تَبَارَكَ الَّذِي نَزَّلَ الْفُرْقَانَ عَلَىٰ عَبْدِهِ لِيَكُونَ لِلْعَالَمِينَ نَذِيرًا (1) Ibukun ni fun Eni ti O so oro-ipinya (ohun t’o n sepinya laaarin ododo ati iro) kale fun erusin Re nitori ki o le je olukilo fun gbogbo eda |
الَّذِي لَهُ مُلْكُ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ وَلَمْ يَتَّخِذْ وَلَدًا وَلَمْ يَكُن لَّهُ شَرِيكٌ فِي الْمُلْكِ وَخَلَقَ كُلَّ شَيْءٍ فَقَدَّرَهُ تَقْدِيرًا (2) (Oun ni) Eni ti O ni ijoba awon sanmo ati ile. Ko mu eni kan kan ni omo. Ko si akegbe fun Un ninu ijoba (Re). O da gbogbo nnkan. O si yan odiwon (irisi, isemi ati ayanmo) fun un niwon-niwon |
وَاتَّخَذُوا مِن دُونِهِ آلِهَةً لَّا يَخْلُقُونَ شَيْئًا وَهُمْ يُخْلَقُونَ وَلَا يَمْلِكُونَ لِأَنفُسِهِمْ ضَرًّا وَلَا نَفْعًا وَلَا يَمْلِكُونَ مَوْتًا وَلَا حَيَاةً وَلَا نُشُورًا (3) (Awon alaigbagbo) so awon kan di olohun leyin Allahu. Won ko si le da kini kan. A si da won ni. Won ko si ni ikapa inira tabi anfaani kan fun emi ara won. Ati pe won ko ni ikapa lori iku, isemi ati ajinde |
وَقَالَ الَّذِينَ كَفَرُوا إِنْ هَٰذَا إِلَّا إِفْكٌ افْتَرَاهُ وَأَعَانَهُ عَلَيْهِ قَوْمٌ آخَرُونَ ۖ فَقَدْ جَاءُوا ظُلْمًا وَزُورًا (4) Awon t’o sai gbagbo wi pe: “Ki ni eyi bi ko se adapa iro kan ti o da adapa re (mo Allahu), ti awon eniyan miiran si ran an lowo lori re.” Dajudaju (awon alaigbagbo) ti gbe abosi ati iro de |
وَقَالُوا أَسَاطِيرُ الْأَوَّلِينَ اكْتَتَبَهَا فَهِيَ تُمْلَىٰ عَلَيْهِ بُكْرَةً وَأَصِيلًا (5) Won tun wi pe: “Akosile alo awon eni akoko, ti o sadako re ni. Ohun ni won n pe fun un ni owuro ati ni asale.” |
قُلْ أَنزَلَهُ الَّذِي يَعْلَمُ السِّرَّ فِي السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ ۚ إِنَّهُ كَانَ غَفُورًا رَّحِيمًا (6) So pe: "Eni ti O mo ikoko ti n be ninu awon sanmo ati ile l’O so o kale. Dajudaju Oun ni O n je Alaforijin, Asake-orun |
وَقَالُوا مَالِ هَٰذَا الرَّسُولِ يَأْكُلُ الطَّعَامَ وَيَمْشِي فِي الْأَسْوَاقِ ۙ لَوْلَا أُنزِلَ إِلَيْهِ مَلَكٌ فَيَكُونَ مَعَهُ نَذِيرًا (7) Won tun wi pe: “Ki lo mu Ojise yii, t’o n jeun, t’o n rin ninu awon oja? Nitori ki ni Won ko se so molaika kan kale fun un ki o le je olukilo pelu re |
أَوْ يُلْقَىٰ إِلَيْهِ كَنزٌ أَوْ تَكُونُ لَهُ جَنَّةٌ يَأْكُلُ مِنْهَا ۚ وَقَالَ الظَّالِمُونَ إِن تَتَّبِعُونَ إِلَّا رَجُلًا مَّسْحُورًا (8) Tabi (nitori ki ni) won ko se ju apoti-oro kan sodo re, tabi ki o ni ogba oko kan ti o ma maa je ninu re?” Awon alabosi si tun wi pe: “Ta ni e n tele bi ko se okunrin eleedi kan.” |
