| حم (1) Ha mim
 | 
| وَالْكِتَابِ الْمُبِينِ (2) (Allahu) bura pelu Tira t’o yanju oro eda
 | 
| إِنَّا أَنزَلْنَاهُ فِي لَيْلَةٍ مُّبَارَكَةٍ ۚ إِنَّا كُنَّا مُنذِرِينَ (3) Dajudaju Awa so o kale ninu oru ibukun. Dajudaju Awa n je Olukilo
 | 
| فِيهَا يُفْرَقُ كُلُّ أَمْرٍ حَكِيمٍ (4) Ninu oru naa ni won ti maa yanju gbogbo oro ti ko nii tase (lori eda)
 | 
| أَمْرًا مِّنْ عِندِنَا ۚ إِنَّا كُنَّا مُرْسِلِينَ (5) Ase kan ni lati odo Wa. Dajudaju Awa l’A n ran awon Ojise nise
 | 
| رَحْمَةً مِّن رَّبِّكَ ۚ إِنَّهُ هُوَ السَّمِيعُ الْعَلِيمُ (6) Ike kan ni lati odo Oluwa re. Dajudaju Allahu, Oun ni Olugbo, Onimo
 | 
| رَبِّ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ وَمَا بَيْنَهُمَا ۖ إِن كُنتُم مُّوقِنِينَ (7) Oluwa awon sanmo ati ile ati ohunkohun ti n be laaarin mejeeji ti eyin ba je alamodaju
 | 
| لَا إِلَٰهَ إِلَّا هُوَ يُحْيِي وَيُمِيتُ ۖ رَبُّكُمْ وَرَبُّ آبَائِكُمُ الْأَوَّلِينَ (8) Ko si olohun ti ijosin to si afi Oun. O n so eda di alaaye. O si n so eda di oku. Oluwa yin ati Oluwa awon baba yin, awon eni akoko
 | 
| بَلْ هُمْ فِي شَكٍّ يَلْعَبُونَ (9) Sibe, won si wa ninu iyemeji, ti won n sere
 | 
| فَارْتَقِبْ يَوْمَ تَأْتِي السَّمَاءُ بِدُخَانٍ مُّبِينٍ (10) Nitori naa, maa reti ojo ti sanmo yoo mu eefin ponnbele wa
 | 
| يَغْشَى النَّاسَ ۖ هَٰذَا عَذَابٌ أَلِيمٌ (11) O maa bo awon eniyan mole. Eyi ni iya eleta-elero
 | 
| رَّبَّنَا اكْشِفْ عَنَّا الْعَذَابَ إِنَّا مُؤْمِنُونَ (12) (Awon eniyan yoo wi pe): Oluwa wa, gbe iya naa kuro fun wa, dajudaju awa yoo gbagbo ni ododo
 | 
| أَنَّىٰ لَهُمُ الذِّكْرَىٰ وَقَدْ جَاءَهُمْ رَسُولٌ مُّبِينٌ (13) Bawo ni iranti se le wulo fun won (lasiko iya)? Ojise ponnbele kuku ti de ba won
 | 
| ثُمَّ تَوَلَّوْا عَنْهُ وَقَالُوا مُعَلَّمٌ مَّجْنُونٌ (14) Leyin naa, won gbunri kuro ni odo re. Won si wi pe: "Were ti eniyan kan n ko ni eko ni
 | 
| إِنَّا كَاشِفُو الْعَذَابِ قَلِيلًا ۚ إِنَّكُمْ عَائِدُونَ (15) Dajudaju Awa maa gbe iya naa kuro fun igba die. Dajudaju eyin yoo tun pada (sinu aigbagbo)
 | 
| يَوْمَ نَبْطِشُ الْبَطْشَةَ الْكُبْرَىٰ إِنَّا مُنتَقِمُونَ (16) Ojo ti A oo gba (won mu) ni igbamu t’o tobi julo; dajudaju Awa yoo gba esan iya (lara won)
 | 
| ۞ وَلَقَدْ فَتَنَّا قَبْلَهُمْ قَوْمَ فِرْعَوْنَ وَجَاءَهُمْ رَسُولٌ كَرِيمٌ (17) Dajudaju A dan awon eniyan Fir‘aon wo siwaju won. Ojise alapon-onle si de wa ba won
 | 
| أَنْ أَدُّوا إِلَيَّ عِبَادَ اللَّهِ ۖ إِنِّي لَكُمْ رَسُولٌ أَمِينٌ (18) (O so pe): “E ko awon erusin Allahu le mi lowo. Dajudaju emi ni Ojise olufokantan fun yin
 | 
