الَّذِينَ كَفَرُوا وَصَدُّوا عَن سَبِيلِ اللَّهِ أَضَلَّ أَعْمَالَهُمْ (1) Awon t’o sai gbagbo, ti won tun seri awon eniyan kuro loju ona (esin) Allahu, (Allahu) maa so ise won dofo |
وَالَّذِينَ آمَنُوا وَعَمِلُوا الصَّالِحَاتِ وَآمَنُوا بِمَا نُزِّلَ عَلَىٰ مُحَمَّدٍ وَهُوَ الْحَقُّ مِن رَّبِّهِمْ ۙ كَفَّرَ عَنْهُمْ سَيِّئَاتِهِمْ وَأَصْلَحَ بَالَهُمْ (2) Awon t’o gbagbo ni ododo, ti won se awon ise rere, ti won tun gbagbo ninu ohun ti Won sokale fun (Anabi) Muhammad, ohun si ni ododo lati odo Oluwa won, (Allahu) maa pa awon (ise) aburu won re, O si maa se atunse oro won si daadaa |
ذَٰلِكَ بِأَنَّ الَّذِينَ كَفَرُوا اتَّبَعُوا الْبَاطِلَ وَأَنَّ الَّذِينَ آمَنُوا اتَّبَعُوا الْحَقَّ مِن رَّبِّهِمْ ۚ كَذَٰلِكَ يَضْرِبُ اللَّهُ لِلنَّاسِ أَمْثَالَهُمْ (3) Iyen nitori pe dajudaju awon t’o sai gbagbo tele iro. Ati pe dajudaju awon t’o gbagbo tele ododo lati odo Oluwa won. Bayen ni Allahu se n fi apejuwe won lele fun awon eniyan |
فَإِذَا لَقِيتُمُ الَّذِينَ كَفَرُوا فَضَرْبَ الرِّقَابِ حَتَّىٰ إِذَا أَثْخَنتُمُوهُمْ فَشُدُّوا الْوَثَاقَ فَإِمَّا مَنًّا بَعْدُ وَإِمَّا فِدَاءً حَتَّىٰ تَضَعَ الْحَرْبُ أَوْزَارَهَا ۚ ذَٰلِكَ وَلَوْ يَشَاءُ اللَّهُ لَانتَصَرَ مِنْهُمْ وَلَٰكِن لِّيَبْلُوَ بَعْضَكُم بِبَعْضٍ ۗ وَالَّذِينَ قُتِلُوا فِي سَبِيلِ اللَّهِ فَلَن يُضِلَّ أَعْمَالَهُمْ (4) Nitori naa, nigba ti e ba pade awon t’o sai gbagbo (loju ogun esin), e maa be won lorun nso titi di igba ti e maa fi bori won. (Ti e ba segun) ki e de won nigbekun. Leyin naa, e le tu won sile ni ofe tabi ki e tu won sile pelu owo itusile titi (okunfa) ogun esin yoo fi kase nile. Iyen (wa bee). Ti o ba je pe Allahu ba fe, iba gbesan funra Re (lai nii la ogun jija lo), sugbon nitori ki O le dan apa kan yin wo lara apa kan ni. Awon musulumi ti won si pa si oju ogun esin, Allahu ko nii so ise won dofo |
سَيَهْدِيهِمْ وَيُصْلِحُ بَالَهُمْ (5) O maa to won sona. O si maa tun oro won se si daadaa |
وَيُدْخِلُهُمُ الْجَنَّةَ عَرَّفَهَا لَهُمْ (6) O maa fi won wo inu Ogba Idera, eyi ti O ti fi mo won |
يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا إِن تَنصُرُوا اللَّهَ يَنصُرْكُمْ وَيُثَبِّتْ أَقْدَامَكُمْ (7) Eyin ti e gbagbo ni ododo, ti e ba ran (esin) Allahu lowo, (Allahu) maa ran yin lowo. O si maa mu ese yin duro sinsin |
وَالَّذِينَ كَفَرُوا فَتَعْسًا لَّهُمْ وَأَضَلَّ أَعْمَالَهُمْ (8) Awon t’o sai gbagbo, egbe ni fun won. (Allahu) si maa ba ise won je |