انظُرْ كَيْفَ ضَرَبُوا لَكَ الْأَمْثَالَ فَضَلُّوا فَلَا يَسْتَطِيعُونَ سَبِيلًا (9) Wo bi won se fun o ni awon afiwe (buruku)! Nitori naa, won ti sina; won ko si le mona |
تَبَارَكَ الَّذِي إِن شَاءَ جَعَلَ لَكَ خَيْرًا مِّن ذَٰلِكَ جَنَّاتٍ تَجْرِي مِن تَحْتِهَا الْأَنْهَارُ وَيَجْعَل لَّكَ قُصُورًا (10) Ibukun ni fun Eni ti (o je pe) bi O ba fe, O maa soore t’o dara ju iyen fun o. (O si maa je) awon ogba ti awon odo yoo maa san ni isale re. O si maa fun o ni awon aafin kan |
بَلْ كَذَّبُوا بِالسَّاعَةِ ۖ وَأَعْتَدْنَا لِمَن كَذَّبَ بِالسَّاعَةِ سَعِيرًا (11) Nse ni won pe Akoko naa niro. A si ti pese Ina t’o n jo sile de enikeni ti o ba pe Akoko naa niro |
إِذَا رَأَتْهُم مِّن مَّكَانٍ بَعِيدٍ سَمِعُوا لَهَا تَغَيُّظًا وَزَفِيرًا (12) Nigba ti (Ina naa) ba ri won lati aye kan ti o jinna, won yo si maa gbo ohun ibinu ati kikun (re) |
وَإِذَا أُلْقُوا مِنْهَا مَكَانًا ضَيِّقًا مُّقَرَّنِينَ دَعَوْا هُنَالِكَ ثُبُورًا (13) Nigba ti Won ba si ju won si aye t’o ha gadigadi ninu (Ina), ti won de owo won mo won lorun, won yo si maa kigbe iparun nibe |
لَّا تَدْعُوا الْيَوْمَ ثُبُورًا وَاحِدًا وَادْعُوا ثُبُورًا كَثِيرًا (14) (A o so pe): “E ma se kigbe iparun eyo kan, e kigbe iparun lopolopo.” |
قُلْ أَذَٰلِكَ خَيْرٌ أَمْ جَنَّةُ الْخُلْدِ الَّتِي وُعِدَ الْمُتَّقُونَ ۚ كَانَتْ لَهُمْ جَزَاءً وَمَصِيرًا (15) So pe: “Nje iyen lo loore julo ni tabi Ogba Idera gbere, eyi ti A se ni adehun fun awon oluberu Allahu. O si je esan ati ikangun rere fun won |
لَّهُمْ فِيهَا مَا يَشَاءُونَ خَالِدِينَ ۚ كَانَ عَلَىٰ رَبِّكَ وَعْدًا مَّسْئُولًا (16) Ohunkohun ti won ba n fe wa fun won ninu re. Olusegbere ni won (ninu re). (Eyi) je adehun ti won ti toro lodo Oluwa re |
وَيَوْمَ يَحْشُرُهُمْ وَمَا يَعْبُدُونَ مِن دُونِ اللَّهِ فَيَقُولُ أَأَنتُمْ أَضْلَلْتُمْ عِبَادِي هَٰؤُلَاءِ أَمْ هُمْ ضَلُّوا السَّبِيلَ (17) Ati pe (ranti) ojo ti (Allahu) yoo ko awon aborisa ati nnkan ti won n josin fun leyin Allahu jo, (Allahu) yo si so pe: “Se eyin l’e si awon erusin Mi wonyi lona ni tabi awon ni won sina (funra won)?” |
