عَمَّ يَتَسَاءَلُونَ (1) Nipa ki ni won n bira won leere na |
عَنِ النَّبَإِ الْعَظِيمِ (2) Nipa iro ikoko nla ni |
الَّذِي هُمْ فِيهِ مُخْتَلِفُونَ (3) eyi ti won n yapa enu si |
كَلَّا سَيَعْلَمُونَ (4) Rara! Won n bo wa mo |
ثُمَّ كَلَّا سَيَعْلَمُونَ (5) Leyin naa, ni ti ododo won n bo wa mo |
أَلَمْ نَجْعَلِ الْأَرْضَ مِهَادًا (6) Nje Awa ko se ile ni ite bi |
وَالْجِبَالَ أَوْتَادًا (7) ati awon apata ni eekan (fun ile) |
وَخَلَقْنَاكُمْ أَزْوَاجًا (8) A si seda yin ni orisirisi (ako ati abo) |
وَجَعَلْنَا نَوْمَكُمْ سُبَاتًا (9) A se oorun yin ni isinmi |
وَجَعَلْنَا اللَّيْلَ لِبَاسًا (10) A tun se ale ni ibora |
وَجَعَلْنَا النَّهَارَ مَعَاشًا (11) A tun se osan ni (asiko fun) wiwa ije-imu |
وَبَنَيْنَا فَوْقَكُمْ سَبْعًا شِدَادًا (12) A tun mo sanmo meje t’o lagbara soke yin |
وَجَعَلْنَا سِرَاجًا وَهَّاجًا (13) A tun se oorun ni imole t’o n tan gbola |
وَأَنزَلْنَا مِنَ الْمُعْصِرَاتِ مَاءً ثَجَّاجًا (14) Ati pe A so omi t’o n bo telera won kale lati inu awon esujo |
لِّنُخْرِجَ بِهِ حَبًّا وَنَبَاتًا (15) nitori ki A le fi mu koro eso ati irugbin jade |
وَجَنَّاتٍ أَلْفَافًا (16) pelu awon ogba t’o kun digbi fun nnkan oko |
إِنَّ يَوْمَ الْفَصْلِ كَانَ مِيقَاتًا (17) Dajudaju ojo ipinya, o ni gbedeke akoko kan |
يَوْمَ يُنفَخُ فِي الصُّورِ فَتَأْتُونَ أَفْوَاجًا (18) (Iyen ni) ojo ti won a fon fere oniwo fun ajinde. Eyin yo si maa wa nijo-nijo |
وَفُتِحَتِ السَّمَاءُ فَكَانَتْ أَبْوَابًا (19) Won si maa si sanmo sile. O si maa di awon ilekun |
وَسُيِّرَتِ الْجِبَالُ فَكَانَتْ سَرَابًا (20) Won maa mu awon apata rin (bo si aye miiran). O si maa di ahunpeena |
إِنَّ جَهَنَّمَ كَانَتْ مِرْصَادًا (21) Dajudaju ina Jahanamo, o lugo sile loju ona |
لِّلطَّاغِينَ مَآبًا (22) (O je) ibugbe fun awon alakoyo |
لَّابِثِينَ فِيهَا أَحْقَابًا (23) Won yoo maa gbe inu re fun igba gbooro |
لَّا يَذُوقُونَ فِيهَا بَرْدًا وَلَا شَرَابًا (24) Won ko nii ri itura tabi ohun mimu kan towo ninu re |
إِلَّا حَمِيمًا وَغَسَّاقًا (25) ayafi omi gbigbona ati awoyunweje |
جَزَاءً وِفَاقًا (26) (O je) esan t’o se weku (ise won) |
إِنَّهُمْ كَانُوا لَا يَرْجُونَ حِسَابًا (27) Dajudaju won ki i reti isiro-ise |
وَكَذَّبُوا بِآيَاتِنَا كِذَّابًا (28) Won si pe awon ayah Wa niro gan-an |
وَكُلَّ شَيْءٍ أَحْصَيْنَاهُ كِتَابًا (29) Gbogbo nnkan si ni A ti se akosile re sinu Tira kan |
فَذُوقُوا فَلَن نَّزِيدَكُمْ إِلَّا عَذَابًا (30) Nitori naa, e to (iya) wo. A o si nii se alekun kan fun yin bi ko se iya |
إِنَّ لِلْمُتَّقِينَ مَفَازًا (31) Dajudaju igbala wa fun awon oluberu (Allahu) |
حَدَائِقَ وَأَعْنَابًا (32) Awon ogba ati eso ajara |
وَكَوَاعِبَ أَتْرَابًا (33) ati awon olomoge, ti won ko jura won lo lojo-ori |
وَكَأْسًا دِهَاقًا (34) ati ife oti t’o kun denu (ni esan won) |
لَّا يَسْمَعُونَ فِيهَا لَغْوًا وَلَا كِذَّابًا (35) Won ko nii gbo isokuso ati oro iro ninu re |
جَزَاءً مِّن رَّبِّكَ عَطَاءً حِسَابًا (36) (O je) esan lati odo Oluwa re, (o si je) ore ni ibamu si isiro-ise (won) |
رَّبِّ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ وَمَا بَيْنَهُمَا الرَّحْمَٰنِ ۖ لَا يَمْلِكُونَ مِنْهُ خِطَابًا (37) (Esan naa wa lati odo) Oluwa awon sanmo, ile ati ohun t’o wa laaarin mejeeji, Ajoke-aye. Won ko si ni ikapa oro lodo Re |
يَوْمَ يَقُومُ الرُّوحُ وَالْمَلَائِكَةُ صَفًّا ۖ لَّا يَتَكَلَّمُونَ إِلَّا مَنْ أَذِنَ لَهُ الرَّحْمَٰنُ وَقَالَ صَوَابًا (38) Ojo ti molaika Jibril ati awon molaika (miiran) yoo duro ni owoowo. Won ko si nii soro afi eni ti Ajoke-aye ba yonda fun. Onitoun si maa soro t’o se weku |
ذَٰلِكَ الْيَوْمُ الْحَقُّ ۖ فَمَن شَاءَ اتَّخَذَ إِلَىٰ رَبِّهِ مَآبًا (39) Iyen ni ojo ododo. Nitori naa, eni ti o ba fe ki o mu ona to maa gba seri pada si odo Oluwa re pon (ni ti ironupiwada) |
إِنَّا أَنذَرْنَاكُمْ عَذَابًا قَرِيبًا يَوْمَ يَنظُرُ الْمَرْءُ مَا قَدَّمَتْ يَدَاهُ وَيَقُولُ الْكَافِرُ يَا لَيْتَنِي كُنتُ تُرَابًا (40) Dajudaju A fi iya t’o sunmo se ikilo fun yin. Ojo ti eniyan yoo maa wo ohun ti o ti siwaju, alaigbagbo yo si wi pe: "Yee, emi iba si je erupe, (emi iba la ninu iya) |