| لَا أُقْسِمُ بِهَٰذَا الْبَلَدِ (1) Emi (Allahu) bura pelu ilu yii
 | 
| وَأَنتَ حِلٌّ بِهَٰذَا الْبَلَدِ (2) Iwo si ni eto si ilu yii (lati jagun ninu re)
 | 
| وَوَالِدٍ وَمَا وَلَدَ (3) (Mo tun) bura pelu obi ati ohun t’o bi
 | 
| لَقَدْ خَلَقْنَا الْإِنسَانَ فِي كَبَدٍ (4) Dajudaju A seda eniyan sinu isoro
 | 
| أَيَحْسَبُ أَن لَّن يَقْدِرَ عَلَيْهِ أَحَدٌ (5) Se o n lero pe eni kan ko ni agbara lori oun ni
 | 
| يَقُولُ أَهْلَكْتُ مَالًا لُّبَدًا (6) O (si) n wi pe: "Emi ti bana dukia opolopo (lati fi tako Anabi s.a.w)
 | 
| أَيَحْسَبُ أَن لَّمْ يَرَهُ أَحَدٌ (7) Se o n lero pe eni kan ko ri oun ni
 | 
| أَلَمْ نَجْعَل لَّهُ عَيْنَيْنِ (8) Se A ko se oju meji fun un
 | 
| وَلِسَانًا وَشَفَتَيْنِ (9) Ati ahon pelu ete meji (ti A se fun un)
 | 
| وَهَدَيْنَاهُ النَّجْدَيْنِ (10) A si fi ona meji mo on
 | 
| فَلَا اقْتَحَمَ الْعَقَبَةَ (11) Ko si mu akaba igbala gun
 | 
| وَمَا أَدْرَاكَ مَا الْعَقَبَةُ (12) Ki si ni o mu o mo ohun t’o n je akaba igbala
 | 
| فَكُّ رَقَبَةٍ (13) (Ohun ni) titu eru sile loko eru
 | 
| أَوْ إِطْعَامٌ فِي يَوْمٍ ذِي مَسْغَبَةٍ (14) Tabi fifun eniyan ni ounje ni ojo ebi
 | 
| يَتِيمًا ذَا مَقْرَبَةٍ (15) (O le je) omo-orukan ninu ebi
 | 
| أَوْ مِسْكِينًا ذَا مَتْرَبَةٍ (16) tabi mekunnu, eni ileele
 | 
| ثُمَّ كَانَ مِنَ الَّذِينَ آمَنُوا وَتَوَاصَوْا بِالصَّبْرِ وَتَوَاصَوْا بِالْمَرْحَمَةِ (17) Leyin naa, ki o wa ninu awon t’o gbagbo ni ododo, ti won n gbara won niyanju suuru sise, ti won si tun n gbara won niyanju aanu sise
 | 
| أُولَٰئِكَ أَصْحَابُ الْمَيْمَنَةِ (18) Awon wonyen ni ero owo otun
 | 
| وَالَّذِينَ كَفَرُوا بِآيَاتِنَا هُمْ أَصْحَابُ الْمَشْأَمَةِ (19) Awon t’o si sai gbagbo ninu awon ayah Wa, awon ni ero owo osi
 | 
| عَلَيْهِمْ نَارٌ مُّؤْصَدَةٌ (20) A maa ti awon ilekun Ina pa mo won lori patapata
 |