قَالُوا سُبْحَانَكَ مَا كَانَ يَنبَغِي لَنَا أَن نَّتَّخِذَ مِن دُونِكَ مِنْ أَوْلِيَاءَ وَلَٰكِن مَّتَّعْتَهُمْ وَآبَاءَهُمْ حَتَّىٰ نَسُوا الذِّكْرَ وَكَانُوا قَوْمًا بُورًا (18) Won wi pe: “Mimo ni fun O! Ko to fun wa lati mu awon kan ni alatileyin leyin Re. Sugbon Iwo l’O fun awon ati awon baba won ni igbadun, titi won fi gbagbe Iranti. Won si je eni iparun.” |
فَقَدْ كَذَّبُوكُم بِمَا تَقُولُونَ فَمَا تَسْتَطِيعُونَ صَرْفًا وَلَا نَصْرًا ۚ وَمَن يَظْلِم مِّنكُمْ نُذِقْهُ عَذَابًا كَبِيرًا (19) (Allahu so pe): “Dajudaju awon orisa ti pe eyin aborisa ni opuro nipa ohun ti e n so (pe olusipe ni won). Ni bayii won ko le gbe iya Ina kuro fun yin, won ko si le ran yin lowo. Enikeni ti o se abosi (ebo sise) ninu yin, A si maa fun un ni iya t’o tobi to wo.” |
وَمَا أَرْسَلْنَا قَبْلَكَ مِنَ الْمُرْسَلِينَ إِلَّا إِنَّهُمْ لَيَأْكُلُونَ الطَّعَامَ وَيَمْشُونَ فِي الْأَسْوَاقِ ۗ وَجَعَلْنَا بَعْضَكُمْ لِبَعْضٍ فِتْنَةً أَتَصْبِرُونَ ۗ وَكَانَ رَبُّكَ بَصِيرًا (20) A ko ran awon Ojise nise ri siwaju re afi ki won jeun, ki won si rin ninu oja. A ti fi apa kan yin se adanwo fun apa kan, nje e maa se suuru bi? Oluwa Re si n je Oluriran |
۞ وَقَالَ الَّذِينَ لَا يَرْجُونَ لِقَاءَنَا لَوْلَا أُنزِلَ عَلَيْنَا الْمَلَائِكَةُ أَوْ نَرَىٰ رَبَّنَا ۗ لَقَدِ اسْتَكْبَرُوا فِي أَنفُسِهِمْ وَعَتَوْا عُتُوًّا كَبِيرًا (21) Awon ti ko reti ipade Wa (ni orun) wi pe: “Won ko se so awon molaika kale fun wa, tabi ki a ri Oluwa wa (soju nile aye)? Dajudaju won ti segberaga ninu emi won. Won si ti tayo enu-ana ni itayo-enu ala t’o tobi |
يَوْمَ يَرَوْنَ الْمَلَائِكَةَ لَا بُشْرَىٰ يَوْمَئِذٍ لِّلْمُجْرِمِينَ وَيَقُولُونَ حِجْرًا مَّحْجُورًا (22) (Ranti) ojo ti won yoo ri awon molaika, ko nii si iro idunnu fun awon elese ni ojo yen. (Awon molaika) yo si so pe: “Eewo, eewo (ni iro idunnu fun eyin elese).” |
وَقَدِمْنَا إِلَىٰ مَا عَمِلُوا مِنْ عَمَلٍ فَجَعَلْنَاهُ هَبَاءً مَّنثُورًا (23) Ati pe A maa wa sibi ohun ti won se nise, A si maa so o di eruku afedanu |
أَصْحَابُ الْجَنَّةِ يَوْمَئِذٍ خَيْرٌ مُّسْتَقَرًّا وَأَحْسَنُ مَقِيلًا (24) Awon ero inu Ogba Idera, ni ojo yen, (ogba won) maa loore julo ni ibugbe. O si maa dara julo ni ibusinmi |
وَيَوْمَ تَشَقَّقُ السَّمَاءُ بِالْغَمَامِ وَنُزِّلَ الْمَلَائِكَةُ تَنزِيلًا (25) Ati pe (ranti) ojo ti sanmo yo faya pelu awon esujo funfun. A si maa so awon molaika kale taara |
الْمُلْكُ يَوْمَئِذٍ الْحَقُّ لِلرَّحْمَٰنِ ۚ وَكَانَ يَوْمًا عَلَى الْكَافِرِينَ عَسِيرًا (26) Ijoba ododo ti ojo yen n je ti Ajoke-aye. O si je ojo kan ti o maa nira fun awon alaigbagbo |