ذَٰلِكَ بِأَنَّهُمْ كَرِهُوا مَا أَنزَلَ اللَّهُ فَأَحْبَطَ أَعْمَالَهُمْ (9) Iyen nitori pe dajudaju won korira ohun ti Allahu sokale. Nitori naa, (Allahu) si ba ise won je |
۞ أَفَلَمْ يَسِيرُوا فِي الْأَرْضِ فَيَنظُرُوا كَيْفَ كَانَ عَاقِبَةُ الَّذِينَ مِن قَبْلِهِمْ ۚ دَمَّرَ اللَّهُ عَلَيْهِمْ ۖ وَلِلْكَافِرِينَ أَمْثَالُهَا (10) Se won ko rin kiri lori ile ki won wo bi ikangun awon t’o siwaju won se ri? Allahu pa won re. Iru re tun wa fun awon alaigbagbo |
ذَٰلِكَ بِأَنَّ اللَّهَ مَوْلَى الَّذِينَ آمَنُوا وَأَنَّ الْكَافِرِينَ لَا مَوْلَىٰ لَهُمْ (11) Iyen nitori pe dajudaju Allahu ni Oluranlowo awon t’o gbagbo ni ododo. Dajudaju awon alaigbagbo, ko si oluranlowo kan fun won |
إِنَّ اللَّهَ يُدْخِلُ الَّذِينَ آمَنُوا وَعَمِلُوا الصَّالِحَاتِ جَنَّاتٍ تَجْرِي مِن تَحْتِهَا الْأَنْهَارُ ۖ وَالَّذِينَ كَفَرُوا يَتَمَتَّعُونَ وَيَأْكُلُونَ كَمَا تَأْكُلُ الْأَنْعَامُ وَالنَّارُ مَثْوًى لَّهُمْ (12) Dajudaju Allahu yoo fi awon t’o gbagbo ni ododo, ti won si se awon ise rere wo inu awon Ogba Idera, eyi ti awon odo n san ni isale re. Awon t’o si sai gbagbo, awon n gbadun, won si n je (kiri) gege bi awon eran-osin se n je (kiri). Ina si ni ibugbe fun won |
وَكَأَيِّن مِّن قَرْيَةٍ هِيَ أَشَدُّ قُوَّةً مِّن قَرْيَتِكَ الَّتِي أَخْرَجَتْكَ أَهْلَكْنَاهُمْ فَلَا نَاصِرَ لَهُمْ (13) Meloo meloo ninu awon (ara) ilu ti o lagbara ju (ara) ilu re, ti o le o jade, ti A si ti pa won re. Ko si si alaranse kan fun won |
أَفَمَن كَانَ عَلَىٰ بَيِّنَةٍ مِّن رَّبِّهِ كَمَن زُيِّنَ لَهُ سُوءُ عَمَلِهِ وَاتَّبَعُوا أَهْوَاءَهُم (14) Nje eni ti o wa lori eri t’o yanju lati odo Oluwa re, se o da bi eni ti won se ise aburu re ni oso fun, ti won si tele ife-inu won |
مَّثَلُ الْجَنَّةِ الَّتِي وُعِدَ الْمُتَّقُونَ ۖ فِيهَا أَنْهَارٌ مِّن مَّاءٍ غَيْرِ آسِنٍ وَأَنْهَارٌ مِّن لَّبَنٍ لَّمْ يَتَغَيَّرْ طَعْمُهُ وَأَنْهَارٌ مِّنْ خَمْرٍ لَّذَّةٍ لِّلشَّارِبِينَ وَأَنْهَارٌ مِّنْ عَسَلٍ مُّصَفًّى ۖ وَلَهُمْ فِيهَا مِن كُلِّ الثَّمَرَاتِ وَمَغْفِرَةٌ مِّن رَّبِّهِمْ ۖ كَمَنْ هُوَ خَالِدٌ فِي النَّارِ وَسُقُوا مَاءً حَمِيمًا فَقَطَّعَ أَمْعَاءَهُمْ (15) Apejuwe Ogba Idera eyi ti Won se ni adehun fun awon oluberu Allahu (niyi): awon omi odo wa ninu re ti ko nii yi pada ati awon odo wara ti adun re ko nii yi pada ati awon odo oti didun fun awon t’o maa mu un ati awon odo oyin mimo. Awon oniruuru eso wa fun won ninu re ati aforijin lati odo Oluwa won. (Se eni ti o wa ninu Ogba Idera yii) da bi olusegbere ninu Ina bi, ti won n fun won ni omi gbigbona mu, ti o si maa ja awon ifun won putuputu |