| وَأَن لَّا تَعْلُوا عَلَى اللَّهِ ۖ إِنِّي آتِيكُم بِسُلْطَانٍ مُّبِينٍ (19) E ma se segberaga si Allahu. Dajudaju emi ti mu eri ponnbele wa ba yin
 | 
| وَإِنِّي عُذْتُ بِرَبِّي وَرَبِّكُمْ أَن تَرْجُمُونِ (20) Dajudaju Emi sa di Oluwa mi ati Oluwa yin pe ki e ma se so mi loko pa
 | 
| وَإِن لَّمْ تُؤْمِنُوا لِي فَاعْتَزِلُونِ (21) Ti e ko ba si gba mi gbo, e fi mi sile je
 | 
| فَدَعَا رَبَّهُ أَنَّ هَٰؤُلَاءِ قَوْمٌ مُّجْرِمُونَ (22) Nitori naa, o pe Oluwa re pe dajudaju awon wonyi ni ijo elese
 | 
| فَأَسْرِ بِعِبَادِي لَيْلًا إِنَّكُم مُّتَّبَعُونَ (23) (Allahu so pe): "Mu awon erusin Mi rin ni ale (nitori pe) won yoo to yin leyin
 | 
| وَاتْرُكِ الْبَحْرَ رَهْوًا ۖ إِنَّهُمْ جُندٌ مُّغْرَقُونَ (24) Ki o si fi agbami odo sile ni yiyanu sile bee. Dajudaju awon ni omo ogun ti A maa teri sinu agbami
 | 
| كَمْ تَرَكُوا مِن جَنَّاتٍ وَعُيُونٍ (25) Meloo meloo ninu awon ogba oko ati odo iseleru ti won fi sile (leyin iparun won)
 | 
| وَزُرُوعٍ وَمَقَامٍ كَرِيمٍ (26) Ati awon irugbin pelu aye aponle (ti won fi sile)
 | 
| وَنَعْمَةٍ كَانُوا فِيهَا فَاكِهِينَ (27) Ati idera ti won n gbadun ninu re (siwaju iparun won)
 | 
| كَذَٰلِكَ ۖ وَأَوْرَثْنَاهَا قَوْمًا آخَرِينَ (28) Bayen (ni oro won se ri). A si jogun (ilu) won fun ijo eniyan miiran
 | 
| فَمَا بَكَتْ عَلَيْهِمُ السَّمَاءُ وَالْأَرْضُ وَمَا كَانُوا مُنظَرِينَ (29) Nigba naa, sanmo ati ile ko sunkun won. Won ko si fi iya won fale
 | 
| وَلَقَدْ نَجَّيْنَا بَنِي إِسْرَائِيلَ مِنَ الْعَذَابِ الْمُهِينِ (30) Dajudaju A gba awon omo ’Isro’il la ninu iya yepere
 | 
| مِن فِرْعَوْنَ ۚ إِنَّهُ كَانَ عَالِيًا مِّنَ الْمُسْرِفِينَ (31) (A la won) lowo Fir‘aon. Dajudaju o je onigbeeraga. O si wa ninu awon alakoyo
 | 
| وَلَقَدِ اخْتَرْنَاهُمْ عَلَىٰ عِلْمٍ عَلَى الْعَالَمِينَ (32) A kuku sa won lesa lori awon eda (asiko tiwon) pelu imo
 | 
| وَآتَيْنَاهُم مِّنَ الْآيَاتِ مَا فِيهِ بَلَاءٌ مُّبِينٌ (33) A si fun won ni awon ami ti adanwo ponnbele wa ninu re
 | 
| إِنَّ هَٰؤُلَاءِ لَيَقُولُونَ (34) Dajudaju awon wonyi n wi pe
 | 
| إِنْ هِيَ إِلَّا مَوْتَتُنَا الْأُولَىٰ وَمَا نَحْنُ بِمُنشَرِينَ (35) Ko si iku kan ayafi iku akoko (ti o pa wa nile aye). Won ko si nii gbe wa dide
 | 
| فَأْتُوا بِآبَائِنَا إِن كُنتُمْ صَادِقِينَ (36) (Bi bee ko), e mu awon baba wa wa ti e ba je olododo
 | 
| أَهُمْ خَيْرٌ أَمْ قَوْمُ تُبَّعٍ وَالَّذِينَ مِن قَبْلِهِمْ ۚ أَهْلَكْنَاهُمْ ۖ إِنَّهُمْ كَانُوا مُجْرِمِينَ (37) Se awon ni won loore julo ni tabi awon eniyan Tubba‘u ati awon t’o siwaju won? A pa won re; dajudaju won je elese
 | 
| وَمَا خَلَقْنَا السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضَ وَمَا بَيْنَهُمَا لَاعِبِينَ (38) A ko seda awon sanmo, ile ati ohunkohun ti n be laaarin mejeeji pelu ere sise