وَيَوْمَ يَعَضُّ الظَّالِمُ عَلَىٰ يَدَيْهِ يَقُولُ يَا لَيْتَنِي اتَّخَذْتُ مَعَ الرَّسُولِ سَبِيلًا (27) (Ranti) ojo ti alabosi yoo je ika owo re mejeeji, o si maa wi pe: "Yee! Emi iba ti to ona kan (naa) pelu Ojise naa |
يَا وَيْلَتَىٰ لَيْتَنِي لَمْ أَتَّخِذْ فُلَانًا خَلِيلًا (28) Egbe mi o, yee! Emi iba ti mu lagbaja ni ore ayo |
لَّقَدْ أَضَلَّنِي عَنِ الذِّكْرِ بَعْدَ إِذْ جَاءَنِي ۗ وَكَانَ الشَّيْطَانُ لِلْإِنسَانِ خَذُولًا (29) Dajudaju o ti si mi lona kuro nibi Iranti leyin ti o de ba mi. Dajudaju Esu n je adani-dasoro fun omoniyan |
وَقَالَ الرَّسُولُ يَا رَبِّ إِنَّ قَوْمِي اتَّخَذُوا هَٰذَا الْقُرْآنَ مَهْجُورًا (30) Ojise naa so pe: “Oluwa mi dajudaju awon eniyan mi ti pa al-Ƙur’an yii ti.” |
وَكَذَٰلِكَ جَعَلْنَا لِكُلِّ نَبِيٍّ عَدُوًّا مِّنَ الْمُجْرِمِينَ ۗ وَكَفَىٰ بِرَبِّكَ هَادِيًا وَنَصِيرًا (31) Bayen ni A se awon kan ninu awon elese ni ota fun Anabi kookan. Oluwa re si to ni Afinimona ati Alaranse |
وَقَالَ الَّذِينَ كَفَرُوا لَوْلَا نُزِّلَ عَلَيْهِ الْقُرْآنُ جُمْلَةً وَاحِدَةً ۚ كَذَٰلِكَ لِنُثَبِّتَ بِهِ فُؤَادَكَ ۖ وَرَتَّلْنَاهُ تَرْتِيلًا (32) Awon t’o sai gbagbo wi pe: “Won ko se so al-Ƙur’an kale fun un ni apapo ni ee kan naa?” (A so o kale diedie) bayen nitori ki A le fi rinle sinu okan re. A si ke e fun o diedie |
وَلَا يَأْتُونَكَ بِمَثَلٍ إِلَّا جِئْنَاكَ بِالْحَقِّ وَأَحْسَنَ تَفْسِيرًا (33) Won ko nii mu apeere kan wa fun o (bi ibeere lati fi tako o) afi ki A mu ododo (iyen, al-ƙur’an) ati alaye t’o dara julo wa fun o (lori re) |
الَّذِينَ يُحْشَرُونَ عَلَىٰ وُجُوهِهِمْ إِلَىٰ جَهَنَّمَ أُولَٰئِكَ شَرٌّ مَّكَانًا وَأَضَلُّ سَبِيلًا (34) Awon ti A maa ko jo lo sinu ina Jahanamo ni idojubole, awon wonyen ni aye won buru julo. Won si sina julo |
وَلَقَدْ آتَيْنَا مُوسَى الْكِتَابَ وَجَعَلْنَا مَعَهُ أَخَاهُ هَارُونَ وَزِيرًا (35) Dajudaju A fun (Anabi) Musa ni Tira. A tun se arakunrin re, Harun, ni amugbalegbee fun un |
فَقُلْنَا اذْهَبَا إِلَى الْقَوْمِ الَّذِينَ كَذَّبُوا بِآيَاتِنَا فَدَمَّرْنَاهُمْ تَدْمِيرًا (36) A si so pe: “Eyin mejeeji, e lo sodo ijo t’o pe awon ayah Wa niro. A si pa ijo naa run patapata |
