إِذَا السَّمَاءُ انشَقَّتْ (1) Nigba ti sanmo ba faya perepere | 
وَأَذِنَتْ لِرَبِّهَا وَحُقَّتْ (2) o gbo, o si tele ase Oluwa re ni. O si di dandan fun un lati se bee – | 
وَإِذَا الْأَرْضُ مُدَّتْ (3) ati nigba ti A ba fe ile loju | 
وَأَلْقَتْ مَا فِيهَا وَتَخَلَّتْ (4) o maa ju ohun ti o wa ninu re sita, o si maa pa sofo | 
وَأَذِنَتْ لِرَبِّهَا وَحُقَّتْ (5) – o gbo, o si tele ase Oluwa re ni. O si di dandan fun un lati se bee – (ni ojo yen ni eda maa ri ise owo re) | 
يَا أَيُّهَا الْإِنسَانُ إِنَّكَ كَادِحٌ إِلَىٰ رَبِّكَ كَدْحًا فَمُلَاقِيهِ (6) Iwo eniyan dajudaju iwo n se ise karakara ni ise asepade Oluwa re. O si maa mu un pade Re | 
فَأَمَّا مَنْ أُوتِيَ كِتَابَهُ بِيَمِينِهِ (7) Nitori naa, ni ti eni ti won ba fun ni iwe ise re ni owo otun re | 
فَسَوْفَ يُحَاسَبُ حِسَابًا يَسِيرًا (8) laipe A maa se isiro-ise (re) ni isiro irorun | 
وَيَنقَلِبُ إِلَىٰ أَهْلِهِ مَسْرُورًا (9) O si maa pada si odo awon eniyan re (ninu Ogba Idera) leni idunnu | 
وَأَمَّا مَنْ أُوتِيَ كِتَابَهُ وَرَاءَ ظَهْرِهِ (10) Ni ti eni ti won ba si fun ni iwe ise re lati eyin re | 
فَسَوْفَ يَدْعُو ثُبُورًا (11) laipe o maa kigbe iparun | 
وَيَصْلَىٰ سَعِيرًا (12) O si maa wo inu Ina t’o n jo fofo | 
إِنَّهُ كَانَ فِي أَهْلِهِ مَسْرُورًا (13) Dajudaju o ti wa laaarin awon eniyan re leni idunnu (si aigbagbo nile aye) | 
إِنَّهُ ظَنَّ أَن لَّن يَحُورَ (14) Dajudaju o lero pe oun ko nii pada (si odo Allahu ni) | 
بَلَىٰ إِنَّ رَبَّهُ كَانَ بِهِ بَصِيرًا (15) Rara (o maa pada). Dajudaju Oluwa re je Oluriran nipa re | 
فَلَا أُقْسِمُ بِالشَّفَقِ (16) Nitori naa, Emi (Allahu) n bura pelu awonpapa | 
وَاللَّيْلِ وَمَا وَسَقَ (17) Mo tun bura pelu oru ati ohun ti o ko jo sinu re | 
وَالْقَمَرِ إِذَا اتَّسَقَ (18) Mo tun bura pelu osupa nigba ti o ba degba (pelu imole re) | 
لَتَرْكَبُنَّ طَبَقًا عَن طَبَقٍ (19) Dajudaju eyin yoo maa bo sinu wahala kan lati inu wahala kan | 
فَمَا لَهُمْ لَا يُؤْمِنُونَ (20) Ki l’o se won na ti won ko fi gbagbo ni ododo | 
وَإِذَا قُرِئَ عَلَيْهِمُ الْقُرْآنُ لَا يَسْجُدُونَ ۩ (21) Nigba ti won ba si ke al-Ƙur’an fun won, won ko nii fori kanle | 
بَلِ الَّذِينَ كَفَرُوا يُكَذِّبُونَ (22) Rara, nse ni awon t’o sai gbagbo n pe e niro | 
وَاللَّهُ أَعْلَمُ بِمَا يُوعُونَ (23) Allahu si nimo julo nipa ohun ti won n fi pamo (sinu okan won) | 
فَبَشِّرْهُم بِعَذَابٍ أَلِيمٍ (24) Nitori naa, fun won ni iro iya eleta-elero | 
إِلَّا الَّذِينَ آمَنُوا وَعَمِلُوا الصَّالِحَاتِ لَهُمْ أَجْرٌ غَيْرُ مَمْنُونٍ (25) Ayafi awon t’o gbagbo ni ododo, ti won si se awon ise rere, esan ti ko nii pin n be fun won |