| وَالْمُرْسَلَاتِ عُرْفًا (1) Allahu bura pelu awon ategun t’o n sare ni telentele
 | 
| فَالْعَاصِفَاتِ عَصْفًا (2) O bura pelu awon iji ategun t’o n ja
 | 
| وَالنَّاشِرَاتِ نَشْرًا (3) O bura pelu awon ategun t’o n tu esujo ka
 | 
| فَالْفَارِقَاتِ فَرْقًا (4) O bura pelu awon t’o n sepinya laaarin ododo ati iro
 | 
| فَالْمُلْقِيَاتِ ذِكْرًا (5) O tun bura pelu awon molaika t’o n mu iranti wa (ba awon Ojise)
 | 
| عُذْرًا أَوْ نُذْرًا (6) (Iranti naa je) awijare tabi ikilo
 | 
| إِنَّمَا تُوعَدُونَ لَوَاقِعٌ (7) Dajudaju ohun ti A se ni adehun fun yin kuku maa sele
 | 
| فَإِذَا النُّجُومُ طُمِسَتْ (8) Nitori naa, nigba ti won ba pa (imole) irawo re
 | 
| وَإِذَا السَّمَاءُ فُرِجَتْ (9) ati nigba ti won ba si sanmo sile gbagada
 | 
| وَإِذَا الْجِبَالُ نُسِفَتْ (10) ati nigba ti won ba ku awon apata danu
 | 
| وَإِذَا الرُّسُلُ أُقِّتَتْ (11) ati nigba ti won ba fun awon Ojise ni asiko lati kojo, (Akoko naa ti de niyen)
 | 
| لِأَيِّ يَوْمٍ أُجِّلَتْ (12) Ojo wo ni won so (awon isele wonyi) ro fun na
 | 
| لِيَوْمِ الْفَصْلِ (13) Fun ojo ipinya (laaarin awon eda) ni
 | 
| وَمَا أَدْرَاكَ مَا يَوْمُ الْفَصْلِ (14) Ki si ni o mu o mo ohun t’o n je Ojo ipinya
 | 
| وَيْلٌ يَوْمَئِذٍ لِّلْمُكَذِّبِينَ (15) Egbe ni ni ojo yen fun awon olupe-ododo-niro
 | 
| أَلَمْ نُهْلِكِ الْأَوَّلِينَ (16) Nje Awa ko ti pa awon eni akoko re bi
 | 
| ثُمَّ نُتْبِعُهُمُ الْآخِرِينَ (17) Leyin naa, A si maa fi awon eni Ikeyin tele won (ninu iparun)
 | 
| كَذَٰلِكَ نَفْعَلُ بِالْمُجْرِمِينَ (18) Bayen ni A o ti se pelu awon elese
 | 
| وَيْلٌ يَوْمَئِذٍ لِّلْمُكَذِّبِينَ (19) Egbe ni ni ojo yen fun awon olupe-ododo-niro
 | 
| أَلَمْ نَخْلُقكُّم مِّن مَّاءٍ مَّهِينٍ (20) Se A o seda yin lati inu omi lile yepere bi
 | 
| فَجَعَلْنَاهُ فِي قَرَارٍ مَّكِينٍ (21) Leyin naa, A fi sinu aye aabo (iyen, ile-omo)
 | 
| إِلَىٰ قَدَرٍ مَّعْلُومٍ (22) titi di gbedeke akoko kan ti A ti mo (iyen, ojo ibimo)
 | 
| فَقَدَرْنَا فَنِعْمَ الْقَادِرُونَ (23) A si ni ikapa ati ayanmo (lori re). (Awa si ni) Olukapa ati Olupebubu eda t’o dara
 | 
| وَيْلٌ يَوْمَئِذٍ لِّلْمُكَذِّبِينَ (24) Egbe ni ni ojo yen fun awon olupe-ododo-niro
 | 
| أَلَمْ نَجْعَلِ الْأَرْضَ كِفَاتًا (25) Nje Awa ko se ile ni ohun t’o n ko eda jo mora won
 | 
| أَحْيَاءً وَأَمْوَاتًا (26) (iyen) awon alaaye ati awon oku
 | 
| وَجَعَلْنَا فِيهَا رَوَاسِيَ شَامِخَاتٍ وَأَسْقَيْنَاكُم مَّاءً فُرَاتًا (27) A si fi awon apata gbagidi giga-giga sinu re. A si fun yin ni omi didun mu