وَقَوْمَ نُوحٍ لَّمَّا كَذَّبُوا الرُّسُلَ أَغْرَقْنَاهُمْ وَجَعَلْنَاهُمْ لِلنَّاسِ آيَةً ۖ وَأَعْتَدْنَا لِلظَّالِمِينَ عَذَابًا أَلِيمًا (37) (Ranti) ijo (Anabi) Nuh. Nigba ti won pe awon Ojise ni opuro, A te won ri sinu omi. A si se won ni ami kan fun awon eniyan. A si ti pese iya eleta-elero sile de awon alabosi |
وَعَادًا وَثَمُودَ وَأَصْحَابَ الرَّسِّ وَقُرُونًا بَيْنَ ذَٰلِكَ كَثِيرًا (38) (Ranti) awon ijo ‘Ad, ijo Thamud, ijo Rass ati awon opolopo iran miiran (t’o n be) laaarin won |
وَكُلًّا ضَرَبْنَا لَهُ الْأَمْثَالَ ۖ وَكُلًّا تَبَّرْنَا تَتْبِيرًا (39) Ikookan won ni A fun ni awon apejuwe (nipa awon t’o tako ododo). Ikookan won si ni A parun patapata |
وَلَقَدْ أَتَوْا عَلَى الْقَرْيَةِ الَّتِي أُمْطِرَتْ مَطَرَ السَّوْءِ ۚ أَفَلَمْ يَكُونُوا يَرَوْنَهَا ۚ بَلْ كَانُوا لَا يَرْجُونَ نُشُورًا (40) Ati pe dajudaju won koja ni ilu ti A ro ojo buruku le lori. Se won ki i ri i ni? Rara, nse ni won ko reti Ajinde |
وَإِذَا رَأَوْكَ إِن يَتَّخِذُونَكَ إِلَّا هُزُوًا أَهَٰذَا الَّذِي بَعَثَ اللَّهُ رَسُولًا (41) Nigba ti won ba si ri o, ko si ohun ti won yoo fi o se bi ko se yeye. (Won a wi pe): “Se eyi ni eni ti Allahu gbe dide ni Ojise |
إِن كَادَ لَيُضِلُّنَا عَنْ آلِهَتِنَا لَوْلَا أَن صَبَرْنَا عَلَيْهَا ۚ وَسَوْفَ يَعْلَمُونَ حِينَ يَرَوْنَ الْعَذَابَ مَنْ أَضَلُّ سَبِيلًا (42) O ma fee seri wa kuro nibi awon olohun wa, ti ki i ba se pe a taku sori re.” Laipe won maa mo eni ti o sina julo nigba ti won ba ri iya |
أَرَأَيْتَ مَنِ اتَّخَذَ إِلَٰهَهُ هَوَاهُ أَفَأَنتَ تَكُونُ عَلَيْهِ وَكِيلًا (43) So fun mi nipa eni ti o so ife-inu re di olohun re! Nitori naa, se iwo maa je alaabo fun un ni (nibi iya) |
أَمْ تَحْسَبُ أَنَّ أَكْثَرَهُمْ يَسْمَعُونَ أَوْ يَعْقِلُونَ ۚ إِنْ هُمْ إِلَّا كَالْأَنْعَامِ ۖ بَلْ هُمْ أَضَلُّ سَبِيلًا (44) Tabi iwo n ro pe dajudaju opolopo won n gboran tabi pe won n se laakaye? Ki ni won na, bi ko se bi agutan. Won wule sina julo |
أَلَمْ تَرَ إِلَىٰ رَبِّكَ كَيْفَ مَدَّ الظِّلَّ وَلَوْ شَاءَ لَجَعَلَهُ سَاكِنًا ثُمَّ جَعَلْنَا الشَّمْسَ عَلَيْهِ دَلِيلًا (45) Se o o ri (ise) Oluwa re ni, bi O se fe okunkun owuro loju (soju sanmo)? Ti O ba fe ni, iba da a duro sibe. Leyin naa, A fi oorun se atoka si bibe okunkun |
ثُمَّ قَبَضْنَاهُ إِلَيْنَا قَبْضًا يَسِيرًا (46) Leyin naa, A (fi imole oorun) mu okunkun (kuro nita) wa si odo Wa ni mimu diedie (ki ojumo le mo) |