 | 
| مَا خَلَقْنَاهُمَا إِلَّا بِالْحَقِّ وَلَٰكِنَّ أَكْثَرَهُمْ لَا يَعْلَمُونَ (39) A ko da awon mejeeji bi ko se pelu ododo, sugbon opolopo won ni ko mo
 | 
| إِنَّ يَوْمَ الْفَصْلِ مِيقَاتُهُمْ أَجْمَعِينَ (40) Dajudaju ojo opinya (iyen, ojo ajinde) ni akoko adehun fun gbogbo won patapata
 | 
| يَوْمَ لَا يُغْنِي مَوْلًى عَن مَّوْلًى شَيْئًا وَلَا هُمْ يُنصَرُونَ (41) Ni ojo ti ore kan ko nii fi kini kan ro ore kan loro. A o si nii ran won lowo
 | 
| إِلَّا مَن رَّحِمَ اللَّهُ ۚ إِنَّهُ هُوَ الْعَزِيزُ الرَّحِيمُ (42) Ayafi eni ti Allahu ba ke. Dajudaju Allahu, Oun ni Alagbara, Asake-orun
 | 
| إِنَّ شَجَرَتَ الزَّقُّومِ (43) Dajudaju igi zaƙum
 | 
| طَعَامُ الْأَثِيمِ (44) ni ounje elese
 | 
| كَالْمُهْلِ يَغْلِي فِي الْبُطُونِ (45) O da bi epo gbigba ti n ho ninu ikun
 | 
| كَغَلْيِ الْحَمِيمِ (46) (t’o) da bi hiho omi gbigbona
 | 
| خُذُوهُ فَاعْتِلُوهُ إِلَىٰ سَوَاءِ الْجَحِيمِ (47) E mu un. Ki e wo o saarin gbungbun inu ina Jehim
 | 
| ثُمَّ صُبُّوا فَوْقَ رَأْسِهِ مِنْ عَذَابِ الْحَمِيمِ (48) Leyin naa, e ro iya olomi gbigbona le e lori
 | 
| ذُقْ إِنَّكَ أَنتَ الْعَزِيزُ الْكَرِيمُ (49) To o wo (sebi) dajudaju iwo ni alagbara, alapon-onle (gege bi o se pe ara re)
 | 
| إِنَّ هَٰذَا مَا كُنتُم بِهِ تَمْتَرُونَ (50) Dajudaju (iya) eyi ni nnkan ti e n seyemeji nipa re
 | 
| إِنَّ الْمُتَّقِينَ فِي مَقَامٍ أَمِينٍ (51) Dajudaju awon oluberu Allahu yoo wa ni aye ifayabale
 | 
| فِي جَنَّاتٍ وَعُيُونٍ (52) (Won yoo wa) ninu awon Ogba Idera pelu awon omi iseleru (ni isale re)
 | 
| يَلْبَسُونَ مِن سُندُسٍ وَإِسْتَبْرَقٍ مُّتَقَابِلِينَ (53) Won yoo maa wo aso aran felefele ati aran t’o nipon; won yo si maa koju sira won
 | 
| كَذَٰلِكَ وَزَوَّجْنَاهُم بِحُورٍ عِينٍ (54) Bayen (ni oro won yo se ri). A si maa fi awon obinrin eleyinju-ege se iyawo fun won
 | 
| يَدْعُونَ فِيهَا بِكُلِّ فَاكِهَةٍ آمِنِينَ (55) Won yoo maa beere fun gbogbo nnkan eleso ninu (Ogba Idera) pelu ifayabale
 | 
| لَا يَذُوقُونَ فِيهَا الْمَوْتَ إِلَّا الْمَوْتَةَ الْأُولَىٰ ۖ وَوَقَاهُمْ عَذَابَ الْجَحِيمِ (56) Won ko nii to iku wo nibe ayafi iku akoko (ti won ti ku nile aye). (Allahu) si maa so won nibi iya ina Jehim
 | 
| فَضْلًا مِّن رَّبِّكَ ۚ ذَٰلِكَ هُوَ الْفَوْزُ الْعَظِيمُ (57) O je oore ajulo lati odo Oluwa re. Iyen ni erenje nla
 | 
| فَإِنَّمَا يَسَّرْنَاهُ بِلِسَانِكَ لَعَلَّهُمْ يَتَذَكَّرُونَ (58) Nitori naa, A se (al-Ƙur’an) ni irorun lori ahon re nitori ki won le lo iranti
 | 
| فَارْتَقِبْ إِنَّهُم مُّرْتَقِبُونَ (59) Nitori naa, maa reti . Dajudaju awon naa n reti
 |