وَمِنْهُم مَّن يَسْتَمِعُ إِلَيْكَ حَتَّىٰ إِذَا خَرَجُوا مِنْ عِندِكَ قَالُوا لِلَّذِينَ أُوتُوا الْعِلْمَ مَاذَا قَالَ آنِفًا ۚ أُولَٰئِكَ الَّذِينَ طَبَعَ اللَّهُ عَلَىٰ قُلُوبِهِمْ وَاتَّبَعُوا أَهْوَاءَهُمْ (16) O wa ninu won, eni ti o teti si oro re titi di igba ti won ba jade kuro ni odo re tan, won yo si wi fun awon onimo-esin pe: "Ki l’o so leee kan na?" Awon wonyen ni awon ti Allahu ti di okan won pa. Won si tele ife-inu won |
وَالَّذِينَ اهْتَدَوْا زَادَهُمْ هُدًى وَآتَاهُمْ تَقْوَاهُمْ (17) Awon t’o si tele imona, (Allahu) salekun imona fun won. O si maa fun won ni iberu won (ninu Allahu) |
فَهَلْ يَنظُرُونَ إِلَّا السَّاعَةَ أَن تَأْتِيَهُم بَغْتَةً ۖ فَقَدْ جَاءَ أَشْرَاطُهَا ۚ فَأَنَّىٰ لَهُمْ إِذَا جَاءَتْهُمْ ذِكْرَاهُمْ (18) Se won n reti kini kan bi ko se Akoko naa, ti o maa de ba won ni ojiji? Awon ami re kuku ti de. Nitori naa, bawo ni iranti (yo se wulo fun) won nigba ti o ba de ba won |
فَاعْلَمْ أَنَّهُ لَا إِلَٰهَ إِلَّا اللَّهُ وَاسْتَغْفِرْ لِذَنبِكَ وَلِلْمُؤْمِنِينَ وَالْمُؤْمِنَاتِ ۗ وَاللَّهُ يَعْلَمُ مُتَقَلَّبَكُمْ وَمَثْوَاكُمْ (19) Nitori naa, mo pe dajudaju ko si olohun ti ijosin to si afi Allahu. Ki o si toro aforijin fun ese re ati fun awon onigbagbo ododo lokunrin ati awon onigbagbo ododo lobinrin. Allahu mo lilo-bibo yin ati ibusinmi yin |
وَيَقُولُ الَّذِينَ آمَنُوا لَوْلَا نُزِّلَتْ سُورَةٌ ۖ فَإِذَا أُنزِلَتْ سُورَةٌ مُّحْكَمَةٌ وَذُكِرَ فِيهَا الْقِتَالُ ۙ رَأَيْتَ الَّذِينَ فِي قُلُوبِهِم مَّرَضٌ يَنظُرُونَ إِلَيْكَ نَظَرَ الْمَغْشِيِّ عَلَيْهِ مِنَ الْمَوْتِ ۖ فَأَوْلَىٰ لَهُمْ (20) Awon t’o gbagbo ni ododo n so pe: "Ki ni ko je ki Won so surah kan kale?" Nigba ti won ba so surah alainipon-na kale, ti won si so oro ija ogun esin ninu re, iwo yoo ri awon ti arun wa ninu okan won, ti won yoo maa wo o ni wiwo bi eni pe won ti daku lo ponrangandan. Ohun ti o si dara julo fun won |
طَاعَةٌ وَقَوْلٌ مَّعْرُوفٌ ۚ فَإِذَا عَزَمَ الْأَمْرُ فَلَوْ صَدَقُوا اللَّهَ لَكَانَ خَيْرًا لَّهُمْ (21) ni itele ase (Allahu) ati (siso) oro rere. Nigba ti ogun esin si ti di dandan, won iba ni igbagbo ododo ninu Allahu, iba dara julo fun won |