وَهُوَ الَّذِي جَعَلَ لَكُمُ اللَّيْلَ لِبَاسًا وَالنَّوْمَ سُبَاتًا وَجَعَلَ النَّهَارَ نُشُورًا (47) Ati pe Oun ni Eni ti O se oru ni ibora fun yin. (O se) oorun ni isinmi (fun yin). O tun se osan ni asiko itusita (fun wiwa ije-imu) |
وَهُوَ الَّذِي أَرْسَلَ الرِّيَاحَ بُشْرًا بَيْنَ يَدَيْ رَحْمَتِهِ ۚ وَأَنزَلْنَا مِنَ السَّمَاءِ مَاءً طَهُورًا (48) Oun si ni Eni t’’O n ran ategun ni iro-idunnu siwaju ike Re. A si so omi mimo kale lati sanmo |
لِّنُحْيِيَ بِهِ بَلْدَةً مَّيْتًا وَنُسْقِيَهُ مِمَّا خَلَقْنَا أَنْعَامًا وَأَنَاسِيَّ كَثِيرًا (49) nitori ki A le fi so oku ile di aye ile ati nitori ki A le fun eran-osin ati opolopo eniyan ninu awon ti A da ni omi mu |
وَلَقَدْ صَرَّفْنَاهُ بَيْنَهُمْ لِيَذَّكَّرُوا فَأَبَىٰ أَكْثَرُ النَّاسِ إِلَّا كُفُورًا (50) Dajudaju A ti pin omi yii laaarin won nitori ki won le ranti (ike Oluwa won). Sugbon opolopo eniyan ko (lati ranti) afi aimoore |
وَلَوْ شِئْنَا لَبَعَثْنَا فِي كُلِّ قَرْيَةٍ نَّذِيرًا (51) Ti o ba je pe A ba fe ni, A iba gbe olukilo kan dide ninu ilu kookan |
فَلَا تُطِعِ الْكَافِرِينَ وَجَاهِدْهُم بِهِ جِهَادًا كَبِيرًا (52) Nitori naa, ma se tele awon alaigbagbo. Ki o si fi (al-Ƙur’an) ja won ni ogun t’o tobi |
۞ وَهُوَ الَّذِي مَرَجَ الْبَحْرَيْنِ هَٰذَا عَذْبٌ فُرَاتٌ وَهَٰذَا مِلْحٌ أُجَاجٌ وَجَعَلَ بَيْنَهُمَا بَرْزَخًا وَحِجْرًا مَّحْجُورًا (53) Oun ni Eni ti O mu awon odo meji san kiri. Eyi (ni omi) t’o dun gan-an. Eyi si (ni omi) iyo t’o moro. O fi gaga si aarin awon mejeeji. (O si) se e ni eewo ponnbele (fun won lati ko inira ba eda) |
وَهُوَ الَّذِي خَلَقَ مِنَ الْمَاءِ بَشَرًا فَجَعَلَهُ نَسَبًا وَصِهْرًا ۗ وَكَانَ رَبُّكَ قَدِيرًا (54) Oun ni Eni ti O seda abara lati inu omi. O se ibatan ebi ati ibatan ana fun un, Oluwa re si n je Alagbara |
وَيَعْبُدُونَ مِن دُونِ اللَّهِ مَا لَا يَنفَعُهُمْ وَلَا يَضُرُّهُمْ ۗ وَكَانَ الْكَافِرُ عَلَىٰ رَبِّهِ ظَهِيرًا (55) Won n josin fun leyin Allahu ohun ti ko le se won ni anfaani, ti ko si le ko inira ba won. Alaigbagbo je oluranlowo (fun Esu) lati tako Oluwa re |
وَمَا أَرْسَلْنَاكَ إِلَّا مُبَشِّرًا وَنَذِيرًا (56) A ko si ran o nise tayo ki o je oniroo-idunnu ati olukilo |
قُلْ مَا أَسْأَلُكُمْ عَلَيْهِ مِنْ أَجْرٍ إِلَّا مَن شَاءَ أَن يَتَّخِذَ إِلَىٰ رَبِّهِ سَبِيلًا (57) So pe: “Emi ko beere owo-oya kan lowo yin lori re afi eni ti o ba fe mu ona (daadaa) to lo si odo Oluwa re.” |
