وَالسَّمَاءِ ذَاتِ الْبُرُوجِ (1) (Allahu) bura pelu sanmo ti awon ibuso (oorun, osupa ati awon irawo) wa ninu re |
وَالْيَوْمِ الْمَوْعُودِ (2) O tun bura pelu ojo ti won se ni adehun |
وَشَاهِدٍ وَمَشْهُودٍ (3) O tun bura pelu olujerii ati ohun t’o jerii si |
قُتِلَ أَصْحَابُ الْأُخْدُودِ (4) A sebi le awon t’o gbe koto (ina) |
النَّارِ ذَاتِ الْوَقُودِ (5) (iyen) ina ti won n fi igi ko (ninu koto) |
إِذْ هُمْ عَلَيْهَا قُعُودٌ (6) (Ranti) nigba ti won jokoo si itosi re |
وَهُمْ عَلَىٰ مَا يَفْعَلُونَ بِالْمُؤْمِنِينَ شُهُودٌ (7) Won si n wo ohun ti won n se fun awon onigbagbo ododo |
وَمَا نَقَمُوا مِنْهُمْ إِلَّا أَن يُؤْمِنُوا بِاللَّهِ الْعَزِيزِ الْحَمِيدِ (8) Ko si si kini kan ti won tori re je won niya bi ko se pe won ni igbagbo ododo ninu Allahu, Alagbara, Olope |
الَّذِي لَهُ مُلْكُ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ ۚ وَاللَّهُ عَلَىٰ كُلِّ شَيْءٍ شَهِيدٌ (9) Eni ti O ni ijoba awon sanmo ati ile. Allahu si ni Elerii lori gbogbo nnkan |
إِنَّ الَّذِينَ فَتَنُوا الْمُؤْمِنِينَ وَالْمُؤْمِنَاتِ ثُمَّ لَمْ يَتُوبُوا فَلَهُمْ عَذَابُ جَهَنَّمَ وَلَهُمْ عَذَابُ الْحَرِيقِ (10) Dajudaju awon t’o fi inira kan awon onigbagbo ododo lokunrin ati awon onigbagbo ododo lobinrin, leyin naa ti won ko ronu piwada, iya ina Jahanamo n be fun won. Iya ina t’o n jo si wa fun won |
إِنَّ الَّذِينَ آمَنُوا وَعَمِلُوا الصَّالِحَاتِ لَهُمْ جَنَّاتٌ تَجْرِي مِن تَحْتِهَا الْأَنْهَارُ ۚ ذَٰلِكَ الْفَوْزُ الْكَبِيرُ (11) Dajudaju awon t’o gbagbo ni ododo, ti won si se awon ise rere, tiwon ni awon Ogba Idera kan, ti awon odo n san ni isale re. Iyen si ni erenje nla |
إِنَّ بَطْشَ رَبِّكَ لَشَدِيدٌ (12) Dajudaju igbamu ti Oluwa re ma le |
إِنَّهُ هُوَ يُبْدِئُ وَيُعِيدُ (13) Dajudaju Oun ni O pile (eda), O si maa da (eda) pada (fun ajinde) |
وَهُوَ الْغَفُورُ الْوَدُودُ (14) Oun ni Alaforijin, Ololufe (eda) |
ذُو الْعَرْشِ الْمَجِيدُ (15) Oun l’O ni Ite-ola, Eni-owo julo |
فَعَّالٌ لِّمَا يُرِيدُ (16) Oluse-ohun-t’O-ba-fe |
هَلْ أَتَاكَ حَدِيثُ الْجُنُودِ (17) Sebi iro awon omo ogun ti de odo re |
فِرْعَوْنَ وَثَمُودَ (18) (omo ogun) Fir‘aon ati (ijo) Thamud |
بَلِ الَّذِينَ كَفَرُوا فِي تَكْذِيبٍ (19) Sibesibe awon t’o sai gbagbo si n pe ododo niro |
وَاللَّهُ مِن وَرَائِهِم مُّحِيطٌ (20) Allahu si yi won ka leyin won |
بَلْ هُوَ قُرْآنٌ مَّجِيدٌ (21) Amo sa, ohun (ti A fi ranse si o ni) al-Ƙur’an alapon-onle |
فِي لَوْحٍ مَّحْفُوظٍ (22) ti o wa ninu walaa ti A n so |