فَهَلْ عَسَيْتُمْ إِن تَوَلَّيْتُمْ أَن تُفْسِدُوا فِي الْأَرْضِ وَتُقَطِّعُوا أَرْحَامَكُمْ (22) Nje ko sunmo ti eyin (alaisan okan wonyi) ba de’po ase, pe e o nii sebaje lori ile ati pe e o nii ja okun-ibi yin |
أُولَٰئِكَ الَّذِينَ لَعَنَهُمُ اللَّهُ فَأَصَمَّهُمْ وَأَعْمَىٰ أَبْصَارَهُمْ (23) Awon wonyen ni awon ti Allahu ti sebi le. Nitori naa, O di won leti pa. O si fo iriran won |
أَفَلَا يَتَدَبَّرُونَ الْقُرْآنَ أَمْ عَلَىٰ قُلُوبٍ أَقْفَالُهَا (24) Se won ko nii ronu nipa al-Ƙur’an ni tabi awon agadagodo ti wa lori okan won ni |
إِنَّ الَّذِينَ ارْتَدُّوا عَلَىٰ أَدْبَارِهِم مِّن بَعْدِ مَا تَبَيَّنَ لَهُمُ الْهُدَى ۙ الشَّيْطَانُ سَوَّلَ لَهُمْ وَأَمْلَىٰ لَهُمْ (25) Dajudaju awon t’o peyin da (si ’Islam) leyin ti imona ti foju han si won, Esu lo se isina ni oso fun won. O si fun won ni ireti asan nipa emi gigun |
ذَٰلِكَ بِأَنَّهُمْ قَالُوا لِلَّذِينَ كَرِهُوا مَا نَزَّلَ اللَّهُ سَنُطِيعُكُمْ فِي بَعْضِ الْأَمْرِ ۖ وَاللَّهُ يَعْلَمُ إِسْرَارَهُمْ (26) Iyen nitori pe (awon alaisan okan) n so fun awon t’o korira ohun ti Allahu sokale pe: "Awa yoo tele yin ninu apa kan oro naa." Allahu si mo asiri won |
فَكَيْفَ إِذَا تَوَفَّتْهُمُ الْمَلَائِكَةُ يَضْرِبُونَ وُجُوهَهُمْ وَأَدْبَارَهُمْ (27) Bawo ni (o se maa ri) nigba ti awon molaika ba gba emi won, ti won yo si maa gba oju won ati eyin won |
ذَٰلِكَ بِأَنَّهُمُ اتَّبَعُوا مَا أَسْخَطَ اللَّهَ وَكَرِهُوا رِضْوَانَهُ فَأَحْبَطَ أَعْمَالَهُمْ (28) Iyen nitori pe dajudaju won tele ohun ti o bi Allahu ninu. Won si tun korira iyonu Re. Nitori naa, Allahu ti ba awon ise won je |
أَمْ حَسِبَ الَّذِينَ فِي قُلُوبِهِم مَّرَضٌ أَن لَّن يُخْرِجَ اللَّهُ أَضْغَانَهُمْ (29) Tabi awon ti arun wa ninu okan won n lero pe Allahu ko nii se afihan adisokan buruku won ni |
وَلَوْ نَشَاءُ لَأَرَيْنَاكَهُمْ فَلَعَرَفْتَهُم بِسِيمَاهُمْ ۚ وَلَتَعْرِفَنَّهُمْ فِي لَحْنِ الْقَوْلِ ۚ وَاللَّهُ يَعْلَمُ أَعْمَالَكُمْ (30) Ati pe ti A ba fe Awa iba fi won han o, iwo iba si mo won pelu ami won. Dajudaju iwo yoo mo won nipa ipekoro-soro (won). Allahu si mo awon ise (owo) yin |
وَلَنَبْلُوَنَّكُمْ حَتَّىٰ نَعْلَمَ الْمُجَاهِدِينَ مِنكُمْ وَالصَّابِرِينَ وَنَبْلُوَ أَخْبَارَكُمْ (31) Dajudaju A maa dan yin wo titi A fi maa safi han awon olujagun-esin ati awon onisuuru ninu yin. A si maa gbidanwo awon iro yin |