وَتَوَكَّلْ عَلَى الْحَيِّ الَّذِي لَا يَمُوتُ وَسَبِّحْ بِحَمْدِهِ ۚ وَكَفَىٰ بِهِ بِذُنُوبِ عِبَادِهِ خَبِيرًا (58) Gbarale Alaaye ti ko nii ku. Se afomo pelu idupe fun Un. Allahu si to ni Alamotan nipa ese awon erusin Re |
الَّذِي خَلَقَ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضَ وَمَا بَيْنَهُمَا فِي سِتَّةِ أَيَّامٍ ثُمَّ اسْتَوَىٰ عَلَى الْعَرْشِ ۚ الرَّحْمَٰنُ فَاسْأَلْ بِهِ خَبِيرًا (59) (Oun ni) Eni ti O seda awon sanmo, ile ati awon nnkan t’o n be laaarin mejeeji laaarin ojo mefa. Leyin naa, O gunwa sori Ite-ola. Ajoke-aye ni, nitori naa, beere nipa Re (lodo Re nitori pe, O je) Alamotan |
وَإِذَا قِيلَ لَهُمُ اسْجُدُوا لِلرَّحْمَٰنِ قَالُوا وَمَا الرَّحْمَٰنُ أَنَسْجُدُ لِمَا تَأْمُرُنَا وَزَادَهُمْ نُفُورًا ۩ (60) Nigba ti won ba so fun won pe: “E fori kanle fun Ajoke-aye.” Won a wi pe: “Ki ni Ajoke-aye? Se ki a fori kanle fun ohun ti o n pa wa lase re ni?” (Ipepe naa) si mu won lekun ni sisa-seyin |
تَبَارَكَ الَّذِي جَعَلَ فِي السَّمَاءِ بُرُوجًا وَجَعَلَ فِيهَا سِرَاجًا وَقَمَرًا مُّنِيرًا (61) Ibukun ni fun Eni ti O se awon irawo sinu sanmo. O tun se oorun ati osupa ni imole sinu re |
وَهُوَ الَّذِي جَعَلَ اللَّيْلَ وَالنَّهَارَ خِلْفَةً لِّمَنْ أَرَادَ أَن يَذَّكَّرَ أَوْ أَرَادَ شُكُورًا (62) Oun ni Eni ti O se oru ati osan ni itelentele (ti ikini yato si ikeji) nitori eni ti o ba gbero lati se iranti (Allahu) tabi ti o ba gbero idupe (fun Un) |
وَعِبَادُ الرَّحْمَٰنِ الَّذِينَ يَمْشُونَ عَلَى الْأَرْضِ هَوْنًا وَإِذَا خَاطَبَهُمُ الْجَاهِلُونَ قَالُوا سَلَامًا (63) Awon erusin Ajoke-aye ni awon t’o n rin jeeje lori ile. Nigba ti awon ope ba si doju oro ko won, won yoo so oro alaafia |
وَالَّذِينَ يَبِيتُونَ لِرَبِّهِمْ سُجَّدًا وَقِيَامًا (64) (Awon ni) awon t’o n lo oru won ni iforikanle ati iduro-kirun fun Oluwa won |
وَالَّذِينَ يَقُولُونَ رَبَّنَا اصْرِفْ عَنَّا عَذَابَ جَهَنَّمَ ۖ إِنَّ عَذَابَهَا كَانَ غَرَامًا (65) (Awon ni) awon t’o n so pe: “Oluwa wa, gbe iya ina Jahanamo kuro fun wa. Dajudaju iya re je iya ainipekun |
إِنَّهَا سَاءَتْ مُسْتَقَرًّا وَمُقَامًا (66) Dajudaju o buru ni ibugbe ati ibuduro |
وَالَّذِينَ إِذَا أَنفَقُوا لَمْ يُسْرِفُوا وَلَمْ يَقْتُرُوا وَكَانَ بَيْنَ ذَٰلِكَ قَوَامًا (67) Awon ti o je pe nigba ti won ba nawo, won ko na ina-apa, won ko si sahun; (inawo won) wa laaarin iyen ni iwontun-wonsi |