 | 
| وَيْلٌ يَوْمَئِذٍ لِّلْمُكَذِّبِينَ (28) Egbe ni ni ojo yen fun awon olupe-ododo-niro
 | 
| انطَلِقُوا إِلَىٰ مَا كُنتُم بِهِ تُكَذِّبُونَ (29) E maa lo si ibi ti e n pe niro
 | 
| انطَلِقُوا إِلَىٰ ظِلٍّ ذِي ثَلَاثِ شُعَبٍ (30) E maa lo si ibi eefin eleka meta
 | 
| لَّا ظَلِيلٍ وَلَا يُغْنِي مِنَ اللَّهَبِ (31) Ki i se iboji tutu. Ko si nii ro won loro ninu ijofofo Ina
 | 
| إِنَّهَا تَرْمِي بِشَرَرٍ كَالْقَصْرِ (32) Dajudaju (Ina naa) yoo maa ju etapara (re soke t’o maa da) bi peteesi
 | 
| كَأَنَّهُ جِمَالَتٌ صُفْرٌ (33) (O maa da) bi awon rakunmi alawo omi osan
 | 
| وَيْلٌ يَوْمَئِذٍ لِّلْمُكَذِّبِينَ (34) Egbe ni ni ojo yen fun awon olupe-ododo-niro
 | 
| هَٰذَا يَوْمُ لَا يَنطِقُونَ (35) Eyi ni ojo ti won ko nii soro
 | 
| وَلَا يُؤْذَنُ لَهُمْ فَيَعْتَذِرُونَ (36) A o si nii yonda (oro siso) fun won, ambosibosi pe won yoo mu awawi wa
 | 
| وَيْلٌ يَوْمَئِذٍ لِّلْمُكَذِّبِينَ (37) Egbe ni ni ojo yen fun awon olupe-ododo-niro
 | 
| هَٰذَا يَوْمُ الْفَصْلِ ۖ جَمَعْنَاكُمْ وَالْأَوَّلِينَ (38) Eyi ni ojo ipinya. Awa yo si ko eyin ati awon eni akoko jo
 | 
| فَإِن كَانَ لَكُمْ كَيْدٌ فَكِيدُونِ (39) Ti e ba ni ete kan lowo, e dete si Mi wo
 | 
| وَيْلٌ يَوْمَئِذٍ لِّلْمُكَذِّبِينَ (40) Egbe ni ni ojo yen fun awon olupe-ododo-niro
 | 
| إِنَّ الْمُتَّقِينَ فِي ظِلَالٍ وَعُيُونٍ (41) Dajudaju awon oluberu Allahu yoo wa nibi iboji ati awon omi iseleru
 | 
| وَفَوَاكِهَ مِمَّا يَشْتَهُونَ (42) ati awon eso eyi ti won ba n fe
 | 
| كُلُوا وَاشْرَبُوا هَنِيئًا بِمَا كُنتُمْ تَعْمَلُونَ (43) E je, ki e si mu pelu igbadun nitori ohun ti e n se nise
 | 
| إِنَّا كَذَٰلِكَ نَجْزِي الْمُحْسِنِينَ (44) Dajudaju bayen ni Awa se n san awon oluse-rere ni esan (rere)
 | 
| وَيْلٌ يَوْمَئِذٍ لِّلْمُكَذِّبِينَ (45) Egbe ni ni ojo yen fun awon olupe-ododo-niro
 | 
| كُلُوا وَتَمَتَّعُوا قَلِيلًا إِنَّكُم مُّجْرِمُونَ (46) E je, ki e si gbadun fun igba die. Dajudaju elese ni yin
 | 
| وَيْلٌ يَوْمَئِذٍ لِّلْمُكَذِّبِينَ (47) Egbe ni ni ojo yen fun awon olupe-ododo-niro
 | 
| وَإِذَا قِيلَ لَهُمُ ارْكَعُوا لَا يَرْكَعُونَ (48) Nigba ti won ba so fun won pe ki won kirun, won ko nii kirun
 | 
| وَيْلٌ يَوْمَئِذٍ لِّلْمُكَذِّبِينَ (49) Egbe ni ni ojo yen fun awon olupe-ododo-niro
 | 
| فَبِأَيِّ حَدِيثٍ بَعْدَهُ يُؤْمِنُونَ (50) Nigba naa, oro wo ni won yoo gbagbo leyin re
 |