إِنَّ الَّذِينَ كَفَرُوا وَصَدُّوا عَن سَبِيلِ اللَّهِ وَشَاقُّوا الرَّسُولَ مِن بَعْدِ مَا تَبَيَّنَ لَهُمُ الْهُدَىٰ لَن يَضُرُّوا اللَّهَ شَيْئًا وَسَيُحْبِطُ أَعْمَالَهُمْ (32) Dajudaju awon t’o sai gbagbo, ti won si seri awon eniyan kuro loju ona (esin) Allahu, ti won tun ko inira ba Ojise Allahu leyin ti imona ti foju han si won, won ko le ko inira kini kan ba Allahu. (Allahu) yo si ba ise won je |
۞ يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا أَطِيعُوا اللَّهَ وَأَطِيعُوا الرَّسُولَ وَلَا تُبْطِلُوا أَعْمَالَكُمْ (33) Eyin ti e gbagbo ni ododo, e tele (oro) Allahu, e tele (oro) Ojise naa, ki e si ma se ba awon ise yin je |
إِنَّ الَّذِينَ كَفَرُوا وَصَدُّوا عَن سَبِيلِ اللَّهِ ثُمَّ مَاتُوا وَهُمْ كُفَّارٌ فَلَن يَغْفِرَ اللَّهُ لَهُمْ (34) Dajudaju awon t’o sai gbagbo, ti won si seri awon eniyan kuro loju ona (esin) Allahu, leyin naa ti won ku nigba ti won je alaigbagbo, Allahu ko nii forijin won |
فَلَا تَهِنُوا وَتَدْعُوا إِلَى السَّلْمِ وَأَنتُمُ الْأَعْلَوْنَ وَاللَّهُ مَعَكُمْ وَلَن يَتِرَكُمْ أَعْمَالَكُمْ (35) E ma se kaaare, ki e si ma se pepe fun kosogunmo, nigba ti e ba n leke lowo. Allahu wa pelu yin; ko si nii ko adinku ba esan awon ise yin |
إِنَّمَا الْحَيَاةُ الدُّنْيَا لَعِبٌ وَلَهْوٌ ۚ وَإِن تُؤْمِنُوا وَتَتَّقُوا يُؤْتِكُمْ أُجُورَكُمْ وَلَا يَسْأَلْكُمْ أَمْوَالَكُمْ (36) Ere ati iranu ni isemi aye. (Amo) ti e ba gbagbo (ninu Allahu), ti e si beru (Re), O maa fun yin ni awon esan yin. Ko si nii beere awon dukia yin (pe ki e fi gbogbo re yo Zakah) |
إِن يَسْأَلْكُمُوهَا فَيُحْفِكُمْ تَبْخَلُوا وَيُخْرِجْ أَضْغَانَكُمْ (37) Ti (Allahu) ba beere re ni owo yin (pe ki e fi gbogbo re yo Zakah), ti O si wonkoko mo yin, e maa sahun. O si maa mu arun okan yin jade (asiri yin yo si tu sita) |
هَا أَنتُمْ هَٰؤُلَاءِ تُدْعَوْنَ لِتُنفِقُوا فِي سَبِيلِ اللَّهِ فَمِنكُم مَّن يَبْخَلُ ۖ وَمَن يَبْخَلْ فَإِنَّمَا يَبْخَلُ عَن نَّفْسِهِ ۚ وَاللَّهُ الْغَنِيُّ وَأَنتُمُ الْفُقَرَاءُ ۚ وَإِن تَتَوَلَّوْا يَسْتَبْدِلْ قَوْمًا غَيْرَكُمْ ثُمَّ لَا يَكُونُوا أَمْثَالَكُم (38) Eyin naa ma niwonyi ti won n pe lati nawo fun esin Allahu. Sugbon eni t’o n sahun wa ninu yin. Enikeni ti o ba sahun, o se e fun emi ara re. Allahu ni Oloro. Eyin si ni alaini. Ti e ba gbunri, (Allahu) maa fi ijo miiran paaro yin. Leyin naa, won ko si nii da bi iru yin |