وَالَّذِينَ لَا يَدْعُونَ مَعَ اللَّهِ إِلَٰهًا آخَرَ وَلَا يَقْتُلُونَ النَّفْسَ الَّتِي حَرَّمَ اللَّهُ إِلَّا بِالْحَقِّ وَلَا يَزْنُونَ ۚ وَمَن يَفْعَلْ ذَٰلِكَ يَلْقَ أَثَامًا (68) (Awon ni) awon ti ko pe olohun miiran mo Allahu. Won ko pa emi ti Allahu se (pipa re) ni eewo afi ni ona eto. Ati pe won ko se zina. Enikeni ti o ba se (aburu) yen, o maa pade (iya) ese |
يُضَاعَفْ لَهُ الْعَذَابُ يَوْمَ الْقِيَامَةِ وَيَخْلُدْ فِيهِ مُهَانًا (69) A oo se iya ni ilopo fun un ni Ojo Ajinde. O si maa se gbere ninu re ni eni yepere |
إِلَّا مَن تَابَ وَآمَنَ وَعَمِلَ عَمَلًا صَالِحًا فَأُولَٰئِكَ يُبَدِّلُ اللَّهُ سَيِّئَاتِهِمْ حَسَنَاتٍ ۗ وَكَانَ اللَّهُ غَفُورًا رَّحِيمًا (70) Afi eni ti o ba ronu piwada, ti o gbagbo ni ododo, ti o si se ise rere. Awon wonyen ni Allahu yoo fi ise rere ropo ise aburu won (iyen, nipa ironupiwada won). Allahu si n je Alaforijin, Asake-orun |
وَمَن تَابَ وَعَمِلَ صَالِحًا فَإِنَّهُ يَتُوبُ إِلَى اللَّهِ مَتَابًا (71) Enikeni ti o ba ronu piwada, ti o si se ise rere, (ki o mo) pe dajudaju o n ronu piwada patapata sodo Allahu ni |
وَالَّذِينَ لَا يَشْهَدُونَ الزُّورَ وَإِذَا مَرُّوا بِاللَّغْوِ مَرُّوا كِرَامًا (72) (Awon ni) awon ti ko jerii eke. Ti won ba si koja nibi ibaje, won a koja pelu aponle |
وَالَّذِينَ إِذَا ذُكِّرُوا بِآيَاتِ رَبِّهِمْ لَمْ يَخِرُّوا عَلَيْهَا صُمًّا وَعُمْيَانًا (73) (Awon ni) awon ti o je pe ti won ba fi awon ayah Oluwa won seranti fun won, won ko da lule bi aditi ati afoju |
وَالَّذِينَ يَقُولُونَ رَبَّنَا هَبْ لَنَا مِنْ أَزْوَاجِنَا وَذُرِّيَّاتِنَا قُرَّةَ أَعْيُنٍ وَاجْعَلْنَا لِلْمُتَّقِينَ إِمَامًا (74) (Awon ni) awon t’o n so pe: “Oluwa wa, ta wa ni ore itutu-oju lati ara awon iyawo wa ati awon omo wa. Ki O si se wa ni asiwaju fun awon oluberu (Re).” |
أُولَٰئِكَ يُجْزَوْنَ الْغُرْفَةَ بِمَا صَبَرُوا وَيُلَقَّوْنَ فِيهَا تَحِيَّةً وَسَلَامًا (75) Awon wonyen, ipo giga (ninu Ogba Idera) ni A maa fi san won ni esan nitori pe won se suuru. Ikini ati sisalamo ni A oo fi maa pade won ninu re |
خَالِدِينَ فِيهَا ۚ حَسُنَتْ مُسْتَقَرًّا وَمُقَامًا (76) Olusegbere ni won ninu re. O dara ni ibugbe ati ibuduro |
قُلْ مَا يَعْبَأُ بِكُمْ رَبِّي لَوْلَا دُعَاؤُكُمْ ۖ فَقَدْ كَذَّبْتُمْ فَسَوْفَ يَكُونُ لِزَامًا (77) So pe: "Oluwa mi ko ka yin kun ti ki i ba se adua yin. E kuku ti pe (awon ayah Re) niro. Laipe o si maa di iya ainipekun (fun yin) |