وَيْلٌ لِّلْمُطَفِّفِينَ (1) Egbe ni fun awon oludin-osuwon-ku |
الَّذِينَ إِذَا اكْتَالُوا عَلَى النَّاسِ يَسْتَوْفُونَ (2) awon (ontaja) t’o je pe nigba ti won ba won nnkan lodo awon eniyan, won a gba a ni ekun |
وَإِذَا كَالُوهُمْ أَو وَّزَنُوهُمْ يُخْسِرُونَ (3) nigba ti awon (ontaja naa) ba si lo iwon fun awon (onraja) tabi lo osuwon fun won, won yoo din in ku |
أَلَا يَظُنُّ أُولَٰئِكَ أَنَّهُم مَّبْعُوثُونَ (4) Se awon wonyen ko mo daju pe dajudaju A maa gbe won dide |
لِيَوْمٍ عَظِيمٍ (5) ni Ojo nla kan |
يَوْمَ يَقُومُ النَّاسُ لِرَبِّ الْعَالَمِينَ (6) Ni ojo ti awon eniyan yoo dide naro fun Oluwa gbogbo eda |
كَلَّا إِنَّ كِتَابَ الْفُجَّارِ لَفِي سِجِّينٍ (7) Bee ni, dajudaju iwe ise awon eni ibi kuku wa ninu Sijjin |
وَمَا أَدْرَاكَ مَا سِجِّينٌ (8) Ki si l’o mu o mo ohun t’o n je Sijjin |
كِتَابٌ مَّرْقُومٌ (9) Iwe ti won ti ko ise aburu eda sinu re (ti won si fi pamo sinu ile keje ni Sijjin) |
وَيْلٌ يَوْمَئِذٍ لِّلْمُكَذِّبِينَ (10) Ni ojo yen, egbe ni fun awon olupe-ododo- niro |
الَّذِينَ يُكَذِّبُونَ بِيَوْمِ الدِّينِ (11) awon t’o n pe Ojo esan niro |
وَمَا يُكَذِّبُ بِهِ إِلَّا كُلُّ مُعْتَدٍ أَثِيمٍ (12) Ko si si eni t’o n pe e niro afi gbogbo alakoyo, elese |
إِذَا تُتْلَىٰ عَلَيْهِ آيَاتُنَا قَالَ أَسَاطِيرُ الْأَوَّلِينَ (13) Nigba ti won ba n ke awon ayah Wa fun un, o maa wi pe: "Awon akosile alo awon eni akoko (niwonyi) |
كَلَّا ۖ بَلْ ۜ رَانَ عَلَىٰ قُلُوبِهِم مَّا كَانُوا يَكْسِبُونَ (14) Rara ko ri bee, amo ohun ti won n se nise ibi l’o joba lori okan won |
كَلَّا إِنَّهُمْ عَن رَّبِّهِمْ يَوْمَئِذٍ لَّمَحْجُوبُونَ (15) Ni ti ododo, dajudaju won yoo wa ninu gaga, won ko si nii ri Oluwa won ni ojo yen |
ثُمَّ إِنَّهُمْ لَصَالُو الْجَحِيمِ (16) Leyin naa, dajudaju won yoo wo inu ina Jehim |
ثُمَّ يُقَالُ هَٰذَا الَّذِي كُنتُم بِهِ تُكَذِّبُونَ (17) Leyin naa, won maa so (fun won) pe: "Eyi ni ohun ti e n pe niro |
كَلَّا إِنَّ كِتَابَ الْأَبْرَارِ لَفِي عِلِّيِّينَ (18) Bee ni. Dajudaju iwe ise awon eni rere wa ninu ‘illiyyun |
وَمَا أَدْرَاكَ مَا عِلِّيُّونَ (19) Ki si l’o mu o mo ohun t’o n je ‘illiyyun |
كِتَابٌ مَّرْقُومٌ (20) Iwe ti won ti ko ise rere eda sinu re (ti won si fi pamo si oke sanmo ni ‘illiyyun) |
يَشْهَدُهُ الْمُقَرَّبُونَ (21) Awon (molaika) ti won sunmo Allahu n jerii si i |
إِنَّ الْأَبْرَارَ لَفِي نَعِيمٍ (22) Dajudaju awon eni rere maa wa ninu igbadun |
عَلَى الْأَرَائِكِ يَنظُرُونَ (23) Won yoo maa woran lori awon ibusun |
تَعْرِفُ فِي وُجُوهِهِمْ نَضْرَةَ النَّعِيمِ (24) Iwo yoo da itutu oju igbadun mo ninu oju won |
يُسْقَوْنَ مِن رَّحِيقٍ مَّخْتُومٍ (25) Won yoo maa fun won mu ninu oti onideeri |
خِتَامُهُ مِسْكٌ ۚ وَفِي ذَٰلِكَ فَلْيَتَنَافَسِ الْمُتَنَافِسُونَ (26) Alumisiki ni (oorun) ipari re. Ki awon alapaantete sapantete ninu iyen |
وَمِزَاجُهُ مِن تَسْنِيمٍ (27) Tesnim ni won yoo maa popo (mo oti naa) |
عَيْنًا يَشْرَبُ بِهَا الْمُقَرَّبُونَ (28) (Tesnim ni) omi iseleru kan, ti awon olusunmo (Allahu) yoo maa mu |
إِنَّ الَّذِينَ أَجْرَمُوا كَانُوا مِنَ الَّذِينَ آمَنُوا يَضْحَكُونَ (29) Dajudaju awon t’o dese, won maa n fi awon t’o gbagbo ni ododo rerin-in |
وَإِذَا مَرُّوا بِهِمْ يَتَغَامَزُونَ (30) Nigba ti won ba gba egbe won koja, (awon adese) yoo maa seju sira won ni ti yeye |
وَإِذَا انقَلَبُوا إِلَىٰ أَهْلِهِمُ انقَلَبُوا فَكِهِينَ (31) Nigba ti won ba si pada si odo awon eniyan won, won a pada ti won yoo maa se faari |
وَإِذَا رَأَوْهُمْ قَالُوا إِنَّ هَٰؤُلَاءِ لَضَالُّونَ (32) Ati pe nigba ti won ba ri (awon onigbagbo ododo) won a wi pe: "Dajudaju awon wonyi ni olusina |
وَمَا أُرْسِلُوا عَلَيْهِمْ حَافِظِينَ (33) Awa ko si ran won nise oluso si won |
فَالْيَوْمَ الَّذِينَ آمَنُوا مِنَ الْكُفَّارِ يَضْحَكُونَ (34) Nitori naa, ni oni awon t’o gbagbo ni ododo yoo fi awon alaigbagbo rerin-in |
عَلَى الْأَرَائِكِ يَنظُرُونَ (35) Won yoo maa woran lori awon ibusun |
هَلْ ثُوِّبَ الْكُفَّارُ مَا كَانُوا يَفْعَلُونَ (36) Sebi won ti fi ohun ti awon alaigbagbo n se nise san won lesan (bayii) |