko si nii gbo agboye |
۞ وَإِذَا رَأَيْتَهُمْ تُعْجِبُكَ أَجْسَامُهُمْ ۖ وَإِن يَقُولُوا تَسْمَعْ لِقَوْلِهِمْ ۖ كَأَنَّهُمْ خُشُبٌ مُّسَنَّدَةٌ ۖ يَحْسَبُونَ كُلَّ صَيْحَةٍ عَلَيْهِمْ ۚ هُمُ الْعَدُوُّ فَاحْذَرْهُمْ ۚ قَاتَلَهُمُ اللَّهُ ۖ أَنَّىٰ يُؤْفَكُونَ (4) Nigba ti o ba ri won, irisi won yoo jo o loju. Ti won ba n soro, iwo yoo teti gbo oro won. Won si da bi igi ti won gbe ti ogiri. Won si n lero pe gbogbo igbe (ibosi) n be lori won (nipa isobe-selu won). Ota ni won. Nitori naa, sora fun won. Allahu ti sebi le won. Bawo ni won se n seri won kuro nibi ododo |
وَإِذَا قِيلَ لَهُمْ تَعَالَوْا يَسْتَغْفِرْ لَكُمْ رَسُولُ اللَّهِ لَوَّوْا رُءُوسَهُمْ وَرَأَيْتَهُمْ يَصُدُّونَ وَهُم مُّسْتَكْبِرُونَ (5) Ati pe nigba ti won ba so fun won pe: “E wa ki Ojise ba yin toro aforijin.” Won a gbunri. O si maa ri won ti won yoo maa gbunri lo, ti won yoo maa segberaga |
سَوَاءٌ عَلَيْهِمْ أَسْتَغْفَرْتَ لَهُمْ أَمْ لَمْ تَسْتَغْفِرْ لَهُمْ لَن يَغْفِرَ اللَّهُ لَهُمْ ۚ إِنَّ اللَّهَ لَا يَهْدِي الْقَوْمَ الْفَاسِقِينَ (6) Bakan naa ni fun won; yala o ba won toro aforijin tabi o o ba won toro aforijin. Allahu ko nii forijin won. Dajudaju Allahu ko nii fi ona mo ijo obileje |
هُمُ الَّذِينَ يَقُولُونَ لَا تُنفِقُوا عَلَىٰ مَنْ عِندَ رَسُولِ اللَّهِ حَتَّىٰ يَنفَضُّوا ۗ وَلِلَّهِ خَزَائِنُ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ وَلَٰكِنَّ الْمُنَافِقِينَ لَا يَفْقَهُونَ (7) Awon ni awon t’o n wi pe: “Eyin ko gbodo na owo fun awon t’o wa lodo Ojise Allahu titi won yoo fi fonka. Ti Allahu si ni awon apoti-oro sanmo ati ile, sugbon awon sobe-selu musulumi ko nii gbo agboye |
يَقُولُونَ لَئِن رَّجَعْنَا إِلَى الْمَدِينَةِ لَيُخْرِجَنَّ الْأَعَزُّ مِنْهَا الْأَذَلَّ ۚ وَلِلَّهِ الْعِزَّةُ وَلِرَسُولِهِ وَلِلْمُؤْمِنِينَ وَلَٰكِنَّ الْمُنَافِقِينَ لَا يَعْلَمُونَ (8) Won n wi pe: “Dajudaju ti a ba pada de sinu ilu Modinah, nse ni awon alagbara (ilu) yoo yo awon eni yepere jade kuro ninu ilu." Agbara si n je ti Allahu, ati ti Ojise Re ati awon onigbagbo ododo, sugbon awon sobe-selu musulumi ko mo |
يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا لَا تُلْهِكُمْ أَمْوَالُكُمْ وَلَا أَوْلَادُكُمْ عَن ذِكْرِ اللَّهِ ۚ وَمَن يَفْعَلْ ذَٰلِكَ فَأُولَٰئِكَ هُمُ الْخَاسِرُونَ (9) Eyin ti e gbagbo ni ododo, e ma se je ki awon dukia yin ati awon omo yin ko airoju ba yin nibi iranti Allahu. Enikeni ti o ba ko sinu (airoju) yen, awon wonyen, awon ni eni ofo |
وَأَنفِقُوا مِن مَّا رَزَقْنَاكُم مِّن قَبْلِ أَن يَأْتِيَ أَحَدَكُمُ الْمَوْتُ فَيَقُولَ رَبِّ لَوْلَا أَخَّرْتَنِي إِلَىٰ أَجَلٍ قَرِيبٍ فَأَصَّدَّقَ وَأَكُن مِّنَ الصَّالِحِينَ (10) E na ninu ohun ti A pese fun yin siwaju ki iku to de ba eni kan yin, ki o wa wi pe: "Oluwa mi, ki o si je pe O lo mi lara si i titi di igba kan to sunmo, emi iba si le maa tore, emi iba si wa lara awon eni rere |
وَلَن يُؤَخِّرَ اللَّهُ نَفْسًا إِذَا جَاءَ أَجَلُهَا ۚ وَاللَّهُ خَبِيرٌ بِمَا تَعْمَلُونَ (11) Allahu ko si nii lo emi kan lara nigba ti ojo iku re ba de. Allahu si ni Alamotan nipa ohun ti e n se nise |